ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 8/8 ojú ìwé 14-16
  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Nǹkan Tó Ń Jẹ́ Àgbèrè
  • Àwọn Ewu Tó Lè Tìdí Ẹ̀ Wá
  • Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
  • Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ṣé Ìbálòpọ̀ Máa Jẹ́ Ká Túbọ̀ Fẹ́ràn Ara Wa?
    Jí!—2010
  • Ṣé Ìbálòpọ̀ Máa Jẹ́ Ká Túbọ̀ Fẹ́ràn Ara Wa?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 8/8 ojú ìwé 14-16

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?

“Mo máa ń rò ó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé bóyá ni ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó fi burú tó bẹ́ẹ̀, pàápàá jù lọ nígbà tí jíjẹ́ tí mo ṣì jẹ́ wúńdíá bá ń ṣe mí bákan.”—Jordon.a

Kelly sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n dán ìbálòpọ̀ wò. Èmi rò pé gbogbo wa ló máa ń wù láti ní ìbálòpọ̀.” Ó tún fi kún un pé: “Ibi yòówù kó o dé, orí ìbálòpọ̀ lọ̀rọ̀ wọn ń dá lé!”

ṢÉ KÌ í ṣe ìwọ náà bó ṣe máa ń ṣe Jordon àti Kelly? Ó ṣe tán, ṣebí àwọn àṣà àti ìlànà àtijọ́ tó ka ìbálòpọ̀ láìgbéyàwó léèwọ̀ ti dọ̀rọ̀ ìtàn. (Hébérù 13:4) Ìwádìí tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè kan tó wà nílẹ̀ Éṣíà fi hàn pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọkùnrin tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógún ló fara mọ́ ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, wọ́n sì tún gbà pé ohun tó yẹ káwọn máa ṣe ni. Abájọ tó fi jẹ́ pé káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́ ló ti ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.

Àwọn ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ wà tí wọn ò fẹ́ ní ìbálòpọ̀ tààràtà ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n láwọn fi ń dá a bí ọgbọ́n, irú bíi káwọn àti ẹlòmíràn máa jùmọ̀ fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara wọn (èyí tí wọ́n máa ń pè ní jíjùmọ̀ mú ara ẹni gbóná nígbà míì). Ìròyìn kan tó ń kọni lóminú tó jáde nínú ìwé ìròyìn The New York Times fi hàn pé “ìbálòpọ̀ àtẹnuṣe lọ̀pọ̀ sábà máa ń fi bẹ̀rẹ̀ ìbálòpọ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló gbà pé kò la ìbára-ẹni-sùn lọ, kò sì fi bẹ́ẹ̀ léwu nínú bí ìbálòpọ̀ tààràtà . . . ọ̀nà tó dáa [sì] ni láti má ṣe gboyún, kí wọ́n má sì já ìbálé ẹni.”

Irú ojú wo ló tiẹ̀ yẹ kí Kristẹni máa fi wo ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó? Àwọn èyí tí wọ́n ń pè ní dídá a bí ọgbọ́n ńkọ́, ìyẹn ìbálòpọ̀ tí ò ṣe tààràtà? Ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí wọn? Ṣé kò léwu nínú lóòótọ́? Ṣé lóòótọ́ ló sì máa jẹ́ kéèyàn wà ní wúńdíá?

Àwọn Nǹkan Tó Ń Jẹ́ Àgbèrè

Ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la ti lè rí ìdáhùn tí ò ṣeé já ní koro sí àwọn ìbéèrè yìí. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì sọ fún wa pé ká “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Kí nìyẹn túmọ̀ sí gan-an ná? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí wọ́n túmọ̀ sí “àgbèrè” kò mọ sórí ìbálòpọ̀ nìkan àmọ́ ó ní nínú oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣèṣekúṣe. Nítorí náà, bí àwọn méjì tí wọn kì í ṣe tọkọtaya bá lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ àtẹnuṣe, tàbí fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara wọn, wọ́n jẹ̀bi àgbèrè.

Ṣùgbọ́n ṣé wúńdíá ṣì ni wọ́n ṣá, lójú Ọlọ́run là ń sọ o? Nínú Bíbélì, àpẹẹrẹ ìwà mímọ́ tónítóní ni wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “wúńdíá” fún. (2 Kọ́ríńtì 11:2-6) Ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń lò ó fún ẹni tí kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Rèbékà. Bíbélì sọ pé “wúńdíá ni, kò sì sí ọkùnrin kankan tí ó tíì ní ìbádàpọ̀ takọtabo pẹ̀lú rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 24:16) Ó dùn mọ́ni pé, ẹ̀rí wà pé ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà tí wọ́n ń lò fún “ìbádàpọ̀” túmọ̀ sí àwọn nǹkan míì tó lè wáyé yàtọ̀ sí ìbálòpọ̀ tààràtà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. (Jẹ́nẹ́sísì 19:5) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, bí ọ̀dọ̀ kan bá lọ́wọ́ nínú irú àgbèrè èyíkéyìí, a ò lè pè é ní wúńdíá mọ́.

Àgbèrè nìkan kọ́ ni Bíbélì rọ àwọn Kristẹni láti sá fún, ó tún ní kí wọ́n sá fún gbogbo onírúurú ìwà àìmọ́ tó lè yọrí sí àgbèrè.b (Kólósè 3:5) Àwọn ẹlòmíì lè máa fi ẹ ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé o kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ẹ̀. Kristẹni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Kelly sọ pé: “Wọ́n máa ń sọ fún mi ní gbogbo ìgbà tí mo wà nílé ìwé gíga pé, ‘o ò mọ bí ìgbádùn tó ò ń pàdánù ṣe pọ̀ tó!’” Àmọ́, kò sí ìgbádùn kankan nínú ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó ju “jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀” lọ. (Hébérù 11:25) Ó lè dá ìṣòro sínú àgọ́ ara wa, ó lè kó ọgbẹ́ ọkàn bá wa, ó sì lè tì wá sínú ìṣòro tẹ̀mí.

Àwọn Ewu Tó Lè Tìdí Ẹ̀ Wá

Bíbélì sọ fún wa pé nígbà kan rí, Ọba Sólómọ́nì ṣàkíyèsí ọ̀dọ́kùnrin kan tẹ́nì kan tàn débi tó fi lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó. Sólómọ́nì fi ọ̀dọ́kùnrin náà wé “akọ màlúù tí ń bọ̀ . . . fún ìfikúpa.” Màlúù tí wọ́n bá fẹ́ pa kì í sábà mọ ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí òun. Báwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ṣe sábà máa ń hùwà náà nìyẹn, ó dà bíi pé wọn ò mọ̀ pé àtẹ̀yìnbọ̀ nǹkan tí wọ́n ń ṣe ò ní dáa! Sólómọ́nì sọ pé ọ̀dọ́kùnrin yẹn “kò sì mọ̀ pé ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.” (Òwe 7:22, 23) Bẹ́ẹ̀ gan-an ló rí, “ọkàn” rẹ, ìyẹn ẹ̀mí ẹ wà nínú ewu.

Bí àpẹẹrẹ, lọ́dọọdún ni ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn ọ̀dọ́ ń kárùn látinú ìbálòpọ̀. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lydia sọ pé: “Nígbà tí mo rí i pé mo ti kó àrùn ìléròrò ẹ̀yà ìbímọ, mo fẹ́ sá lọ.” Ó kábàámọ̀, ó sọ pé: “Àrùn yìí máa ń fa ìrora fún èèyàn, kì í sì í kúrò lára ẹni tó bá mú.” Èyí tó ju ìlàjì àwọn tí àrùn éèdì ń ràn lágbàáyé (tí wọ́n tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà èèyàn lójúmọ́) ni ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógún.

Àwọn obìnrin ló sábà máa ń forí fá ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń tínú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó wá. Kódà, àwọn obìnrin làwọn èèyàn ń bẹ̀rù pé àrùn tí wọ́n ń kó látinú ìbálòpọ̀ (títí kan àrùn éèdì) lè mú jù. Bí ọmọdébìnrin kan bá gboyún, ó ti fi ara ẹ̀ àti ọmọ inú ẹ̀ sínú ewu. Kí nìdí? Ìdí ni pé ara ọmọdébìnrin kan lè máà tíì gbó débi tá a fi lè rù ú tá á sì sọ̀ ọ́ láyọ̀.

Ká tiẹ̀ sọ pé ọmọbìnrin kan tí ò tíì pé ogún ọdún dí ìyá àbúrò tí ò sì ṣàkóbá fún ìlera ẹ̀ nígbà tó ń bímọ, ojú ẹ̀ á ṣì rí màbo kó tó tọ́ ọmọ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin ló ti yé pé báwọn ṣe rò pé á rọrùn tó láti gbọ́ bùkátà ara àwọn àti ti ọmọ táwọn bá bí kọ́ ló wá rí mọ́ nígbà tí wọ́n bímọ ọ̀hún tán.

Ká tiẹ̀ pa ìyẹn tì, àtẹ̀yìnbọ̀ rẹ̀ kì í sábà nípa tó dáa lórí wọn nípa tẹ̀mí, wọn kì í sì í ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ tí Ọba Dáfídì dá fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ ọ́ di ọ̀tá Ọlọ́run, díẹ̀ ló sì kù kó pa run nípa tẹ̀mí. (Sáàmù 51) Lóòótọ́ Dáfídì kọ́fẹ padà nípa tẹ̀mí o, àmọ́ títí tó fi kú ló ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Àwọn ọ̀dọ́ pẹ̀lú lè jẹ irú ìyà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Cherie wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún ó tẹ́ra ẹ̀ silẹ̀ fún ọmọkùnrin kan. Ó rò pé ọmọkùnrin náà nífẹ̀ẹ́ òun ni. Ọ̀pọ̀ ọdún ló ti kọjá lẹ́yìn ìgbà náà, àmọ́ ó ṣì ń jẹ̀ka àbámọ̀. Ó fìka àbámọ̀ bọnu, ó sọ pé: “Mo fọwọ́ yẹpẹrẹ mú òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, mo sì jẹ̀rán ẹ̀. Mo pàdánù ojú rere Jèhófà, ó mà dùn mí o.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Trish náà gbà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Àṣìṣe tí mo ṣe tó tíì dùn mí jù lọ láyé mi ni ti ìbálòpọ̀ tí mo ní láìtíì ṣègbéyàwó. Ká ló ṣeé ṣe ni kò sí nǹkan tí mi ò ní ṣe kí ń fi lè padà jẹ́ wúńdíá.” Bó ṣe máa ń rí nìyẹn, ọgbẹ́ ọkàn tó máa ń fà máa ń dun èèyàn fọ́dún gbọọrọ, ó sì máa ń fa ìdààmú àti ìrora ọkàn.

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ìkóra-Ẹni-Níjàánu

Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Shanda béèrè ìbéèrè pàtàkì kan, ó ní, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fi ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ nígbà tó mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n ní ìbálòpọ̀ títí di ẹ̀yìn ìgbéyàwó?” Òótọ́ ni pé ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an pàápàá ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe.” (1 Kọ́ríńtì 7:36) Kódà, ara àwọn ọ̀dọ́ míì á kàn máa dédé dìde láìnídìí kankan. Ṣùgbọ́n ìyẹn ò fi hàn pé èèyàn búburú ni wọ́n. Bí ara ṣe máa ń ṣe nìyẹn nígbà téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà, kó tó di pé èèyàn tó ọmọ bí.c

Òótọ́ ni pẹ̀lú pé bí Jèhófà ṣe ṣètò ìbálòpọ̀ ní adùn nínú. Èyí bá ète rẹ̀ láti jẹ́ káwọn èèyàn kún ilẹ̀ ayé mu. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Síbẹ̀, Ọlọ́run ò fìgbà kankan ní in lọ́kàn pé ká máa lo agbára ìbímọ wa nílòkulò. Bíbélì sọ pe: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.” (1 Tẹsalóníkà 4:4) Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tọ́kàn èèyàn bá ń fà sí ìbálòpọ̀ náà lá á fẹ́ máa tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn, lọ́nà kan ṣáá, ńṣe lonítọ̀hún á dà bí òmùgọ̀ tó máa ń lu ẹlòmíràn ní gbogbo ìgbà tí inú bá ń bí i.

Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fáwọn èèyàn ni ìbálòpọ̀, ó sì ní ìgbà tó yẹ kéèyàn jẹ̀gbádùn ẹ̀, ìyẹn ni ìgbà téèyàn bá tó ṣègbéyàwó. Báwo lá ṣe rí lójú Ọlọ́run téèyàn bá ń wá ọ̀nà láti ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó? Ó dáa, jẹ́ ká sọ pé o ra ẹ̀bùn kan fún ọ̀rẹ́ ẹ kan. Kó o tó fi ẹ̀bùn náà lé e lọ́wọ́, ó ti jí i! Ṣé inú ò ní bí ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wo bó ṣe máa rí lójú Ọlọ́run nígbà tẹ́nì kan tí ò tíì ṣègbéyàwó bá ń lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀, tó ń ṣi ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún un lò.

Kí ló yẹ kó o ṣe nípa èrò ìbálòpọ̀ tó máa ń wá sọ́kàn rẹ? Kò sí ṣíṣe, kò sí àìṣe, wà á kọ́ bó o ṣe máa ṣàkóso ẹ̀ náà ni. Máa rán ara ẹ létí pé “Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.” (Sáàmù 84:11) Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Gordon sọ pé: “Nígbà tí mo rí i pé mò ń rò pé ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ò lè fi bẹ́ẹ̀ burú, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí ipa búburú tó máa ní lórí mi nípa tẹ̀mí mo sì rí i pé kò sí bí ẹ̀ṣẹ̀ kan ṣe lè dùn tó tí máà wá tìtorí ẹ̀ pàdánù ojúure Jèhófà.” Láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu lè má rọrùn. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Adrian ṣe rán wa létí, “á jẹ́ kó o lè ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ wà á sì lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wà á lè ráyè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù, láìsí pé ọkàn ẹ ń dà ẹ lẹ́bí lórí àwọn nǹkan tó o ti ṣe sẹ́yìn.”—Sáàmù 16:11.

Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi ṣe pàtàkì pé kó o “ta kété sí àgbèrè” ní gbogbo ọ̀nà tó lè gbà wáyé. (1 Tẹsalóníkà 4:3) A mọ̀ pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà yóò jíròrò bí yóò ti ṣeé ṣe fún ẹ láti “pa ara rẹ mọ́ ní oníwàmímọ́.”—1 Tímótì 5:22.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Tó o bá fẹ́ ka ìjíròrò nípa àgbèrè, ìwà àìmọ́ àti ìwà àìníjàánu, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Dé Àyè Wo Ni ‘Lílọ Jìnnà Jù’?” tó jáde nínu Jí! ìtẹ̀jáde October 22, 1993.

c Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Eeṣe Tí Eyi Fi Ńṣẹlẹ̀ sí Ara Mi?” tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa ti February 8, 1990.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

Bí ọ̀dọ́ kan bá lọ́wọ́ nínú irú àgbèrè èyíkéyìí, ṣé wúńdíá ṣì ni lójú Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Níní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó lè ba ẹ̀rí ọkàn ọ̀dọ́ kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó ń rìn ní règbèrégbè àtikárùn ìbálòpọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́