ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 2/8 ojú ìwé 16-17
  • Irọ́ Pípa—Ǹjẹ́ Àwíjàre Kankan Wà fún Un?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irọ́ Pípa—Ǹjẹ́ Àwíjàre Kankan Wà fún Un?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Bíbélì Tó Ta Yọ
  • “Ẹ Jẹ́ Oníṣọ̀ọ́ra Gẹ́gẹ́ Bí Ejò”
  • Eeṣe Ti Ó Fi Rọrùn Tobẹẹ Lati Purọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ohun Tí Ó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Irọ́ Pípa
    Jí!—1997
  • Ṣé Òtítọ́ Ṣì Lérè?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Máa Sọ Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 2/8 ojú ìwé 16-17

Ojú Ìwòye Bíbélì

Irọ́ Pípa—Ǹjẹ́ Àwíjàre Kankan Wà fún Un?

“IRỌ́ DÍẸ̀, ÒÓTỌ́ DÍẸ̀, NI KÌ Í JẸ́ KÍ ÀLÀYÉ TÁA MÁA ṢE PỌ̀ JÙ.”

Ọ̀RỌ̀ yìí ṣàlàyé bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń ronú nípa irọ́ pípa. Lójú tiwọn, kò sóhun tó burú nínú irọ́ pípa bí kò bá sáà ti pa ẹnikẹ́ni lára. Irú èrò bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lórúkọ tí àwọn ọ̀mọ̀wé ń pè é—híhùwà nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ dípò híhùwà nítorí ọ̀pá ìdiwọ̀n títọ́, tó sọ pé òfin kan ṣoṣo tí o ní láti tẹ̀ lé ni èyí tí a pè ní òfin ìfẹ́. Lédè mìíràn, òǹkọ̀wé Diane Komp ṣàlàyé pé, “bí ohun tó sún ẹ ṣe nǹkan bá tọ́, tọ́kàn ẹ sì mọ́, (nígbà náà) bó tiẹ̀ jẹ́ pé irọ́ lo pa . . . kò sí nǹkan bàbàrà ńbẹ̀.”

Irú èrò bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ lóde òní. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń dójú tini tó jẹ́ nípa irọ́ tí àwọn òṣèlú tó gbajúmọ̀ àti àwọn aṣáájú ayé mìíràn pa ti fa rúkèrúdò láwùjọ. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn jó rẹ̀yìn nínú ìpinnu wọn láti máa sọ òótọ́. Ní àwọn àdúgbò kan, irọ́ pípa tiẹ̀ ti di ìlànà tí wọ́n fàṣẹ sí. Akọ̀wé ọjà kan ṣàwáwí pé: “Apurọ́ jẹun ni mí. Mo máa ń gbẹ̀bùn nínú àwọn ìdíje ọjà títà, wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún mi gan-an lọ́dọọdún nígbà tí wọ́n bá rí i pé mo mọrọ́ pa. . . . Ó jọ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ọjà títà níbi gbogbo nìyẹn.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé irọ́ tí a ń pè ní irọ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kò ba nǹkan kan jẹ́. Ṣé òótọ́ ni? Ṣé ìgbà kankan wà tí àwọn Kristẹni lè wí àwíjàre fún irọ́ pípa?

Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Bíbélì Tó Ta Yọ

Ojú burúkú ni Bíbélì fi wo gbogbo onírúurú irọ́ pípa. Onísáàmù sọ pé: “[Ọlọ́run] yóò pa àwọn tí ń purọ́.” (Sáàmù 5:6; wo Ìṣípayá 22:15.) Nínú ìwé Òwe 6:16-19, Bíbélì to àwọn ohun méje tí Jèhófà kórìíra gan-an. Lọ́nà tó hàn gbangba, “ahọ́n èké” àti “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ” wà lára wọn. Èé ṣe? Nítorí pé Jèhófà kórìíra jàǹbá tí irọ́ pípa máa ń ṣe. Ìyẹn jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí Jésù fi pe Sátánì ní òpùrọ́ àti apààyàn. Irọ́ tó pa ló kó ìran ènìyàn sínú làásìgbò àti ikú.—Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5; Jòhánù 8:44; Róòmù 5:12.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ananíà àti Sáfírà jẹ́ ká mọ bí ọ̀ràn irọ́ pípa ṣe wúwo tó lójú Jèhófà. Àwọn méjì yìí mọ̀ọ́mọ̀ purọ́ fún àwọn àpọ́sítélì níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti fi hàn pé àwọn lawọ́ ju bí wọ́n ṣe jẹ́ lọ. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é ni, wọ́n sì ti gbìmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi wí pé: “Kì í ṣe ènìyàn ni o ṣèké sí, bí kò ṣe Ọlọ́run.” Nítorí èyí, Ọlọ́run pa àwọn méjèèjì.—Ìṣe 5:1-10.

Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Kólósè 3:9) Ní pàtàkì, ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí ṣe pàtàkì nínú ìjọ Kristẹni. Jésù sọ pé ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà ni yóò jẹ́ àmì ìdánimọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́. (Jòhánù 13:34, 35) Ibi tí àwọn èèyàn ti ń sọ òtítọ́ tí kò sì sí àbòsí ni irú ìfẹ́ tí kò lágàbàgebè nínú bẹ́ẹ̀ ti lè gbèrú. Ó ṣòro láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan bí ọkàn wa ò bá balẹ̀ pé yóò máa sọ òtítọ́ fún wa nígbà gbogbo.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo irọ́ ni kò ṣètẹ́wọ́gbà, àwọn irọ́ kan le ju àwọn mìíràn lọ. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè purọ́ nítorí ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù. Òmíràn lè dìídì sọ irọ́ pípa di àṣà nítorí àtiṣe àwọn èèyàn lọ́ṣẹ́. Nítorí èrò búburú tí ẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ ń purọ́ ní lọ́kàn, ewu ló jẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, a ó sì yọ ọ́ nínú ìjọ bí kò bá ronú pìwà dà. Níwọ̀n bí kì í ti í ṣe inú burúkú ló máa ń fa gbogbo irọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká máà dẹ́bi fún èèyàn láìyẹ, ṣùgbọ́n ká rí i dájú pé a mọ gbogbo ohun tó wà nídìí ọ̀rọ̀ tó fà á tí ẹnì kan fi parọ́. A gbọ́dọ̀ gbé èrò ọkàn àti àwọn ipò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ yẹ̀ wò.—Jákọ́bù 2:13.

“Ẹ Jẹ́ Oníṣọ̀ọ́ra Gẹ́gẹ́ Bí Ejò”

Àmọ́ ṣá o, sísọ òtítọ́ kò wá túmọ̀ sí pé ká má mọ béèyàn ti ń ṣẹ́nu po o. Jésù kìlọ̀ nínú Mátíù 7:6 pé: “Ẹ má ṣe fi ohun tí ó jẹ́ mímọ́ fún àwọn ajá, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, kí wọ́n má bàa . . . yíjú padà, kí wọ́n sì fà yín ya.” Fún àpẹẹrẹ, ẹni tó bá ní èrò búburú lọ́kàn lè máà ní ẹ̀tọ́ láti mọ àwọn ohun kan. Àwọn Kristẹni mọ̀ pé ayé ọ̀tá làwọ́n ń gbé. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò,” kí wọ́n sì jẹ́ “ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.” (Mátíù 10:16; Jòhánù 15:19) Jésù kì í fi gbogbo ìgbà la òtítọ́ ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀, ní pàtàkì tó bá ṣẹlẹ̀ pé sísọ gbogbo ohun tó wà nídìí ọ̀rọ̀ lè fa ìpalára tí kò yẹ fún ara rẹ̀ tàbí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ pàápàá, kì í purọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń yàn láti má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí láti gbé ọ̀rọ̀ náà gba ibòmíì.—Mátíù 15:1-6; 21:23-27; Jòhánù 7: 3-10.

Àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ tí a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì bíi Ábúráhámù, Ísákì, Ráhábù, àti Dáfídì, jẹ́ ọlọgbọ́n, wọ́n sì máa ń ṣọ́ra bí wọ́n bá ń bá àwọn tó lè wá di ọ̀tá lò. (Jẹ́nẹ́sísì 20:11-13; 26:9; Jóṣúà 2:1-6; 1 Sámúẹ́lì 21:10-14) Bíbélì ka irú àwọn ọkùnrin àti obìnrin bẹ́ẹ̀ sí olùjọ́sìn tó jẹ́ olùṣòtítọ́, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn jálẹ̀ ìgbà ayé wọn. Ìyẹn ló mú kí wọ́n di ẹni tó ṣeé fi ṣe àwòkọ́ṣe.—Róòmù 15:4; Hébérù 11:8-10, 20, 31, 32-39.

Àwọn àkókò kan lè wà tó máa jọ pé irọ́ pípa á mú kó rọrùn fún wa láti bọ́ nínú wàhálà. Ṣùgbọ́n yóò dára kí àwọn Kristẹni òde òní tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n sì tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn wọn tí a ti fi Bíbélì kọ́ nígbà tí wọ́n bá kojú àwọn ipò tó ṣòro gan-an.— Hébérù 5:14.

Bíbélì rọ̀ wá láti máa sọ òtítọ́ kí á má sì ṣàbòsí. Irọ́ pípa kò dára, a sì gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì pé: “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí ọkàn wa á mọ́, a óò mú kí àlàáfíà àti ìfẹ́ pọ̀ sí i nínú ìjọ, a ó sì máa bá a lọ ní bíbọlá fún “Ọlọ́run òtítọ́.”—Sáàmù 31:5; Hébérù 13:18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ananíà àti Sáfírà kú nítorí irọ́ tí wọ́n pa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́