Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Èé Ṣe Tí Mo Fi Rí Tẹ́ẹ́rẹ́ Báyìí?
JUSTIN jẹ́ èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́, ara rẹ̀ sì le, ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kò dùn bó ṣe rí yẹn. Ó sọ pé: “Mo ń gbìyànjú láti sanra díẹ̀.” Nítorí náà, ẹ̀ẹ̀marùn-ún ló ń jẹun lójúmọ́ báyìí, ìyẹn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin kálórì lápapọ̀. Ṣùgbọ́n ó kàn fẹ́ kí iṣu ẹran ara òun ki sí i ni. Ìdí nìyẹn tó tún fi sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan máa ń jí ní ìdájí kí iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ láti lọ gbé irin.”
Vanessa pẹ̀lú jẹ́ èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n bó ṣe rí tẹ́ ẹ lọ́rùn. Vanessa sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì kéré, àwọn ọmọdé ẹgbẹ́ mi sábà máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á sì máa pè mí ní atẹ́ẹ́rẹ́-máà-ṣẹ́. Ṣùgbọ́n mi ò dààmú ara mi nípa ìyẹn mọ́. Mo ti fara mọ́ bí mo ṣe rí.”
‘Fara mọ́ bí o ṣe rí.’ Ìmọ̀ràn rere nìyẹn o. Ṣùgbọ́n ó lè máà jẹ́ ìmọ̀ràn tó rọrùn fún ọ láti gbà. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba kan, o lè wà ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe.” (1 Kọ́ríńtì 7:36) Ní pàtàkì, àkókò tí ìrísí máa ń yí padà bìrí yẹn, tí a ń pè ní àkókò ìbàlágà kún fún rúkèrúdò gan-an. Ní àkókò ìbàlágà, bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀yà ara rẹ ṣe ń yára dàgbà lè yàtọ̀ síra; ìrísí apá, ẹsẹ̀, àti ti ojú rẹ lè dà bí èyí tí kò bára jọ.a Èyí lè mú kí o máa nímọ̀lára pé ńṣe ni o rí wúruwùru, tí o sì burẹ́wà. Òótọ́ ọ̀rọ̀ mìíràn tún ni pé kì í ṣe bákan náà ni gbogbo èwe ṣe máa ń yára dàgbà. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn ẹgbẹ́ rẹ ti taagun tàbí kí wọ́n ti ní ìrísí obìnrin tó ti bàlágà, síbẹ̀ kí ó ṣì jọ pé ìwọ rí tẹ́ẹ́rẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun púpọ̀ làwọn èèyàn ti sọ nípa àwọn èwe tí wọ́n rò pé àwọn ti sanra jù, àmọ́ wọ́n sábà máa ń gbójú fo àwọn èwe tí wọ́n rò pé àwọn rí tẹ́ẹ́rẹ́ jù. Ó lè jẹ́ pé bí ọ̀ràn ṣe rí gan-an nìyẹn láàárín àwọn ẹ̀yà kan àti ní àwọn orílẹ̀-èdè kan níbi tí wọn kì í ti í ka jíjẹ́ ẹni tẹ́ẹ́rẹ́ sí àmì pé èèyàn lẹ́wà. Ní irú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀, wọ́n lè máa fi ọmọbìnrin tó bá rí tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ pé ó “gbẹ.”
Àwọn ọmọkùnrin wa ńkọ́ o? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí olùwádìí Susan Bordo sọ, “ìwádìí tí a ṣe ní àwọn ẹ̀wádún tó ṣáájú ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1980, nípa ohun tí àwọn obìnrin rò nípa ìrísí wọn, fi hàn pé tí àwọn obìnrin bá wo ara wọn nínú dígí, àbùkù nìkan ṣáá ni wọ́n máa ń rí.” Àwọn ọkùnrin ńkọ́? Bordo ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí àwọn ọkùnrin bá wo dígí, wọ́n á ní àwọn jojú ní gbèsè tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ní àwọn dára ju bí àwọ́n ṣe rí gan-an lọ.” Ṣùgbọ́n ní ẹnu àìpẹ́ yìí, ìyẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí yí padà. Àwọn ọkùnrin lé ní ìdá mẹ́rin lára gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ láti mú kí ojú wọn gún régé, Bordo sọ pé ìdí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin fi ń fẹ́ láti ní ìrísí tó jojú ní gbèsè ní báyìí jẹ́ nítorí pé wọ́n ń rí àwòrán àwọn ọmọkùnrin tó ní ìrísí “tó gbayì,” nínú ìpolówó àwọn aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, èyí ti ní ipa lórí àwọn ọmọdékùnrin. Wọ́n lè rò pé nǹkan ń ṣe àwọn bí àwọn kò bá taagun bíi tàwọn ọkùnrin afìmúra-polówó-ọjà.
Nítorí náà, bí o bá jẹ́ èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló ń ṣe mí?’ Ohun ìdùnnú nípa rẹ̀ ni pé ó lè jẹ́ pé nǹkan kan kò ṣe ọ́.
Ìdí Tí O Fi Rí Tẹ́ẹ́rẹ́
Lójú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́, kò sí ohun tó burú nínú jíjẹ́ èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó wulẹ̀ máa ń jẹ́ àbájáde ìyípadà bìrí tó máa ń bá ìdàgbàsókè rìn ni àti ìyípadà àwọn kẹ́míkà inú ara tó máa ń yára ṣẹlẹ̀ lákòókò ìṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà. Bó ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀, bí ìyípadà kẹ́míkà ara rẹ ṣe ń yára sí yóò dín kù bí o ṣe ń dàgbà sí i. Bó ti wù kó rí, bó bá ṣẹlẹ̀ pé o rí tẹ́ẹ́rẹ́ jù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ń jẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore, yóò dára kí o lọ rí dókítà rẹ kí o lè mọ̀ bóyá o ní àrùn kan lára ni, àrùn bí àtọ̀gbẹ tó lè mú kí èèyàn rù hangogo.
Steven Levenkron, tí í ṣe gbajúmọ̀ ògbógi tó mọ̀ nípa ìṣòro àṣà ìjẹun, sọ fún Jí! pé: “Mo rántí ọ̀dọ́bìnrin kan tó rí tẹ́ẹ́rẹ́ gan-an, tí wọ́n ní kó wá gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ mi nítorí pé ó ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra, béèyàn bá wò ó, ṣe ló dà bí ẹni tó ní ìṣòro àṣà ìjẹun lóòótọ́. Ṣùgbọ́n, mo wá rí i pé ìṣòro nípa ìrísí ló ní, kì í ṣe ti ìrònú òun ìhùwà. Dókítà tó ń tọ́jú ìdílé rẹ̀ kò mọ̀ pé ó ní àrùn Crohn lára, àrùn tó máa ń wà nínú ìfun. Àṣìṣe yẹn ì bá pa ọ̀dọ́bìnrin náà.” Bí o bá ní àrùn àtọ̀gbẹ tàbí àrùn èyíkéyìí tó ń mú kí o rù hangogo, yóò bọ́gbọ́n mu kí o fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn dókítà rẹ.
Àmọ́ ṣá o, nígbà mìíràn tí èèyàn bá rí tẹ́ẹ́rẹ́, ó lè jẹ́ àmì pé ó ní ìdààmú ọkàn ni. Nínú ìwé tí Dókítà Levenkron kọ tí ń jẹ́ Anatomy of Anorexia, ó sọ ohun tí àwọn olùwádìí kan sọ, pé ọ̀pọ̀ “àwọn alárùn àtọ̀gbẹ tí wọ́n ń gba abẹ́rẹ́ insulin láti máa fi gbéra ló ní ìṣòro àṣà ìjẹun, láti orí ìṣòro àjẹjù dé orí ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra.” Oníṣègùn kan tó tóótun lè mọ̀ bí ẹnì kan bá ní irú ìṣòro àṣà ìjẹun bẹ́ẹ̀.b
Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Gbéṣẹ́
Ká sọ pé o ti lọ rí dókítà rẹ, tí o ṣì rí tẹ́ẹ́rẹ́ síbẹ̀, ṣùgbọ́n tí ara rẹ le. Kí wá ló yẹ kí o ṣe? Nínú Jóòbù 8:11, Bíbélì sọ pé: “Òrépèté ha lè dàgbà sókè láìsí ibi irà? Esùsú ha lè di ńlá láìsí omi?” Bó ṣe jẹ́ pé ohun ọ̀gbìn máa ń hù dáadáa tí wọ́n bá gbìn ín síbi tó yẹ tó sì ń rí èròjà tó yẹ ni ìwọ alára nílò oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ pé bí o bá fẹ́ dàgbà di àgbàlagbà tí ara rẹ̀ le. Èyí ṣe pàtàkì yálà o ń gbìyànjú láti sanra tàbí láti fọn.
Ṣùgbọ́n ṣá o, máà wá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àjẹjù oúnjẹ ọlọ́ràá nítorí kóo lè tètè sanra. Nígbà tí ògbógi onímọ̀ nípa oúnjẹ náà, Susan Kleiner ń ṣe ìwádìí nípa oúnjẹ táwọn tó ń ṣe eré ìmárale ń jẹ, ó rí i pé wọ́n ń jẹ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà kálórì lóòjọ́! Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Kleiner ti sọ, “ohun tó ń rúni lójú nípa ìwádìí yìí ni pé, ní ìpíndọ́gba, wọ́n máa ń jẹ ju igba gíráàmù ọ̀rá lọ lóòjọ́. Ìyẹn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀rá tó wà nínú bọ́tà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọgọ́fà àti márùn-ún gíráàmù! Láàárín sáà kúkúrú, ìyẹn ti tó láti mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ṣàìsàn. Béèyàn bá sọ jíjẹ ọ̀rá tó pọ̀ tó ìyẹn dàṣà láàárín sáà kan, ó lè fa àrùn ọkàn.”
Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà (USDA) ti sọ, lájorí oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ pé ni oúnjẹ tó ní àwọn èròjà onítááṣì nínú bíi búrẹ́dì, ọkà, ìrẹsì, àti oúnjẹ alápòpọ̀. Èyí tó tún ṣe pàtàkì tẹ̀ lé e ni ewébẹ̀ àti èso. Ẹ̀ka USDA dámọ̀ràn pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni kí èèyàn máa jẹ ẹran àti àwọn oúnjẹ tí ń wá láti ara ẹran ọ̀sìn.
Láti lè ṣọ́ oúnjẹ jẹ, o lè gbìyànjú láti ṣàkọsílẹ̀ bóo ṣe ń jẹun. Máa kọ gbogbo ohun tí o bá jẹ láàárín ọ̀sẹ̀ kan àti ìgbà tí o jẹ́ wọ́n sínú ìwé kan. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí i pé o kì í jẹun tó bóo ṣe rò rárá, ní pàtàkì tí o kì í bá dúró sójú kan. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba tí ara rẹ̀ jí pépé, ara rẹ lè tètè lo ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kálórì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lójúmọ́! O tún lè rí i pé àwọn èròjà aṣaralóore inú àwọn oúnjẹ tí o ń jẹ kò pọ̀ tó bó ṣe yẹ, ìyẹn ni pé bóyá àwọn oúnjẹ àrójẹ, bíi búrẹ́dì tí wọ́n fi ẹran sáàárín rẹ̀ àti búrẹ́dì tí wọ́n kó ewébẹ̀ àti wàràkàṣì sínú rẹ̀ pọ̀ jù, tí èso àti ewébẹ̀ kò sì pọ̀ tó.
Àwọn èròjà tí ń ṣàlékún oúnjẹ tí àwọn náà wọ́n ńkọ́? O lè máà nílò wọn. Ọ̀pọ̀ ògbógi gbà gbọ́ pé o lè rí gbogbo èròjà aṣaralóore tí ara rẹ nílò tóo bá ń jẹ àwọn oúnjẹ tó gbámúṣé. Lékè gbogbo rẹ̀, má ṣe máa lo àwọn oògùn tí ń jẹ́ kí iṣu ara tóbi bí àwọn oògùn aleṣan. Ó bani nínú jẹ́ pé lílo àwọn oògùn aleṣan nílòkulò kì í wulẹ̀ ṣe ìṣòro tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọmọdékùnrin ọ̀dọ́langba nìkan. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Iye àwọn ọmọdébìnrin tí ń lo [àwọn oògùn aleṣan], tí àwọn kan lára àwọn olùwádìí sọ pé lọ́nà kan, ó jẹ́ oríṣi òdì kejì ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra, ti ń pọ̀ gan-an tó iye àwọn ọmọdékùnrin tí ń lò ó láàárín ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1980.” Ó bani lẹ́rù gan-an pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́sàn-án [175,000] àwọn ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló jẹ́wọ́ pé àwọn ń lo àwọn oògùn aleṣan. Ọ̀pọ̀ nǹkan búburú ló ń tìdí lílo àwọn oògùn wọ̀nyí yọ, títí kan híhu irùngbọ̀n, kí nǹkan oṣù máa tàsé, jẹjẹrẹ ọmú tó máa ń ṣe àwọn obìnrin, jẹjẹrẹ inú okùn àpòòtọ̀ ọkùnrin, àti òpójẹ̀ dídí àti jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀ tó ń ṣe tọkùnrin tobìnrin. Má ṣe lo àwọn oògùn aleṣan láìjẹ́ pé dókítà kọ ọ́ fún ọ tó sì ń ṣàyẹ̀wò rẹ bóo ti ń lò ó.
Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà, Kí O sì Ní Èrò Tó Yẹ
Bíbélì ní ká jẹ́ ‘ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run wa rìn.’ (Míkà 6:8) Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà kan mímọ ibi tí agbára ẹni mọ. Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ni yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní èrò tó yẹ nípa ìrísí rẹ. A kò sọ pé ó burú láti fẹ́ ní ìrísí tó jojú ní gbèsè o. Ṣùgbọ́n jíjẹ́ kí ìrísí ẹni jẹni lọ́kàn kò ṣeni láǹfààní kankan—àfi tó bá máa ṣe àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ohun ìṣoge àti àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe oúnjẹ láǹfààní. Àwọn ògbógi onímọ̀ nípa ìrísí tó dára gbà pé bó ti wù kí ọkùnrin kan ṣe máa jẹun dáadáa tó, kí ó sì máa ṣeré ìmárale gidigidi tó, kò ní taagun bí kò bá ní apilẹ̀ àbùdá èyí tẹ́lẹ̀. Bó bá sì jẹ obìnrin ni ọ́, ó lè má sanra, láìka bí o bá ṣe jẹun tó sí.
Ó dùn mọ́ni pé fífún àwọn aṣọ tí o ń wọ̀ láfiyèsí díẹ̀ lè ṣèrànwọ́ gan-an láti mú ohun tí o lè máa ronú pé ó jẹ́ ìrísí tí kò bójú mu kúrò. Má ṣe máa wọ àwọn aṣọ tó ń pe àfiyèsí tí kò yẹ sí irú ìrísí tí o kò fẹ́ yẹn. Àwọn kan dámọ̀ràn wíwọ aṣọ aláwọ̀ títàn nítorí pé aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ṣú máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́ dà bíi pé wọ́n rí tẹ́ẹ́rẹ́ sí i.
Rántí pẹ̀lú pé àkópọ̀ ìwà rẹ ṣe pàtàkì gan-an ju ìrísí rẹ lọ. Níkẹyìn, ẹ̀rín músẹ́ tó ń fani mọ́ra àti ìwà inú rere sáwọn èèyàn yóò túbọ̀ jẹ́ kí o wu àwọn ẹlòmíràn ju iṣu ẹran ara tó yọ lọ tàbí irú aṣọ kan ní pàtó. Bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ń fojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ léraléra nítorí ìrísí rẹ, wá àwọn èèyàn tó mọyì rẹ nítorí ohun tí o jẹ́ nínú—nítorí ohun tí Bíbélì pè ní “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.” (1 Pétérù 3:4) Paríparí rẹ̀, má ṣe gbàgbé pé “ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Mo Ha Ń Dàgbà Lọ́nà Wíwàdéédéé Bí?” nínú Jí!, September 22, 1993.
b Wo àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Èrò Bí Mo Ṣe Tóbi Tó Fi Gbà Mí Lọ́kàn?” àti “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ọ̀ràn Sísanra Tó Gbà Mí Lọ́kàn?,” nínú ìtẹ̀jáde wa ti May 8, àti June 8, 1999.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Àwọn èwe kan ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ara wọn nítorí pé wọ́n rí tẹ́ẹ́rẹ́