Àṣírí Tí Ò Gbọ́dọ̀ Tú
“A kò gbọ́dọ̀ fi ẹnikẹ́ni ṣẹrú tàbí ká mú un sìnrú: onírúurú àṣà fífi èèyàn ṣẹrú àti ṣíṣòwò ẹrú ni a ó kà léèwọ̀.”—Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé.
ÌGBÀKIGBÀ tóo bá fi ṣúgà sínú kọfí, kóo rántí Prevot, ọmọ ilẹ̀ Haiti tí àwọn ará orílẹ̀-èdè kan ní Caribbean ṣèlérí fún pé àwọn á fún un níṣẹ́ tó dára. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n tà á ní dọ́là mẹ́jọ.
Ohun tójú Prevot rí yìí náà ló ṣẹlẹ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ìlú ẹ̀ tí wọ́n fi ṣẹrú, tí wọ́n fipá mú ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó lóko ìrèké fún oṣù mẹ́fà sí méje láìfún wọn lówó tó ní láárí kan. Ibì kan tó há gádígádí, tó sì dọ̀tí ni wọ́n kó àwọn tí wọ́n kó wọ̀nyí sí. Ẹ̀yìn èyí ni wọ́n gba gbogbo ẹrù wọn kúrò lọ́wọ́ wọn tí wọ́n sì kó àdá lé wọn lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa roko lọ kùrà. Tí wọn ò bá ṣiṣẹ́, wọn ò ní jẹun. Bí wọ́n bá gbìyànjú láti sá lọ, àlùpamáàkú ni.
Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lin-Lin, ọmọdébìnrin tó wá láti Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni nígbà tí ìyá ẹ̀ kú. Ilé iṣẹ́ kan tó ń fi èèyàn ṣiṣẹ́ ló rà á ní ọ̀rìnlénírínwó [480] dọ́là lọ́wọ́ bàbá ẹ̀, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn á wá iṣẹ́ tó dáa fún un. Wọ́n pe iye tí wọ́n san lórí ẹ̀ ní “àsansílẹ̀ owó iṣẹ́ rẹ̀”—ọgbọ́n àtità á pa sọ́wọ́ àwọn ọ̀gá rẹ̀ tuntun ni wọ́n dá yẹn o. Dípò kí wọ́n wáṣẹ́ gidi fún Lin-Lin, ńṣe ni wọ́n mú un lọ sí ilé aṣẹ́wó kan, níbi tí àwọn ọkọ aṣẹ́wó ti máa ń san dọ́là mẹ́rin fún ọ̀gá rẹ̀ láti bá a lò pọ̀ fún wákàtí kan. Lin-Lin fẹ́rẹ̀ẹ́ má yàtọ̀ sí ẹlẹ́wọ̀n, nítorí pé kò lè lọ síbikíbi àyàfi tó bá san gbèsè rẹ̀ tán. Àti iye tí ẹni tó nilé aṣẹ́wó náà fi rà á, ìyẹn ò kan èléwó àti àwọn ìnáwó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Bí Lin-Lin kò bá ṣe ohun tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́, baba ńlá ìyà ló ń kọ lẹ́tà sí yẹn. Èyí tó tún wá burú jù níbẹ̀ ni pé, tó bá gbìyànjú láti sá lọ, ikú ni yóò gbẹ̀yìn rẹ̀.
Ṣé Gbogbo Èèyàn Ló Ti Gbòmìnira?
Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé òwò ẹrú ti di nǹkan àtijọ́. Òótọ́ ni pé lẹ́yìn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àdéhùn, ìpolongo, àti àbádòfin, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti kéde pé kò sóhun tí í jẹ́ òwò ẹrú mọ́. Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń fi hàn pé àwọn kórìíra àṣà fífi èèyàn ṣẹrú. Àwọn òfin orílẹ̀-èdè fagi lé àṣà fífi èèyàn ṣẹrú, àwọn òfin tó kà á léèwọ̀ sì wà nínú àwọn ìwé òfin àgbáyé—ní pàtàkì Ẹ̀ka Kẹrin nínú Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé ti Ọdún 1948, tí a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀.
Síbẹ̀, àṣà fífi èèyàn ṣẹrú ṣì ń bá a lọ láìdáwọ́dúró—bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójú àwọn kan, àṣírí tí ò gbọ́dọ̀ tú ni. Láti ìlú Phnom Penh dé Paris, láti Mumbai dé Brasília, ńṣe ni wọ́n ń fipá mú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn bíi tiwa—àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé—láti máa ṣiṣẹ́ bí ẹrú tàbí kí wọ́n máa gbé nínú ipò tí kò yàtọ̀ sí ti ẹrú. Àjọ Tó Ń Gbógun Ti Àṣà Ìfiniṣẹrú tó fìdí kalẹ̀ sí ìlú London, tó jẹ́ àjọ tó tíì pẹ́ jù lọ tó ń rí sí ọ̀ràn ìfipámúni-ṣiṣẹ́, sọ pé ẹgbàágbèje èèyàn ló wà lóko ẹrú. Ní gidi, iye àwọn ẹrú tó wà láyé lónìí lè pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ!
Lóòótọ́, àwòrán àwọn ẹrú tí a sábà máa ń rí tí wọ́n so ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ lẹ́sẹ̀, tí wọ́n ń nà ní pàṣán, tí wọ́n sì ń lù ní gbàǹjo kò sí nínú ọ̀ràn àwọn ẹrú tòde òní. Díẹ̀ lára àṣà ìfiniṣẹrú táa mọ̀ láyé ìsinyìí ni fífipá kó èèyàn ṣiṣẹ́, lílo ìyàwó bí ẹrú, fífini sọfà, kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́, àti lọ́pọ̀ ìgbà kíkó èèyàn ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó. Wọ́n lè fi ẹrú ṣe àlè, tàbí ẹni tí ń da ràkúnmí kiri, ẹni tí ń bẹ́ ìrèké, ẹni tí ń hun ìnusẹ̀, tàbí ẹni tí ń ṣe ọ̀nà. Òótọ́ ni pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ni a kò lù ní gbàǹjo, ṣùgbọ́n wọn ò sàn ju àwọn tayé àtijọ́ lọ. Ìgbésí ayé àwọn kan tiẹ̀ burú jáì.
Àwọn wo ni wọ́n ń di ẹrú? Báwo ni wọ́n ṣe ń di ẹrú? Kí ni a ń ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Ǹjẹ́ a lè mú àṣà ìfiniṣẹrú kúrò pátápátá láìpẹ́?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
KÍ NI ÌFINIṢẸRÚ TÚMỌ̀ SÍ LÓDE ÒNÍ?
Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pàápàá kò tíì rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti dáhùn rẹ̀. Wọ́n fún ọ̀rọ̀ náà, ìfiniṣẹrú nítumọ̀ kan ní ọdún 1926, nínú Ìwé Àdéhùn Nípa Àṣà Ìfiniṣẹrú, tó sọ pé: “Ìfiniṣẹrú jẹ́ ipò tí ẹnì kan wà tí ẹlòmíì sì ní agbára kan tàbí gbogbo agbára tó fi lè sọ pé òun lòún ni onítọ̀hún.” Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn lè ṣàlàyé ìtumọ̀ náà lóríṣiríṣi ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí oníròyìn Barbara Crossette ṣe sọ, “ẹrú jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a máa ń lò fún àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń fún lówó pọ́ọ́kú ní àwọn ilé iṣẹ́ ìhunṣọ àti ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe aṣọ eré ìdárayá lókè òkun àti àwọn ilé iṣẹ́ tí ń loni nílò omi òjò ní àwọn ìlú ńlá Amẹ́ríkà. Wọ́n ń lò ó láti dẹ́bi fún òwò kíkó èèyàn ṣaṣẹ́wó àti iṣẹ́ àṣekúdórógbó lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.”
Mike Dottridge, olùdarí Àjọ Tí Ń Gbógun Ti Àṣà Ìfiniṣẹrú Lágbàáyé, gbà gbọ́ pé, “ní báyìí tó jọ pé ọ̀nà tuntun ni àṣà ìfiniṣẹrú ń gbà yọ—tàbí bí ó ti wá jẹ́ pé oríṣiríṣi ipò la ń lo ọ̀rọ̀ náà fún báyìí—ewu tó wà níbẹ̀ ni pé ọ̀rọ̀ náà ò ní nítumọ̀ mọ́ tàbí kí ìtumọ̀ rẹ̀ má tiẹ̀ tà létí mọ́.” Ó gbà pé “ohun tí a fi ń dá ẹni tí wọ́n fi ń ṣẹrú mọ̀ ni kí ẹnì kan máa lo ẹni náà tàbí kó máa darí ayé rẹ̀ lọ́nà kan ṣáá bí ẹni pé Ọlọ́run kọ́ ló ṣẹ̀dá ẹni yẹn.” Ìfipámúni àti ṣíṣàìjẹ́ kéèyàn rìn fàlàlà wà lára rẹ̀, àní “èèyàn ò lómìnira láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, kó wá iṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ ẹlòmíràn.”
A. M. Rosenthal sọ nínú ìwé ìròyìn The New York Times pé: “Ìgbésí ayé ẹrú làwọn ẹrú ń gbé—wọ́n ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó, wọ́n ń fipá bá wọn lò pọ̀, wọ́n ń febi pa wọ́n, wọ́n ń dá wọn lóró, kò sí àbùkù tí wọn kì í fi í kàn wọ́n.” Ó tún sọ pé: “Èèyàn lè rí ẹrú rà ní àádọ́ta dọ́là, ìdí nìyẹn tí [àwọn ọ̀gá] wọ́n kì í bìkítà nípa bí wọ́n ṣe lò wọ́n pẹ́ tó kí wọ́n tó kú, tí wọ́n á sì gbé òkú wọn jù sómi.”
[Credit Line]
Ricardo Funari