Ẹ̀rín Músẹ́—Á Ṣe Ẹ́ Láǹfààní!
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JAPAN
BÓ BÁ jẹ́ ojúlówó ni, kò lè fa ìfura rárá. Ó ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tanú tó ti wà lọ́kàn fún ọ̀pọ̀ ọdún kúrò. Ó ń sọ àwọn ọkàn tó ti yigbì nítorí àìgbàgbọ́ àti àìnígbẹkẹ̀lé di rírọ̀. Ó ń mú ìtura àti ayọ̀ wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Ó ń sọ pé, “Má ṣèyọnu. Ó yé mi.” Ó máa ń rọni pé, “mo nírètí pé a lè di ọ̀rẹ́.” Kí tilẹ̀ ni nǹkan alágbára yìí? Ẹ̀rín músẹ́ ni. Ó lè jẹ́ ẹ̀rín músẹ́ ti ÌWỌ alára.
Kí ni ẹ̀rín músẹ́? Àwọn ìwé atúmọ̀ èdè sábà máa ń túmọ̀ ẹ̀rín músẹ́ sí ‘ṣíṣe ojú ẹni lọ́nà tí igun ẹnu méjèèjì á fí rọra tẹ̀ sókè díẹ̀, lọ́nà tó ń fi ìdùnnú, ìtẹ́wọ́gbà, tàbí ayọ̀ han.’ Nínú èyí ni àṣírí ẹ̀rín ọlọ́yàyà wà. Ẹ̀rín músẹ́ jẹ́ ọ̀nà tí ẹnì kan ń gbà fi bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ̀ hàn tàbí tó ń gbà bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ láìlo ọ̀rọ̀ ẹnu. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rín músẹ́ tún lè fi hàn pé a ń fi èèyàn ṣẹlẹ́yà ni tàbí pé a ń pẹ̀gàn rẹ̀ ni, ṣùgbọ́n kókó ọ̀rọ̀ mìíràn nìyẹn.
Ṣé lóòótọ́ ni pé rírẹ́rìn-ín músẹ́ máa ń mú ìyàtọ̀ wá? Ó dáa, ṣé o rántí ìgbà tí ẹ̀rín músẹ́ ẹnì kan mú kí ara tù ọ́ tàbí tó mú kára rẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀? Tàbí ìgbà tí àìsí ẹ̀rín músẹ́ mú kí ojora mú ẹ tàbí tó mú kí o nímọ̀lára pé a ṣá ẹ tì? Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀rín músẹ́ máa ń yí nǹkan padà. Ó máa ń nípa lórí ẹni tó ń rẹ́rìn-ín àti ẹni tí a ń rẹ́rìn-ín sí. Jóòbù, ọkùnrin tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ náà, sọ nípa àwọn elénìní rẹ̀ pé: “Èmi yóò rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn—wọn kì yóò gbà á gbọ́—wọn kì yóò sì mú ìmọ́lẹ̀ ojú mi rẹ̀wẹ̀sì.” (Jóòbù 29:24) Ó lè jẹ́ ìdùnnú tàbí títúraká rẹ̀ ni “ìmọ́lẹ̀” ojú Jóòbù túmọ̀ sí.
Irú ìyọrísí rere bẹ́ẹ̀ tó máa ń tinú ẹ̀rín músẹ́ wá ṣì ń ṣẹlẹ̀ títí dòní olónìí. Ẹ̀rín músẹ́ ọlọ́yàyà lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdààmú tó ti ṣẹ́jọ di èyí tó túká. Ó lè dà bí ohun kan tó ṣínà fún ìmí ẹ̀dùn táa ti dé mọ́nú tipẹ́ láti rọ́nà jáde kúrò. Nígbà tára bá kan wá tàbí tí a tán wa ní sùúrù, ẹ̀rín músẹ́ lè dín àìfararọ wa náà kù, tí yóò sì mú kí á lè kojú títán tí a tán wa ní sùúrù náà. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Tomoko ti ṣàkíyèsí pé àwọn mìíràn ń wo òun. Ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni pé àbùkù òun ni wọ́n ń wá, nítorí pé tí wọ́n bá rí i pé ojú rẹ ti ká àwọn mọ́, wọ́n á wá tètè gbójú wọn kúrò. Dídánìkanwà ló ń yọ Tomoko lẹ́nu, kò sì láyọ̀. Lọ́jọ́ kan lọ̀rẹ́ rẹ̀ kan wá gbà á nímọ̀ràn pé kó máa rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn èèyàn nígbà tójú ẹ̀ bá ṣe mẹ́rin pẹ̀lú tiwọn. Tomoko gbìyànjú ẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ méjì, ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ fún un pé ńṣe làwọn èèyàn ń rẹ́rìn-ín sí i padà! Ìdààmú ti wábi gbà. Ó sọ pé: “Ìgbésí ayé ti wá di èyí tó gbádùn mọ́ mi ní ti gidi.” Dájúdájú, ẹ̀rín músẹ́ máa ń mú kára túbọ̀ tù wá táa bá wà lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ di ẹni bí ọ̀rẹ́.
Ipa Rere Tó Ń Ní Lórí Rẹ àti Àwọn Mìíràn
Rírẹ́rìn-ín músẹ́ lè nípa lórí ìmọ̀lára ẹnì kan. Ó máa ń jẹ́ kí ọpọlọ èèyàn jí pépé. Ó tún ń mú kára le. Wọ́n máa ń sọ ọ̀rọ̀ kan pé, “Oògùn tó dáa lẹ̀rín jẹ́.” Ní tòótọ́, àwọn aláṣẹ ìṣègùn ti ṣàkíyèsí pé bí èrò orí ẹnì kan ṣe rí ní í ṣe gan-an pẹ̀lú ìlera ẹni náà. Ọ̀pọ̀ ìwádìí fi hàn pé, másùnmáwo tí kò dáwọ́ dúró, ìmọ̀lára òdì, àti nǹkan míì tó jọ ọ́ máa ń sọ ìgbékalẹ̀ adènà àrùn inú ara wa di aláìlágbára. Àmọ́, lódì kejì, ẹ̀rín músẹ́ máa ń mú ká láyọ̀, kódà ẹ̀rín tilẹ̀ máa ń fún ìgbékalẹ̀ adènà àrùn ara wa lágbára.
Ẹ̀rín músẹ́ ń nípa títóbi lórí àwọn ẹlòmíràn. Fojú inú wò ó pé o ń gbàmọ̀ràn tàbí pé wọ́n ń ṣí ẹ létí. Báwo ni wàá ṣe fẹ́ kí ẹni tó ń gbà ẹ́ nímọ̀ràn ṣe ṣojú? Ojú tó kọ́rẹ́ lọ́wọ́ tàbí tó le koko lè fi ìbínú, ìkanra, ìṣátì, tàbí ẹ̀mí ìṣọ̀tá pàápàá hàn. Ní ìdàkejì, ǹjẹ́ ẹ̀rín músẹ́ ọlọ́yàyà tó hàn lójú ẹni tó ń gbà ẹ́ nímọ̀ràn náà kò ní jẹ́ kára ẹ balẹ̀, tí wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ tẹ́tí sí ìmọ̀ràn náà? Dájúdájú, ẹ̀rín músẹ́ lè báni dín àìgbọ́ra-ẹni-yé kù nígbà tí nǹkan ò bá rọgbọ.
Èrò Dídára Ń Mú Ẹ̀rín Músẹ́ Rọrùn
Ó dájú pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa kò dà bí àwọn tó ń ṣe eré orí ìtàgé jẹun, tó jẹ́ pé ìgbàkígbà ní wọ́n lè bú sẹ́rìn-ín; ó sì dájú pé a ò ní fẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. A fẹ́ kí ẹ̀rín músẹ́ wa bára dé, kó sì jẹ́ ojúlówó. Ẹnì kan tó jẹ́ olùkọ́ nípa ìbánisọ̀rọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ sọ pé: ‘Ó ṣe pàtàkì láti fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ kéèyàn sì rẹ́rìn-ín látọkàn wá, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀rín ojú ayé lásán ló máa jẹ́.’ Báwo la ṣe lè rẹ́rìn-ín látọkàn wa wá, láìṣàbòòsí? Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ níbi táa dé yìí. Ní ti ọ̀rọ̀ ẹnu wa, ó sọ fun wa nínú Mátíù 12:34, 35 pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ. Ènìyàn rere láti inú ìṣúra rere rẹ̀ ń mú àwọn ohun rere jáde, nígbà tí ó jẹ́ pé ènìyàn burúkú láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀ ń mú àwọn ohun burúkú jáde.”
Rántí o, ẹ̀rín músẹ́ jẹ́ ọ̀nà kan tí a ń gbà sọ èrò wa jáde láìlo ọ̀rọ̀ ẹnu. Ní fífi sọ́kàn pé a ń sọ “lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà” àti pé “ohun rere” ń ti inú “ìṣúra rere” wá, ó hàn gbangba pé bí ẹ̀rín músẹ́ yóò bá jẹ́ ojúlówó, ó sinmi lé bí èrò inú àti ìmí ẹ̀dùn wa ti rí. Láìsí iyèméjì, bópẹ́-bóyá, ó dájú pé ohun tó wà nínú ọkàn wa á hàn jáde, kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe nìkan, àmọ́ nípasẹ̀ ìrísí ojú wa pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, a ní láti máa bá a lọ ní ṣíṣiṣẹ́ lórí jíjẹ́ kí àwọn èrò inú wa máa dá lórí àwọn nǹkan tó dára. Èrò wa nípa àwọn ẹlòmíràn máa ń nípa gan-an lórí bí ìrísí ojú wa yóò ṣé rí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn ànímọ́ wíwuni ti àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa, àwọn aládùúgbò wa, àti àwọn ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Á wá túbọ̀ rọrùn fún wa láti rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn. Yóò jẹ́ ojúlówó ẹ̀rín músẹ́, nítorí pé yóò wá látinú ọkàn kan tó kún fún oore, àánú, àti inú rere. Ayọ̀ á hàn rekete lójú wa, àwọn èèyàn yòókù á sì mọ̀ pé bó ṣe rí lọ́kàn wa nìyẹn lóòótọ́.
Bó ti wù kó rí, ó yẹ ká mọ̀ pé, kò rọrùn fún àwọn èèyàn kan láti rẹ́rìn-ín músẹ́ bíi ti àwọn mìíràn nítorí ipò àti ìdílé tí wọ́n ti jáde tàbí àyíká tí wọ́n ti wá. Kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ ní inú rere sáwọn aládùúgbò wọn, kì í kàn ṣe àṣà tiwọn ni láti máa rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn. Fún àpẹẹrẹ, àṣà àwọn ará Japan béèrè pé kí àwọn ọkùnrin wọn máa kóra wọn níjàánu kí wọ́n sì máa wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ní gbogbo ìgbà. Nítorí bẹ́ẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lára wọn ni kò mọ́ lára láti máa rẹ́rìn-ín sáwọn tí wọ́n bá kà sí àjèjì. Ó lè jẹ́ pé bí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn kan náà ti rí nìyẹn. Àwọn kan sì rèé, ó lè jẹ́ àbùdá wọn ni láti máa tijú, ó sì lè má rọrùn fún wọn láti rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn ẹlòmíì. Fún ìdí yìí, a ò gbọ́dọ̀ dá àwọn ẹlòmíì lẹ́bi ní ti bí ẹ̀rín músẹ́ wọ́n ṣe tó tàbí bí wọ́n ṣe lè rẹ́rìn-ín tó. Àwọn èèyàn yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ànímọ́ wọn àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà báni sọ̀rọ̀ ṣe yàtọ̀ síra.
Síbẹ̀síbẹ̀, bó bá ṣòro fún ẹ láti rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn ẹlòmíràn, kí ló dé tóò ṣiṣẹ́ lé e lórí? Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ . . . Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:9, 10) Ọ̀nà kan ti a lè fi ṣe “ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀” sí àwọn ẹlòmíràn ni láti máa rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn—èyí sì wà ní ìkáwọ́ rẹ! Nítorí náà, gbìyànjú láti kọ́kọ́ kí àwọn ẹlòmíràn, kí o sì sọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́. Wọ́n á mọyì ẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Bákan náà, wàá wá rí i pé rírẹ́rìn-ín músẹ́ á wá di nǹkan tó túbọ̀ rọrùn si i bí o ṣe ń mú àṣà náà dàgbà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ọ̀rọ̀ Ìkìlọ̀ Kan Rèé O
Ó bani nínú jẹ́ pé, kì í ṣe gbogbo ẹ̀rín músẹ́ táwọn èèyàn ń rín síni ló jẹ́ ojúlówó. Àwọn ẹlẹ́tàn, àwọn oníjìbìtì, àwọn gbájú-ẹ̀, àtàwọn míì lè rẹ́rìn-ín músẹ́ lọ́nà tó máa fa èèyàn mọ́ra gan-an. Wọ́n mọ̀ pé ẹ̀rín músẹ́ lásán ti tó láti mú àwọn èèyàn túra ká, kí wọ́n má sì fura títí ọwọ́ á fi tẹ̀ wọ́n. Àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, tàbí térò ọkàn wọn kò mọ́ náà lè lo ẹ̀rín músẹ́ láti fi fajú èèyàn mọ́ra. Síbẹ̀, irọ́ ni ẹ̀rín wọn; ẹlẹ́tàn ni wọ́n. (Oníwàásù 7:6) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní máa fura lọ́nà òdì sáwọn ẹlòmíràn, ó yẹ kí a mọ̀ pé bí a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” èyí tó nira láti bá lò, a gbọ́dọ̀ ‘jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí a jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà,’ gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra ẹ̀ ti dámọ̀ràn.—2 Tímótì 3:1; Mátíù 10:16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Gbìyànjú láti kọ́kọ́ kí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́