ÌBÉÈRÈ 7
Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìbálòpọ̀ Lọ̀ Mí?
KÍ LO MÁA ṢE?
Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Kò tíì ju oṣù méjì lọ tí Heather àti Mike ti ń fẹ́ra, àmọ́ lójú Heather, àfi bíi pé wọ́n ti mọra tipẹ́. Wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn ní gbogbo ìgbà, ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n fi máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù, kódà, níbi tọ́rọ̀ wọn wọ̀ dé, bí ọ̀kan nínú wọn bá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀, èkejì lè bá a parí ẹ̀ torí ó ti mọ ohun tó fẹ́ sọ! Àmọ́ ohun tí Mike ń wá jùyẹn lọ.
Láàárín oṣù méjì tó kọjá, Mike àti Heather ò ṣe kọjá kí wọ́n kàn dira wọn lọ́wọ́ mú kí wọ́n sì fẹnu konu fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Heather ò sì fẹ́ kó jùyẹn lọ. Síbẹ̀, kò fẹ́ kí Mike fi òun sílẹ̀. Kò sẹ́ni tó gba tiẹ̀ bíi Mike, ṣe ni Mike máa ń kẹ́ ẹ lójú kẹ́ ẹ nímú. Ó tún ń rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Èmi àti Mike kúkú fẹ́ràn ara wa gan-an . . . ’
Tó bá jẹ́ ìwọ ni Heather, tó o sì ti dàgbà tẹ́ni tó ń ní àfẹ́sọ́nà, kí lo máa ṣe?
RÒ Ó WÀ NÁ!
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìbálòpọ̀, àwọn tó sì ti ṣègbéyàwó nìkan ló wà fún. Tó o bá ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó, ṣe lò ń ṣe ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ẹ báṣubàṣu. Ṣe nìyẹn sì dà bí ìgbà tó o sọ aṣọ olówó iyebíye tẹ́nì kan fún ẹ di aṣọ ìnulẹ̀
Ẹni bá finá ṣeré, iná á jó o. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí tó o bá rú òfin tó jẹ mọ́ irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, bí èyí tó sọ pé: “Ẹ ta kété sí àgbèrè.”—1 Tẹsalóníkà 4:3.
Kí làwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá rú òfin yìí? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí?
Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé ọ̀kan tàbí jú bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn nǹkan tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ti ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó.
ÌDÀÀMÚ ỌKÀN. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó ló sọ pé àwọn pa dà kábàámọ̀ rẹ̀.
WỌN KÌ Í FỌKÀN TÁN ARA WỌN. Lẹ́yìn táwọn méjì tí kò tíì ṣègbéyàwó bá ti ní ìbálòpọ̀, wọ́n á máa sọ lọ́kàn ara wọn pé, ‘Ta ló mọ ẹlòmíì tó ti tún bá sùn?’
ÌJÁKULẸ̀. Nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, àwọn ọmọbìnrin sábà máa ń fẹ́ ẹni tó máa tọ́jú wọn, kì í ṣẹni tó kàn máa bá wọn sùn tán, táá sì já wọn jù sílẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin sì máa ń sọ pé àwọn ò lè fẹ́ ọmọbìnrin táwọn ti bá sùn.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá lọ ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, ṣe lo ta ara rẹ lọ́pọ̀, ohun iyebíye lo sì gbé sọ nù yẹn. (Róòmù 1:24) O ṣeyebíye gan-an, kò sì ní dáa kó o tara ẹ lọ́pọ̀!
Séra ró, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ “ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Tó o bá sì wá pa dà ṣègbéyàwó, wàá lómìnira láti ní ìbálòpọ̀. Wàá sì lè gbádùn rẹ̀ dáadáa, láìsí ìdààmú tàbí àbámọ̀, o ò sì ní kó sínú ìṣòro àìbalẹ̀ ọkàn tí àwọn tó ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó máa ń ní.—Òwe 7:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 7:3.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
Ṣẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ lóòótọ́ á ṣe ohun tó máa pa ẹ́ lára táá sì tún kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ?
Ṣẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ dénú á tàn ẹ́ láti ṣe ohun tó máa mú kí àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run bà jẹ́?—Hébérù 13:4.