ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 5/8 ojú ìwé 13-15
  • Ṣé Kéèyàn Bímọ—La Fi Ń Mọ̀ Pọ́kùnrin Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Kéèyàn Bímọ—La Fi Ń Mọ̀ Pọ́kùnrin Ni?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ń Fa Ìṣòro Tó Ń Ràn Kiri Náà
  • Ojú tí Ọlọ́run Fi Wò Ó
  • “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Bí Ọkùnrin”
  • Àwọn Ìsáǹsá Bàbá Ọmọ—Ṣé Lóòótọ́ Ni Wọ́n Lè Bọ́?
    Jí!—2000
  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
    Jí!—2004
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Mú Kí N Ṣèṣekúṣe?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 5/8 ojú ìwé 13-15

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣé Kéèyàn Bímọ—La Fi Ń Mọ̀ Pọ́kùnrin Ni?

“Mo mọ àwọn [ọ̀dọ́mọkùnrin] mélòó kan tó máa ń sọ pé, ‘Ibí yìí lọmọ obìnrin tí mo bí ń gbé, ibẹ̀ yẹn lọmọ ọkùnrin tí mo bí ń gbé,’ téèyàn bá sì wo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ ọ́, kò jọ pé wọ́n tiẹ̀ bìkítà.”—Harold.

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àwọn obìnrin ọ̀dọ́langba tó ń lóyún lọ́dọọdún ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọmọ tí irú àwọn ìyá bẹ́ẹ̀ ń bí ni wọ́n bí láìṣègbéyàwó. Ó kéré tán, ká tó tún rí ọdún méjì míì, ìkan nínú mẹ́rin lára àwọn ọ̀dọ́langba tó ti di ìyá wọ̀nyí yóò tún bí ọmọ kejì. Ìwé ìròyìn Atlantic Monthly sọ pé: “Bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí bá ń báa lọ bẹ́ẹ̀, a ò ní rí tó ìdajì lára gbogbo ọmọ tí wọ́n ń bí láyé ìsinyìí tó máa gbé ọ̀dọ̀ ìyá àti bàbá wọn dàgbà. Èyí tó sì pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ Amẹ́ríkà ló jẹ́ pé inú ìdílé oníyàá nìkan ni wọ́n ti máa lo díẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn.”

Òótọ́ ni pé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni àwọn ọ̀dọ́langba ti ń lóyún jù táa bá fi wé àwọn orílẹ̀-èdè míì tó ti gòkè àgbà, àmọ́ bíbímọ láìṣègbéyàwó ti wá di ìṣòro kárí ayé. Iye àwọn tó ń bímọ lọ́nà yìí láwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù kan, bíi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Faransé, ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ táa bá fi wéra pẹ̀lú ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀rọ̀ ò yàtọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà àti Gúúsù Amẹ́ríkà o, iye àwọn ọ̀dọ́langba obìnrin tó ń bímọ níbẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Kí ló tiẹ̀ ń fa ìṣòro tó ń ràn káàkiri yìí?

Ohun Tó Ń Fa Ìṣòro Tó Ń Ràn Kiri Náà

Lọ́nà tó gbòòrò, ohun tó ń fa ìṣòro yìí ni ìwà rere tó ń forí ṣánpọ́n ní “àkókò lílekoko” tí à ń gbe yìí. (2Tímótì 3:1-5) Ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ iye ìkọ̀sílẹ̀ ti ròkè lálá. Ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ àti oríṣi ọ̀nà ìgbésí mìíràn bẹ́ẹ̀ ti wá gbòde kan. Àwọn ọ̀dọ́ ni àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde wá dójú sọ, tí wọ́n ń lò wọ́n láti gbé ọ̀pọ̀ nǹkan jáde, irú bíi orin àti fídíò tí ń múni ro ìròkurò, àwọn àpilẹ̀kọ àti àwọn ìpolówó ọjà bíburú jáì nínú ìwé ìròyìn, àwọn sinimá àti eré orí tẹlifíṣọ̀n tó ń gbé níní ìbálòpọ̀ bí ẹranko lárugẹ. Bí iṣẹ́ ṣẹ́yúnṣẹ́yún àti àwọn oògùn ìfètòsọ́mọbíbí ṣe wá di èyí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí ti túbọ̀ dá kún èrò àwọn ọ̀dọ́ pé kò sí nǹkan kan tó máa tẹ̀yìn ìbálòpọ̀ jáde. Bàbá kan tí kò ṣègbéyàwó sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ ní ìbálòpọ̀ ṣùgbọ́n mi ò fẹ́ ẹrù iṣẹ́ tó ń tìdí ẹ̀ yọ.” Òmíràn sọ pé: “Ìgbádùn àti eré àṣedárayá ni ìbálòpọ̀ jẹ́.”

Irú ìṣarasíhùwà báyìí lè wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́. Elijah Anderson, tó jẹ́ olùwádìí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ̀ tó ń gbé níbi tí àwọn tálákà pọ̀ sí jù láàárín ìlú lẹ́nu wò, ó sì sọ pé: “Lójú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ìbálòpọ̀ jẹ́ àmì pàtàkì táa fi máa ń dá ẹni tó gbayì mọ̀ láwùjọ; bóo bá sì ṣe lè bá obìnrin sùn tó ló ṣe máa gbayì tó.” Àní, bàbá kan tí kò ṣègbéyàwó sọ fún Jí! pé bí ìgbà téèyàn gba “àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n ń gbé kọ́ sára ògiri” lojú tí wọ́n fi máa ń wo ẹni tó bá bá obìnrin sùn. Kí ló ń fa irú ìṣarasíhùwà aláìgbatẹnirò bẹ́ẹ̀? Anderson ṣàlàyé pé lọ́pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ pe àwọn ènìyàn tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé ọ̀dọ́ kan tó ń gbé níbi tí àwọn tálákà pọ̀ sí láàárín ìlú ni “àwọn tó jẹ́ ojúgbà ẹ̀. Àwọn ló ń lànà bó ṣe máa hùwà, nǹkan pàtàkì ló sì jẹ́ lójú ẹ̀ tó bá lè gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà yẹn.”

Nípa báyìí, Anderson sọ pé lójú ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin, eré ìdárayá lásán ni bíbá obìnrin sùn jẹ́, “ète rẹ̀ ò sì ju pé kí wọ́n lè mú ẹni tibí lómùgọ̀, ní pàtàkì ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n bá sùn.” Ó fi kún un pé “ohun tí eré àṣedárayá yìí ní nínú ò ju pé kí ọ̀dọ́kùnrin mọ bóun ṣe lè fi hàn pé òun ò kẹ̀rẹ̀ rárá, ìyẹn kan irú aṣọ tó wọ̀, ìmúra ẹ̀, ìrísí ẹ̀, bó ṣe mọ̀ ọ́n jó tó, àti bó ṣe lè jíròrò tó.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdékùnrin ni ò kẹ̀rẹ̀ tó bá di ká borí nínú eré “àṣedárayá” yìí. Ṣùgbọ́n Anderson sọ pé: “Bí ọmọdébìnrin náà bá wá lóyún, ṣe ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà á fẹ́ yẹra lọ́dọ̀ ẹ̀.”—Young Unwed Fathers—Changing Roles and Emerging Policies, láti ọwọ́ Robert Lerman àti Theodora Ooms.

Ojú tí Ọlọ́run Fi Wò Ó

Ṣé òótọ́ ni pé kéèyàn bímọ la fi ń mọ̀ pọ́kùnrin ni? Ìbálòpọ̀ ha wulẹ̀ jẹ́ eré àṣedárayá lásán bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ ló rí lójú Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, Ọlọ́run mú un ṣe kedere pé ìbálòpọ̀ ní ète tó ga lọ́lá. Lẹ́yìn ti Bíbélì ti sọ nípa ìṣẹ̀dá ọkùnrin àti obìnrin kìíní, ó ní: “Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.’” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ọlọ́run kò ní in lọ́kàn nígbà kankan rí pé kí àwọn bàbá pa àwọn ọmọ wọn tì. Ó so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀ nínú ìdè ìgbéyàwó kan tó wà pẹ́ títí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Nítorí náà, ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kí olúkúlùkù ọmọ ní bàbá kan àti ìyá kan.

Kò pẹ́ kò jìnnà, làwọn ènìyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ju aya kan lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 4:19) Jẹ́nẹ́sísì 6:2 sọ fún wa pé àwọn ẹ̀dá áńgẹ́lì kan tiẹ̀ “bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé ara ènìyàn wọ̀, àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí “sì ń mú aya fún ara wọn,” wọ́n fi ìwọra mú “gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” Ìkún omi ọjọ́ Nóà ló fi ipá lé àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyí padà sí ilẹ̀-àkóso ẹ̀mí. Bí ó ti wù kó rí, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé sàkáání ilẹ̀ ayé ni wọ́n wà nísinsìnyí. (Ìṣípayá 12:9-12) Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń tipa báyìí lo ipa tó lágbára lórí àwọn ènìyàn lónìí. (Éfésù 2:2) Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin bá sì ń di bàbá àwọn ọmọ tí wọn ò fẹ́ bí, tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́, ṣe ni wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ jọ̀wọ́ ara wọn fún agbára ìdarí búburú yẹn láìmọ̀.

Nígbà náà, Ìwé Mímọ́ ní ìdí rere tó fi sọ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, sísọ yín di mímọ́, pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè; pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo irúfẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì pẹ̀lú tí kò mọ Ọlọ́run ní; pé kí ẹnì kankan má ṣe lọ títí dé àyè ṣíṣe ìpalára fún àti rírakakalé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí, nítorí Jèhófà ni ẹni tí ń fi ìyà jẹni ní dandan fún gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tẹsalóníkà 4:3-6.

“Ta kété sí àgbèrè” kẹ̀? Yẹ̀yẹ́ lọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin máa fi ọ̀rọ̀ yìí ṣe. Ó ṣe tán, ara wọ́n ṣì jí pépé, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́-ọkàn wọn ṣì lágbára! Ṣùgbọ́n kíyè sí i pé àgbèrè ní nínú ‘ṣíṣe ìpalára fún’ àwọn ẹlòmíràn ‘àti rírakakalé ẹ̀tọ́’ wọn. Ṣé kò ní pa ọmọdébìnrin kan lára táa bá fi í sílẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ọwọ́ kan láìsí ìtìlẹ́yìn ọkọ kankan? Kí ni ká tún sọ nípa ti ewu pé ó lè kó àrùn ìbálòpọ̀, àwọn bí àrùn abẹ́ tó ń jẹ́ herpes, àrùn rẹ́kórẹ́kó, àtọ̀sí, tàbí àrùn éèdì? Òótọ́ ni pé ó lè ṣeé ṣe nígbà míì kéèyàn mú àwọn àbájáde wọ̀nyí jẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ṣì rakaka lé ẹ̀tọ́ ọmọdébìnrin kan láti pa orúkọ rere ẹ̀ mọ́, kó sì wọ inú ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí wúńdíá. Títakété sí àgbèrè, nígbà náà, mú ọgbọ́n dání, ó sì fi ìdàgbàdénú hàn. Òótọ́ ni pé, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìpinnu ló ń béèrè láti ‘ṣèkáwọ́ ohun èlò ẹni’ ká sì ta kété sí ìbálòpọ̀ ká tó ṣègbéyàwó. Àmọ́ o, Aísáyà 48:17, 18 sọ fún wa pé, ṣe ni Ọlọ́run ń ‘kọ́ wa kí á lè ṣe ara wa láǹfààní’ nípasẹ̀ àwọn òfin rẹ̀.

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Bí Ọkùnrin”

Nígbà náà, báwo ni ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe lè fi hàn pé òún jẹ́ ọkùnrin ni ti gidi? Dájúdájú, kò dìgbà tó bá bímọ síta. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ wà lójúfò, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa bá a nìṣó bí ọkùnrin, ẹ di alágbára ńlá. Kí gbogbo àlámọ̀rí yín máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.”—1Kọ́ríńtì 16:13, 14.

Ṣàkíyèsí pé ‘bíbá a nìṣó bí ọkùnrin’ ní nínú wíwà lójúfò, dídúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, jíjẹ́ onígboyà, àti lílo ìfẹ́. Gbogbo wa la gbà pé, tọkùnrin tobìnrin ni ìlànà yìí kàn láìdá ẹnì kan sí. Ṣùgbọ́n bí ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan bá mú àwọn ànímọ́ tẹ̀mí bíi irú ìwọ̀nyí dàgbà, àwọn ènìyàn yóò ní ìdí rere láti bọ̀wọ̀ fún ọ, wọ́n á sì máa pọ́n ẹ lé pé ọkùnrin gidi ni ẹ́! Kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù Kristi—ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. Ìwọ tiẹ̀ ro ìhùwàsí rẹ̀ bí ọkùnrin akin àti onígboyà nígbà tó dojú kọ ìdálóró àti ikú pàápàá. Ṣùgbọ́n báwo ni Jésù ṣe hùwà sí àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà kejì?

Dájúdájú Jésù ní àǹfààní láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn obìnrin. Ó ní ọ̀pọ̀ ọmọlẹ́yìn tó jẹ́ obìnrin, díẹ̀ lára wọn sì “ń ṣèránṣẹ́ fún [òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀] láti inú àwọn nǹkan ìní wọn.” (Lúùkù 8:3) Òun ní pàtàkì jù lọ tiẹ̀ tún sún mọ́ àwọn arábìnrin Lásárù méjèèjì. Àní Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀.” (Jòhánù 11:5) Ǹjẹ́ Jésù lo òye tó ní, ànímọ́ fífanimọ́ra rẹ̀, tàbí ìrísí rẹ̀ fífani mọ́ra, láti fi tan àwọn obìnrin wọ̀nyí sínú ìwà pálapàla, níwọ̀n bí kò ti sí àní-àní pé gbogbo ìwọ̀nyí la bí mọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin pípé kan? Ká má ri, Bíbélì sọ pé Jésù “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:22) Kò hùwà lọ́nà àìtọ́ rárá, kódà nígbà tí obìnrin kan báyìí tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀, tó jọ pé aṣẹ́wó ni pàápàá, bẹ̀rẹ̀ sí ‘sunkún, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, tó sì ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò.’ (Lúùkù 7:37, 38) Jésù ò tiẹ̀ ronú pé kóun jìfà lára obìnrin yìí! Ṣe ló fi agbára tó ní láti ṣàkóso ìmọ̀lára rẹ̀ hàn gbangba—ìyẹn ni àmì táa fi ń mọ ọkùnrin gidi. Kò hùwà sí àwọn obìnrin bí ẹni pé nǹkan èlò fún ìbálòpọ̀ ni wọ́n, ṣùgbọ́n ó hùwà sí wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn tó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ká sì bọ̀wọ̀ fún.

Bí ìwọ bá jẹ́ Kristẹni ọkùnrin ọ̀dọ́ kan, tí o ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi tí o kò sì tẹ̀ lé ti àwọn ojúgbà rẹ kan—ìyẹn kò ní jẹ́ kí o ‘ṣe ìpalára tàbí kí o rakaka lé àwọn ẹ̀tọ́’ ẹlòmíì. Á tún yọ ẹ́ kúrò nínú wàhálà tó ń bá bíbímọ síta rìn. Òótọ́ ni pé, àwọn kan lè máa fi ọ́ rẹ́rìn-ín nítorí pé o ta kété sí àgbèrè. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, jíjèrè ojú rere Ọlọ́run á ṣe ẹ́ láǹfààní ju jíjèrè ìtẹ́wọ́gbà àwọn ojúgbà rẹ fún ìgbà díẹ̀ lọ.—Òwe 27:11.

Tó bá wá jẹ́ pé ọ̀dọ́ kan ti gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla nígbà kan rí ńkọ́, ṣùgbọ́n tó ti wá yí padà kúrò nínú ìwà pálapàla ẹ̀, tó sì ronú pìwà dà ní tòótọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọba Dáfídì, tóun náà ní ìbálòpọ̀ oníwà pálapàla, ó lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run á dárí ji òun. (2 Sámúẹ́lì 11:2-5; 12:13; Sáàmù 51:1, 2) Ṣùgbọ́n tóyún bá ti lọ wáyé láìṣègbéyàwó, ọ̀dọ́kùnrin kan lè ní àwọn ìpinnu wíwúwo díẹ̀ láti ṣe. Ṣé kó fẹ́ ọmọdébìnrin yẹn ni? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ní ojúṣe èyíkéyìí tó gbọ́dọ̀ ṣe fún ọmọ rẹ̀? Àpilẹ̀kọ kan lọ́jọ́ iwájú yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àṣìṣe ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó gbà gbọ́ pé kò sí nǹkan kan tó máa tẹ̀yìn ìbálòpọ̀ jáde ń ṣe o

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́