ORÍ 24
Ṣé Ìbálòpọ̀ Máa Jẹ́ Ká Túbọ̀ Fẹ́ràn Ara Wa?
Kò tíì ju oṣù méjì péré lọ tí Heather àti Mike bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra, àmọ́ lójú Heather, ṣe ló dà bíi pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọra. Ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú ni wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn lórí fóònù, ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n tún máa fi ń bára wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù, ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì wọ̀ gan-an ni! Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ́wọ́ alẹ́ tí òṣùpá lé téńté, ohun tí Mike fẹ́ látọ̀dọ̀ Heather ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ.
Láàárín oṣù méjì tó kọjá, Mike àti Heather ò ṣe ju kí wọ́n kàn di ara wọn lọ́wọ́ mú, kí wọ́n sì fẹnu konu fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lọ. Heather kò fẹ́ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀, kò fẹ́ kí Mike fi òun sílẹ̀. Kò sẹ́ni tó gba tiẹ̀ tó Mike, ńṣe ni Mike máa ń kẹ́ ẹ lójú méjèèjì. Ó tún rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Èmi àti Mike nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an ni . . . ’
Ó ṢEÉ ṢE kó o ti máa ro ibi tí ọ̀rọ̀ Heather àti Mike máa já sí. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o má ronú kan bí ìbálòpọ̀ ṣe máa mú kí nǹkan yí pa dà bìrí láàárín wọn, ó sì dájú pé kì í ṣe àyípadà sí rere. Ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí ná:
Tó o bá rú òfin àbáláyé kan, irú bí òfin òòfà, èyí tó máa ń mú kí gbogbo ohun tó bá lọ sókè pa dà wálẹ̀, ìwọ lo máa jìyà rẹ̀. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ tó o bá rú òfin nípa irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, bí èyí tó sọ pé: “Ẹ ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Kí làwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá rú òfin yìí? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? Gbìyànjú wò bóyá wàá lè kọ ohun búburú mẹ́ta tó lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó.
1 ․․․․․
2 ․․․․․
3 ․․․․․
Ní báyìí, wo àwọn ohun tó o kọ. Ṣé o kọ àrùn téèyàn máa ń kó látinú ìbálòpọ̀, oyún ẹ̀sín àti pípàdánù ojú rere Ọlọ́run? Ó dájú pé àwọn ohun búburú yìí lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tó bá rú òfin Ọlọ́run nípa àgbèrè.
Síbẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o lọ́wọ́ nínú rẹ̀. O lè máa ronú pé, ‘kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi.’ Kó o máa rò ó pé, ṣebí gbogbo èèyàn ṣáà ló ń ní ìbálòpọ̀. Àti pé, àwọn ojúgbà rẹ nílé ìwé kì í fọ̀rọ̀ bò rárá nígbà tí wọ́n bá ń ṣàlàyé báwọn ṣe ń gbádùn ìbálòpọ̀, ó sì dà bíi pé nǹkan kan ò ṣe wọ́n. Bóyá o tiẹ̀ ń ronú bíi ti Heather tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, pé ìbálòpọ̀ á jẹ́ kíwọ àti ẹni tó ò ń fẹ́ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín dáadáa. Kò kúkú sẹ́ni tó máa fẹ́ kí wọ́n máa fòun ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé òun ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Ṣé kò wá ní sàn kéèyàn kúkú ní ìbálòpọ̀?
Ó tì o, tún rò ó wò dáadáa! Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ mọ̀ ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń ṣe é. Òótọ́ ni pé, o lè ti ka ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé àìmọye àwọn ọ̀dọ́ ló ń ní ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, ọ̀dọ́ méjì nínú mẹ́ta lórílẹ̀-èdè yẹn ló ti ń ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó jáde ilé ìwé girama. Àmọ́, ṣe ni èyí náà ń fi hàn pé ọ̀dọ́ kan nínú mẹ́ta ni kò tíì ní ìbálòpọ̀, iye yìí náà sì pọ̀ díẹ̀. Àwọn tó wá ń ní ìbálòpọ̀ ńkọ́? Àwọn olùwádìí kan ti rí i pé, ọ̀pọ̀ irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ẹ̀dùn ọkàn tá a tò sísàlẹ̀ yìí máa ń dà láàmú.
Ẹ̀DÙN ỌKÀN ÀKỌ́KỌ́ ÌDÁLẸ́BI. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó ló sọ pé àwọn kábàámọ̀ rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Ẹ̀DÙN ỌKÀN KEJÌ ÀÌFỌKÀN TÁN ARA ẸNI. Lẹ́yìn tí ọkùnrin àti obìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó bá ti ní ìbálòpọ̀, wọ́n á máa ronú pé, ‘Ta ló mọ ẹlòmíì tó tún ti bá a lò pọ̀?’
Ẹ̀DÙN ỌKÀN KẸTA ÌJÁKULẸ̀. Nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, àwọn ọmọbìnrin sábà máa ń fẹ́ ẹni tó máa tọ́jú wọn, kì í ṣe ẹni tó kàn máa bá wọn sùn tán, tí á sì já wọn jù sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọkùnrin ló jẹ́ pé wọn kì í gba ti ọmọbìnrin kan mọ́ tí wọ́n bá ti lè bá a sùn.
Yàtọ̀ sáwọn ohun tá a sọ yìí, àìmọye àwọn ọmọkùnrin ló máa ń sọ pé àwọn ò lè fẹ́ ọmọbìnrin tí àwọn bá ti bá sùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé, wọ́n máa ń gbà pé irú ọmọbìnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́ oníṣekúṣe!
Tó o bá jẹ́ ọmọbìnrin, ṣé ọ̀rọ̀ yìí yà ẹ́ lẹ́nu? Bóyá ó tiẹ̀ múnú bí ẹ pàápàá. Torí náà, rántí pé: Àwọn ohun tí wọ́n máa ń fi hàn nínú fíìmù àti lórí tẹlifíṣọ̀n nípa ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó yàtọ̀ sí bọ́rọ̀ náà ṣe rí gan-an lóòótọ́. Àwọn tó ń ṣe fíìmù àtàwọn olórin máa ń gbé ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún lárugẹ, wọ́n sì ń mú kó dà bíi pé ìfẹ́ tòótọ́ ni. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́ jẹ o! Ńṣe làwọn tó fẹ́ dọ́gbọ́n tàn ẹ́ kó o lè ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó kàn fẹ́ tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ṣé o rò pé ẹni tó bá fẹ́ràn ẹ lóòótọ́ á ṣe ohun tó máa ṣàkóbá fún ẹ tá a sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ? (Òwe 5:3, 4) Ṣé ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ẹ dénú á tàn ẹ́ láti ṣe ohun tó máa mú kí àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run bà jẹ́?—Hébérù 13:4.
Tó o bá jẹ́ ọmọkùnrin tó o sì ní ọmọbìnrin tó ò ń fẹ́, ó dájú pé ohun tá a jíròrò nínú orí yìí máa jẹ́ kó o ronú jinlẹ̀ nípa ìfẹ́ tó wà láàárín yín. Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo nífẹ̀ẹ́ ẹni tí mò ń fẹ́ yìí dénú lóòótọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tó dára jù wo lo lè gbà fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú lóòótọ́?’ Ṣe ni wàá máa sa gbogbo agbára rẹ láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, wàá jẹ́ ẹni tó ń lo ọgbọ́n débi tí wàá fi máa yẹra fún àwọn ipò tó lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe, wàá sì máa fi hàn pé o ní ìfẹ́ rẹ̀ débi pé o ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa ṣàkóbá fún un. Tó o bá ní àwọn ìwà yìí, tó o sì ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí, inú ọmọbìnrin tó ò ń fẹ́ máa dùn bíi ti ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì tó jẹ́ oníwà rere, tó sọ pé: “Tèmi ni olólùfẹ́ mi, tirẹ̀ sì ni èmi.” (Orin Sólómọ́nì 2:16) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa gbà pé ọkùnrin dáadáa ni ẹ́!
Bóyá ọkùnrin ni ẹ́ o tàbí obìnrin, tó o bá lọ ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, ṣe lo ta ara rẹ lọ́pọ̀, tó o sì sọ nǹkan tó níye lórí gan-an nù. (Róòmù 1:24) Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kó sí pàkúté yìí fi máa ń wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, bíi pé àwọn ti jẹ́ kí ẹnì kan jí ohun pàtàkì kan lọ nínú ara àwọn! Má ṣe jẹ́ kírú èyí ṣẹlẹ̀ sí ẹ! Bí ẹnì kan bá fẹ́ dọ́gbọ́n tàn ẹ́ kẹ́ ẹ lè bá ara yín lò pọ̀, tó ń sọ pé, “Tó o bá nífẹ̀ẹ́ mi, wàá gbà fún mi,” kí ìwọ náà fún un lésì láìyẹhùn pé, “Tí ìwọ náà bá nífẹ̀ẹ́ mi, o ò ní fi lọ̀ mí!”
Máa fi sọ́kàn pé ara rẹ ṣe iyebíye gan-an, kò sì ní dáa kó o ta ara rẹ lọ́pọ̀. Fi hàn pé o lè pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ pé ká sá fún àgbèrè. Tó o bá sì wá ṣègbéyàwó nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wàá lómìnira láti ní ìbálòpọ̀. Wàá sì lè gbádùn ẹ̀ dáadáa, láìsí ìdààmú, àbámọ̀ tàbí àìbalẹ̀ ọkàn tí àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń ní.—Òwe 7:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 7:3.
KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 4 ÀTI 5 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ
Báwo ni àṣà fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara ẹni ṣe burú tó?
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ẹ máa sá fún àgbèrè. . . . Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
ÌMỌ̀RÀN
Tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin máa ṣe pẹ̀lú ara wọn, ìlànà tó dára tó yẹ kó o máa tẹ̀ lé rèé: Tí o kò bá ti ní fẹ́ káwọn òbí ẹ ká ohun kan mọ́ ẹ lọ́wọ́, a jẹ́ pé kò yẹ kó o máa ṣe ohun náà nìyẹn.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Tí ọmọkùnrin kan bá ti lè bá ọmọbìnrin tó ń fẹ́ lò pọ̀, ṣe ni irú wọn sábà máa ń já ọmọbìnrin náà jù sílẹ̀, tí á sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹlòmíì.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Tí mo bá wà pẹ̀lú ọkùnrin (tàbí obìnrin), àwọn nǹkan tí màá yẹra fún ni ․․․․․
Bí ọkùnrin (tàbí obìnrin) kan bá fẹ́ kí a pàdé níbi tó dá, màá sọ pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó lè máa wu àwa ẹ̀dá aláìpé, kí nìdí tí kò fi yẹ kó o lọ́wọ́ sí i?
● Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan bá ní kó o jẹ́ kẹ́ ẹ jọ ní ìbálòpọ̀?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 176]
“Torí pé o jẹ́ Kristẹni, o ní àwọn ìwà tó máa jẹ́ káwọn ẹlòmíì fẹ́ràn rẹ. Torí náà, o gbọ́dọ̀ máa kíyè sára, kó o sì kọ̀ jálẹ̀ táwọn kan bá fẹ́ kó o ṣohun tí kò tọ́. Má ṣe fi ìwà rere tó o ní yẹn sílẹ̀ o. Má sì ṣe ta ara rẹ lọ́pọ̀!”—Joshua
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 176, 177]
Tó o bá ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó, ṣe lo tara rẹ lọ́pọ̀, bí ìgbà tó o sọ ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye kan di ìnusẹ̀