Oyún Ọ̀dọ́langba Ìṣòro Tó Kárí Ayé
ÀWỌN èèyàn ti gbà kárí ayé pé oyún àwọn ọ̀dọ́langba ti di ìṣòro. Àmọ́ o, ìgbà tá a bá wo ipa tí oyún ní lórí ọmọbìnrin kékeré kan tí jìnnìjìnnì dà bò, la tó lè mọ bí ìṣòro tó wà níbẹ̀ ṣe lágbára tó. Ó kéré pin, àwọn ìyípadà pípabanbarì á wáyé nínú ìgbésí ayé ẹ̀. Àwọn ìyípadà náà á nípa tó pọ̀ lórí òun alára, tó fi mọ́ ará àtọ̀rẹ́ ẹ̀.
Àwọn ọ̀dọ́langba wà ní àkókò tí Bíbélì pè ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ìyẹn àkókò tí òòfà takọtabo máa ń lágbára jù lọ. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Síbẹ̀, kíkóyán ọ̀rọ̀ kéré ló máa jẹ́ bá a bá wulẹ̀ ń ronú pé àìlo oògùn málòóyún ló ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́langba lóyún. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé báa bá ń sọ̀rọ̀ nípa oyún àwọn ọ̀dọ́langba àtàwọn nǹkan tó ń fà á, ohun tó ń bẹ lẹ́yìn ọ̀fà ju òje lọ.
Àwọn Ohun Tó Ń Fà Á
Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n ti di ìyá ọmọ ló wá látinú ìdílé tó ti dà rú. Igbe kan náà tí gbogbo àwọn ọ̀dọ́langba tó lóyún ń fi bọnu ni pé: “Ohun tí mò ń fẹ́ láyé mi ni pé kí n ṣáà ti wà nínú ìdílé tí nǹkan ti ń lọ déédéé.” Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé, ìdílé ráuràu lè jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń fà á táwọn ọ̀dọ́langba fi ń gboyún. Ètò délé-dóko kan tí wọ́n fi ń ran àwọn ọ̀dọ́langba tó ti di ìyá lọ́wọ́ ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé “kì í sí àjọṣe tó fìdí múlẹ̀ láàárín àwọn àti màmá wọn, ìná àwọn àti bàbá wọn kì í sì í wọ̀ rárá.” Anita, tó di ìyá ọmọ lẹ́ni ọdún méjìdínlógún, rántí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyá òun tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ kó bàa lè pèsè fóun nípa tara, síbẹ̀, Anita ò jẹ́ gbàgbé àárò tó máa ń sọ ọ́ nítorí àìsí bàbá rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn.
Ìfipábánilòpọ̀ ló máa ń sọ àwọn ọmọbìnrin mìíràn di ìyá ọmọ láìtíì wọlé ọkọ. Ó lè jẹ́ pé irú ìfipábánilòpọ̀ bẹ́ẹ̀ ló máa ń dọ́gbẹ́ sí àwọn kan lára wọn lọ́kàn, tí ìyẹn á sì wá mú kí wọ́n máa ṣe bí ẹni tó ti gbékú tà nígbà tó bá yá. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni Jasmine nígbà tí wọ́n fipá bá a lòpọ̀. Ó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Mi ò kọ ohunkóhun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀ sí mi. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, mo lóyún.” Bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe tún lè mú kí wọ́n máa wo ara wọn bí aláìjámọ́ nǹkan kan. Jasmine kédàárò pé: “Mi ò ronú ẹ̀ rí láé pé màá tún wúlò fún ohunkóhun.” Bí ọ̀rọ̀ ti Anita náà ṣe rí nìyẹn, ó sọ pé: “Láàárín ìgbà tí mo fi wà lọ́mọ ọdún méje sí mọ́kànlá, ọ̀dọ́langba kan bá mi ṣe ìṣekúṣe. Mo kórìíra ara mi. Ńṣe ni mò ń dá ara mi lẹ́bi.” Ó lóyún nígbà tó di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.
Àwọn ọ̀dọ́langba kan sì wà tó jẹ́ pé dídá tí wọ́n dá ara wọn lójú àti ojúmìító tára wọn gan-an ló kó bá wọn. Nicole, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, sọ pé: “Mo rò pé mo mọwá mẹ̀yìn gbogbo ọ̀rọ̀ ni, pé kò sí ohun tó kọjá agbára mi. Nígbà tí màá sì wá para mi láyò, mo ti wá rí i nísinsìnyí pé mi ò kọjá ẹni tó lè bímọ.” Ńṣe ni Carol, tóun náà ti ìgbà kékeré di ìyá ọmọ láìtíì dẹni ilé ọkọ, ní kóun náà dán bó ti máa ń rí wò. Ó sọ pé, “ó ń ṣe mí bíi pé adùn kan wà tí mo fi ń du ara mi.”
Mímọ̀ táwọn ọ̀dọ́langba ò mọ ibi tí ìbálòpọ̀ máa já sí náà ní ipa tó ń kó nínú bí wọ́n ṣe ń gboyún. Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Karen Rowlingson àti Stephen McKay ṣe sọ, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn ọ̀dọ́ kan “ò ní ìmọ̀ pípéye nípa . . . ohun tó lè tìdí kí ọkùnrin àti obìnrin máa ṣe wọlé wọ̀de wá àti ohun tó túmọ̀ sí láti lóyún.” Ó dà bí ẹni pé àwọn ọ̀dọ́ kan ò fi bẹ́ẹ̀ lóye pé ìbálòpọ̀ ló ń di oyún. Nínú ìwádìí kan, àwọn ọ̀dọ́langba tó di ìyá “sábà máa ń ròyìn pé ó bá àwọn lójijì ó sì ṣe àwọn ní kàyéfì pé àwọn lóyún bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ò lo oògùn málòóyún.”
Àmọ́ o, ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìbálòpọ̀ ni olórí ohun tó ń fa oyún àwọn ọ̀dọ́langba. À ń gbé ní àkókò tí àwọn èèyàn ti jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-4) Àwọn olùṣèwádìí ará Ọsirélíà, Ailsa Burns àti Cath Scott, sọ pé “láwùjọ, lágbo àwọn ẹlẹ́sìn àti ní ti owó àfiṣèrànwọ́, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ jìyà ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó mọ́.” Nígbà àtijọ́, ojútì gbáà ni pé kéèyàn bímọ láìtíì relé ọkọ, ó fẹ́rẹ̀ máà rí bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí o. Àwọn àgbègbè kan tiẹ̀ wà níbi táwọn ọ̀dọ́langba ti ń wo ọmọ bíbí gẹ́gẹ́ bí àṣeyọrí àrà ọ̀tọ̀ tàbí àmì pé mo-dẹni-àpọ́nlé láwùjọ!
Ìdààmú Ọkàn Tó Máa Ń Tìdí Ẹ̀ Wá
Ibi tí dídi ìyá ọlọ́mọ nígbà ọ̀dọ́langba máa ń pàpà yọrí sí máa ń yàtọ̀ pátápátá sí ohun táwọn èwe lè máa rò lọ́kàn. Gbàrà táwọn ọmọbìnrin bá ti mọ̀ pé àwọn lóyún báyìí, ńṣe làyà wọn á kó sókè. Ọ̀pọ̀ lára wọn tiẹ̀ sọ pé ó bá àwọn lábo, jẹbẹtẹ sì gbọ́mọ lé àwọn lọ́wọ́. Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Nípa Ìrònú, Ìhùwà àti Ọpọlọ Àwọn Ọmọdé àti Tàwọn Ọ̀dọ́langba ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Lára ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni kí wọ́n máa bínú, kí wọ́n máa dá ara wọn lẹ́bi, kí wọ́n sì máa ronú pé kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ríronú pé kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀ léwu ṣá o, nítorí pé ó lè mú kí ọmọbìnrin kan máà fẹ́ láti lọ gba ìtọ́jú tó yẹ lọ́dọ̀ dókítà.
Nígbà tí ìbálòpọ̀ tí Elvenia “gbìdánwò” ẹ̀ já jó o lójú, ó sọ pé, “ẹ̀rù bà mí.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin tó lóyún ò lẹ́ni tí wọ́n lè finú hàn, ó sì lè jẹ́ pé ìtìjú ló pọ̀ jù fún wọn tí wọn ò fi lè sọ pé àwọn ti lóyún. Abájọ nígbà náà tí ọkàn àwọn ọ̀dọ́langba kan tí wọ́n gboyún fi máa ń dá wọn lẹ́bi tí ẹ̀rù sì máa ń bà wọ́n. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́langba tó lóyún tún máa ń ní àárẹ̀ ọkàn tó le gan-an. Jasmine sọ pé: “Ayé ọ̀hún ti ẹ̀ wá sú mi pátápátá, mo rò ó pé bíkú bá yá, ó yá náà nìyẹn o jàre.”a
Ohun yòówù kó jẹ́ ìṣarasíhùwà ọ̀dọ́mọbìnrin kan nígbà tó bá kọ́kọ́ lóyún, bópẹ́bóyá á di dandan pé kó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan nípa ara rẹ̀ àti ọmọ tó bá bí. Báwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe lè fọgbọ́n ṣe irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ ni àpilẹ̀kọ wa tó kàn dá lé lórí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bó o ṣe lè kojú èrò fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni, wo ìtẹ̀jáde Jí! ti November 8, 2001, ojú ìwé 13-22.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Oyún Ọ̀dọ́langba—Bí Ìṣòro Tó Wà Níbẹ̀ Ṣe Pọ̀ Tó
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlàyé nípa bọ́ràn ṣe rí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà la ṣe síbí, ó jẹ́ ká rí díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn ọ̀dọ́langba tó gboyún ń dojú kọ níbi gbogbo lágbàáyé.
● Nínú ọmọbìnrin mẹ́wàá, mẹ́rin ló ń gboyún kí wọ́n tó pé ọmọ ogún ọdún, ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùnlélógójì [900,000] oyún ọ̀dọ́langba lọ́dún.
● Lára ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n ti di ìyá, nǹkan bí ogójì ni ò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún.
● Àwọn ọmọ táwọn òbí tó jẹ́ ọ̀dọ́langba bí ni ìyà máa ń pá lórí tí wọ́n sì máa ń pa tì ju ọmọ táwọn òbí tó ti dàgbà bí lọ.
● Lára àwọn tí wọ́n di ìyá láìtíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, mẹ́rin péré nínú mẹ́wàá ló rójú parí ilé ìwé gíga.
● Bá a bá fi àwọn bàbá táwọn ọ̀dọ́langba ń lóyún fún dá ọgọ́rùn-ún, ìdá ọgọ́rin lára wọn ni kì í fẹ́ wọn sílé gẹ́gẹ́ bí aya.
● Nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọ̀dọ́langba tó di ìyá, tí wọ́n sì ṣègbéyàwó lẹ́yìn tí wọ́n bímọ tán, ìdá ọgbọ̀n péré ni ìgbéyàwó wọn ò tíì tú ká; ó rọrùn gan-an fún ìgbéyàwó àwọn ọ̀dọ́langba láti tètè tú ká ju àwọn ìgbéyàwó tí obìnrin ò ti dín lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.
● Àwọn òbí tó jẹ́ ọ̀dọ́langba sábà máa ń bí ọmọ wọn ní kògbókògbó, wọ́n á sì rí kóńkóló, èyí tó lè fa pé kí wọ́n kú ní rèwerèwe, kí wọ́n fọ́jú, kí wọ́n yadi, kí wọ́n ní ìṣòro àìlèmí dáadáa tó le gan-an, kí wọ́n ya dìndìnrìn, kí wọ́n ní àìsàn ọpọlọ, kí wọ́n ní àrùn tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ lè darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀, kí wọ́n ní àrùn dyslexia, tó máa ń jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti kàwé, kí wọ́n sì máa ṣe wọ́nranwọ̀nran.
[Credit Line]
A mú ìsọfúnni yìí látinú ìwé kékeré náà, Not Just Another Single Issue: Teen Pregnancy Prevention’s Link to Other Critical Social Issues, Ìpolongo Jákèjádò Orílẹ̀-Èdè Láti Dẹ́kun Oyún Ọ̀dọ́langba, February 2002.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Oyún Ọ̀dọ́langba Lágbàáyé
BRAZIL: Ìròyìn tá a rí gbà fi hàn pé “lọ́dún 1998, ẹgbẹ̀rún méjìdínlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin, òjìlénírínwó ó dín kan [698,439] ọmọdébìnrin tí wọn ò tíì pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ló jẹ́ pé àǹfààní Ètò Ìlera tí Orílẹ̀-Èdè Brazil Pèsè Fàwọn Aráàlú ni wọ́n fi bímọ . . . ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ó dín mẹ́tàlélógóje [31,857] lára àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí ni wọ́n jẹ́ ọmọdé tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí mẹ́rìnlá, tí wọ́n sì ti kéré jù láti bímọ.”—Ìwé ìròyìn Folha de S. Paulo, ti August 25, 1999.
ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ: “Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì làwọn ọ̀dọ́langba tó ń di ìyá ọmọ pọ̀ sí jù lọ ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù . . . Àwọn ọ̀dọ́langba tó gboyún nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1997 tó nǹkan bí ẹgbàá márùnlélógójì [90,000]. Nǹkan bí ìdá mẹ́tà nínú márùn-ún (ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta) lára oyún náà ni wọ́n bí, ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún (nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n) lára ọmọ táwọn ọ̀dọ́langba náà bí lọ́dún 1997 ni wọn ò sì bí sílé ọkọ.”—Ìwé Lone Parent Families, tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 2002.
MALAYSIA: “Àwọn ọmọ tí wọn ò bí sílé ọkọ lórílẹ̀-èdè yìí ti ń pọ̀ sí i látọdún 1998, èyí tó pọ̀ nínú àwọn ìyá tó bí wọn ni ò sì tíì pé ogún ọdún.”—Ìwé ìròyìn New Straits Times–Management Times, ti April 1, 2002.
RỌ́ṢÍÀ: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ẹyọ kan lára gbogbo ọmọ mẹ́ta tí wọ́n bí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ́dún tó kọjá, ni wọn ò bí sílé ọkọ. Àkọsílẹ̀ ìṣirò ìjọba fi hàn pé èyí jẹ́ ìlọ́po méjì iye tó jẹ́ lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, kò sì tíì tó iye yìí rí látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ọ̀dọ́langba làwọn tó bí ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọ wọ̀nyẹn.”—Ìwé ìròyìn The Moscow Times, ti November 29, 2001.
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ọ̀dọ́langba tó ń gboyún túbọ̀ ń lọ sílẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, mẹ́rin nínú àwọn ọmọbìnrin mẹ́wàá tó jẹ́ ọ̀dọ́langba ló ń gboyún lẹ́ẹ̀kan, ó kéré tán kí wọ́n tó pé ọmọ ogún ọdún.”—Àpilẹ̀kọ́ kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Whatever Happened to Childhood? The Problem of Teen Pregnancy in the United States, ọdún 1997.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Nígbà táwọn òbí bá fira wọn sílẹ̀, ewu pé káwọn ọ̀dọ́langba lóyún máa ń pọ̀ sí i ni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ó dà bí ẹni pé àwọn ọ̀dọ́ kan ò mọ̀ pé ìbálòpọ̀ ló máa ń doyún
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ipa tí oyún máa ń ní lórí ọmọbìnrin tó lóyún àtàwọn aráalé ẹ̀ kì í ṣe kékeré