Ìdí Tó Fi Yẹ Kí O Yẹra Fún Ìbẹ́mìílò
KÁ NÍ wọ́n ti kọ́ ọ pé irú àwọn ìbẹ́mìílò kan jẹ́ ọ̀nà láti bá àwọn ẹ̀mí rere sọ̀rọ̀, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbẹ́mìílò. Bí àpẹẹrẹ, ó wí pé: “Ẹ má ṣe yíjú sí àwọn abẹ́mìílò, ẹ má sì ṣe wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, láti di aláìmọ́ nípasẹ̀ wọn.”—Léfítíkù 19:31; 20:6, 27.
Ní tòótọ́, Bíbélì ṣàpèjúwe pé àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò jẹ́ “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:11, 12) Èé ṣe? Ṣíṣàyẹ̀wò dáadáa nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀kan pàtàkì nínú àṣà ìbẹ́mìílò—sísọ pé èèyàn ń bá òkú sọ̀rọ̀—yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.
Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Wà Láàyè?
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò, Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fi kọ́ni pé kò ṣeé ṣe fún èèyàn láti bá àwọn èèyàn wọn tó ti kú sọ̀rọ̀. Kí ló dé tí kò fi ṣeé ṣe? Ó dáa, bí ẹnì kan yóò bá bá òkú sọ̀rọ̀, a jẹ́ pé òkú yẹn gbọ́dọ̀ wà láàyè. Apá kan nínú ara wọn gbọ́dọ̀ ṣì wà láàyè lẹ́yìn tí wọ́n kú. Àwọn kan máa ń sọ pé ọkàn máa ń wà láàyè nìṣó nígbà tí ara bá kú. Ṣé òótọ́ nìyẹn?
Àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ǹjẹ́ èyí kò fi hàn pé èèyàn fúnra rẹ̀ ni ọkàn àti pé kò ní ọkàn tí kò leè kú tó máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú? Ní ti tòótọ́, ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù,” sàréè gbogbo aráyé.—Oníwàásù 9:5, 10.
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọkàn kì í ṣe ohun kan tó máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú, tí àwọn tí ń bẹ láàyè lè máa bá a sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà. Wo àpẹẹrẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bíbélì méjì tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún, tí wọ́n ti dé orí ìparí èrò náà pé ọkàn máa ń kú. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tó jẹ́ ará Kánádà náà, Clark H. Pinnock, wí pé: “Èròǹgbà náà [pé ọkàn èèyàn jẹ́ aláìleèkú] ti ní ipa lórí ẹ̀kọ́ ìsìn fún ìgbà pípẹ́, ó ti pẹ́ lóòótọ́ ṣùgbọ́n kò bá Bíbélì mu. Bíbélì kò fi kọ́ni pé a dá ènìyàn pẹ̀lú ọkàn aláìleèkú.” Bákan náà, ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, John R. W. Stott, wí pé: “Àìleèkú ọkàn, tó túmọ̀ sí àìleèparun ọkàn, jẹ́ èròǹgbà àwọn ará Gíríìkì, kì í ṣe ti Bíbélì.”
Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn máa ń gba ìhìn, wọ́n sì máa ń gbọ́ ohùn tó máa ń dà bíi pé ọ̀dọ̀ òkú ló ti wá. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ta ló ń sọ̀rọ̀?
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Ta Ni?
Bíbélì ṣàlàyé pé ẹ̀dá ẹ̀mí kan tí a kò lè fojú rí lo ejò, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́sanyìn ṣe máa ń lo ère, láti fi bá obìnrin àkọ́kọ́, Éfà, sọ̀rọ̀ kí ó sì mú kó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Bíbélì pe ẹni ẹ̀mí, tàbí áńgẹ́lì yìí ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Ẹni yẹn, ìyẹn Sátánì, ṣàṣeyọrí láti fi ẹ̀tàn fa àwọn áńgẹ́lì mìíràn sínú ìṣọ̀tẹ̀. (Júúdà 6) Àwọn áńgẹ́lì burúkú wọ̀nyí ni a ń pè ní ẹ̀mí èṣù, wọ́n sì jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run.
Bíbélì fi hàn pé àwọn ẹ̀mí èṣù ní agbára láti ní ipa lórí àwọn èèyàn. (Lúùkù 8:26-34) Nígbà náà, kò yani lẹ́nu pé Òfin Ọlọ́run wí pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni . . . tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:10-12) Kí lewu tó wà nínú dídágunlá sí òfin yìí?
Ìrírí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì dáhùn ìbéèrè yẹn. Nítorí pé ẹ̀rù àwọn ọ̀tá ń ba Sọ́ọ̀lù Ọba, ó tọ abẹ́mìílò kan lọ. Ó ní kí obìnrin yẹn bá òun bá wòlíì Sámúẹ́lì tó ti kú sọ̀rọ̀. Nígbà tó gbọ́ bí abẹ́mìílò náà ṣe ṣàpèjúwe bàbá arúgbó kan, Sọ́ọ̀lù ronú pé Sámúẹ́lì ni ẹ̀dá abàmì yẹn gbọ́dọ̀ jẹ́. Kí ló sọ fún Sọ́ọ̀lù? Ó sọ pé a óò fi Ísírẹ́lì lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, àti pé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú “Sámúẹ́lì,” tó túmọ̀ sí pé wọn yóò kú. (1 Sámúẹ́lì 28:4-19) Kí ni Ọlọ́run sọ nípa ìpinnu tí Sọ́ọ̀lù ṣe tó fi lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ abẹ́mìílò kan? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Bí Sọ́ọ̀lù ṣe kú nìyẹn nítorí ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀ . . . àti pẹ̀lú fún bíbéèrè lọ́wọ́ abẹ́mìílò pé kí ó ṣe ìwádìí.” (1 Kíróníkà 10:13) Ohun tó ná an kò kéré rárá!
Bákan náà lónìí, àwọn tó bá ń bẹ́mìí lò ń fẹ̀mí ara wọn wewu gan-an ni. Bíbélì kìlọ̀ pé “àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò” yóò jìyà “ikú kejì [tàbí, ikú àìnípẹ̀kun].” (Ìṣípayá 21:8; 22:15) Nígbà náà, ó ṣe kedere pé, ọ̀nà ọgbọ́n, tó sì ń gba ẹ̀mí là to yẹ láti tọ̀ ni láti yẹra fún gbogbo onírúurú ìbẹ́mìílò.
Bí A Ṣe Lè Dènà Àwọn Ẹ̀mí Burúkú
Ká ní o ti lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò ńkọ́? Nígbà náà, yóò dára pé kí o gbégbèésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ láti dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ kí àwọn ẹ̀mí burúkú má bàa ṣe ọ́ léṣe. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni? Láti ṣàkàwé: Báwo ni ẹnì kan ṣe máa ń dáàbò bo ilé àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ eku? Lẹ́yìn tó bá ti pa wọ́n tán nínú ilé rẹ̀, á kó àwọn nǹkan tó máa ń fa eku wá kúrò nínú ilé. Á dí àwọn ihò, á sì tún ògiri ṣe kí àwọn eku má lè wọlé, bí àwọn eku kò bá sì dẹ̀yìn, ó lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn láti rẹ́yìn wọn.
O lè ṣe ohun tó jọ èyí láti dènà àwọn ẹ̀mí burúkú, kí o sì gba ara rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Éfésù, tí wọ́n bá ẹ̀mí lò kí wọ́n tó di Kristẹni. Lẹ́yìn tí wọ́n ti pinnu láti jáwọ́ nínú bíbá ẹ̀mí lò, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ mẹ́ta láti dáàbò bo ara wọn kúrò lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ẹ̀mí burúkú, tó dà bí ìgbà tí eku bá gbógun tini. Kí ni wọ́n ṣe?
Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́
Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.” (Ìṣe 19:19) Nípa sísun àwọn ìwé wọn tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ wíwò, àwọn Kristẹni tuntun wọ̀nyẹn fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ dènà àwọn ẹ̀mí burúkú lónìí. Kó gbogbo nǹkan tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò dà nù. Lára nǹkan wọ̀nyí ni gbogbo ìwé, ìwé ìròyìn, ìwé àkàrẹ́rìn-ín, fídíò, ìwé àlẹ̀mógiri, àwọn ọ̀rọ̀ orí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n, àti orin tí wọ́n gbà sílẹ̀ tó lè máa dọ́gbọ́n sọ nípa ìbẹ́mìílò, títí kan oògùn tàbí àwọn nǹkan mìíràn tí àwọn èèyàn máa ń fi sára nítorí “ààbò.”—Diutarónómì 7:25, 26; 1 Kọ́ríńtì 10:21.
Ní Gúúsù Amẹ́ríkà, ọkùnrin kan tó ti jingíri sínú ìbẹ́mìílò fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yìí sọ́kàn. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, mo kó gbogbo nǹkan tí mo fi ń bá ẹ̀mí lò jọ sí iwájú ilé mi, ni mo bá mú àáké, mo fi gé wọn sí wẹ́wẹ́.” Lẹ́yìn náà, ó jó gbogbo wọn di eérú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí, kò sì pẹ́ tó fi di òjíṣẹ́ onítara ní ọ̀kan nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ṣùgbọ́n o, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ yẹn kò tó. Èé ṣe tí kò fi tó? Ẹ wò ó, kódà ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù yẹn ti sun àwọn ìwé idán wọn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.” (Éfésù 6:12) Àwọn ẹ̀mí èṣù kò tíì dẹ̀yìn o. Wọ́n ṣì ń wá àǹfààní tí wọ́n á lò. Kí tún làwọn Kristẹni yẹn gbọ́dọ̀ ṣe?
Ìgbésẹ̀ Kejì
Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará ní Éfésù ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Èṣù.” (Éfésù 6:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ìmọ̀ràn yẹn ṣì gbéṣẹ́ lónìí. Gan-an bíi tẹni tó fẹ́ lé àwọn eku kúró nínú ilé rẹ̀, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ fún ohun ìgbèjà rẹ̀ tó dà bí ògiri, lágbára kí ó lè wà níbi tí ọwọ́ àwọn ẹ̀mí burúkú kò ti ní lè tó o. Kí ni ìgbésẹ̀ kejì yìí ní nínú?
Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfésù 6:16) Apata yìí ṣe pàtàkì gan-an. Bí ìgbàgbọ́ rẹ bá ṣe dúró ṣinṣin tó, bẹ́ẹ̀ náà ni o ṣe máa lè dènà agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú tó.—Mátíù 17:20.
Nígbà náà, báwo lo ṣe lè fún ohun ìgbèjà tí yóò dáàbò bò ọ́ lágbára? Nípa bíbá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ nínú Bíbélì nìṣó ni. Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́? Ní gidi, bó ṣe jẹ́ pé bí ìpìlẹ̀ ògiri kan ba ti lágbára tó ni ògiri náà ṣe máa ń dúró gbọin gbọin tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé bí ìpìlẹ̀ tí ẹnì kan fi lélẹ̀ bá ṣe lágbára tó ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ á ṣe dúró gbọin gbọin tó. Kí ni ìpìlẹ̀ náà?
Ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́. Ẹ̀wẹ̀, ohun tí a gbọ́ jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa Kristi.” (Róòmù 10:17) A rọ̀ ọ́ pé kí o ké sí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wá bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, ní àkókò àti ibi tó bá rọrùn fún ọ. Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ yóò fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. (Róòmù 1:11, 12; Kólósè 2:6, 7) Kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀? Kò ní pẹ́ tí ìgbàgbọ́ rẹ yóò fi di odi ààbò tí yóò jẹ́ apata fún ọ kúrò lọ́wọ́ ìdarí àwọn ẹ̀mí burúkú.—Sáàmù 91:4; 1 Jòhánù 5:5.
Kí ni ìgbésẹ̀ kẹta tí àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ní Éfésù gbé?
Ìgbésẹ̀ Kẹta
Ní Éfésù ìgbàanì, àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́ wọ̀nyẹn ti gbé ìgbésẹ̀ láti dènà àwọn ẹ̀mí burúkú, ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni yẹn ṣì ń gbé ní ìlú tí ìbẹ́mìílò ti wọ́pọ̀. Wọ́n ṣì nílò ààbò síwájú sí i. Nítorí náà, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ yìí, ó sọ ohun tí wọ́n á ṣe fún wọn, ó ní: “Pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ . . . ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí. Àti pé fún ète yẹn, ẹ wà lójúfò pẹ̀lú gbogbo àìyẹsẹ̀ àti pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí gbogbo ẹni mímọ́.”—Éfésù 6:18.
Dájúdájú, gbígbàdúrà lọ́nà gbígbóná janjan láìdábọ̀ fún ààbò Jèhófà jẹ́ ìgbésẹ̀ tó pọndandan fún ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí burúkú, àní ó ṣì jẹ́ bẹ́ẹ̀ títí di ìsinsìnyí. Ó sì tuni nínú láti mọ̀ pé Jèhófà yóò dáhùn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá rẹ nípa dídáàbò bò ọ́, àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ yóò sì tì ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú. (Sáàmù 34:7; 91:2, 3, 11, 14; 145:19) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a máa gbàdúrà sí Ọlọ́run láìdábọ̀ pé, “Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”—Mátíù 6:13; 1 Jòhánù 5:18, 19.
Antônio, tó jẹ́ abẹ́mìílò tẹ́lẹ̀ rí ní Brazil, wá mọrírì agbára tí àdúrà ní. Lẹ́yìn tó ti tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run lọ́nà gbígbóná janjan fún ìrànwọ́ láti jáwọ́ nínú bíbá ẹ̀mí lò. Nígbà tó ronú nípa ohun tó ti kọjá, ó wí pé: “Gbígbàdúrà sí Jèhófà ti jẹ́ ààbò fún mi àti fún ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí àwọn ẹ̀mí burúkú ti sọ di ẹrú tẹ́lẹ̀.”—Òwe 18:10.
O Lè Ṣàṣeyọrí
Ó ṣe pàtàkì pé lẹ́yìn tí o bá mọ Jèhófà, kí o ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú rẹ̀, kí o máa tẹrí ba fún ọlá àṣẹ rẹ̀, kí o sì máa ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Bí o bá ṣe èyí, nígbà tí o bá ké pè é pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì pe orúkọ tirẹ̀ alára, yóò dáàbò bò ọ́. Antônio rí irú ààbò bẹ́ẹ̀ gbà. Lónìí, ó ti di Kristẹni alàgbà ní ọ̀kan nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní São Paulo, ó sì kún fún ìmoore pé òun rí òtítọ́ tó sọ òun di òmìnira.—Jòhánù 8:32.
Gẹ́gẹ́ bíi ti Antônio àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn mìíràn tí wọ́n ti jẹ́ abẹ́mìílò tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n ń sin Jèhófà Ọlọ́run nísinsìnyí, o lè bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ́mìílò. Nítorí náà, kó gbogbo nǹkan tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò jù nù, fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí o sì máa gbàdúrà fún ààbò Jèhófà. Gbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí—ìwàláàyè rẹ sinmi lé e!
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, alààyè kò lè bá òkú sọ̀rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
1. Kó gbogbo nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò dà nù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
2. Máa bá kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
3. Máa gbàdúrà lọ́nà gbígbóná janjan lọ́pọ̀ ìgbà