Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Bọ́gbọ́n mu?
LÓNÌÍ, àwọn alátìlẹyìn ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ náà. Ṣùgbọ́n, báwo ni ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ṣe bọ́gbọ́n mu tó? Gbé àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò.
Ṣẹ́dà tí aláǹtakùn máa ń ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun èlò tó lágbára jù lọ tí a mọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ti sọ, “tí a bá fa fọ́nrán kọ̀ọ̀kan tantan ó lè fi ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún gùn ju bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ rí lọ, ó sì lè gba agbára tó tó ti irin sára ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún láìjá.” Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ṣẹ́dà àrà ọ̀tọ̀ yìí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé, omi mọ̀dẹ̀mọ̀dẹ̀ kan, protein, gba inú àwọn ihò kéékèèké kọjá nínú ara aláǹtakùn, omi náà wá yí padà di okùn tó lágbára nípasẹ̀ ṣíṣàtúntò àwọn èérún protein inú rẹ̀.
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Aláǹtakùn ti gbé àwọn ìlànà tó ju ti onímọ̀ apokẹ́míkà tó mọṣẹ́ jù lọ jáde.” Ǹjẹ́ ó ṣeé gbà gbọ́ pé aláǹtakùn ti gbé ìlànà ìṣeǹkan jáde, èyí tó díjú gan-an débi pé èèyàn ò tíì lóye rẹ̀?
Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Wall Street Journal, tí Phillip E. Johnson, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì California, kọ, sọ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò ní ẹ̀rí, ṣùgbọ́n pé àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ṣì máa ń fi àwọn tó gbé ìbéèrè dìde sí i ṣe ẹlẹ́yà nígbà gbogbo. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ti ń ko ìṣòro tó le gan-an látàrí àwọn ẹ̀rí tó wà—ṣùgbọ́n àwọn alágbàwí rẹ̀ kò fẹ́ ìjíròrò tó jẹ́ òtítọ́, tó lè jin èrò òdì tí wọ́n ní lẹ́sẹ̀.”
Àpẹẹrẹ míì tó ń fi hàn pé èrò nípa ẹfolúṣọ̀n kò bọ́gbọ́n mu ni ti àwọn irúgbìn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ń ṣèwádìí ní Mòrókò ti hú àádọ́jọ àkẹ̀kù ewéko archaeopteris jáde, ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti London sì sọ pé, “àwọn ló tan mọ́ àwọn irúgbìn àkọ́kọ́ oníhóró, lára ìwọ̀nyí tí àwọn igi táa ní lónìí ti wá.” Olóòtú ìwé ìròyìn náà ní ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé irúgbìn yìí “ló jẹ́ kí á lè darí ayé òde-òní nítorí pé ó hùmọ̀ àwọn ewé àti ẹ̀ka igi.” “Láti hùmọ̀” túmọ̀ sí “láti ronú, ká sì hùmọ̀ nǹkan.” Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé irúgbìn lágbára láti ronú, kó sì hùmọ̀?
Sólómọ́nì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tó gbọ́n jù lọ, gbà wá níyànjú láti ‘ṣọ́ agbára wa láti ronú,’ kí a ronú fúnra wa. Ìsinsìnyí ni ìdí tí a ní fún ríronú fúnra wa yẹ kí ó pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ—Òwe 5:2.