ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 10/8 ojú ìwé 22-23
  • Àwọn Òkè Aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ní Mẹ́síkò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Òkè Aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ní Mẹ́síkò
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Teotihuacán—“Ìlú Àwọn Ọlọ́run”
  • Àwọn Ibòmíràn Tí Òkè Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ Wà
  • Àwọn Maya Rí Òmìnira Tòótọ́ Gbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Sísìn Tọkàntọkàn Lójú Onírúurú Àdánwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àwọn Èèyàn Aztec Òde Òní Di Kristẹni Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 10/8 ojú ìwé 22-23

Àwọn Òkè Aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ní Mẹ́síkò

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ

Ọ̀PỌ̀ jù lọ àwọn èèyàn lónìí ló mọ̀ nípa àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ní Íjíbítì. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà pẹ̀lú, àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó dà bí òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀, pàápàá ní Mẹ́síkò. Bíi ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ní Íjíbítì, àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó jẹ́ ti àwọn ará Mẹ́síkò ti wà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àràmàǹdà sì lọ̀ràn wọn jẹ́.

Òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ti àwọn ará Íjíbítì jẹ́ ibojì tí wọ́n fi òkúta ńláńlá yí po lọ sókè. Àwọn ọ̀nà àbákọjá inú rẹ̀ lọ́hùn-ún ló lọ sínú ibojì náà, tó jẹ́ ibi tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ti àwọn ará Mẹ́síkò jẹ́ òkìtì iyẹ̀pẹ̀ ńláǹlà tó ní tẹ́ńpìlì kan lórí rẹ̀, ó sì ní àtẹ̀gùn kan níta tó ń jẹ́ kí èèyàn lè gun orí rẹ̀. Àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ to wà ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà sì yàtọ̀ díẹ̀, wọn kì í ṣe ibojì.

Teotihuacán—“Ìlú Àwọn Ọlọ́run”

Ọ̀kan nínú àwọn ibi tí a ti lè rí òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó gba iwájú jù lọ ní Mẹ́síkò ni Teotihuacán. Teotihuacán tó wà ní nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà ní ìhà àríwá Ìlú Ńlá Mẹ́síkò ṣì jẹ́ àràmàǹdà lójú àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, àti àwọn awalẹ̀pìtàn. Àwọn tó ń kọ́ olú ìlú ìgbàanì náà pa á tì ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ṣáájú kí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn èèyàn Aztec tó bẹ̀rẹ̀. Orúkọ náà, Teotihuacán, wá látinú èdè Nahuatl, tó túmọ̀ sí “Ìlú Àwọn Ọlọ́run” tàbí “Ibi Tí Àwọn Èèyàn ti Di Àwọn Ọlọ́run.” Àwọn kan ronú pé àwọn èèyàn Aztec ló fún ìlú náà lórúkọ yìí nígbà tí wọ́n ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.

George Stuart, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóòtú ìwé ìròyìn National Geographic, ṣàlàyé pé, “Teotihuacan ni ìlú ńlá àkọ́kọ́ ní ti gidi ní Ìlàjì Ilẹ̀ Ayé ní Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn . . . Ó bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì Kristẹni, ó sì wà fún nǹkan bíi ọ̀rúndún méje, lẹ́yìn náà ló wá di nǹkan ìtàn. Nígbà tó fi láásìkí jù lọ, ní nǹkan bí ọdún 500 Sànmánì Tiwa, wọ́n díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn èèyàn tó gbé ibẹ̀ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gọ́fà [125,000] sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba [200,000].”

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àárín ìlù náà ni Òkè Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ti Oòrùn wà. Ìsàlẹ̀ rẹ̀ fẹ̀ tó okòólérúgba [220] mítà níbùú àti igba ó lé márùndínlọ́gbọ̀n [225] mítà lóròó, tí ìpele títẹ́jú márùn-ún tó ní sì wá ga sókè dé ibi tó ga dé nísinsìnyí tó jẹ́ nǹkan bíi mítà mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63]. Láti lè dé orí òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ náà, èèyàn á gùn tó òjìlérúgba [240] àtẹ̀gùn. Òkè Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ti Òṣùpá wà ní àríwá ìlú àtijọ́ yìí, tí orí rẹ̀ sì ga tó ogójì mítà. Ìgbà kan wà tí àwọn tẹ́ńpìlì wà lórí àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ méjì tó ṣe pàtàkì jù lọ wọ̀nyí.

Láwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, ohun púpọ̀ la ti mọ̀ nípa àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Stuart ṣe sọ, “agbára káká la fi mọ ohunkóhun nípa ibi tí àwọn ará Teotihuacan ti ṣẹ̀ wá, èdè tí wọ́n sọ, bí wọ́n ṣe ṣètò àwùjọ wọn, àti ohun tó fà á tí wọ́n fi pòórá.”

Àwọn Ibòmíràn Tí Òkè Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ Wà

Láàárín Ìlú Ńlá Mẹ́síkò gan-an, èèyàn lè ṣèbẹ̀wò sí Tẹ́ńpìlì Pàtàkì ti àwọn èèyàn Aztec. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn kò ní rí òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ níbẹ̀, èèyàn lè rí àwókù òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ náà tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún tẹ́ńpìlì pàtàkì yẹn. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí pẹpẹ méjì tí wọ́n ti máa ń fi èèyàn rúbọ níbẹ̀.

Chichén Itzá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tí àwọn èèyàn máa ń ṣèbẹ̀wò sí jù lọ ní Mẹ́síkò. Ọ̀pọ̀ àwókù ìgbàanì ló wà ní ẹkùn ilẹ̀ àwọn Maya, ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí lèèyàn lè tètè dé ìdí wọn jù lọ nítorí pé tòsí ìlú Mérida ní Yucatán, ni wọ́n wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpínlẹ̀ àwọn Maya ni wọ́n kọ́ wọn sí, ìgbékalẹ̀ wọn fi hàn pé àwọn èèyàn Nahuatlan ní ipa gidigidi lórí àwọn ẹkùn ilẹ̀ wọ̀nyí nígbà kan rí. Àwọn ilé kan fi hàn pé àwọn tó kọ́ wọn mọ̀ nípa ìṣirò gidigidi, wọ́n sì ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa sánmà.

Ní Palenque, àwọn olùṣèbẹ̀wò lè rí ilé àwọn èèyàn Maya tí igbó Chiapas bò. Ààfin àti Tẹ́ńpìlì Àwọn Ìkọ̀wé wà lára ọ̀pọ̀ àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ àtàwọn ilé tó wà níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The Mayas—3000 Years of Civilization, ti sọ, Tẹ́ńpìlì Àwọn Ìkọ̀wé “jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tẹ́ńpìlì tó gbajúmọ̀ jù lọ ní gbogbo ẹkùn ilẹ̀ Gúúsù Àríwá Amẹ́ríkà nítorí pé kì í ṣe pé ó wulẹ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ fún tẹ́ńpìlì kan gẹ́gẹ́ bíi ti gbogbo àwọn yòókù ni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìrántí ìsìnkú. Nínú rẹ̀, àtẹ̀gùn abẹ́lẹ̀ wà tó lọ sísàlẹ̀ síbi ìyẹ̀wù ìsìnkú tó jẹ́ ọlọ́lá ńlá jù lọ tí a tíì rí ní àgbègbè Maya.” Ṣe ni wọ́n kọ́ ibojì náà fún gómìnà kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹrin, tó ń jẹ́ Pacal, tàbí Uoxoc Ahau.

Díẹ̀ ni ìwọ̀nyí lára àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó wà ní Mẹ́síkò. A lè rí àwọn àwókù àti àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ mìíràn ti àwọn ará Gúúsù Àríwá Amẹ́ríkà níbi púpọ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ńlá tún wà ní Guatemala àti Honduras. Gbogbo ilé ìgbàanì wọ̀nyí fi hàn pé àwọn olùgbé Gúúsù Àríwá Amẹ́ríkà fẹ́ràn ilẹ̀ tó ga, tí wọ́n lè kọ́ àwọn ibi ìjọsìn wọn sórí rẹ̀. Walter Krickeberg, tó ṣe ìwé Las Antiguas Culturas Mexicanas, kọ̀wé pé: “Àṣà kíkọ́ àwọn tẹ́ńpìlì sórí ìpìlẹ̀ tó ní àtẹ̀gùn bẹ̀rẹ̀ látayé ọjọ́un nígbà tí àwọn èèyàn ń jọ́sìn àwọn ibi gíga.” Ó fi kún un pé: “Nígbà tí àwa ní tiwa ronú pé ọ̀run dà bí ‘ibojì,’ àwọn ẹlòmíràn gbà pé ṣe ló dà bí òkè nípasẹ̀ èyí tí oòrùn fi ń yọ ní òwúrọ̀, tí yóò sì wọ̀ ní ìrọ̀lẹ́; nítorí náà, pé ńṣe ni gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ rẹ̀ ní àtẹ̀gùn gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ilé ńlá. Nípa báyìí, wọ́n sọ ‘òkè àtọwọ́dá’ náà . . . di òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó ní àtẹ̀gùn, bí a sì ṣe gbọ́ ọ nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu, tí a sì rí i nínú àṣà, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Gúúsù Àríwá Amẹ́ríkà ló sọ ọ́ di àmì ọ̀run.”

Èròǹgbà yìí lè rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì létí àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Ilé Gogoro Bábélì, tó wà ní ìlú tí a wá mọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn sí Bábílónì. Jẹ́nẹ́sísì 11:4 sọ nípa àwọn tó kọ́ ilé gogoro yẹn pé: “Wọ́n sọ wàyí pé: ‘Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú ńlá kan dó fún ara wa kí a sì tún kọ́ ilé gogoro tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run, ẹ sì jẹ́ kí a ṣe orúkọ lílókìkí fún ara wa.’” Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àwọn ìgbékalẹ̀ òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tí ń jẹ́ tẹ́ńpìlì ilẹ̀ Mesopotámíà tí ó jẹ́ ipele-ipele àgbékà aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ní ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí àwọn àwókù ti Bábílónì.

Irú ìjọsìn tó bẹ̀rẹ̀ ní Bábílónì tàn dé apá ibi púpọ̀ láyé, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó dé ẹkùn ilẹ̀ tí a wá mọ̀ sí Mẹ́síkò. Kò ní yani lẹ́nu bó bá jẹ́ pé tẹ́ńpìlì tí ó jẹ́ ipele-ipele àgbékà aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ti Bábílónì títí kan ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀, ni àwòfiṣàpẹẹrẹ fún àwọn òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ àràmàǹdà tí ń gbàfiyèsí, tó wà ní Mẹ́síkò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Teotihuacán

[Credit Line]

CNCA.-INAH.-MEX Reproducción Autorizada por el Instituto Nacional de Antropología e Historia

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Palenque

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́