Wíwo Ayé
Àwọn Àrùn Aṣekúpani ní Australia
Ìwé agbéròyìnjáde Herald Sun ti Melbourne sọ pé: “Iye àwọn ará Australia tí àwọn àrùn tí ó jẹ mọ́ àrùn AIDS ń pa ti dín kù fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà tí a ti ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tí fáírọ́ọ̀sì náà ń ṣe.” Tí a bá gbé ìwádìí náà karí ìsọfúnni oníṣirò tí a gbé jáde láìpẹ́ yìí láti Ọ́fíìsì Àkójọ Ìsọfúnni Oníṣirò ní Australia, ó fi hàn pé, ènìyàn 666 ni àrùn AIDS pa ní 1995—tí ó fi ìpín 13 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù. Àpapọ̀ iye àwọn tí ń kú ní orílẹ̀-èdè náà fi ìpín 4 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù, tí àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn sì jẹ́ okùnfà ikú tí ó gba iwájú síbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iye àwọn ará Australia tí ń pọ̀ sí i ni àrùn ọdẹ orí abọ́jọ́-ogbó-rìn àti àwọn àrùn míràn tí ó tàn mọ́ àrùn wèrè ń pa nísinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé àpapọ̀ orílẹ̀-èdè fún Ẹgbẹ́ Tí Ń Rí Sí Ọ̀ràn Àrùn Ọdẹ Orí Abọ́jọ́-Ogbó-Rìn ní Australia ti sọ, “ohun tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa pípọ̀ tí àwọn wèrè ń pọ̀ sí i lọ́nà yíyára kánkán yóò gbé ipa ńlá kan karí àwọn ohun èlò ìtọ́jú tó wà, tí a pète láti fi ran àwọn alárùn àti àwọn tí ń tọ́jú wọn lọ́wọ́.”
Ohun Tí Àwọn Ènìyàn Rò Nípa Ọjọ́ Ọ̀la
Bí ọ̀rúndún kọkànlélógún ti ń sún mọ́lé, àwọn ènìyàn ń ro oríṣiríṣi nípa ọjọ́ ọ̀la. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu-wò kan tí ìwé ìròyìn Newsweek ṣe ní United States, ó bi àwọn ènìyàn léèrè nípa ohun tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún ní ọ̀rúndún tí ń wọlé bọ̀. Nǹkan bí ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ti a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn arìnrìn-àjò sánmà yóò rìn lórí pílánẹ́ẹ̀tì Máàsì. Nǹkan bí ìpín 55 nínú ọgọ́rùn-ún ló retí pé ẹ̀dá ènìyàn yóò lọ máa gbé àwọn ibòmíràn nínú àgbáálá ayé. Ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ronú pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ yóò rí ìwòsàn fún àrùn AIDS, ìpín 72 nínú ọgọ́rùn-ún sì sọ tẹ́lẹ̀ pé, a óò ní ìwòsàn fún àrùn jẹjẹrẹ. Lọ́nà àìfojúsọ́nà-fún-rere, ìpín 73 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló rí àrítẹ́lẹ̀ àlàfo tí yóò fẹ̀ sí i láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn aláìní, tí ìpín 48 nínú ọgọ́rùn-ún sì fojú sọ́nà fún ogun púpọ̀ sí i ju èyí tí ó ti jà ní 100 ọdún tó kọjá lọ. Nǹkan bí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ronú pé, ènìyàn kò ní lè mú ebi kúrò.
Hílàhílo Ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ Kan
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn FDA Consumer ti sọ, ìṣẹ̀lẹ̀ ìpalára ìjóni iná àti bí ó ṣe le tó ní United States ti dín kù lọ́nà tí ó lámì láàárín 20 ọdún tó kọjá. Ìwọ̀n àwọn tí iná jó, tí wọ́n sì làájá ti gbé pẹ́ẹ́lí sí i pẹ̀lú. Òṣìṣẹ́ kan nínú Àjọ Abójútó Oúnjẹ àti Oògùn, Charles Durfor, sọ pé, “ní ọgbọ̀n ọdún sí ogójì ọdún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ àwọn tí iná jó, tí a tọ́jú kò làájá. Ìtẹ̀síwájú nínú ọ̀nà ìtọ́jú ti ṣẹ̀dá àwùjọ àwọn tí iná jó tí a tọ́jú, tí kì í ṣe pé wọ́n la hílàhílo náà já nìkan ni, àmọ́ tí wọ́n ní ojúlówó ìgbésí ayé tí ń sunwọ̀n sí i.” Lọ́dọọdún, ó lé ní 50,000 ará America tí ń jìyà ìjóni iná tí ó béèrè pé kí wọ́n wà ní ilé ìwòsàn. Gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Tí Ń Rí Sí Ọ̀ràn Ìjóni Iná ní America ti sọ, nǹkan bí 5,500 ẹni tí iná jó ló ń kú. Ìwé ìròyìn FDA Consumer náà sọ pé: “Ìjóni kan tí ó pọ̀ gan-an jẹ́ ọ̀kan lára àwọn hílàhílo ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ jù lọ tí ó lè jẹ ara níyà.”
Jìbìtì “Tí Kò Lábòsí”
Àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò ní Ajẹntínà ń pàdánù nǹkan bí 200 mílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún nítorí àwọn ìwà jìbìtì tí àwọn oníbàárà wọn ń hù. Ní ìyọrísí rẹ̀, ìnáwó ìbánigbófò ohun ìrìnnà ń náni ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún jù iye tí ń náni ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Ambito Financiero ti sọ, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára àwọn jìbìtì tí àwọn ènìyàn lù ló jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn tí a lè pè ní ‘aráàlú tí kò lábòsí.’” Nǹkan bí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí a ń bá gbófò ni a sọ pé, wọ́n ti fojú ilé iṣẹ́ abánigbófò wọn gbolẹ̀ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ìwé agbéròyìnjáde náà parí ọ̀rọ̀ pé, irú ìwà jìbìtì bẹ́ẹ̀ jẹ́ irú ìgbẹ̀san kan láti ọwọ́ àwọn oníbàárà tí wọn kò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, tí wọ́n lérò pé àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò wọn ti lu àwọn ní jìbìtì.
Òkun Kan Tí Ń Kú Lọ
Òkun Òkú ti ń kéré. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ní báyìí ná, ìwọ́jọ omi tí ó relẹ̀ jù lọ lórí Ilẹ̀ Ayé (1,344 ẹsẹ̀ bàtà [410 mítà] sí ìsàlẹ̀ ìpíndọ́gba ìpele ìtẹ́jú àwọn òkun ayé), ìtẹ́jú Òkun Òkú, ń fà láìdáwọ́ dúró.” Kí ló fà á? Yàtọ̀ sí àwọn ìyọrísí ti oòrùn tí ń fà á gbẹ, àwọn ìgbékalẹ̀ ètò ìbomirinko àti ìsédò mélòó kan ń darí omi láti inú Odò Jọ́dánì, tí ó jẹ́ lájorí orísun omi Òkun Òkú gba ibòmíràn. Bákan náà, “àwọn ilé iṣẹ́ oníkẹ́míkà tí ń fa omi inú Òkun Òkú lọ sínú ọ̀gọ̀dọ̀ tí ń fa omi gbẹ láti wa kùsà ti mú kí dídi kékeré náà yára.” Láti àárín àwọn ọdún 1950, ìtẹ́jú Òkun Òkú ti fi nǹkan bí 20 mítà fà. Ìgbésẹ̀ ìṣàtúnṣe kan tí a ń jíròrò lé lórí lọ́wọ́lọ́wọ́ ni líla ọ̀nà omi oníkìlómítà 190 tí yóò fa omi wá láti inú Òkun Pupa. A óò ní láti fa omi náà sókè ní 120 mítà, kí a wá dá wọn pa dà sísàlẹ̀ ní mítà 530 sínú Òkun Òkú.
Àwọn Ẹ̀jẹ́ Tí A Kò Mú Ṣẹ
Ní Germany, àwọn alájọgbéyàwó díẹ̀ péré ní ń mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn ṣẹ. Ìwé agbéròyìnjáde Nassauische Neue Presse sọ pé, pípọ̀ tí ìwọ̀n ìkọ̀sílẹ̀ àti iye àwọn ọmọdé tí ń jìyà ń pọ̀ sí i ni àbájáde rẹ̀. Ní 1995, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 170,000 ìgbéyàwó tí ó tú ká, èyí sì ṣèpalára fún nǹkan bí 142,300 ọmọdé. Èyí jẹ́ ìgasókè ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún nínú àwọn ọmọ tí ó nípa lé lórí ju ti ọdún tó ṣáájú lọ. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, lára àwọn ìgbéyàwó aláyẹyẹ tí a ṣe láàárín 1950, 1 nínú 10 forí ṣánpọ́n láàárín ọdún 25. Lára àwọn tọkọtaya tí wọ́n ṣègbéyàwó ní 1957, nǹkan bí 1 nínú 8 ló pínyà láàárín ọdún 25. Iye àwọn ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe ní 1965 tí ó tú ká láàárín ọdún 25 jẹ́ 1 nínú 5. Lára àwọn tí wọ́n ṣègbéyàwó láti 1970, 1 lára àwọn tọkọtaya 3 ló jálẹ̀ sí ìkọ̀sílẹ̀.
A Ha Ti Rí Egbòogi Gbogbo-Ǹṣe Bí?
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti sọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times, “fún ìgbà àkọ́kọ́, a ti rí i pé oúnjẹ kan tí kò ní ọ̀rá púpọ̀ nínú, tí ó sì ní èso àti ewébẹ̀ púpọ̀ nínú yóò mú kí ìwọ̀n ìfúnpá lọ sílẹ̀ kíákíá àti lọ́nà gbígbéṣẹ́ gan-an bí oògùn ti ń ṣe.” Dókítà Denise Simon-Morton, olórí Ẹgbẹ́ Ìwádìí Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ fún Ìṣèdíwọ́ Àrùn ní Àjọ Abójútó Ọkàn Àyà, Ẹ̀dọ̀fóró àti Ẹ̀jẹ̀ ti Orílẹ̀-Èdè, sọ pé, ìwádìí náà fi hàn pé, “oúnjẹ kan lè ṣe gbogbo rẹ̀”—ó lè ṣèdíwọ́ fún àrùn ọkàn àyà, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti ọ̀pọ̀ àrùn jẹjẹrẹ. Ìwádìí náà ṣàyẹ̀wò ipa tí yíyí oúnjẹ pa dà ń ní lórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àgbàlagbà ní àwọn ibùdó ìṣègùn mẹ́fà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. A pín àwọn olùkópa sí ọ̀wọ́ mẹ́ta. A fún ọ̀wọ́ àwọn kan ní irú oúnjẹ ilẹ̀ America “tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ.” A fún ọ̀wọ́ èkejì ní irú oúnjẹ tí ó ní ọ̀pọ̀ èso àti ewébẹ̀ nínú, àmọ́, gbogbo àwọn èròjà oúnjẹ yòó kù kò yàtọ̀. A fún ọ̀wọ́ kẹta ní irú oúnjẹ tí ó ní ọ̀pọ̀ èso, ewébẹ̀, àti àwọn ìpèsè tí kò lọ́ràá púpọ̀, tí ń wá láti ara ẹran tí òun pẹ̀lú kò ní ọ̀rá, èròjà cholesterol, àti ògidì ọ̀rá púpọ̀ nínú. Ọ̀wọ́ kejì àti ìkẹta ní ìwọ̀n ìfúnpá tí ó dín kù lọ́nà tí ó lámì ní ti ìṣègùn, àmọ́ irú oúnjẹ tí ọ̀wọ́ tí ó ṣìkẹta ń jẹ fi àbájáde tí ó dára jù lọ hàn. Ní ti àwọn olùkópa tí wọ́n lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru, àbájáde rẹ̀ dára gan-an fún wọn tàbí pé ó dára ju ti àwọn tí ń lo oògùn lọ. Àwọn oúnjẹ méjèèjì ní àwọn èso àti ewébẹ̀ tí a jẹ ìwọ̀n rẹ̀ tí ó tó lójoojúmọ́ nínú.
A Tún Ti Ń Fi Àwọn Ènìyàn Ṣiṣẹ́ ní Japan
Ìwé ìròyìn Far Eastern Economic Review sọ pé: “Ìyípadà ńlá kan ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ilé iṣẹ́ ní Japan. Fún ẹ̀wádún méjì, àwọn ilé iṣẹ́ ní Japan ti lépa kíkúnjú ìwọ̀n iṣẹ́ nípa fífi ẹ̀rọ rọ́pò ènìyàn. Wọ́n tún ti wá ń fi ènìyàn ṣiṣẹ́. Àwọn olùṣeǹkan-jáde mélòó kan ti ń mú àwọn róbọ́ọ̀tì kúrò nínú ìgbékalẹ̀ ilé iṣẹ́ wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ènìyàn rọ́pò wọn.” Èé ṣe? Nítorí pé àwọn ènìyàn ní ohun kan tí àwọn róbọ́ọ̀tì kò ní—ìmọwọ́ọ́yí-padà. Bí ó bá tó àkókò láti yí ẹ̀yà ohun tí a ń ṣe jáde pa dà, àwọn ènìyàn lè tètè yíwọ́ pa dà, nígbà tí ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù láti ṣàtúnṣe ìgbékalẹ̀ ìṣiṣẹ́ àwọn róbọ́ọ̀tì. Tomiaki Mizukami, ààrẹ ilé iṣẹ́ NEC kan, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a ń lo àwọn ènìyàn bíi pé róbọ́ọ̀tì ni wọ́n. Àmọ́, nísinsìnyí a gbọ́dọ̀ máa lo làákàyè wọn. Lílo róbọ́ọ̀tì tẹ́lẹ̀ dára, àmọ́ nísinsìnyí, a ti ń rí i pé lílo àwọn ènìyàn ń múṣẹ́ yá ní gidi.” Fún àpẹẹrẹ, a rí i pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ NEC lè to ẹ̀rọ tẹlifóònù lọ́nà tí ń fi ìwọ̀n ìṣiṣẹ́ tí ó fi ìpín 45 nínú ọgọ́rùn-ún dára ju bí àwọn róbọ́ọ̀tì ti lè ṣe lọ. Àwọn ènìyàn kì í tún gba àyè tó àwọn ẹ̀rọ, àwọn ẹ̀rọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ díjú pọ̀ ń yọrí sí ìwọ̀nba kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ àti ìwọ̀nba owó tí a ń ná lórí wíwàsẹpẹ́ rẹ̀. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún méjì tàbí mẹ́ta tí a ti dín lílo ẹ̀rọ adáṣiṣẹ́ kù, àwọn olùṣèmújáde ń tẹnu mọ́ ọn pé, àwọn ń pa owó tí ó pọ̀ mọ́, àwọn sì ń rí èrè lórí ohun tí àwọn ń ṣe jáde.”
Àwọn Ilé Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ “Tuntun” Láti Wò
Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ti ń rọ́ lọ wo Ilé Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ Ńlá tí ó wà ní Giza, tí Ọba Khufu—tí a tún mọ̀ sí Cheops—kọ́. Àmọ́, àwọn díẹ̀ ni wọ́n rí ohun ìrántí tí bàbá rẹ̀, Snefru, fi sílẹ̀. Ìyẹn jẹ́ nítorí pé, àwọn ẹni pàtó kan kò gbọ́dọ̀ dé ibi èyí tí a mẹ́nu kàn ṣìkejì, tí a pa mọ́ sí ibùdó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ní Dahshûr. Àmọ́ ìyẹn ti yí pa dà. Ìgbìmọ̀ gíga jù lọ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé ní Íjíbítì ti ṣí àgbègbè náà sílẹ̀ fún gbogbogbòò. Lára àwọn ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ 11 tó wà níbẹ̀, 3 ni Snefru kọ́—gbogbo èyí tó kọ́ jẹ́ 5—ó sì ní Ilé Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ Pupa náà nínú, èyí tí wọ́n kọ́kọ́ kọ́ tí àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ dán mọ́rán. Àwọn ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ tí ó ti kọ́ tẹ́lẹ̀ jẹ́ alákàsọ̀-lẹ́gbẹ̀ẹ́. Bóyá Ilé Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ Títẹ̀ náà, tí a pè bẹ́ẹ̀ nítorí pé apá ìsàlẹ̀ òkè ibi tó ti dagun yí pa dà lójijì lápá òkè àárín rẹ̀, yóò túbọ̀ fani lọ́kàn mọ́ra. Ìsàlẹ̀ òkè ibi tó ti dagun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tí ń digun jí òkúta, èyí tí ó lè jẹ́ ìdí tí ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ yí fi ní àkámọ́ tí a pa mọ́ dáradára ju àwọn ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ èyíkéyìí ní Íjíbítì lọ. Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí àwọn ọba tí wọ́n ti jẹ ṣáájú kú tán ni a sọ wọ́n di ọlọ́run, ìwé ìròyìn Time sọ pé, Snefru “polongo pé òun jẹ́ ọlọ́run alààyè oòrùn náà, Re. Wọ́n sin Snefru sínú Ilé Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀bẹ̀tẹ̀ Pupa náà, wọ́n gbé sàréè rẹ̀ sínú ibi oníyàrá-mẹ́ta kíkàmàmà kan tí a kà sí èyí tí ó dára jù ní sáà Ìjọba Ògbólógbòó náà.”