ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 9/8 ojú ìwé 26-27
  • Àṣàrò Tó Ṣàǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àṣàrò Tó Ṣàǹfààní
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣàrò Kì Í Ṣe Ọ̀ràn Yẹpẹrẹ
  • Ṣíṣàṣàrò Lóde Òní
  • Àṣàrò
    Jí!—2014
  • Máa Ṣàṣàrò Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àṣàrò àti Àdúrà Ṣe Pàtàkì fún Àwọn Òjíṣẹ́ Onítara
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àṣàrò Ọkàn Mi
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 9/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Àṣàrò Tó Ṣàǹfààní

“KÍ ÀWỌN ÀSỌJÁDE ẸNU MI ÀTI ÀṢÀRÒ ỌKÀN-ÀYÀ MI DÙN MỌ́ Ọ, ÌWỌ JÈHÓFÀ ÀPÁTA MI ÀTI OLÙTÚNNIRÀPADÀ MI.”—SÁÀMÙ 19:14.

KÍ LO mọ̀ táà ń pè ní “àṣàrò”? Bóo bá fi ojú ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀sìn kan ní Ìlà Oòrùn wò ó, o lè parí èrò sí pé ohun kan tó ń jẹ́ kí èrò ẹni túbọ̀ ṣe kedere tàbí kí èèyàn ní ìlàlóye pàtàkì ni. Ọ̀nà báa ṣe lè mú ọkàn ṣófo láìro ohunkóhun ni irú àṣàrò táwọn onísìn Búdà ń ṣe ń fi kọ́ni. A gbọ́ pé àwọn oríṣi àṣàrò kan tún wà tó ń béèrè pé kí èèyàn fi “ohun tí gbogbo ayé tẹ́wọ́ gbà pé ó jẹ́ òtítọ́ nípa ọgbọ́n” kún èrò inú rẹ̀.

Ojú ìwòye Bíbélì nípa àṣàrò yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí. Lọ́nà wo? Gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ísákì, tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yẹ̀ wò, tó jẹ́ pé nígbà tó wà ní ẹni ogójì ọdún, ó ní ohun púpọ̀ láti ṣàṣàrò lé lórí. Jẹ́nẹ́sísì 24:63 sọ pé: “Ísákì sì ń rìn níta kí ó lè ṣe àṣàrò nínú pápá nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ ní ìrọ̀lẹ́.” Kò sí ìdí láti ronú pé Ísákì mú ọkàn rẹ̀ ṣófo tàbí pé ó wulẹ̀ ń ronú nípa ‘ohun tí gbogbo ayé tẹ́wọ́ gbà pé ó jẹ́ òtítọ́ nípa ọgbọ́n’ tí kò ṣe kedere kan. Á fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé Ísákì ní àwọn ohun pàtó kan láti ronú nípa rẹ̀, àwọn nǹkan bí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀, ikú ìyá rẹ̀, tàbí ẹni tí yóò fi ṣaya. Bóyá ó ń lo àwọn àkókò kan tọ́wọ́ rẹ̀ dilẹ̀ nírọ̀lẹ́ láti ṣàṣàrò nípa irú àwọn ọ̀ràn pàtàkì bẹ́ẹ̀. Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ nípa àṣàrò ju wíwulẹ̀ máa lálàá tí kò lè ṣẹ lọ.

Àṣàrò Kì Í Ṣe Ọ̀ràn Yẹpẹrẹ

Gbé àpẹẹrẹ onísáàmù náà, Dáfídì, yẹ̀ wò. Ó dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro tó jọ pé kò ṣeé borí, ó sì mọ̀ dáadáa pé òun, gẹ́gẹ́ bí aláìpé ènìyàn, nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti tọ́ ìṣísẹ̀ òun. Kí ló fún Dáfídì lókun tó fi la àwọn ipò lílekoko já? Gẹ́gẹ́ bó ti wà lákọsílẹ̀ nínú Sáàmù 19:14, Dáfídì sọ pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta mi àti Olùtúnniràpadà mi.” Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí wọ́n tú sí “àṣàrò” níhìn-ín wá láti inú ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ náà tó túmọ̀ sí láti “bá ara ẹni sọ̀rọ̀.” Òótọ́ ni, Dáfídì ‘bá ara rẹ̀ sọ̀rọ̀’ nípa Jèhófà, ìgbòkègbodò rẹ̀, àwọn iṣẹ́ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti òdodo rẹ̀.—Sáàmù 143:5.

Bákan náà, ó lè jẹ́ pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kà á sí apá kan ìjọsìn tòótọ́ láti ya àkókò kan sọ́tọ̀ láti fi ṣàṣàrò nípa àwọn ohun tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ìṣílétí pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” (Fílípì 4:8) Dájúdájú, láti lè máa ro àwọn ohun tí ń gbéni ró, “àwọn ohun” wọ̀nyí tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn ní láti wọ̀ wá lọ́kàn ní àkókò pàtó kan. Báwo ni yóò ṣe wọ̀ wá lọ́kàn?

Onísáàmù náà dáhùn ìbéèrè yẹn. Sáàmù 1:1, 2 kà pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú . . . Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.” Òtítọ́ ni, onísáàmù náà máa ń ka òfin Ọlọ́run déédéé. Ó wá lè máa ṣàṣàrò nípa àwọn ohun tó ti kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá.

Ṣíṣàṣàrò Lóde Òní

Bíbélì kíkà ṣe pàtàkì gan-an ni, ṣùgbọ́n lẹ́yìn kíkà á, a gbọ́dọ̀ ṣàṣàrò, ká ronú jinlẹ̀, tàbí “ká bá ara wa sọ̀rọ̀” nípa ohun tí a kà. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí oúnjẹ dà nínú wa bí yóò bá ṣe ara wá lóore dáadáa náà ni a ṣe nílò àṣàrò bí a bá fẹ́ kí ohun tí a kà nínú Bíbélì wọ̀ wá lọ́kàn. Ṣíṣàṣàrò lọ́nà tó tọ́ ń ṣe ju wíwulẹ̀ gbé àwọn èrò òdì kúrò lọ́kàn. Ó tún ń jẹ́ ká lè ronú nípa àwọn ojútùú tí a gbé karí Bíbélì tí a lè fi yanjú àwọn ìṣòro wa. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí nínú bíbójútó àwọn àníyàn wa ojoojúmọ́.—Mátíù 6:25-32.

Onísáàmù náà, Dáfídì, mọ ipa tí àṣàrò ń kó nínú mímú inú Ọlọ́run dùn. Ó sọ pé: “Ẹnu olódodo ní ń sọ ọgbọ́n jáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.” (Sáàmù 37:30) Òtítọ́ ni, àṣàrò jẹ́ àmì tí a fi ń dá àwọn olùjọsìn tòótọ́ mọ̀. Ìbùkún gidi ni láti jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo, ó sì ń ṣeni lóore nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé, “ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Nítorí náà, Kristẹni tó jẹ́ onígbọràn tó “ń sọ ọgbọ́n jáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” lè retí pé kí òun lóye Bíbélì sí i.

Bíbélì tún ṣí àwọn Kristẹni létí pé kí wọ́n máa ṣàṣàrò nípa ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti là á sílẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn. Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:15, 16) Òtítọ́ ni, ohun tí a sọ, tí a sì ṣe lè ní ipa tó lágbára lórí àwọn ẹlòmíràn.

Ní kedere, a ní ìdí púpọ̀ láti pọkàn pọ̀, ká sì ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì. Ó ṣe pàtàkì láti ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ká fẹ̀sọ̀ ronú nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ká sì ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wa. Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, àṣàrò táa bá ń ṣe ni yóò là wá lóye jù lọ, ìyẹn táa bá gbé èrò wa karí ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwòrán “Ẹni Tó Ń Ronú,” tí Rodin yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́