Ìsẹ̀lẹ̀!
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ TAIWAN
“Ṣe ni mo dùbúlẹ̀ tí mo ń kàwé ní ilé tí mo ń gbé àjà kẹsàn-án rẹ̀ ní Taipei nígbà tí iná bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ràkọ̀ràkọ̀. Lẹ́yìn náà, iyàrá bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Ṣe ló dà bíi pé òmìrán kan di ilé náà mú, tó sì ń mì í tìtì síhìn-ín sọ́hùn-ún. Ẹ̀rù bà mí bí mo ṣe ń gbọ́ ìró àwọn nǹkan tó ń já lulẹ̀ ní àjà ilé tó wà lókè mi bíi pé àjà ilé náà yóò já lulẹ̀, ni mo bá sá sí abẹ́ tábìlì kan. Ṣe ló dà bíi pé ìmìtìtì náà kò lópin.”—Akọ̀ròyìn kan tí ń gbé ní Taiwan.
ÌSẸ̀LẸ̀. Ṣe làyà èèyàn á já pàà bí wọ́n bá mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ṣeé ṣe kí o máa gbọ́ ọ déédéé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, kó sì máa kó ìdààmú bá ọ. Gẹ́gẹ́ bí Ìwádìí Ìmọ̀ Nípa Ilẹ̀ àti Ohun Inú Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti fi hàn, ìsẹ̀lẹ̀ ńláńlá tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1999 túbọ̀ pọ̀ ju iye tí ó ti máa ń ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀, iye àwọn tó sì pàdánù ẹ̀mí wọn jẹ́ ìlọ́po méjì iye tí ó máa ń jẹ́ ìpíndọ́gba ọdọọdún.
Ìsẹ̀lẹ̀ tó tóbi jù lọ lọ́dún 1999 ṣẹlẹ̀ ní Taiwan, níbi tí ìpele àdìpọ̀ ilẹ̀ méjì pàtàkì ti ojú ilẹ̀ ayé ti pàdé. Lápapọ̀, ibi tí ojú ilẹ̀ ayé ti sán, tí a mọ̀, tó gba Taiwan kọjá tó mọ́kànléláàádọ́ta. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ìmìtìtì ilẹ̀ ni wọ́n máa ń ròyìn níbẹ̀ lọ́dọọdún. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ló kéré púpọ̀ débi pé a kì í mọ̀ pé wọ́n ṣẹlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ ní September 21, 1999. Ní agogo méjì ku ìṣẹ́jú mẹ́tàlá òwúrọ̀, ìsẹ̀lẹ̀ kan mi Taiwan tìtì, ó sì le débi pé Ààrẹ Lee Teng-hui sọ pé òun “ló tíì burú jù lọ nínú ọ̀rúndún yẹn ní erékùṣù yẹn.” Ààbọ̀ ìṣẹ́jú ló gbà, ṣùgbọ́n ó wọn 7.6 lórí òṣùwọ̀n Richter.a Ìmìtìtì ilẹ̀ náà wulẹ̀ fi díẹ̀ jinlẹ̀ ju kìlómítà kan ni, nítorí pé kò jinlẹ̀ ló sì mú kí ó ṣọṣẹ́ gidigidi. Liu Xiu-Xia, tó ń gbé nítòsí ibi tí ìsẹ̀lẹ̀ yẹn ti ṣẹlẹ̀ gan-an sọ pé: “Ìmìtìtì ńláǹlà yẹn ló jí mi. Àwọn ohun èlò ilé ń já bọ́, kódà iná mànàmáná tó ń bẹ lára àjà ilé pàápàá já lulẹ̀. Mi ò lè jáde nítorí pé àwọn nǹkan tó já lulẹ̀ àti dígí tó fọ́ ti dí ojú ọ̀nà.” Ìṣòro tí Huang Shu-Hong, tí ìsẹ̀lẹ̀ náà jù sọnù látorí bẹ́ẹ̀dì, bá pàdé yàtọ̀. Ó wí pé: “Ojú ẹsẹ̀ ni iná mànàmáná kú, lòkùnkùn biribiri bá bolẹ̀. Mo táràrà jáde, ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò mi ni mo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà títí tí ilẹ̀ fi mọ́. Ó dà bíi pé ṣe ni ilẹ̀ ń mì tìtì ṣáá.”
Ìsapá Láti Gba Ẹ̀mí Là
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ọṣẹ́ tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ṣe fara hàn gbangba. Àwọn ilé tó wó tó ẹgbẹ̀rún méjìlá, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì títí dórí àwọn ilé alájà púpọ̀. Bí ìròyìn àjálù náà ṣe ń tàn kálẹ̀, àwọn ògbóǹtagí tó máa ń gba ẹ̀mí là láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún wá sí Taiwan láti ran àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn lórílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí ni àwọn pàǹtírí kò tíì jẹ́ kí wọ́n ráyè jáde.
Ó máa ń ṣe pàtàkì pé, láàárín wákàtí méjìléláàádọ́rin tí jàǹbá kan bá ṣẹlẹ̀, kí wọ́n wá àwọn tí ó lè là á já, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là rí àwọn ohun tó yà wọ́n lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n rí ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́fà kan fà jáde lẹ́yìn tí kò ti ráyè jáde fún wákàtí mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún. Ní Taipei pẹ̀lú, nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ń fi ẹ̀rọ ńlá kó àwókù ilé alájà méjìlá tí àwọn èèyàn ń gbé, tó wó lulẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin kan ṣàdédé jáde. Ó ju ọjọ́ márùn-ún lọ tí òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin ti há sí ibẹ̀, àwọn méjèèjì ló sì la àjálù ọ̀hún já!
Ṣùgbọ́n, ó ṣeni láàánú pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ṣeé ṣe láti fà jáde, àwọn ìgbà kan sì wà tí àwọn òṣìṣẹ́ tí ń gba ẹ̀mí là rí ohun tó bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ gidigidi. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ayọni-nínú-ewu kan kédàárò pé: “A gbọ́ tí ọmọ kan ń ké títí di wákàtí mẹ́jọ sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́.” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, iye àwọn tó kú ní Taiwan lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àti ọ̀ọ́dúnrún, ó sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àbọ̀ tó fara pa.
Kíkojú Àbájáde Rẹ̀
Wọ́n sapá takuntakun láti pèsè ibùgbé fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti ba ilé wọn jẹ́. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn kan lára àwọn tí ọ̀ràn ṣẹlẹ̀ sí kò fẹ́ padà sínú ilé. A ò kúkú lè bá wọn wí, nítorí láàárín ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn tí ìsẹ̀lẹ̀ náà kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìmìtìtì pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó tún ṣẹlẹ̀! Ọ̀kan lára àwọn ìmìtìtì náà wọn 6.8 lórí òṣùwọ̀n Richter, ó sì wó ọ̀pọ̀ àwọn ilé tí kò lágbára mọ́ tẹ́lẹ̀ lulẹ̀.
Bó ti wù kí ó rí, iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ ń bá a nìṣó. Àwọn àjọ kan tí kì í ṣe ti ìjọba—títí kan àwọn ẹgbẹ́ tí ń gba ẹ̀mí là tí wọ́n jẹ́ ti ilẹ̀ òkèèrè, ẹgbẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn Búdà tí ń jẹ́ Tzu Chi, àti àwọn panápaná—lo àkókò àti òye wọn fún ṣíṣe iṣẹ́ náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú kópa nínú iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ yìí. Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà ní Gálátíà 6:10, góńgó méjì ni wọ́n ní. Wọ́n fẹ́ láti (1) pèsè fún àwọn tó bá wọn tan nínú ìgbàgbọ́, àti (2) kí wọ́n ṣe rere sí gbogbo ènìyàn, títí kan àwọn tí kì í ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe.
Nígbà tó fi di òpin ọjọ́ kìíní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí fi ọkọ̀ ẹrù kó oúnjẹ, omi, àgọ́, àti àwọn èlò tí èèyàn fi ń se oúnjẹ ní ìta wá. Níwọ̀n bí gbogbo àwọn ohun ìbánisọ̀rọ̀ ti bà jẹ́, àwọn alàgbà láti ìjọ mẹ́fà tó wà ní àgbègbè tí ọ̀ràn kan náà jọ sapá láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn àti ìdílé wọn rí, títí kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn. Wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí tí kò nílé mọ́ níṣìírí láti tẹ̀dó sí ojú kan náà kí wọ́n lè bójú tó gbogbo wọn dáadáa, kí ó sì lè rọrùn láti rí wọn. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Taiwan ṣèbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ àwùjọ àti ìjọ kọ̀ọ̀kan láti fún wọn níṣìírí.
Títún àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ ṣe ni ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé lẹ́yìn náà. Ìjọ kọ̀ọ̀kan kọ orúkọ àwọn tó ń fẹ́ ìrànwọ́. Lẹ́yìn náà, lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, wọ́n rán àwùjọ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni lọ láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Láàárín oṣù kan lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n parí iṣẹ́.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ṣèrànwọ́ fún àwọn aládùúgbò wọn tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé ìwòsàn àti ibi tí àwọn èèyàn pàgọ́ sí láti tù wọ́n nínú. Wọ́n tún pín ẹ̀dà àpilẹ̀kọ kan tó ní àkọlé náà, “Àwọn Ìjábá Àdánidá—Ríran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Wọn,” tí a tẹ̀ jáde nínú Jí!, June 22, 1996. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fi ìmoore hàn pé àwọn rí ìsọfúnni yìí gbà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á lójú ẹsẹ̀. Bí ọ̀nà ti ń ṣí sílẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi àwọn ọkọ̀ ẹrù tó kó onírúurú ìpèsè ránṣẹ́ sí àwọn àgbègbè olókè ńlá, tí wọ́n wà ní àdádó, tí ìsẹ̀lẹ̀ náà bà jẹ́ gidigidi.
Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ó pẹ́ tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “ìsẹ̀lẹ̀ . . . láti ibì kan dé ibòmíràn” yóò sàmì sí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (Mátíù 24:7) Ṣùgbọ́n, Bíbélì tún mú un dá wa lójú pé láìpẹ́, lábẹ́ àkóso alálàáfíà ti Ìjọba Ọlọ́run, aráyé kò tún ní máa gbé ìgbé ayé wọn kí wọ́n sì máa bẹ̀rù àjálù mọ́. Ní àkókò yẹn, Párádísè ni ilẹ̀ ayé yìí yóò jẹ́ lóòótọ́.—Aísáyà 65:17, 21, 23; Lúùkù 23:43.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láìdà bí èyí, ìsẹ̀lẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́ tó ṣẹlẹ̀ ní Turkey ní August 1999 wọn 7.4, síbẹ̀, ó kéré tán, iye àwọn èèyàn tó pa fi ìlọ́po méje ju ti èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Taiwan lọ.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àwọn ìpàdé wọn nígbà tí wọ́n ń gbé ní àgọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìsẹ̀lẹ̀ náà ba ọ̀pọ̀ ojú ọ̀nà jẹ́
[Credit Line]
San Hong R-C Picture Company
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
San Hong R-C Picture Company
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Àkọsílẹ̀ nípa ìmìtìtì ilẹ̀ lójú ìwé 23 sí 25: Àwọn fígọ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Berkeley Seismological Laboratory