ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 4
  • Ohun 1—Máa Ṣọ́ Oúnjẹ Jẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun 1—Máa Ṣọ́ Oúnjẹ Jẹ
  • Jí!—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyan Oúnjẹ Tí Ń Ṣara Lóore
    Jí!—1997
  • Ohun Méje Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Oúnjẹ Léwu Táá sì Ṣara Lóore
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìgbà Tí Kò Dára Láti Sanra
    Jí!—1997
  • Bóo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 4

Ohun 1​—Máa Ṣọ́ Oúnjẹ Jẹ

“Máa jẹun. Má jẹ àjẹjù. Ọ̀gbìn oko ni kó o máa jẹ jù.” Ọ̀rọ̀ ṣókí tó sì rọrùn yìí ni òǹṣèwé náà Michael Pollan fi gbani nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn oúnjẹ, èyí táwọn èèyàn ti ń tẹ̀ lé fún ìgbà pípẹ́ tí wọ́n sì rí i pé ó ṣàǹfààní. Kí ni òǹṣèwé yìí ní lọ́kàn?

◯ Máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore. Oúnjẹ “gidi” ni kó o máa jẹ, irú bí àwọn oúnjẹ aṣaralóore táwọn èèyàn ti máa ń jẹ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, dípò tí wàá fi máa jẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti fi ẹ̀rọ yí pa dà. Ṣúgà, iyọ̀ àti ọ̀rá sábà máa ń pọ̀ jù nínú àwọn oúnjẹ inú agolo àtàwọn oúnjẹ tí wọ́n máa ń sáré sè láwọn ilé oúnjẹ, èyí sì máa ń fa àrùn ọkàn, rọpárọsẹ̀, jẹjẹrẹ àtàwọn àìsàn lílekoko míì. Tó o bá fẹ́ se oúnjẹ, o lè fi ooru omi gbígbóná sè é, o lè yan án, o sì lè sun ún, dípò tí wàá fi dín in. Gbìyànjú kó o túbọ̀ máa lo ewé àti ohun amóúnjẹ-ta-sánsán láti fi se oúnjẹ, kó o sì dín iyọ̀ tó ò ń lò kù. Máa rí i dájú pé o se ẹran jìnnà dáadáa, má sì ṣe máa jẹ oúnjẹ tó ti bà jẹ́.

◯ Má ṣe máa jẹ àjẹjù. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé àwọn tó tóbi jù àtàwọn tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́nà tó lékenkà kárí ayé, ohun tó sì ń fa èyí ni jíjẹ àjẹjù. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní àwọn apá ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà fi hàn pé “àwọn ọmọ tí wọ́n sanra jù pọ̀ gan-an ju àwọn ọmọ tí kò jẹunre kánú lọ.” Àwọn ọmọ tí wọ́n sanra jù lè ní ìṣòro àìlera ní báyìí tàbí tí wọ́n bá dàgbà, tó fi mọ́ àrùn àtọ̀gbẹ. Ẹ̀yin òbí, ẹ́ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ yín nípa jíjẹ oúnjẹ tó mọ níwọ̀n.

◯ Ọ̀gbìn oko ni kó o máa jẹ jù. Ó dáa kéèyàn máa jẹ onírúurú èso, ewébẹ̀ àtàwọn oúnjẹ oníhóró ju ẹran àti sítáàṣì lọ. Máa jẹ ẹja dípò ẹran ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Dín bó o ṣe ń jẹ àwọn oúnjẹ alápòpọ̀ irú bí oúnjẹ tí wọ́n fi ìyẹ̀fun ṣe, búrẹ́dì funfun àti ìrẹsì funfun èyí tí wọ́n ti yọ àwọn ohun aṣaralóore tó wà nínú rẹ̀ kù. Àmọ́ ṣá o, má ṣe ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ ṣíṣa oúnjẹ jẹ o. Ẹ̀yin òbí, ẹ mú kí ìlera àwọn ọmọ yín dára sí i nípa jíjẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn oúnjẹ aṣaralóore. Bí àpẹẹrẹ, máa fún wọn ní ẹ̀pà àti èso tẹ́ ẹ fọ̀ mọ́ dáadáa àti ewébẹ̀, dípò tí wàá fi máa fún wọn ní àwọn ìpápánu bíi kókóró tàbí súìtì.

◯ Máa mu omi tó pọ̀ gan-an. Tàgbà tọmọdé ló yẹ kó máa mu omi àti àwọn nǹkan olómi míì tí kò ní ṣúgà lójoojúmọ́. Máa mu omi tó pọ̀ gan-an nígbà tí oòrùn bá mú àti nígbà tó o bá ń ṣe iṣẹ́ agbára àti eré ìmárale. Téèyàn bá mu omi tó pọ̀, ó máa ń jẹ́ kí oúnjẹ tètè dà nínú èèyàn, kì í jẹ́ kí májèlé dúró lára, ó máa ń jẹ́ kí àwọ̀ èèyàn máa dán, ó sì máa ń jẹ́ kí ẹni tó sanra fọn. Ó máa ń jẹ́ kí ìrísí ẹni dára. Ṣọ́ra fún mímu ọtí líle àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò lámujù. Tó o bá ń mu ọtí ẹlẹ́rìndòdò kan lójúmọ́, ó lè mú kó o fí kìlógíráàmù méje sanra sí i lọ́dún kan.

Láwọn ilẹ̀ kan, ó máa ń ṣòro láti rí omi tó mọ́ tàbí kí owó rẹ̀ wọ́n. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì láti máa mu omi tó mọ́. A ní láti se omi tó bá dọ̀tí tàbí ká lo àwọn kẹ́míkà tó máa pa àwọn kòkòrò inú rẹ̀ ká tó mú un. Wọ́n sọ pé àwọn tí omi tí kò mọ́ máa ń pa ju iye èèyàn tí ogun àti ìmìtìtì ilẹ̀ ń pa lọ; omi tí kò mọ́ máa ń pa ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] àwọn ọmọdé lójúmọ́. Àjọ Ìlera Àgbáyé dábàá pé kí wọ́n máa fún àwọn ọmọ ìkókó ní ọmú nìkan fún oṣù mẹ́fà, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa fún wọn lọ́mú àtàwọn oúnjẹ míì títí dìgbà tí wọ́n á fi pé ọmọ ọdún méjì, ó kéré tán.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́