Àwọn Wo Lẹrú Lóde Òní?
ÌWỌ sá tiẹ̀ ronú nípa iye wọn ná. Wọ́n fojú díwọ̀n pé nǹkan bí igba sí àádọ́ta lé nígba mílíọ̀nù ọmọdé tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló ń lo wákàtí tó pọ̀ jù lóòjọ́ lẹ́nu iṣẹ́. Ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] àwọn ọmọdé, tí àwọn kan ṣì jẹ́ ọmọ ọdún méje, ni wọ́n kó lọ sójú ogun láàárín ọdún 1995 sí 1996, tí àwọn kan lára wọ́n sì wá di ẹrú tí wọ́n ń kó jagun. Wọ́n fojú díwọ̀n pé iye àwọn obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n ń tà sóko ẹrú lọ́dọọdún pọ̀ ju mílíọ̀nù kan lọ.
Ṣùgbọ́n àwọn iye tí a kọ sílẹ̀ wọ̀nyí lásán ò lè fi bí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn wọ̀nyí ṣe pọ̀ tó hàn. Fún àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan ní àríwá Áfíríkà, òǹkọ̀wé Elinor Burkett bá ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Fatma pàdé, ẹni tó jàjà ráyè sá lọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ tó rorò gan-an lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí Burkett bá Fatma sọ̀rọ̀ tán, ó wá rí i pé “títí ayé ni ọkàn ọmọbìnrin náà á máa sọ fún un pé ẹrú lòun.” Ǹjẹ́ Fatma tiẹ̀ lè ronú pé tòun á dáa lọ́jọ́ iwájú? Burkett sọ pé: “Kò rí ara rẹ̀ bí ẹni tí nǹkan lè sàn fún. Ọjọ́ iwájú wulẹ̀ dà bí ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èròǹgbà tí kò nítumọ̀ kankan sí i.”
Òtítọ́ ni pé bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ẹgbàágbèje àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa ló jẹ́ ẹrú, tí wọn ò sì nírètí kankan. Kí ló sọ gbogbo àwọn wọ̀nyí di ẹrú, báwo ni wọ́n sì ṣe di ẹrú? Irú ẹrú wo ni wọ́n jẹ́?
Àwọn Tí Ń Fi Ẹ̀dá Ṣòwò
Ìwé pẹlẹbẹ tí wọ́n ń pín fún àwọn arìnrìn-àjò ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló kúkú fọ́gbá yánga ọ̀rọ̀ náà nígbà tó sọ pé: “Lílọ sí Thailand lọ gbọ́mọge sùn. Àwọn òló ẹlẹ́jẹ̀ tútù. Ìbàdí layé wà. Ọ̀pọ̀kúyọ̀kú . . . Ǹjẹ́ o mọ̀ pé tóo bá ní igba dọ́là péré lọ́wọ́ wàá bá wúńdíá sùn?” Ohun tí ìwé pẹlẹbẹ náà kò sọ ni pé ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n jí “àwọn wúńdíá” wọ̀nyí gbé tàbí kí wọ́n fipá tà wọ́n sí àwọn ilé aṣẹ́wó, níbi tí ìpíndọ́gba nǹkan bí ẹni mẹ́wàá sí ogún ti ń bá wọn sùn lójoojúmọ́. Bí wọ́n bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n bá àwọn sùn, wọ́n á fi ìyà pá wọn lórí. Nígbà tí iná jó ilé aṣẹ́wó kan ní Erékùṣù Phuket, ibì kan táwọn èèyàn ti ń ṣeré ìtura ní gúúsù Thailand, àwọn aṣẹ́wó márùn-ún ni iná jó pa. Èé ṣe? Nítorí pé àwọn ọ̀gá wọ́n fi ẹ̀wọ̀n so wọ́n mọ́ bẹ́ẹ̀dì kí wọ́n má bàa sá lọ.
Ibo làwọn ọ̀dọ́mọbìnrin wọ̀nyẹn ti wá? A gbọ́ pé ẹgbàágbèje ọmọdébìnrin àtàwọn àgbàlagbà obìnrin ni àwọn tó ń fi ìṣekúṣe ṣòwò jí gbé, tí wọ́n fipá mú, tí wọ́n sì tà sínú iṣẹ́ aṣẹ́wó. Òwò ìṣekúṣe lágbàáyé ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nítorí ipò òṣì tí ń bẹ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àti ọrọ̀ táwọn èèyàn ń gbádùn ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀, àti bí òfin kò ti lè dènà kíkó èèyàn wọ̀lú onílùú láìgbàṣẹ àti àdéhùn ìsìnrú fún ẹlòmíràn.
Àwọn ẹgbẹ́ táwọn obìnrin dá sílẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà ti fojú díwọ̀n pé láti àárín ọdún 1975 sí 1977 títí wá di 1990 sí 1994, ọgbọ̀n mílíọ̀nù obìnrin ni wọ́n tà jákèjádò ayé. Àwọn tí ń fi ẹ̀dá ṣòwò ń yára fojú wálẹ̀ kiri àwọn ibùdó ọkọ̀ ojú irin, àwọn abúlé tó kúṣẹ̀ẹ́, àti àwọn òpópó àárín ìlú ńlá, wọ́n ń wá àwọn ọ̀dọ́bìnrin àti àwọn àgbàlagbà obìnrin tó ṣeé ṣe kí ọwọ́ wọ́n tẹ̀. Àwọn tí wọ́n sábà máa ń rí mú ni àwọn tí kò kàwé, àwọn ọmọ aláìníbaba, àwọn tí ẹnikẹ́ni ò ṣú já, àti àwọn aláìní. Wọ́n á tàn wọ́n jẹ pé àwọn á wáṣẹ́ fún wọn, wọ́n á wá kó wọn lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n á sì tà wọ́n sí àwọn ilé aṣẹ́wó.
Láti ìgbà tí àwọn orílẹ̀-èdè Kọ́múníìsì ti pínyà ní ọdún 1991 la tún ti ń rí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin àti àwọn àgbàlagbà obìnrin tí wọ́n ń di aláìní. Fífagilé àwọn òfin, sísọ àwọn òwò di ti àdáni, àti àṣà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tó ń pọ̀ sí i ti mú kí ìwà ipá, ipò òṣì, àti àìríṣẹ́ṣe máa pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà obìnrin àti àwọn ọ̀dọ́bìnrin ará Rọ́ṣíà àti Ìlà Oòrùn Yúróòpù ti wá di ìjẹ tí ń mówó wálé nínú òwò aṣẹ́wó lágbàáyé. Alábòójútó Ètò Ìdájọ́ ní Ilẹ̀ Yúróòpù tẹ́lẹ̀ rí, Anita Gradin, sọ pé: “Ewu tó wà nínú kíkó àwọn èèyàn lọ sí orílẹ̀-èdè míì kéré sí ewu tó wà nínú gbígbé oògùn olóró.”
Àdánù Ìgbà Ọmọdé
Ní ilé iṣẹ́ kékeré kan tí wọ́n ti ń hun ìnusẹ̀ ní Éṣíà, àwọn ọmọ tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún péré máa ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láti agogo mẹ́rin ìdájí títí di agogo mọ́kànlá alẹ́, wọn kì í sì í san kọ́bọ̀ fún wọn. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọdé tí wọ́n ń kó ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń kojú àwọn ohun tó lè fa àìlera tó burú gan-an: ẹ̀rọ tí kò dára, lílo àkókò gígùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀ dáadáa, tí atẹ́gùn kì í sì í dé dáadáa, àti ṣíṣí ara sílẹ̀ sí àwọn kẹ́míkà olóró tí wọ́n ń lò nílé iṣẹ́.a
Kí ló wá dé tó jẹ́ pé àwọn ọmọdé làwọn èèyàn ń lé kiri gan-an láti fi ṣe lébìrà? Ohun tó fà á ni pé kì í náni lówó púpọ̀ láti kó ọmọdé ṣiṣẹ́ àti pé àwọn ọmọdé kì í janpata, wọ́n rọrùn láti bá wí, ẹ̀rù sì máa ń bà wọ́n gan-an láti ṣàwáwí. Àwọn aláìmọra tó ń gbà wọ́n síṣẹ́ máa ń lo kíkéré tí wọ́n kéré àti ọwọ́ wọn tó yá fún àǹfààní láti ṣe irú àwọn iṣẹ́ bíi híhun ìnusẹ̀. Wọ́n sábà máa ń gbéṣẹ́ fún irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn òbí wọ́n jókòó sílé láìníṣẹ́ lọ́wọ́.
Èyí tó tún mú ọ̀ràn wọn burú sí i ni pé àwọn ọmọdé táwọn èèyàn fi ń ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ sábà máa ń bọ́ sọ́wọ́ ìyà, wọ́n sì lè bá wọn ṣèṣekúṣe. Wọ́n ń jí ọ̀pọ̀ ọmọ gbé, wọ́n á wá kó wọn sí àwọn àgọ́ tó jìnnà gan-an, wọ́n sì máa ń so wọ́n mọ́lẹ̀ lóru kí wọ́n má bàa sá lọ. Lójúmọmọ, wọ́n lè máa lò wọ́n níbi iṣẹ́ ṣíṣe ọ̀nà àti gbígbẹ́ òkúta.
Ọ̀nà mìíràn tí àwọn kan fi ń pàdánù ìgbà ọmọdé wọn jẹ́ nípa fífi wọ́n fọ́kọ tí yóò máa lò wọ́n bí ẹrú. Àjọ Tí Ń Gbógun Ti Àṣà Ìfiniṣẹrú Lágbàáyé mẹ́nu kan ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ó ní: “Wọ́n sọ fún ọmọ ọdún méjìlá kan pé àwọn ẹbí rẹ̀ ti ṣètò pé kí bàbá kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún fẹ́ ẹ. Dájúdájú, ọmọbìnrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò gbà, ṣùgbọ́n àṣà wọn ká a lọ́wọ́ kò, kò jẹ́ kó láǹfààní láti lè jà fún ẹ̀tọ́ yẹn, kò sì mọ̀ pé òun ní irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀.”
Àwọn Tí Gbèsè Sọ Dẹrú
Ẹgbàágbèje àwọn alágbàṣe ló ń sọfà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀gá wọn àti níbi iṣẹ́ wọn nítorí owó tí àwọn tàbí àwọn òbí wọ́n yá. Ibi tí àṣà fífini sọfà ti wọ́pọ̀ ni àwọn àgbègbè tí àwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ oko, tí àwọn alágbàṣe ti máa ń ṣiṣẹ́ bí ìránṣẹ́ tàbí àgbẹ̀. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, gbèsè máa ń ti ìran dé ìran, àwọn èèyàn máa ń ṣe é kí àwọn ìdílé kan máa sìnrú títí lọ. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, àwọn ọ̀gá táwọn èèyàn jẹ lówó máa ń ta gbèsè tí wọ́n jẹ wọ́n fún ọ̀gá míì. Nínú àwọn ọ̀ràn tó le gan-an, wọn kì í fún àwọn tí a fi sọfà lówó iṣẹ́ wọn rárá. Wọ́n sì lè máa san àsansílẹ̀ díẹ̀ lórí owó ọ̀yà wọn kí wọ́n má bàa bọ́ nínú oko ọfà tí àwọn ọ̀gá wọ́n fi wọ́n sí.
Fífini Ṣẹrú Nítorí Ìsìn
Binti jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá. Ó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọbìnrin tó ń sìn bíi trocosi, tó túmọ̀ sí “ẹrú òòṣà,” lédè Ewe. Wọ́n fipá mú un láti máa gbé bí ẹrú láti san ohun tí kò rà, kó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí ò dá—ìfipábánilò tó yọrí sí ìbí rẹ̀! Ní báyìí, iṣẹ́ ilé nìkan ló ń ṣe nílé bàbá àwòrò kan. Tó bá yá, iṣẹ́ Binti á pọ̀ sí i, bàbá àwòrò tó ń mú un ṣẹrú á máa bá a lòpọ̀. Tí Binti bá sì ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbó, wọ́n á pààrọ̀ ẹ̀—bàbá àwòrò náà á wá àwọn ọmọbìnrin mìíràn tó jojú ní gbèsè táá máa sìn ín bíi trocosi.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n sọ di ẹrú nítorí ẹ̀sìn, bíi Binti, ló jẹ́ àwọn ẹbí wọn ló fà wọ́n kalẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ lọ bí ẹrú nítorí àtiṣe ètùtù fún ìwà tí wọ́n kà sí wọn lọ́rùn bí ẹ̀ṣẹ̀ tàbí nítorí ṣíṣe ohun tó jẹ́ èèwọ̀ òrìṣà. Ní àwọn apá ibi púpọ̀ láyé, ó jẹ́ ọ̀ranyàn fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin tàbí àwọn àgbàlagbà obìnrin láti ṣe àwọn ohun kan nítorí ẹ̀sìn, kí àwọn àwòrò tàbí àwọn mìíràn sì máa bá wọn lòpọ̀—nítorí wọ́n sọ pé ìyàwó òrìṣà nirú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn obìnrin wọ̀nyẹn máa ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí wọn kì í rí nǹkan gbà lórí ẹ̀. Wọn kì í lómìnira láti kó kúrò níbi tí wọ́n ń gbé tàbí kí wọ́n fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì máa ń sìnrú fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Òwò Ríra Ẹrú àti Títà Wọ́n
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń sọ pé àwọn ti ṣòfin tó fagi lé òwò ẹrú, ṣùgbọ́n ní àwọn àgbègbè kan, òwò ríra ẹrú àti títà wọ́n tún ti ń yọjú. Èyí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn àgbègbè tí gbọ́nmisi-omi-òto wà tàbí tí ogun abẹ́lé ti ń jà. Àjọ Tí Ń Gbógun Ti Àṣà Ìfiniṣẹrú Lágbàáyé sọ pé: “Ní àwọn àgbègbè tí àwọn ogun ti ń jà, ńṣe ni wọ́n ń fagi lé ètò òfin, àwọn sójà tàbí àwọn ẹgbẹ́ ológun sì máa ń fipá mú àwọn èèyàn láti ṣiṣẹ́ fún wọn láìsan kọ́bọ̀ . . . láìbẹ̀rù pé ẹ̀san lè ké; a gbọ́ pé irú àṣà yẹn wọ́pọ̀ ní àwọn àgbègbè tí àwọn ológun ń ṣàkóso tí gbogbo ayé ò tíì mọ̀.” Bó ti wù kó rí, àjọ náà tún sọ pé, “a tún ń gbọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé àwọn sójà ìjọba ń fipá mú àwọn aráàlú láti máa ṣiṣẹ́ bí ẹrú, òfin èyíkéyìí kan ò sì fọwọ́ sí i. A tún gbọ́ pé àwọn sójà àti àwọn ẹgbẹ́ ológun pẹ̀lú ti ń ṣòwò ẹrú, wọ́n ń ta àwọn tí wọ́n kó ní ìkógun fún àwọn mìíràn láti máa ṣiṣẹ́ sìn wọ́n.”
Ó dunni pé ìṣòro àṣà ìfiniṣẹrú ṣì ń pọ́n ẹ̀dá lójú lóríṣiríṣi ọ̀nà tó fara sin. Tún ronú wò nípa iye àwọn tọ́ràn yìí kàn—àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó jẹ́ ẹrú, tí wọ́n sì ń jìyà jákèjádò ayé. Lẹ́yìn náà, tún ronú nípa ẹnì kan tàbí méjì lára àwọn tí o kà nípa wọn nínú ìwé yìí, tí wọ́n ń fi ṣẹrú lóde òní—bóyá Lin-Lin tàbí Binti. Ṣé o fẹ́ kí àṣà burúkú yẹn, àṣà ìfiniṣẹrú lóde òní, dópin? Ṣé àṣà ìfiniṣẹrú tiẹ̀ lè ṣeé mú kúrò pátápátá lóòótọ́? Kí èyí tó lè ṣẹlẹ̀, àwọn ìyípadà tegbòtigaga gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. Jọ̀wọ́ kà nípa wọn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo “Àṣà Kíkó Ọmọdé Ṣiṣẹ́—Kò Ní Pẹ́ Dópin!” nínú Jí!, June 8, 1999.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
WÍWÁ OJÚTÙÚ RẸ̀
Onírúurú àjọ ńláńlá, bí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé àti Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé, ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti gbé àwọn ètò kan kalẹ̀ láti fòpin sí àṣà fífi èèyàn ṣẹrú lóde òní. Ní àfikún sí i, ọ̀pọ̀ àjọ tí kì í ṣe ti ìjọba, bí Àjọ Tí Ń Gbógun Ti Àṣà Ìfiniṣẹrú Lágbàáyé àti Àjọ Tí Ń Rí Sí Ọ̀ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, ti sapá láti túbọ̀ la àwọn èèyàn lójú nípa àṣà fífi èèyàn ṣẹrú lóde òní àti láti dá àwọn tí wọ́n ti wà lóko ìsìnrú sílẹ̀. Àwọn kan lára àjọ wọ̀nyí ń làkàkà láti rí sí i pé àwọn èèyàn gbà láti máa lẹ àwọn àkọlé pàtàkì sára àwọn ọjà kan tó máa sọ pé kì í ṣe àwọn ẹrú tàbí àwọn ọmọdé ló ṣe àwọn ọjà náà. Àwọn àjọ mìíràn ń béèrè pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tó pilẹ̀ àṣà “bíbá ọ̀ràn ìbálòpọ̀ lọ sídàálẹ̀” ṣe òfin, kí wọ́n lè máa bá àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe ṣẹjọ́ nígbà tí wọ́n bá padà sí orílẹ̀-èdè wọn. Àwọn kan tí wọ́n máa ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tiẹ̀ ti ṣe é débi sísanwó ńlá fún àwọn tí ń ṣòwò ẹrú àti ọ̀gá àwọn ẹrú kí wọ́n lè dá àwọn ẹrú sílẹ̀ bó bá ṣe lè pọ̀ tó. Èyí ti dá àwọn awuyewuye kan sílẹ̀, nítorí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣínà àǹfààní tí ń mówó wọlé sílẹ̀ fún títa ẹrú, kí wọ́n sì gbé owó lé iye tí wọ́n ń tà wọ́n.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Wọ́n ń fipá mú ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin relé ọkọ
[Credit Line]
ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ/J.P. LAFFONT
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn ẹrú tí wọ́n fi sọfà ń tò gba oúnjẹ
[Credit Line]
Ricardo Funari
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Nígbà míì, wọ́n ń fipá ti àwọn ọmọdé síṣẹ́ ológun
[Credit Line]
ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ/J.P. LAFFONT