ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 4/8 ojú ìwé 5-8
  • Ṣé Ìwà Àwọn Èèyàn Ń Burú Sí I Ju Tàtijọ́ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìwà Àwọn Èèyàn Ń Burú Sí I Ju Tàtijọ́ Ni?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rúndún Ogún—Àkókò Ìyípadà Ńlá
  • Àìka Ẹ̀sìn Kún
  • Ìmọtara-Ẹni-Nìkan àti Ìwọra
  • Ohun Táwọn Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn Ń Gbé Jáde
  • A Ti Padà sí “Ìwà Ìgbà Ojú Dúdú”
  • Àmì Kí Ni Gbogbo Nǹkan Wọ̀nyí Jẹ́?
    Jí!—2000
  • Ìdí Tí Ìwà Ọmọlúwàbí Fi Ṣe Pàtàkì
    Jí!—2019
  • Ìlànà Ìwà Híhù Ò Dúró Sójú Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Wíwá Ìgbésí Ayé Ìdẹ̀ra
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 4/8 ojú ìwé 5-8

Ṣé Ìwà Àwọn Èèyàn Ń Burú Sí I Ju Tàtijọ́ Ni?

BÓO bá bi àwọn òpìtàn pé, “Ṣé ìwà àwọn èèyàn ń dáa sí i láyé ìsinyìí ni àbí ó ń burú sí i ju ti àtijọ́ lọ?” àwọn kan lè dáhùn pé ó ṣòro láti fi ìwà àwọn èèyàn tó gbé sáà kan wéra pẹ̀lú ti sáà mìíràn. Wọ́n lè rò pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní sáà kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu.

Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn bí ìwà ọ̀daràn ṣe ń gbèrú sí i ní Yúróòpù láti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ní irínwó ọdún sẹ́yìn ìpànìyàn ò ṣàìsí. Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣe tinú wọn láìka òfin sí, ìjà àárín ẹbí sì pọ̀ nígbà náà.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òpìtàn Arne Jarrick àti Johan Söderberg sọ nínú ìwé Människovärdet och makten (Iyì àti Agbára Ẹ̀dá) pé, láàárín ọdún 1600 sí 1850, “àwọn ènìyàn ń hùwà ọmọlúwàbí gan-an” ní àwọn ibì kan. Àwọn èèyàn túbọ̀ ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò—wọ́n túbọ̀ ń fọ̀rọ̀ rora wọn wò. Fún àpẹẹrẹ, àwọn òpìtàn míì sọ pé olè jíjà àti àwọn ìwà bàsèjẹ́ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún tó bó ṣe rí láyé ìsinyìí. Kò wọ́pọ̀ kí àwọn èèyàn kó ẹgbẹ́ olè jọ pàápàá jù lọ ní àwọn ìgbèríko.

Bó ti wù kó rí, òwò ẹrú wà nígbà yẹn, òun ló sì fa àwọn kan lára ìwà ọ̀daràn tó burú jú lọ nínú ìtàn ẹ̀dá—jíjí tí àwọn oníṣòwò ará Yúróòpù ń jí àwọn èèyàn gbé ní Áfíríkà àti bí wọ́n ṣe ń ṣe àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹrú wọ̀nyí bọ́ṣẹ ṣe ń ṣojú ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n kó wọn lọ́.

Nítorí náà, báa bá bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, ó ṣeé ṣe ká rí i pé táa bá yẹ ìtàn wò, àwọn ipò kan sàn ju ti ìsinyìí lọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn míì burú jù ú lọ. Bó ti wù kó rí, ohun kan tó yàtọ̀ gan-an, tó sì burú gan-an, tí irú ẹ̀ ò tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí, wá ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún, ó ṣì ń ṣẹlẹ̀.

Ọ̀rúndún Ogún—Àkókò Ìyípadà Ńlá

Òpìtàn Jarrick àti Söderberg sọ pé: “Láàárín ọdún 1930 sí 1939 ìpànìyàn tún pọ̀ sí i, ó sì bani nínú jẹ́ pé láti ìgbà náà wá ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ń bá a bọ̀ fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún báyìí.”

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé ṣe sọ, ńṣe ni ìwà àwọn èèyàn burú sí i ní ọ̀rúndún ogún. Àròkọ kan nípa àyẹ̀wò ìwà ẹ̀dá sọ pé: “Èèyàn lè rí i kedere pé ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìbálòpọ̀ takọtabo àti ohun tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà bí ìwà rere ti yí padà gan-an láàárín ọgbọ̀n ọdún sí ogójì ọdún tó kọjá—láyé àtijọ́, àwọn èèyàn máa ń ṣe òfin aláìgbagbẹ̀rẹ́ láti fi ìwà tó tọ́ kọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ ayé ìsinyìí gbàgbàkugbà, kálukú ló sì ń ṣe tiẹ̀.”

Ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àṣà ìbálòpọ̀ àti àwọn ìwà mìíràn tó para pọ̀ jẹ́ ọ̀nà ìhùwà ẹ̀dá ti di ohun táwọn èèyàn púpọ̀ jù lọ wá ń ronú pé àwọn fúnra àwọn lè pinnu báwọn ṣe fẹ́ máa ṣe é. Láti ṣàpèjúwe èyí, àròkọ náà gbé àwọn ìṣirò kan jáde tó ń fi hàn pé ní ọdún 1960, kìkì nǹkan bí ìpín márùn-ún ààbọ̀ lára gbogbo ọmọdé tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni àwọn ìyá wọ́n bí láìsí nílé ọkọ. Ní ọdún 1990, ó ti di ìpín méjìdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún.

Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tó wáyé ní Yunifásítì Notre Dame, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin, Joe Lieberman ṣàpèjúwe bí ìwà àwọn èèyàn ṣe rí lásìkò wa pé, ó dà bí ìgbà tí “kò sí ìwà ọmọlúwàbí mọ́, . . . tí àwọn èrò àbáláyé nípa ohun tó dára àti èyí tí kò dára ti di nǹkan àtijọ́.” Lieberman sọ pé ìṣòro yìí “ti ń bá a bọ̀ díẹ̀díẹ̀ láti ìran méjì tó ti kọjá sẹ́yìn.”

Àìka Ẹ̀sìn Kún

Kí ni àwọn òpìtàn àti àwọn alálàyé míì sọ pé ó ń fa ìṣẹ̀lẹ̀ arabaríbí yìí ní ọ̀rúndún ogún? Ìwé Människovärdet och makten sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì tó yí padà láàárín ọ̀rúndún méjì tó kọjá ni ṣíṣàìka ẹ̀sìn kún.” Àìka ẹ̀sìn kún túmọ̀ sí pé “a óò fún àwọn èèyàn láǹfààní láti fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ níbàámu pẹ̀lú èrò oríṣiríṣi tí wọ́n ní. Ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ ọgbọ́n Ìlanilóye ní ọ̀rúndún kejìdínlógún ni èròǹgbà yìí . . . ti ṣẹ̀ wá, àwọn ni wọ́n kọ́kọ́ . . . pa Bíbélì tì, tí wọ́n sọ pé òun nìkan kọ́ ni orísun òtítọ́.” Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn ò fi fi bẹ́ẹ̀ yíjú sí àwọn ẹ̀sìn mọ́, pàápàá àwọn ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù, láti kọ́ wọn ní ìwà rere, bíi ti ayé àtijọ́.

Ṣùgbọ́n èé ṣe tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí wọ́n pilẹ̀ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún fi gba ohun tó lé ní igba ọdún kó tó ṣètẹ́wọ́gbà? Ìwé táa tọ́ka sí lókè yẹn sọ pé: “Àwọn èròǹgbà wọ̀nyí kì í tètè tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ìlú. Díẹ̀díẹ̀ ni ẹ̀mí àìka ẹ̀sìn kún ń gbèèràn.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀sí láti pa àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà ọmọlúwàbí táa bá láyé àti ìlànà Kristẹni tì kò yá kánkán ní apá tó pọ̀ ju lọ láàárín igba ọdún tó kọjá, ṣùgbọ́n kíá ló gbèèràn láàárín ọ̀rúndún ogún. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn pàápàá láàárín ẹ̀wádún mélòó kan tó kọjá. Kí ló dé tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Ìmọtara-Ẹni-Nìkan àti Ìwọra

Ohun pàtàkì kan tó fà á ni ìtẹ̀síwájú yíyára kánkán nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ọrọ̀ ajé láwùjọ ẹ̀dá láàárín ọ̀rúndún ogún. Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n kọ sínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà, Die Zeit, sọ pé a ń gbé “sáà tí nǹkan ti ń yí padà, kì í ṣe èyí tí nǹkan ti dúró sójú kan bó ṣe rí ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá.” Àpilẹ̀kọ náà ṣàlàyé pé èyí ti ṣamọ̀nà sí ètò ìṣòwò bòńbàtà, tó dá lórí ìbánidíje tó kún fún ìmọtara-ẹni-nìkan.

Àpilẹ̀kọ náà tún sọ pé: “Kò sí ohun tó lè dá ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan yìí dúró. Àbájáde rẹ̀ ni ìwà òǹrorò tó ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́, àti ìwà ìbàjẹ́, tí àwọn tó ń ṣèjọba pẹ̀lú ti hù ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àwọn èèyàn ń ro tara wọn nìkan àti bí wọ́n ṣe lè tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn dọ́ba.”

Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Robert Wuthnow, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Princeton, ṣe ìwádìí kínníkínní nípa lílọ béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn èèyàn, àbájáde ìwádìí náà ni pé, owó làwọn ará Amẹ́ríkà tòní ń wá kiri lójú méjèèjì ju bí ìran wọn tó kọjá ti ṣe. Ìròyìn tí wọ́n kọ nípa ìwádìí náà sọ pé, “ọ̀pọ̀ àwọn ará Amẹ́ríkà ń ṣàníyàn nípa eré àsákú táwọn èèyàn ń sá nítorí owó, tó wá di ohun tó borí àwọn ìwà ọmọlúwàbí mìíràn bíi bíbọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, àìlábòsí níbi iṣẹ́ àti ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láwùjọ wọn.”

Ìwà ìwọra tún ń pọ̀ sí i láwùjọ nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀gá níbi iṣẹ́ ń kọ owó ọ̀yà gọbọi àti owó ìfẹ̀yìntì tó pọ̀ gan-an fún ara wọn, àmọ́ wọ́n ń rọ àwọn òṣìṣẹ́ wọn pé kí wọ́n máà béèrè owó ọ̀yà tó pọ̀. Kjell Ove Nilsson, tó jẹ́ igbá kejì ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìlànà ìwà híhù, tó tún jẹ́ olùdarí ẹ̀kọ́ ìsìn nínú Ẹgbẹ́ Alábòójútó Àwọn Ẹlẹ́sìn Kristẹni ní orílẹ̀-èdè Sweden sọ pé: “Ìṣòro tí àwọn òléwájú oníṣòwò tó ń lépa èrè àjẹpajúdé ń dá sílẹ̀ ni pé wọ́n ń kó ìwà yìí ran àwọn míì àti pé wọ́n ń ba ìwà ọmọlúwàbí àwọn èèyàn jẹ́ lápapọ̀. Láìṣe àní-àní, èyí sì ń sọ àwọn èèyàn di oníwàkiwà—láwùjọ àti lẹ́nìkọ̀ọ̀kan.”

Ohun Táwọn Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn Ń Gbé Jáde

Nǹkan pàtàkì míì tó tún ń mú kí ìwà àwọn èèyàn máa burú sí i lápá ìparí ọ̀rúndún ogún ni ohun táwọn oníròyìn ń gbé jáde. Ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà, Lieberman sọ pé: “Àwọn tó tún ń sọ ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù báyìí ni àwọn tó ń gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n jáde, àwọn gbajúgbajà òṣèré inú sinimá, àwọn tó ń polówó nǹkan oge tó lòde, àwọn akọrin ọlọ́rọ̀ wótòwótò, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olókìkí tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan ilé iṣẹ́ ìròyìn. Àwọn tó ń kó àwọn èèyàn jẹ̀ yìí ti fagbára darí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa gan-an ni, pàápàá jù lọ ó nípa lórí àwọn ọmọ wa, wọn kì í sì í ronú nípa àwọn ìwà burúkú tí wọ́n ń tàn kálẹ̀.”

Fún àpẹẹrẹ, Lieberman sọ nípa àwo orin kan tí ẹgbẹ́ olórin onílù dídún kíkankíkan, tórúkọ wọn ń jẹ́ Cannibal Corpse gbé jáde. Nínú orin wọn, àwọn akọrin náà ṣàpèjúwe lẹ́sẹẹsẹ bí wọ́n ṣe yọ̀bẹ sí obìnrin kan tí wọ́n sì fipá bá a lò pọ̀. Òun àti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé kí ilé iṣẹ́ tó ń gbé àwo orin jáde lọ kó àwo orin náà kúrò lórí àtẹ. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Lieberman ti sọ, asán ni ìsapá wọn já sí.

Ìdí nìyẹn tí àwọn òbí tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ lóde òní fi ń jà raburabu kó má bàa di pé àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láá máa darí àwọn ọmọ wọ́n, táa sì máa tọ́ àwọn ọmọ náà. Ṣùgbọ́n àwọn ìdílé tí àwọn òbí ò ti múṣẹ́ wọn lọ́kùn-únkúndùn ńkọ́? Lieberman sọ pé: “Ní ti àwọn wọ̀nyẹn, a jẹ́ pé kò sẹ́ni tó máa bá ilé iṣẹ́ ìròyìn du ọ̀ràn gbígbé ọ̀pá ìdiwọ̀n kalẹ̀ nìyẹn, ohun tí ọmọ náà ń kọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, sinimá àti àwo orin ni yóò máa sọ ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ fún un, nǹkan wọ̀nyí ni yóò sì máa sọ ohun tó yẹ kó kọ́kọ́ mú gbọ́ láyé ẹ̀ fún un.” Ní báa sì ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, a lè fi Íńtánẹ́ẹ̀tì kún àwọn ohun náà.

A Ti Padà sí “Ìwà Ìgbà Ojú Dúdú”

Báwo ni ìyọrísí àwọn ìdarí burúkú wọ̀nyí ṣe ń fara hàn láàárín àwọn ọ̀dọ́? Lọ́nà kan, ọ̀pọ̀ ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́langba ló ti ṣèkà bíburú jáì fáwọn ọmọdé ẹgbẹ́ wọn àti àwọn àgbàlagbà pàápàá láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.

Ohun tó bani lẹ́rù kan ṣẹlẹ̀ ní Sweden lọ́dún 1998. Àwọn ọmọdékùnrin méjì, tí ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún méje, fún ọmọ ọdún mẹ́rin kan tí wọ́n jọ ń ṣeré lọ́rùn pa! Ìbéèrè tọ́pọ̀ èèyàn ń béèrè ni pé: Ṣé kò sí nǹkan kan nínú àwọn ọmọdé tó ń dá wọn lẹ́kun tí wọ́n bá fẹ́ ṣàṣejù ni? Oníṣègùn ọpọlọ tó jẹ́ àwọn ọmọdé lòún ń tọ́jú sọ ọ̀rọ̀ tí ń lani lóye yìí pé: “Wọ́n ní láti kọ́ ohun tó máa dá wọn lẹ́kun láti má ṣàṣejù. . . . Ó lè ní í ṣe pẹ̀lú . . . irú àwọn tó jẹ́ àwòkọ́ṣe fáwọn ọmọ náà àti ohun tí wọ́n ń kọ́ lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà tó yí wọn ká.”

A lè rí irú ìṣòro kan náà nínú àwọn ọ̀daràn paraku. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Sten Levander, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìṣègùn ọpọlọ ní Sweden, ó tó ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ìpín ogún lára gbogbo àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n lóde òní tó jẹ́ alárùn ọpọlọ ni wọ́n—àwọn anìkànjọpọ́n, tí kò lójú àánú, tí kò lè lóye èròǹgbà ìwà tó dára àti èyí tí kò dára, tàbí kó jẹ́ pé wọn ò fẹ́ lóye ẹ̀. Àwọn alákìíyèsí ti kíyè sí i pé ìwà ọmọlúwàbí kò nítumọ̀ mọ́ láàárín àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ tó jọ pé orí wọ́n pé pàápàá. Christina Hoff Sommers, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí, sọ pé: “A ti padà sí ìwà Ìgbà Ojú Dúdú.” Ó sọ pé nígbà tó bá di dandan káwọn ọ̀dọ́ tóun ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣèpinnu láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn làyà wọn á bẹ̀rẹ̀ sí í já. Wọ́n á wá fèsì pé kò sí nǹkan tó ń jẹ́ ohun tó tọ́ tàbí ohun tí ò tọ́. Wọ́n gbà gbọ́ pé olúkúlùkù ló gbọ́dọ̀ mọ ohun tó dára fún òun.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, púpọ̀ lára àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ti ta ko ìlànà iyì aláìlẹ́gbẹ́ àti ìníyelórí ìwàláàyè ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí a bi wọ́n léèrè èyí tí wọ́n máa mú nínú gbígba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn wọn là tàbí kí wọ́n gba ẹ̀mí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọn ò mọ̀ rí là, púpọ̀ lára wọn ló sọ pé ẹran ọ̀sìn làwọn á gbà là.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Sommers sọ pé: “Ìṣòro náà kì í ṣe pé àwọn ọ̀dọ́ ò mọ̀kan, tàbí pé wọn ò fọkàn tánni, tàbí pé wọ́n ya òǹrorò, tàbí aládàkàdekè. Láìdéènà pẹnu, wọn ò mọ pé ohun kan ló dáa tàbí ìkan ló burú.” Ó sọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lónìí ló ń béèrè bóyá ohun kan wà lóòótọ́ táa lè pè ní títọ́ tàbí àìtọ́, àti pé ó lérò pé irú ìrònú yìí jẹ́ ọ̀kan lára ewu tó le jù lọ tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí àwùjọ ènìyàn.

Ká sòótọ́, ìwà ọmọlúwàbí ti di nǹkan yẹpẹrẹ lákòókò wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló bẹ̀rù pé ó lè yọrí sí nǹkan burúkú. Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Die Zeit tí a mẹ́nu kàn níṣàájú sọ pé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ètò ìṣòwò bòńbàtà tó wà láyé ìsinyìí lè bẹ̀rẹ̀ sí “bà jẹ́, ó sì lè di ọjọ́ kan kó fọ́ yángá bí ètò ìjọba àjùmọ̀ní ṣe tú ká láìpẹ́ yìí.”

Kí wá ni gbogbo èyí túmọ̀ sí o? Irú ọjọ́ iwájú wo la sì lè máa wọ̀nà fún?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

“Àwọn tó tún ń sọ ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù báyìí ni àwọn tó ń gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n jáde, àwọn gbajúgbajà òṣèré inú sinimá, àwọn tó ń polówó nǹkan oge tó lòde, àwọn akọrin ọlọ́rọ̀ wótòwótò . . . ”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́