ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 10/8 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ọmọdé Tó Ń Di Ìyá Ọmọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọmọdé Tó Ń Di Ìyá Ọmọ
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oyún Ọ̀dọ́langba Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2004
  • Bí Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Di Ìyá Ọmọ Ṣe Lè Kojú Àwọn Ìṣòro Wọn
    Jí!—2004
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Ká sì Dáàbò Bò Wọ́n
    Jí!—2004
  • Abiyamọ Kú Ọrọ̀ Ọmọ!
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 10/8 ojú ìwé 3

Àwọn Ọmọdé Tó Ń Di Ìyá Ọmọ

“Ọ̀rẹ́kùnrin mi ti lọ wà jù. Ó lówó, a sì jọ máa ń gbéra wa káàkiri láti lọ gbádùn ẹ̀mí wa. Nígbà tí mi ò rí nǹkan oṣù mi, mo mọ̀ pé mo ti lóyún nìyẹn. Báwo ni màá ṣe sọ fún màámi o? Báwo ni mo ṣe fẹ́ ṣe irú eléyìí sí báyìí? Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré ni mí, mi ò sì mọ ohun tí ǹ bá ṣe.”—Nicole.

BÁ A ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, Nicolea ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún dáadáa, ó ti bímọ mẹ́ta, ara ẹ̀ dá ṣáṣá, ó sì ti mọ̀rọ̀ ara ẹ̀ bójú tó. Àkọ́bí ẹ̀ ti pé ọmọ ogún ọdún. Síbẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó wà lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n lóyún láìtíì wọlé ọkọ. Bíi tàwọn ọ̀dọ́langba míì tí wọ́n di ìyá ọmọ, ńṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú u bó ti ń kojú àwọn ìṣòro tó dà bíi pé ó ju agbára rẹ̀ lọ àtàwọn ìpinnu líle koko, tó sì ń ìbẹ̀rù nítorí àìmọ ibi tọ́rọ̀ ara ẹ̀ máa já sí.

Nicole kì í sábàá sọ̀rọ̀ nípa ìpayà, àrúnmọ́ra, ìbẹ̀rù, ìbínú àti àìnírètí tó bá a fínra nígbà tó ń pé ogún ọdún lọ, àkókò tó jẹ́ pé aṣọ àti máàkì ilé ẹ̀kọ́ nìkan ló jẹ àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀ lógún. Àmọ́ ṣá o, bíbà ló bà kò tíì bàjẹ́ fún Nicole. Látinú ìdílé tí ìfẹ́ ti jọba táwọn òbí sì ti ń sapá láti fi ìlànà ìwà rere gíga kọ́ ọ ló ti wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ fìgbà kan kọtí ikún sáwọn ìlànà wọ̀nyẹn, tó sì jẹyán ẹ̀ níṣu, nígbà tó ṣe, àwọn ìlànà kan náà yẹn ló tẹ̀ lé débi tó fi wá ń gbé ìgbésí ayé tó níláárí tó sì nítumọ̀. Ìyẹn ló fà á tí ọ̀rọ̀ náà, “Bá ò kú ìṣe ò tán” fi wá di àkọmọ̀nà rẹ̀.

Ó ṣeni láàánú pé kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́langba tó di ìyá ọmọ ló wá látinú ìdílé tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, gbogbo wọn kọ́ ló sì ń lérò pé nǹkan ń bọ̀ wá dára. Kì í pẹ́ tí ọ̀pọ̀ fi máa ń rí i pé inú òṣì robo làwọn há sí. Àwọn kan sì wà tí àròkàn ń mú kí wọ́n sun ẹkún àsun-ùn-dá nítorí pé wọ́n fipá bá wọn lò pọ̀ àti nítorí pé wọ́n ń hùwà ipá sí wọn.

Àwọn ìṣòro báwọ̀nyí kì í jẹ́ kí ọ̀dọ́langba tó di ìyá lè tọ́jú ọmọ lọ́nà tó yàn, tó yanjú. Ìwé Teen Moms—The Pain and the Promise, sọ nípa ọmọ táwọn ìyá tó jẹ́ ọ̀dọ́langba bá bí pé “ó dà bí ẹni pé wọ́n máa ń rí rodoríndín bí wọ́n bá bí wọn tán, wọ́n máa ń ṣàìsàn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, àwọn ló sábà máa ń kú ní rèwerèwe, wọ́n kì í rí ìtọ́jú ìṣègùn tó péye gbà, ebi máa ń pa wọ́n gan-an, wọn kì í sì í róúnjẹ tó dáa tó jẹ; wọ́n tètè máa ń hùwà ipá sí wọn, wọ́n sì máa ń rán ju àwọn ọmọ tí àwọn ìyá tó bí wọn dàgbà.” Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọbìnrin tí ọ̀dọ́langba bí náà di ìyá nígbà tí wọ́n bá ṣì wà ní ọ̀dọ́langba, èyí tí kì í sábà ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ tí ìyá tó dàgbà bí.

Báwo ni ọ̀ràn oyún ọ̀dọ́langba ṣe gbilẹ̀ tó? Báwo làwọn ọ̀dọ́langba tó ti di ìyá ṣe lè kógo já nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà? Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà tá a lè gbà ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa kó sínú irú ìjàngbọ̀n bẹ́ẹ̀ rárá? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò bá wa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ díẹ̀ padà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́