ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 24-25
  • Ìgbàgbọ́ Tòótọ́—Kí Ló Jẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbàgbọ́ Tòótọ́—Kí Ló Jẹ́?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìgbàgbọ́ Gidi Ni Tàbí Gbígba Ohunkóhun Gbọ́?
  • Ìgbàgbọ́ Tòótọ́ Ń So Ènìyàn Pọ̀ Mọ́ Ọlọ́run
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Lo Igbagbọ Ti A Gbekari Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìgbàgbọ́—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 24-25

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ìgbàgbọ́ Tòótọ́—Kí Ló Jẹ́?

“LÁÌSÍ ÌGBÀGBỌ́ KÒ ṢEÉ ṢE LÁTI WÙ Ú DÁADÁA, NÍTORÍ ẸNI TÍ Ó BÁ Ń TỌ ỌLỌ́RUN WÁ GBỌ́DỌ̀ GBÀ GBỌ́ PÉ Ó Ń BẸ ÀTI PÉ ÒUN NI OLÙSẸ̀SAN FÚN ÀWỌN TÍ Ń FI TARATARA WÁ A.”—HÉBÉRÙ 11:6.

KÍ NI ìgbàgbọ́? Àwọn kan ṣàlàyé pé ìgbàgbọ́ jẹ́ èrò fífọkàn tán Ọlọ́run lọ́nà ti ẹ̀sìn láìsí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé ó wà. H. L. Mencken, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tó ń ṣiṣẹ́ ìròyìn ṣàlàyé pé ìgbàgbọ́ jẹ́ “gbígbọ́kàn lé ohun tó ṣeé ṣe kó máà jóòótọ́, láìsí ẹ̀rí tó bọ́gbọ́n mu.” Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ tòótọ́ tí Bíbélì ṣàpèjúwe lèyí? Ó ṣe pàtàkì pé ká lóye tó gún régé nípa ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́ nítorí ẹsẹ tí a fà yọ lókè yẹn sọ pé, ‘láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run.’

Bíbélì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ jẹ́ níní ìdánilójú nínú ohun tí a ń retí.” (Hébérù 11:1, The New Testament in the Language of Today) Nítorí náà, ìgbàgbọ́ sinmi lórí ìmọ̀ pípéye, òkodoro ọ̀rọ̀ tí a lè gbé ìpinnu tó tọ́ karí rẹ̀. Kì í ṣe gbígbọ́kàn lé nǹkan lásán ló ń béèrè ṣùgbọ́n ó tún ń béèrè ìdí tí a fi ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀.

Àpèjúwe kan rèé: Ká ní o ní ọ̀rẹ́ kan tí o lè fọwọ́ sọ̀yà nípa rẹ̀ pé: “Mo jẹ́rìí ọkùnrin yẹn. Ọkàn mí balẹ̀ pé kò jẹ́ yí ọ̀rọ̀ ẹ̀. Mo mọ̀ pé tí mo bá níṣòro, á ràn mí lọ́wọ́.” Ó dájú pé kì í ṣe ẹnì kan tóo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ lánàá tàbí níjẹta lo máa gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, àbírú ẹni bẹ́ẹ̀ ni? Onítọ̀hún ti ní láti jẹ́ ẹni tó ti fi ẹ̀rí hàn lọ́pọ̀ ìgbà pé òún ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Bákan náà ló yẹ kó rí ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́ tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn, tó yẹ kó jẹ́ kéèyàn ní ìrètí àti ìdánilójú tí a gbé ka ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, tó sì ṣeé gbíyè lé.

Ṣé Ìgbàgbọ́ Gidi Ni Tàbí Gbígba Ohunkóhun Gbọ́?

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára ohun táwọn èèyàn ń pè ní ìgbàgbọ́ gidi lónìí ló jẹ́ gbígba ohunkóhun gbọ́, ìyẹn ni ṣíṣetán láti fọkàn tán nǹkan láìsí ìdí gúnmọ́. Gbígba ohunkóhun gbọ́ sábà máa ń dá lórí èrò àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Irú ìyẹn kì í ṣe ìgbàgbọ́ tó mọ́yán lórí nítorí pé kò ní ìpìlẹ̀ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí a lè tìtorí ẹ̀ ní ìgbọ́kànlé.

Gbígba ohunkóhun gbọ́ lè mú kéèyàn kù gìrì ṣe ìpinnu tí kò bá òtítọ́ Bíbélì mu. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Bíbélì ò fẹ́ kéèyàn kàn ṣáà gba ohunkóhun gbọ́ láìnídìí. Ó rọ̀ wá láti ní ìgbàgbọ́ tí a fi ẹ̀rí tì lẹ́yìn.

Nǹkan pàtàkì ni kéèyàn dá ìgbàgbọ́ tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́ tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Pé ẹnì kan lẹ́mìí ìsìn kò sọ pé kó nígbàgbọ́ tòótọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn kan ní ìgbàgbọ́ tí a gbé karí Bíbélì, ó sì ń nípa lórí ìgbésí ayé wọn.

Ìgbàgbọ́ Tòótọ́ Ń So Ènìyàn Pọ̀ Mọ́ Ọlọ́run

A lè fi ìgbàgbọ́ wé ìlẹ̀kẹ̀ tí okùn rẹ̀ jẹ́ ìfọkàntán àti ìgbọ́kànlé, ìyẹn ló sì so ènìyàn àti Ọlọ́run pọ̀. Ṣùgbọ́n èèyàn máa ń mú irú ìgbàgbọ́ yìí dàgbà ni; a kì í bí i mọ́ èèyàn. Báwo lo ṣe lè ní ìgbàgbọ́ tòótọ́? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́. Ẹ̀wẹ̀, ohun tí a gbọ́ jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa Kristi.”—Róòmù 10:17.

Nítorí náà, o ní láti wá àyè láti mọ Ọlọ́run àti àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, fi kọ́ni. Bẹ́ẹ̀, èèyàn ò lè ní ìmọ̀ yìí tó bá jókòó tẹtẹrẹ, láìgbé nǹkan ṣe. (Òwe 2:1-9) O gbọ́dọ̀ tiraka láti wádìí ohun tí Bíbélì sọ, kí ìṣeégbáralé rẹ̀ bàa lè dá ọ lójú.

Síbẹ̀, ohun tí ó wà nínú ìgbàgbọ́ tòótọ́ ju kéèyàn wulẹ̀ ní ìmọ̀ tàbí kó kàn gbà gbọ́ pé nǹkan kan jẹ́ òótọ́. Ó tún ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn-àyà, èyí tó máa ń súnni ṣe nǹkan. Róòmù 10:10 sọ pé: “Ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́.” Kí ni èyí túmọ̀ sí? Tí o bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, tí o ń fi ìmọrírì hàn fún wọn, ọ̀rọ̀ Bíbélì ni o ń jẹ́ kó wọ inú ọkàn-àyà ẹ lọ yẹn. Bí ọkàn-àyà rẹ ti ń mú kí o máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run, tí o sì ń rí ẹ̀rí ìbùkún rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ á máa gbèrú, á sì máa lókun sí i.—2 Tẹsalóníkà 1:3.

Nǹkan iyebíye ni ẹni tó ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ mà ní o! A ń jàǹfààní nítorí pé a ń lè fara da ìṣòro lílekoko nípa gbígbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, tí a sì gbà gbọ́ pé ó lágbára láti tọ́ ìṣísẹ̀ wa sọ́nà àti pé ó múra tán láti pèsè àwọn ohun tí a nílò fún wa. Láfikún sí i, Jésù Kristi, tí í ṣe Ọmọ Ọlọ́run, sọ nípa ọ̀kan lára àǹfààní pípẹ́títí tó wà nínú níní ìgbàgbọ́, ó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ìyè àìnípẹ̀kun tan-n-tán, ẹ̀bùn yabuga mà lèyí jẹ́ fún àwọn tó ní ìgbàgbọ́ o!

Gbígba ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òún á san àwọn ìránṣẹ́ òun lẹ́san gbọ́ ń sọ ìfojúsọ́nà wa nípa ìwàláàyè dọ̀tun. Hébérù 11:6 sọ pé, ìgbàgbọ́ tòótọ́ kan níní ìgbọ́kànlé nínú agbára Ọlọ́run láti san èrè fún “àwọn tí ń fi taratara wá a.” Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé, ìgbàgbọ́ tòótọ́ kì í ṣe gbígba ohunkóhun gbọ́, ó sì ju wíwulẹ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà lọ. Ó kan gbígbà pé Ọlọ́run lágbára láti san àwọn tí ń fi taratara wá a lẹ́san. Ǹjẹ́ ó tọkàn ẹ wá pé ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan fẹ́ mọ Ọlọ́run lóòótọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gba ìmọ̀ pípé látinú Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ á sì ní ẹ̀san rere.—Kólósè 1:9, 10.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn àwòrán Albrecht Dürer/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́