ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/15 ojú ìwé 21-23
  • Eeṣe Ti Ó Fi Rọrùn Tobẹẹ Lati Purọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Eeṣe Ti Ó Fi Rọrùn Tobẹẹ Lati Purọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Idi fun Pípurọ́
  • Gbé Awọn Àbáyọrí Yẹwo
  • Idi ti Ó Fi Rọrùn Lati Purọ́
  • Eeṣe ti A Fi Nilati Jẹ́ Oloootọ?
  • Irọ́ Pípa—Ǹjẹ́ Àwíjàre Kankan Wà fún Un?
    Jí!—2000
  • Ohun Tí Ó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Irọ́ Pípa
    Jí!—1997
  • Máa Sọ Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ṣé Òtítọ́ Ṣì Lérè?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/15 ojú ìwé 21-23

Eeṣe Ti Ó Fi Rọrùn Tobẹẹ Lati Purọ́

KÒ SÍ ẹni ti ó fẹ́ ki a purọ́ fun oun. Sibẹ, awọn eniyan jakejado ayé ń purọ́ fun araawọn ẹnikinni keji fun oniruuru idi. Iwadiiwo kan ti ó farahan ninu iwe naa The Day America Told the Truth, lati ọwọ James Patterson ati Peter Kim, ṣipaya pe ipin 91 ninu ọgọrun-un awọn ará America ni wọn ń purọ́ deedee. Onkọwe naa sọ pe: “Ó ṣoro fun ọpọ julọ ninu wa lati maṣe purọ́ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ kan. Ẹnikan ninu marun-un kò lè ṣe é ki wọn ma purọ́ lóòjọ́—a sì ń sọrọ nipa awọn irọ́ ti a mọ̀ọ́mọ̀ pa, ti a gbèrò rẹ̀ ṣaaju.”

Irọ́ jẹ́ àṣà kan ti ó wọ́pọ̀ ninu ohun ti ó fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo ìhà igbesi-aye ode-oni. Awọn aṣaaju oṣelu ń purọ́ fun awọn eniyan wọn ati fun araawọn ẹnikinni keji. Leralera, wọn ti farahan lori tẹlifiṣọn lati sẹ́ isopọ eyikeyii pẹlu awọn ìhùmọ̀ ibanilorukọjẹ eyi ti wọn fi taratara lọwọ ninu rẹ̀ niti gidi. Sissela Bok, ninu iwe rẹ̀ Lying—Moral Choice in Public and Private Life, ṣakiyesi pe: “Ninu ofin ati ninu iṣẹ-ikọrohin, ninu ijọba ati ninu awọn imọ-ijinlẹ nipa ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ìtànjẹ ni a ronu pe ó ṣetẹwọgba nigba ti awọn wọnni ti ń purọ́ naa ti wọn sì tun jẹ́ ẹni ti ń ṣe ofin bá nimọlara pe ó ni itẹwọgba.”

Ní titọka si irọ́ pípa ti oṣelu ni United States, Common Cause Magazine ti May/June 1989 ṣakiyesi pe: “Ìlòkulò-ipò ati ogun Vietnam foríwọnrí niti gidi pẹlu ọ̀ràn ìfibòókẹ́lẹ́ ta ohun ìjà-ogun U.S. fun ilo orilẹ-ede Iran ati lílo èrè ti ń wọle wá lati ti awọn ọlọtẹ Nicaragua lẹhin niti ọ̀ràn itanjẹ ati ainigbẹkẹle gbogbo ilu ninu ijọba. Nitori naa ki ni ó mú akoko Reagan jẹ́ ti iru ìkóríta ipinya bẹẹ? Ọpọlọpọ purọ́, ṣugbọn awọn diẹ ni wọn ní ibanujẹ ọkàn.” Ó jẹ́ fun idi rere, nitori naa, ni awọn eniyan gbáàtúù kò fi nigbẹkẹle ninu awọn aṣaaju oṣelu wọn.

Ninu ibaṣepọ orilẹ-ede si orilẹ-ede kò rọrùn fun iru awọn aṣaaju bẹẹ lati gbẹkẹle araawọn ẹnikinni keji. Ọmọran Griki naa Plato sọ pe: “Awọn oluṣakoso Orilẹ-ede . . . ni a lè fun láàyè lati purọ́ fun ire Orilẹ-ede naa.” Ninu ibaṣepọ orilẹ-ede si orilẹ-ede ṣe ni ó rí bí asọtẹlẹ Bibeli ti o wà ni Danieli 11:27 ṣe sọ pe: “Wọn ó sì maa sọrọ èké lori tabili kan.”

Ninu ayé eto iṣowo, irọ́ pípa nipa awọn ohun imujade ati iṣẹ́ ṣiṣe jẹ́ aṣa gbogbogboo. Awọn olùrajà nilati fi iṣọra tọwọbọ awọn adehun ìgbéṣẹ́fúnni, ní rírí i daju pe wọn ka awọn èdè arúmọjẹ daadaa. Awọn orilẹ-ede kan ní awọn aṣoju tí ń darí ninu ijọba lati daabobo awọn eniyan lọwọ ipolowo-ọja èké, kuro lọwọ awọn oniṣowo apaniládàánù ti a ń fihàn gẹgẹ bi awọn ti wọn ṣanfaani tabi jẹ́ alaileepanilara, ati kuro lọwọ jìbìtì. Laika awọn isapa wọnyi sí, awọn eniyan ń baa lọ lati jiya niti iṣunna-owo lati ọwọ́ awọn òpùrọ́ oniṣowo.

Fun awọn eniyan kan, irọ́ pípa rọrùn gan-an debi pe ó ti di aṣa ti ó mọ́ wọn lara. Awọn miiran ni gbogbogboo jẹ́ oloootọ, ṣugbọn nigba ti ojú bá ká wọn mọ́ wọn yoo purọ́. Awọn diẹ kọ̀ lati purọ́ labẹ ipo eyikeyii.

Irọ́ ni a tumọ gẹgẹ bii “1. gbolohun-ọrọ tabi iwa èké, ni pataki ọ̀kan ti a hù pẹlu èrò lati tannijẹ . . . 2. ohunkohun ti ó bá funni ni èrò tabi ti a ní lọ́kàn pe ki o funni ni èrò èké.” Èrò ọkàn naa ni lati mú ki awọn ẹlomiran gba ohun kan tí òpùrọ́ naa mọ̀ pe kìí ṣe otitọ gbọ́. Nipasẹ irọ́ tabi àmúlùmálà irọ́ ati otitọ, ó ń saakun lati tan awọn wọnni ti wọn lẹtọọ sí mímọ otitọ jẹ.

Awọn Idi fun Pípurọ́

Awọn eniyan ń purọ́ fun ọpọlọpọ idi. Awọn kan ronu pe ó jẹ́ aigbọdọmaṣe fun awọn lati purọ́ nipa awọn ohun ti wọn lè ṣe ki ọwọ́ wọn baa lè tẹ aṣeyọri ninu ayé ẹlẹmii ibaradije yii. Awọn miiran ń gbiyanju lati fi irọ́ bo awọn aṣiṣe ati ẹ̀bi wọn mọlẹ. Sibẹ awọn miiran ń sọ awọn irohin dèké lati funni ni èrò naa pe wọn ti ṣe iṣẹ ti wọn kò tíì ṣe. Awọn kan sì wá wà ti wọn ń purọ́ lati ba orukọ rere awọn ẹlomiran jẹ́, lati yẹra fun ìtìjú, lati dá awọn irọ́ iṣaaju láre, tabi lati lu awọn eniyan ní jìbìtì owó wọn.

Ìdáláre ti ó wọ́pọ̀ fun irọ́ ni pe ó ń daabobo ẹlomiran. Awọn kan ka eyi sí irọ́ funfun nitori pe wọn ronu pe kò pa ẹnikẹni lára. Ṣugbọn awọn ohun ti a fẹnu lasan pè ni irọ́ funfun wọnyi kò ha ń fi awọn àbáyọrí buburu silẹ niti tootọ bi?

Gbé Awọn Àbáyọrí Yẹwo

Awọn irọ́ funfun lè fi apẹẹrẹ kan lélẹ̀ ti ó lè ṣamọna si sisọ irọ́ pípa ti ó lè wémọ́ awọn ọ̀ràn ti ó tubọ wúwo dàṣà. Sissela Bok sọ pe: “Gbogbo irọ́ ti a ń pọ́n léwé bii ‘funfun’ ni a kò lè fi tirọruntirọrun gbójú fòdá. Lakọọkọ, àìlèṣèpalára awọn irọ́ ni gbogbo eniyan mọ̀ si ohun ti kò fi taratara jẹ́ otitọ. Ohun ti òpùrọ́ kan fòye mọ̀ gẹgẹ bi aláìlèpanilára tabi gẹgẹ bi ohun ti ó ṣanfaani paapaa lè má rí bẹẹ ni oju ẹni ti a tànjẹ.”

Laika bi irọ́ ti lè dabii alailewu ninu sí tó, wọn a maa ba ipo-ibatan rere tí eniyan ní jẹ́. Ìṣeégbáralé òpùrọ́ naa ni a bàjẹ́, ìwólulẹ̀ titilọ nipa igbẹkẹle sì lè wà bakan naa. Ralph Waldo Emerson gbajumọ olùkọ-àròkọ naa kọwe pe: “Gbogbo ìtàpá sí otitọ kìí wulẹ ṣe iru ifọwọ ara-ẹni pa ara-ẹni kan fun òpùrọ́ naa, ṣugbọn ó jẹ́ ṣiṣe alaafia ẹgbẹ́ awujọ eniyan lọ́ṣẹ́.”

Ó rọrùn fun òpùrọ́ kan lati sọ gbolohun-ọrọ èké kan nipa ẹlomiran. Bi o tilẹ jẹ pe oun kò pese ẹ̀rí kankan, irọ́ rẹ̀ ń gbé iyemeji dide, ọpọlọpọ sì gbà á gbọ́ laisewadii ohun ti ó fidaniloju sọ. Nipa bayii orukọ rere ẹnikan ti kò mọwọ-mẹsẹ ni a bàjẹ́, ó sì ń danikan gbé ẹrù-ìnira ti fífẹ̀rí àìmọwọ́-mẹsẹ̀ rẹ̀ hàn. Nitori naa, ó ń múni ni ijakulẹ nigba ti awọn eniyan bá gba òpùrọ́ naa gbọ́ dipo ẹni ti kò mọwọ́-mẹsẹ̀ naa, ó sì ń pa ipo-ibatan ẹni pẹlu òpùrọ́ naa run.

Òpùrọ́ kan lè fi tirọruntirọrun mú aṣa pípurọ́ dagba. Irọ́ kan sábà maa ń ṣamọna si omiran. Thomas Jefferson, aṣaaju-oṣelu America kan ni ijimiji, ṣakiyesi pe: “Kò sí iwa buburu ti ó tún ṣaláìníláárí, ti ó yẹ ki a ṣalaikasi, ti ó sì jẹ́ ẹlẹgan tobẹẹ; ẹni ti ó bá sì yọnda araarẹ lati purọ́ lẹẹkan, ni yoo rọrùn fun lọpọlọpọ lati ṣe bẹẹ lẹẹkeji ati lẹẹkẹta, titi ti yoo fi di aṣa ti o mọnilara nigba ti ó bá yá.” Ó jẹ́ ọ̀nà ti ń sinni lọ si iwolulẹ iwarere.

Idi ti Ó Fi Rọrùn Lati Purọ́

Irọ́ pípa bẹrẹ nigba ti angẹli ọlọ̀tẹ̀ kan purọ́ fun obinrin akọkọ, ní sisọ fun un pe oun kò ní kú bi ó bá ṣaigbọran si Ẹlẹdaa rẹ̀. Ó yọrisi ipalara ti kò ṣeefẹnusọ fun gbogbo ẹ̀yà-ìran eniyan, ní mímú aipe, aisan, ati ikú wá fun gbogbo eniyan.—Genesisi 3:1-4; Romu 5:12.

Lati ìgbà Adamu ati Efa alaigbọran, agbara-idari eléwu abẹ́nú ti baba èké yii ti dá ipo kan silẹ ninu ayé araye ti ń gbe irọ́ pípa lẹ́sẹ̀. (Johannu 8:44) Ó jẹ́ ayé kan ninu eyi ti iwarere ti lọ silẹ ninu eyi ti otitọ wulẹ ti jẹ́ eyi ti o láàlà. The Saturday Evening Post ti September 1986 ṣakiyesi pe iṣoro irọ́ pípa “kan iṣẹ́-ajé, ijọba, ẹkọ-iwe, eré-idaraya, ati awọn ipo-ibatan ojoojumọ laaarin awọn alájọjẹ́-ọlọ̀tọ̀ ati aladuugbo. . . . A ti gba àbá-èrò-orí nipa ẹkọ ohun-gbogbó-níwọ̀n, irọ́ ń lá kanṣoṣo ti ó sọ pe kò si awọn otitọ pọ́ńbélé.”

Iru iyẹn ni oju-iwoye awọn òpùrọ́ deedee, ti wọn ti padanu ẹmi ifọranrora-ẹni eyikeyii fun awọn miiran ti wọn ń tàn jẹ. Irọ́ pípa rọrùn fun wọn. Ọ̀nà igbesi-aye wọn ni. Ṣugbọn awọn miiran ti wọn kìí ṣe òpùrọ́ deedee lè purọ́ láìlọ́ra nitori ibẹru—ibẹru ìtúnifó, ibẹru ifiyajẹni, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ailera ẹran-ara alaipe ni. Bawo ni a ṣe lè fi ipinnu gbọnyingbọnyin lati sọ otitọ rọ́pò itẹsi yii?

Eeṣe ti A Fi Nilati Jẹ́ Oloootọ?

Otitọ jẹ́ ọ̀pá-ìdiwọ̀n tí Ẹlẹdaa wa ńlá ti fi lélẹ̀ fun gbogbo eniyan. Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, ti a kọ silẹ sọ ni Heberu 6:18 pe “Kò lè ṣeeṣe fun Ọlọrun lati ṣèké.” Ọ̀pá-ìdiwọ̀n kan-naa yii ni Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ti ó jẹ́ aṣoju Ọlọrun funraarẹ lori ilẹ̀-ayé dimu. Fun awọn aṣaaju isin Ju ti wọn wá ọ̀nà lati pa á, Jesu sọ pe: “Nisinsinyi ẹyin ń wá ọ̀nà ati pa mi, ẹni ti o sọ otitọ fun yin, eyi ti mo ti gbọ́ lọdọ Ọlọrun: . . . Bi mo bá sì wi pe, emi kò mọ̀ ọ́n, emi ó di èké gẹgẹ bi ẹyin.” (Johannu 8:40, 55) Ó fi awokọṣe lélẹ̀ fun wa niti pe “kò dẹ́ṣẹ̀, bẹẹ ni a kò sì rí arekereke ni ẹnu rẹ̀.”—1 Peteru 2:21, 22.

Ẹlẹdaa wa, ẹni ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Jehofa, koriira irọ́ pípa, gẹgẹ bi Owe 6:16-19 ti sọ ni kedere: “Ohun mẹfa ni Oluwa koriira: nitootọ, meje ni o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: Oju igberaga, ètè èké, ati ọwọ́ ti ń ta ẹ̀jẹ̀ alaiṣẹ silẹ, àyà ti ń humọ buburu, ẹsẹ ti ó yára ni iré sísá si ìwà-ìkà, ẹlẹ́rìí èké ti ń sọ èké jade, ati ẹni ti ń dá ìjà silẹ laaarin awọn arakunrin.”

Ọlọrun oloootọ yii beere lọwọ wa lati gbé ni ibamu pẹlu awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n rẹ̀ ki a baa lè rí ojurere rẹ̀ gbà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a mísí paṣẹ fun wa pe: “Ẹ ma sì ṣe purọ́ fun ẹnikeji yin, ẹyin sa ti bọ́ ogbologboo ọkunrin ni silẹ pẹlu iṣe rẹ̀.” (Kolosse 3:9) Awọn eniyan ti wọn kọ̀ lati pa aṣa irọ́ pípa tì ni wọn kò ṣetẹwọgba fun un; wọn kò ni gba ẹbun ìyè. Nitootọ, Orin Dafidi 5:6 sọ ni ṣàkó pe Ọlọrun “óò pa awọn ti ń ṣe èké run.” Ìfihàn 21:8 sọ siwaju sii pe ipin “awọn èké gbogbo” ní íṣe “ikú keji,” eyi tíí ṣe iparun ayeraye. Nitori naa gbígbà ti a gba oju-iwoye Ọlọrun nipa irọ́ pípa ń fun wa ni idi lilagbara lati sọ otitọ.

Ṣugbọn ki ni a nilati ṣe ninu ipo kan nibi ti sisọ otitọ ti lè fa ipo ti ń kótìjú bani tabi fa imọlara buburu? Pípurọ́ kò lè jẹ́ ojutuu naa lae, ṣugbọn nigba miiran ó maa ń jẹ́ ṣiṣaisọ ohunkohun. Ki ni eredi pípurọ́ ti yoo wulẹ pa ṣiṣeegbagbọ rẹ̀ run ti yoo sì mú ọ wá sabẹ ailojurere atọrunwa?

Nitori ibẹru ati ailera eniyan, ẹnikan ni a lè dẹwò lati wá ibi-ìsádi sabẹ irọ́. Iyẹn ni ipa-ọna igbesẹ ti ó rọrùn julọ tabi inurere aṣiṣe. Aposteli Peteru ṣubu sinu iru adanwo bẹẹ nigba ti ó sẹ́ lẹẹmẹta pe oun mọ Jesu Kristi. Lẹhin ìgbà naa, ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ nitori pé ó ti purọ́. (Luku 22:54-62) Ojulowo ironupiwada rẹ̀ sún Ọlọrun lati dariji i, gẹgẹ bi o ti ṣe kedere ninu didi ẹni ti a fi ọpọlọpọ anfaani iṣẹ-isin bukun lẹhin naa. Ironupiwada ti a fi ipinnu onimuuratan ṣe lati dawọ irọ́ pípa duro jẹ́ ipa-ọna ti ń mú idariji atọrunwa wá fun ṣiṣe ohun ti Ọlọrun koriira.

Ṣugbọn dipo wíwá idariji lẹhin irọ́ pípa kan, pa ipo-ibatan rere mọ pẹlu Ẹlẹdaa rẹ ki o sì pa iṣeegbagbọ rẹ mọ pẹlu awọn ẹlomiran nipa sisọ otitọ. Ranti ohun ti Orin Dafidi 15:1, 2 sọ: “OLUWA, ta ni yoo ma ṣe àtìpó ninu àgọ́ rẹ? ta ni yoo ma gbé inu oke mimọ rẹ? Ẹni ti o ń rìn deedee, ti ń ṣiṣẹ òdodo, ti ó sì ń sọ otitọ inu rẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́