ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 24-26
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tó Gbọ́n Ni Kó O Máa Bá Rìn
  • Yàgò fún Irọ́ Eléwu Tó Kún Ìgboro
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Ipò Tó Lè Sún Ọ Dé Ìdí Ẹ̀
  • ‘Mú Ọkàn-Àyà Rẹ Ṣọ̀kan’
  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
    Jí!—2004
  • Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Mú Kí N Ṣèṣekúṣe?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 24-26

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?

“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún ọmọkùnrin kan nílé ìwé wa bá mi lò pọ̀. Ó dùn mí kọjá sísọ. Látìgbà náà, mi ò já mọ́ nǹkan kan mọ́ lójú ara mi.”—Laci.a

BÍBÉLÌ pàṣẹ pé: “Ẹ . . . sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ó dà bíi pé díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́ ló máa ń fẹ́ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ yìí kí wọ́n má sì ní ìbálòpọ̀ títí dìgbà tí wọ́n á ṣègbéyàwó. Bíi ti Laci, àwọn kan ti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn láti ní ìbálòpọ̀ lọ́rùn ojú wọn sì ti já a, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀rí ọkàn wọn ò tún jẹ́ kí wọ́n gbádùn.

Lóòótọ́, kò rọrùn láti darí èrò láti ní ìbálòpọ̀ tó máa ń wá síni lọ́kàn. Ńṣe ló dà bí ohun tí ìwé náà Adolescent Development sọ, kò sí àníàní pé nígbà tí àwọn ọmọ bá ń bàlágà, ìyípadà tó máa ń wáyé nínú àgọ́ ara wọn “túbọ̀ máa ń mú kí ọkàn wọn fà sí ìbálòpọ̀.” Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Paul sọ pé: “Nígbà míì, èrò nípa ìbálòpọ̀ á kàn ṣá máa wá sí mi lọ́kàn láìnídìí.”

Síbẹ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó mọ̀ nípa ìtọ́jú àwọn ọmọdé, Howard Kulin, sọ pé: “A ò tíì sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà tá a bá ń sọ pé ohun kan ṣoṣo tó ń mú káwọn ọ̀dọ́ hùwà tí wọ́n ń hù làwọn ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lágọ̀ọ́ ara wọn.” Ó ṣàlàyé pé àwọn nǹkan tó ń lọ láwùjọ pẹ̀lú ń fa ìwà táwọn ọ̀dọ́ ń hù. Òótọ́ sì ni, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ báyìí, pàápàá ohun táwọn ọ̀dọ́ bíi tiwọn ń ṣe, lè sún wọn ṣe ohun tí wọn ò fẹ́ ṣe.

Nínú ìwé rẹ̀ tó ní àkọlé náà A Tribe Apart, òǹkọ̀wé obìnrin náà Patricia Hersch sọ pé “àwọn ọ̀dọ́ ti dá ẹ̀yà tara wọn ní. . . . Èyí kọjá káwọn mélòó kan tí wọ́n jọ jẹ́ ọ̀wọ́ ṣara wọn jọ, ńṣe ni wọ́n yara wọn sọ́tọ̀ [kúrò lọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà] débi tí wọ́n fi láwọn ìlànà àti àṣà tara wọn tí wọ́n ń tẹ̀ lé.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn àṣà tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń tẹ̀ lé lónìí sábà máa ń sún wọn láti ní ìbálòpọ̀ nígbàkúùgbà tí èrò láti ní in bá ti ń wá sí wọn lọ́kàn dípò kí wọ́n kó ara wọn níjàánu. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ bíi kí wọ́n dán ìbálòpọ̀ wò ṣáájú ìgbéyàwó.

Síbẹ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu fáwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ni pé kí wọ́n yẹra fún àgbèrè lónírúurú ọ̀nà tó lè gbà wáyé, níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ pé Ọlọ́run dẹ́bi fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára “àwọn iṣẹ́ ti ara.”b (Gálátíà 5:19) Báwo lo ṣe lè tọ́jú ìwà mímọ́ rẹ bó bá di pé àdánwò láti ní ìbálòpọ̀ ń wá lọ́tùn ún lósì?

Àwọn Tó Gbọ́n Ni Kó O Máa Bá Rìn

Níbi tọ́rọ̀ ọ̀hún dùn sí ni pé, bí ìwà táwọn èèyàn láwùjọ ń hù ṣe lè nípa búburú lórí ẹ náà làwọn ọ̀rẹ́ dáadáa tó o bá yàn ṣe lè nípa tó dáa lórí ẹ. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn òbí wọn, àwọn àgbààgbà mìíràn àtàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn” àti “àwọn tí wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe ń hùwà tí wọ́n sì ní ìlànà gbòógì . . . kì í tètè hùwà tó lè yọrí sí ìbálòpọ̀.”

Tó o bá ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn òbí ẹ, á ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an. Joseph sọ pé: “Àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ débi tí mo fi lè borí àdánwò láti dán ìbálòpọ̀ wò.” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, àwọn òbí ẹ tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run lè mú kí ìgbésí ayé ẹ ní ìtumọ̀ wọ́n sì lè kọ́ ẹ láwọn ìlànà tó wá láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Éfésù 6:2, 3) Wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìgbìyànjú ẹ láti tọ́jú ìwà rẹ.

Lóòótọ́, ó lè máà fẹ́ rọrùn láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ lákọ̀ọ́kọ́ o. Àmọ́, á yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá rí i bí wọ́n ṣe lóye nǹkan tó ń ṣe ẹ́ tó. Má gbàgbé pé wọ́n ti ṣe ọmọdé rí o. Ìdí nìyẹn tí Sonja fi gba àwọn ọ̀dọ́ yòókù nímọ̀ràn pé: “Tọ àwọn òbí ẹ lọ, máà jẹ́ kára máa tì ẹ́ tàbí kó máa kọ́ ẹ lẹ́nu láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀.”

Ṣùgbọ́n ká ní àwọn òbí ẹ kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì yẹ kó o máa bọ̀wọ̀ fún wọn, síbẹ̀ á dáa kó o wá ẹni tá á máa tọ́ ẹ sọ́nà tí kì í ṣe ara ìdílé yín. Paul tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà ni mò ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn tọkọtaya Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú látàrí bí mo ṣe máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Kenji, tí ìyá ẹ̀ jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ bákan náà pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn tó dàgbà dénú tí wọ́n sì lè gbé mi ró nípa tẹ̀mí ni mo máa ń wá ìmọ̀ràn lọ.” Àmọ́, ó sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ kan, ó ní: “Mo máa ń yẹra fáwọn tí ìwà wọn ò dáa, kódà kí wọ́n sọ pé ẹ̀sìn kan náà la jọ ń ṣe.”

Nígbà míì, ó lè gba pé kó o mọ irú ẹni tí wà á máa bá rìn nínú ìjọ Kristẹni. Bíbélì rán wa létí pé láàárín agbo térò bá pọ̀ sí, a sábà máa ń rí àwọn kan tí wọn ò ní hùwà tó lọ́lá. (2 Tímótì 2:20) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá rí i pé ńṣe làwọn ọ̀dọ́ kan nínú ìjọ rẹ “ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́”? (Sáàmù 26:4) Yáa jìnnà sírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kó o sì wá àwọn ọ̀rẹ́ tá á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìwà rere rẹ má bàa bà jẹ́.

Yàgò fún Irọ́ Eléwu Tó Kún Ìgboro

Ó tún yẹ kó o dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ ewu tó ń wá látara ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àwòrán nípa ìbálòpọ̀ àtàwọn èyí tí wọ́n dọ́gbọ́n gbé jáde sínú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, àwọn fídíò orin, ayò orí fídíò, sinimá àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ńṣe làwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń fi ìbálòpọ̀ hàn bí nǹkan tó ládùn, tó gbádùn mọ́ni àti nǹkan tí ò léwu. Ọmọ kí nìyẹn ti wá bí o. Kenji tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú yẹn sọ pé: “Mo wo ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n nínú èyí tí wọ́n ti ń ṣe bíi pé ìbálòpọ̀ ò jọ wọ́n lójú, kódà wọ́n tún dọ́gbọ́n ṣe bí ẹni ń ki ọ̀rọ̀ ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ bọ̀ ọ́. Látàrí èyí, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe burú tó lójú Jèhófà.”

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣètò eré ìnàjú ń dọ́gbọ́n fi júujùu bo àwọn èèyàn lójú kí wọ́n má bàa rí àwọn ìṣòro tó máa ń tìdí ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó wá, ìyẹn àwọn ìṣòro bíi rírí oyún he, ṣíṣègbéyàwó lábàadì, kíkó àwọn àrùn tí ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀. Nítorí náà máà jẹ́ kí “àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára” tàn ẹ́ jẹ.—Aísáyà 5:20.

Rántí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 14:15 tó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Tó o bá dédé já lu àwọn àwòrán tó ń dọ́gbọ́n fi ìbálòpọ̀ hàn tàbí èyí tó ń gbé ọ̀ràn ìbálòpọ̀ sí èèyàn lọ́kàn nígbà tó ò ń kàwé, nígbà tó o wà nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí nígbà tó o bá ń wo tẹlifíṣọ̀n, tètè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀! Pa ìwé yẹn dé, pa kọ̀ǹpútà náà tàbí kó o yí tẹlifíṣọ̀n náà sí ìkànnì mìíràn! Lẹ́yìn náà kó o wá gbé ọkàn rẹ lọ sórí nǹkan mìíràn, ohun tó dáa ni o. (Fílípì 4:8) Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ wà á lè paná àwọn ìfẹ́ ọkàn tó burú kó tó o di pé wọ́n ta gbòǹgbò lọ́kàn rẹ.—Jákọ́bù 1:14, 15.

Ṣọ́ra fún Àwọn Ipò Tó Lè Sún Ọ Dé Ìdí Ẹ̀

Ṣé ìwọ àti ẹnì kan ń bára yín jáde? Nígbà náà yáa máa ṣọ́ra lójú méjèèjì. Bíbélì kì wá nílọ̀ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Ó rọrùn láti fàyè gba ìfararora láti yọrí sí ṣíṣèṣekúṣe. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ bá ara yín jáde, á dáa kẹ́ ẹ ṣètò ẹ̀ lọ́nà tí àgbèrè ò fi ní ṣèèṣì wọ̀ ọ́, bíi kẹ́ ẹ ní alámùúròde tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tàbí kẹ́ ẹ jẹ́ kó jẹ́ láàárín àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó dáa. Ẹ má máa dá wà ní ipò tó lè jẹ́ kẹ́ ẹ kó sínú ìdẹwò láti ṣe àgbèrè.

Ó lè ṣẹlẹ̀ pé ìwọ àti ẹnì kan ti jọ ṣe àdéhùn pé ẹ máa fẹ́ra yín, tó o sì wá rò pé kò sí nǹkan tó burú nínú kẹ́ ẹ máa ṣe àwọn nǹkan kan láti fi ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní sí ara yín hàn. Ká tiẹ̀ ló rí bẹ́ẹ̀, Àjọ Ìlera Àgbáyé kìlọ̀ pé: “Nígbà tó bá kù díẹ̀ kí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn obìnrin ṣègbéyàwó ni wọ́n sábà máa ń ní ìbálòpọ̀, kódà láwọn ibi tí wọ́n ṣì ti ń ka ìbálòpọ̀ láìgbéyàwó sí nǹkan èèwọ̀.”c Nítorí náà, ẹ fi gbèdéke le ibi tí ẹ ó máa fi ìfẹ́ hàn síra yín dé kẹ́ ẹ sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún àbámọ̀ tí ń gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀.

Ó lè ṣe bákan létí o, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ni wọ́n ń fagídí bá lò pọ̀ tàbí kí wọ́n tì wọ́n láti ní ìbálòpọ̀ tipátipá. Àbọ̀ ìwádìí kan fi hàn pé, “ọmọbìnrin mẹ́ta nínú márùn-ún nílẹ̀ Amẹ́ríkà tí wọ́n ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló jẹ́ pé kò tinú wọn wá.” Agbára làwọn tó bá wọn lò pọ̀ sábà máa ń fi mú wọn. (Oníwàásù 4:1) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé Ámínónì ọmọ Ọba Dáfídì “kó sínú ìfẹ́” fún Támárì, ọbàkan ẹ̀, ó sì tàn án títí tó fi ráyè fagídí bá a lò pọ̀.—2 Sámúẹ́lì 13:1, 10-16.

Èyí ò wá túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe láti dènà ìfipábánilòpọ̀ tàbí sísúnni láti ní ìbálòpọ̀ tipátipá. Tó o bá ṣọ́ra fún ewu tó lè fa irú ẹ̀, tí o kì í bá wà nípò tíwọ fúnra ẹ mọ̀ pé kò yẹ kó o wà, tó o sì ń gbé ìgbésẹ̀ lọ́gán tó o bá ti rí i pé irú ẹ̀ fẹ́ ṣẹlẹ̀, wà á lè dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ ìbálòpọ̀ tipátipá.d

‘Mú Ọkàn-Àyà Rẹ Ṣọ̀kan’

A nírètí pé àwọn àbá tá a dá síbí yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí nínú ìjàkadì láti jẹ́ aláìlábààwọ́n. Àmọ́ ṣá o, ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ ló máa pinnu ìwà tí wàá hù ní àbárèbábọ̀. Jésù sọ pé “láti inú ọkàn-àyà ni . . . àgbèrè” ti ń wá. (Mátíù 15:19) Nítorí náà, o ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohun tó bá lè sọ ẹ́ di “aláàbọ̀-ọkàn” (kò-gbóná-kò-tutù) tàbí ‘ọlọ́kàn méjì’ (alágàbàgebè) lórí ọ̀ràn pàtàkì yìí.—Sáàmù 12:2; 119:113.

Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ìpinnu ẹ ò fẹ́ lágbára mọ́ tàbí tí ọkàn ẹ ń ṣe kámi-kàmì-kámi, gba irú àdúrà tí Dáfídì gbà nígbà tó sọ pé: “Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” (Sáàmù 86:11) Lẹ́yìn náà, ṣiṣẹ́ lé àdúrà rẹ lórí nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé látinú Bíbélì àtàwọn ìwé tó ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀. (Jákọ́bù 1:22) Lydia sọ pé: “Ohun tó máa ń fún mi lókun ti n kì í fi í fàyè gba àdánwò láti ní ìbálòpọ̀ ni bí mo ṣe máa ń rántí ní gbogbo ìgbà pé ‘kò sí àgbèrè tàbí aláìmọ́ kankan tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Ọlọ́run.’”—Éfésù 5:5.

Ó lè má rọrùn láti sá fún ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó o. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, o lè tọ́jú ìwà mímọ́ rẹ kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ìrora ọkàn tó ò bá kó bá ara ẹ àti àwọn ẹlòmíràn.—Òwe 5:8-12.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tá a lò padà.

b Lọ ka àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?” tó jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ti August 8, 2004.

c Wo orí kọkàndínlọ́gbọ̀n ìwé náà Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

d Àwọn àbá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn yìí wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ bí “Ìfìbálòpọ̀-Fòòró-Ẹni—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbòbo Ara Mi?” àti “Kí Ni Mo Lè Ṣe Láti Mú Kí Ọ̀rẹ́kùnrin Mi Dẹ́kun Fífìyà Jẹ Mí ?” tí wọ́n jáde nínú abala “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ,” nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa ti August 22, 1995, àti July 8, 2004.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Sísọ ohun tó bá wá nínú ẹ fáwọn òbí ẹ lé ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti wà ní oníwàmímọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ààbò ló jẹ́ fún ẹ tó bá jẹ́ pé àárín àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó dáa lẹ wà nígbà tẹ́ ẹ bá jọ jáde

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́