ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 5/8 ojú ìwé 9-11
  • Ǹjẹ́ Ayé Lè Ṣọ̀kan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ayé Lè Ṣọ̀kan?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá—Ohun Tó Ń Mú Ìṣọ̀kan Wá
  • Bí Ìṣọ̀kan Àgbáyé Yóò Ṣe Wá
  • Ìṣọ̀kan Tòótọ́ —Ìgbà Wo Ló Máa Dé?
  • Pa Ìṣọ̀kan Mọ́ Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Wọ̀nyí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìdílé Jèhófà Ń Gbádùn Ìṣọ̀kan Ṣíṣeyebíye
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìṣọ̀kan La Fi Ń dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìṣọ̀kan Àwa Kristẹni Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 5/8 ojú ìwé 9-11

Ǹjẹ́ Ayé Lè Ṣọ̀kan?

NÍ ÀWỌN ọdún àìpẹ́ yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí ń gbé Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti àwọn ibòmíràn ti jẹ nínú ìyà tí ogun àìṣọ̀kan ń fà. Síbẹ̀, bí àwọn ogunkógun wọ̀nyí ṣe ń jà lọ́wọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kan tí wọ́n ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fi ogun dà rú yìí ṣì mú ìṣọ̀kan tòótọ́ dàgbà láàárín ara wọn, ìṣọ̀kan wọn ò sì yingin. Gbé àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò.

Lọ́dún 1991, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún èèyàn láti onírúurú ilẹ̀ jákèjádò ayé kóra jọ sí ìlú Zagreb, lórílẹ̀-èdè Croatia. Orí ọlọ́pàá kan tó wà níbẹ̀ wú tó fi sọ pé: “Á dáa ká fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní pápá ìṣeré yìí han àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn, níbi tí àwọn ará ilẹ̀ Serbia, Croatia, Slovenia, Montenegro, àti àwọn míì ti jókòó tira wọn láìsíjà.” Kí ló mú kí irú ìṣọ̀kan tí kò wọ́pọ̀ yìí wà?

Lọ́dún 1993, àpéjọpọ̀ míì tó tún tóbi ju ìyẹn lọ wáyé ní Kiev, olú ìlú Ukraine, wọ́n pe àkọlé àpéjọpọ̀ náà ní “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá.” Iye èèyàn tó wá sípàdé náà ròkè tó ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́rin. Wọ́n kọ ọ́ sínú àkọlé ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Evening Kiev pé: “Kì í ṣe báàjì àlẹ̀máyà aláwọ̀ búlúù tó ní àkọlé náà, ‘Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá,’ nìkan ló mú . . . àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣọ̀kan, bí kò ṣe ìgbàgbọ́ tòótọ́.”

Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá—Ohun Tó Ń Mú Ìṣọ̀kan Wá

Ó ha yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ ohun tó ń mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa gbádùn ìṣọ̀kan nígbà tí àwọn èèyàn lọ́tùn-ún lósì kò sí níṣọ̀kan? Ọ̀jọ̀gbọ́n Wojciech Modzelewski, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Poland, tọ́ka sí ohun tó fà á nígbà tó sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí pé: “Lájorí ohun tó ń mú kí wọ́n lẹ́mìí àlàáfíà ni fífi tí wọ́n ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sọ́kàn, tí wọ́n sì ń fi í sílò nísinsìnyí.” Ní gidi, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tí Ẹlẹ́dàá, Jèhófà Ọlọ́run, ń kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ló ń mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan jákèjádò ayé. Kí wá ni ẹ̀kọ́ yìí o?

Jésù Kristi tọ́ka sí ìlànà pàtàkì kan tó mú kí ìṣọ̀kan wà nígbà tó sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” Òótọ́ ni, ipò àìdásí-tọ̀túntòsì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo dì mú ló ń so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan. Èyí wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nígbà tó ń gbàdúrà pé: “Èmi . . . ṣe ìbéèrè . . . kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa.”—Jòhánù 17:16-21.

Ipò àìdásí-tọ̀túntòsì tí wọ́n mú yìí ló ń fún wọn lágbára láti ṣọ̀kan nítorí pé ó ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí lápá ibi gbogbo lágbàáyé láti gbé níbàámu pẹ̀lú ohun tí wòlíì Aísáyà sọ nípa gbogbo àwọn tí Ọlọ́run “yóò fún . . . ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀.” Aísáyà sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò “ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.” Wòlíì náà tún sọ́ pé: “Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:2-4.

Ìwà ìṣọ̀kan àti àlàáfíà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hù láwọn àpéjọpọ̀ wọn tí wọ́n ṣe ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù ní ẹ̀wádún tó kọjá fi hàn kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti ní ìmúṣẹ lọ́nà kékeré. Ní ilẹ̀ Yúróòpù àti láwọn ibòmíràn, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọ́n sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Ní àbájáde rẹ̀, wọ́n ń gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lónìí nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí. Abájọ tí ọ̀rọ̀ olótùú ìwé ìròyìn kan fi sọ nígbà kan pé: “Bí gbogbo ayé bá ń tẹ̀ lé ìlànà [Bíbélì] táwọn Ẹlẹ́rìí [Jèhófà] ń tẹ̀ lé, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìkórìíra á dópin, ìfẹ́ á sì jọba”! Ǹjẹ́ ìyẹn lè ṣeé ṣe láé?

Bí Ìṣọ̀kan Àgbáyé Yóò Ṣe Wá

Láti mú kí ìṣọ̀kan wà jákèjádò gbogbo ayé, a nílò ju ìwọ̀nba àwùjọ àwọn èèyàn elérò rere lọ. Ìjọba kan tún gbọ́dọ̀ wà tó ní agbára láti dín ipa tí àwọn tó ń gbógun ti ìṣọ̀kan àti àlàáfíà ní kù. Ní gidi, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún irú ìjọba yẹn, ó wí pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Òdodo ọ̀rọ̀ ni, Jésù sọ pé ìṣàkóso Ọlọ́run nìkan, ìyẹn “ìjọba ọ̀run,” ló lè yanjú àwọn ìṣòro tó ń yọ ayé lẹ́nu—títí kan ìṣòro àìṣọ̀kan.—Mátíù 4:17.

Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba ọ̀run yẹn. Lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, àwọn èèyàn ayé á ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tí kò sí irú ẹ̀ rí. Àtúnṣe ètò ọrọ̀ ajé látọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn kọ́ ló máa mú ìṣọ̀kan àgbáyé yìí wá. Kìkì ìṣàkóso àgbáyé lọ́wọ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” ló lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.—Aísáyà 9:6, 7.

Gbogbo ìwà ìṣègbè, tí wọ́n sábà máa ń hù sáwọn èèyàn nítorí pé wọ́n jẹ́ òtòṣì àti nítorí ṣíṣi agbára lò ni Ọmọ Aládé Àlàáfíà ò ní fàyè gbà. Bíbélì ṣèlérí pé: “Gbogbo àwọn ọba yóò sì wólẹ̀ fún un; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ní tiwọn, yóò máa sìn ín. Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá . . . Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:11, 12, 14, 16.

Àìríṣẹ́ṣe pẹ̀lú yóò di ohun àtijọ́ lábẹ́ ìṣàkóso Kristi. Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Aísáyà 65:22) Rò ó wò ná, gbogbo èèyàn tó wà láyé á lè ṣe iṣẹ́ tó ní láárí, tó sì fini lọ́kàn balẹ̀!

Ìṣọ̀kan Tòótọ́ —Ìgbà Wo Ló Máa Dé?

Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni Kristi yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ayé? Nígbà tí Jésù Kristi ń dáhùn ìbéèrè yẹn, ó tọ́ka sí àkókò kan tí yóò kún fún ogun, ìròyìn ogun, àrùn, ìsẹ̀lẹ̀, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì. Síbẹ̀, ó tún sọ nípa apá dáadáa mìíràn—ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé. (Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:11) Jésù sọ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yóò dé ògógóró wọn nínú “ìpọ́njú ńlá” tí yóò mú ìyípadà pátápátá wá nínú ìṣàkóso ayé. (Mátíù 24:21) Ka ọ̀rọ̀ tó sọ tí wọ́n kọ sínú Mátíù orí 24 àti Lúùkù orí 21. Fi àwọn ipò nǹkan tó sọ tẹ́lẹ̀ wé àwọn ohun tóo ti ṣàkíyèsí láyé. Wàá rí i kedere pé ó kù fẹ́ẹ́rẹ́ kí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn ìṣàkóso aráyé. Ìjọba Rẹ̀, tí Jésù Kristi yóò ṣàkóso bí Ọba, yóò gba ìṣàkóso. Ayé tó ṣọ̀kan ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé!

Ìbéèrè náà ṣì wà ńlẹ̀, pé, Kí ló yẹ kí o ṣe kí ìlérí yìí baà lè ṣẹ lójú rẹ? Níwọ̀n bí Bíbélì ti kó ipa pàtàkì nínú ìfojúsọ́nà aráyé fún ọjọ́ iwájú, ó bọ́gbọ́n mu láti sapá láti mọ Bíbélì dáadáa. Nítorí náà, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti wá sí ilé rẹ láti bá ẹ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.a Bí o bá fara mọ́ ìkésíni yìí, o ò ní pẹ́ rí i pé ìṣọ̀kan àgbáyé wà lárọ̀ọ́wọ́tó àti pé ìwọ náà lè nípìn-ín nínú rẹ̀!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí o bá fẹ́ gbọ́ àlàyé sí i nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí, kàn sí àwa táa ṣe ìwé ìròyìn yìí tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.

[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Jákèjádò ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn ìṣọ̀kan tó gọntiọ

Kiev, Ukraine

Zagreb, Croatia

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ète Ọlọ́run ni pé kí aráyé di ìdílé àgbáyé tó ṣọ̀kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́