ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 1/8 ojú ìwé 24
  • Yéé Sá fún Jíjẹ Oríṣiríṣi Ẹ̀fọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yéé Sá fún Jíjẹ Oríṣiríṣi Ẹ̀fọ́!
  • Jí!—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oúnjẹ Aṣaralóore Ń Bẹ Níkàáwọ́ Rẹ
    Jí!—2002
  • Ohun 1—Máa Ṣọ́ Oúnjẹ Jẹ
    Jí!—2011
  • Ohun Méje Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Oúnjẹ Léwu Táá sì Ṣara Lóore
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àwọn Ìṣòro Ńlá Tó Ń fà Á Àti Ibi Tí Àbájáde Rẹ̀ Nasẹ̀ Dé
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 1/8 ojú ìwé 24

Yéé Sá fún Jíjẹ Oríṣiríṣi Ẹ̀fọ́!

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRAZIL

“Ó máa ń korò.” “Kò dá a lẹ́nu rárá.” “Mi ò fẹnu mi kàn án rí.”

DÍẸ̀ nìwọ̀nyí jẹ́ lára ìdí tí ọ̀pọ̀ kì í fi í jẹ ẹ̀fọ́. Ìwọ náà ń kọ́? Ṣé o máa ń jẹ ẹ̀fọ́ lójoojúmọ́? Jí! fọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn lẹ́nu wò láti mọ ìdí táwọn kan fi fẹ́ràn ẹ̀fọ́ àti ìdí táwọn kan kò fi nífẹ̀ẹ́ sí i.

Àwọn tó máa ń jẹ ẹ̀fọ́ sọ pé àwọn òbí àwọn ti kọ́ àwọn ní ìjẹ́pàtàkì jíjẹ oríṣiríṣi ẹ̀fọ́, ẹ̀wà àti èso. Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí kò fẹ́ràn ẹ̀fọ́ ló jẹ́ pé láti kékeré ni kò ti mọ́ wọn lára láti máa jẹ ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yàn láti máa jẹ ìmọ́mọ́rán. Ṣùgbọ́n, àwọn pàápàá gbà pé ẹ̀fọ́ jíjẹ dára gan an ni béèyàn bá fẹ́ máa ní ìlera tó dára.

Ẹ̀yin òbí, ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín láti mọ oríṣiríṣi ẹ̀fọ́ í jẹ! Lọ́nà wo? Ìwé Facts for Life, tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé kọ, dá a lábàá pé ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́, kí àwọn òbí máa fún àwọn ọmọ bí ọmọ oṣù mẹ́fà ní ẹ̀fọ́ tí wọ́n ti sè tí wọ́n sì ti fọ́ pọ̀ dáadáa lẹ́yìn tí wọ́n bá fún wọn lọ́mú tán tàbí tí wọ́n bá jẹ oúnjẹ inú ìgò tán. Bí wọ́n bá ṣe fojú wọn mọ onírúurú oúnjẹ tó, bẹ́ẹ̀ làǹfààní táwọn ọmọ máa jẹ ṣe máa pọ̀ tó. Dókítà Vagner Lapate, ọmọ Brazil kan tó jẹ́ ògbógi nínú ìtọ́jú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàrà ṣì ni orísun oúnjẹ ṣíṣe pàtàkì jù ní ọdún méjì àkọ́kọ́, fífún ọmọ ọwọ́ ní irú oríṣi oúnjẹ mìíràn “máa ń jẹ́ kó mọ àwọn adùn tó yàtọ̀.”

Nínú ìwé Medicina—Mitos y Verdades (Oògùn—Àròsọ àti Òtítọ́), Carla Leonel dámọ̀ràn pé a lè bẹ̀rẹ̀ sí fi omi ọsàn díẹ̀ díẹ̀, àwọn èso táa ti tẹ̀ fọ́ dáadáa (bí ọ̀gẹ̀dẹ̀, ápù àti ìbẹ́pẹ), oúnjẹ oníhóró, àti ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ kún oúnjẹ àwọn ọmọ ọwọ́ ṣáájú àkókò tí a mẹ́nu kàn lókè yìí. Bí a ṣe mọ̀, níwọ̀n bí èrò nípa èyí ti máa ń yàtọ̀ síra, yóò bọ́gbọ́n mu láti kúkú bá dókítà ọmọ rẹ sọ̀rọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́