Bí Mo Tilẹ̀ Dití tí Mo Tún Fọ́jú, Mo Rí Ààbò
GẸ́GẸ́ BÍ JANICE ADAMS ṢE SỌ Ọ́
Ká kúkú sọ pé etí mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di tán nígbà tí wọ́n bí mi, síbẹ̀ mo ti kọ́ bí mo ṣe lè ṣe nǹkan láàárín àwọn tó gbọ́ràn. Nígbà tó yá, tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ gíga, jìnnìjìnnì bò mí nígbà tí mo gbọ́ pé mo ṣì máa di afọ́jú. Agbaninímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́ mi tó nífẹ̀ẹ́ mi fún mi ní àpilẹ̀kọ kan nípa béèyàn ṣe lè gbé láìríran àti láìgbọ́ràn. Kíá, ojú mi lọ síbì kan tó sọ pé àwọn tó dití tí wọ́n tún fọ́jú làwọn èèyàn tó dá wà jù lọ láyé. Ńṣe ni mo bú sẹ́kún gbẹ̀ẹ́.
WỌ́N BÍ mi ní Des Moines, Iowa, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní July 11, 1954, èmi lọmọ kan ṣoṣo tí Dale àti Phyllis Den Hartog bí. Àwọn òbí mi ò mọ̀ rárá pé àwọn méjèèjì ló ní nǹkan tó máa ń yọrí sí àrùn Usher tó máa ń fa kí etí èèyàn di kójú ẹni yẹn sì máa fọ́ díẹ̀díẹ̀ lára.
Àwọn òbí mi ò kọ́kọ́ fura pé mo ní ìṣòro kankan. Bóyá nítorí pé mo ṣì lè gbọ́ àwọn ìró kan tí mo sì máa ń dáhùn padà nígbà míì. Àmọ́ nígbà tí mo tẹ́ni tí ń sọ̀rọ̀ tí mi ò sọ̀rọ̀, wọ́n mọ̀ pé nǹkan mìíràn ti wọ̀ ọ́. Dókítà ló wá ṣàwárí níkẹyìn pé adití ni mí nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta.
Ibi tọ́rọ̀ yìí bọ́ sí lára àwọn òbí mi ò dáa. Síbẹ̀, wọ́n pinnu pé àwọ́n á rí i pé mo kẹ́kọ̀ọ́ débi tó bá ṣeé ṣe. Wọ́n fi mí sí ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi dídára jù lọ fáwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ràn. Àmọ́ bó ti jẹ́ pé ńṣe ni ká kúkú sọ pé adití ni mí, òdo ni mo ń gbà wálé. Nígbà míì tọ́kàn mi bá gbọgbẹ́, ńṣe ni màá máa la orí mi mọ́ ògiri.
Wọ́n Mú Mi Lọ Sílé Ẹ̀kọ́ Àkànṣe
Àwọn òbí mi yàn láti fi mí sí Àkànṣe Ilé Ẹ̀kọ́ fún Àwọn Adití (CID) ní ìlú St. Louis, Missouri. Láìka ìnáwó bàǹtàbanta tó wà nídìí ẹ̀ àti ẹ̀dùn ọkàn fífi mí sílẹ̀ lọ́mọ ọdún márùn-ún sí, wọ́n ronú pé ìrètí mi dídára jù lọ nìyẹn láti ṣoríire àti láti láyọ̀ ní ìgbésí ayé. Èmi àtàwọn òbí mi ò lè bára wa sọ̀rọ̀ rárá nígbà yẹn.
Mo ń wo màmá mi bó ti ń di àwọn aṣọ mi sínú àpótí. Ńṣe ni ìrìn-àjò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yẹn dà bíi pé kò ní tán. Nílé ẹ̀kọ́ CID, mó rántí bí mo ṣe rí àwọn ọmọdébìnrin kéékèèké tí ìyá wọn ò sí níbẹ̀ mo sì ronú pé, ‘Ó tiẹ̀ dáa, èmi ò ní dúró síbí torí mo ní mọ́mì àti dádì.’ Nígbà tí àkókò tó fáwọn òbí mi láti máa lọ, wọ́n ṣàlàyé pé àwọn á padà wá lóṣù díẹ̀ sí i. Mo sunkún sunkún tí mo sì so mọ́ wọn pinpin, àmọ́ ìyá ilé náà já mi kúrò lára wọn kí wọ́n lè lọ.
Bí ẹni pé wọ́n pa mí tì ló rí lára mi. Bí mo ti dá wà pẹ̀lú àwọn ọmọdébìnrin tó kù ní alẹ́ àkọ́kọ́ ní ilé ìwé yẹn, mó gbìyànjú láti rẹ ọmọ kan tó ń ké lẹ́kún, tí mo ń ṣe bi ẹni tó lè sọ̀rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè sọ̀rọ̀ rárá nígbà yẹn. Ìyá ilé náà bá mi wí gan an ó sì fi pákó kan pààlà sáàárín wa ká má bàa lè bára wa sọ̀rọ̀ mọ́. Wọn ò gbé pákó yẹn kúrò látìgbà náà. Ìnìkanwà náà kó ìbànújẹ́ ńláǹlà bá mi.
Díẹ̀díẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé aìlègbọ́ràn ló mú gbogbo wa wà níbẹ̀. Ó jọ pé àwọn òbí mi nífẹ̀ẹ́ mi o jàre, àmọ́ mo ronú pé ẹ̀bi mi ni bí mo ṣe fìdí rẹmi níléèwé jẹ́lé-ó-sinmi. Mo pinnu pé lọ́tẹ̀ yìí o, màá rí i pé mo ṣàṣeyege kí n lè padà sọ́dọ̀ àwọn òbí mi lọ́jọ́ kan.
Ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́ni ní CID ò lẹ́gbẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gbà ká lo èdè àwọn adití, wọ́n fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́ni nípa báa ṣe lè máa wo ẹnu àwọn èèyàn ká sì mọ ohun tí wọ́n ń sọ àti báa ṣe lè mọ̀rọ̀ọ́ sọ. Gbogbo ohun tí wọ́n ń kọ́ láwọn ilé ìwé gbogbo gbòò ni wọ́n tún ń kọ́ wa dáadáa. Bí mo tilẹ̀ mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tó jẹ́ adití ni fífi ètè wíwò mọ ohun tí à ń sọ kò ṣiṣẹ́ fún dáadáa, ó ṣiṣẹ́ fún èmi, mo sì mọ̀ pé mo ṣàṣeyọrí. Nípa lílo ohun èlò àfigbọ́ròó mi, mo kọ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ nípa wíwo bí ètè àwọn èèyàn ṣe ń jì àti pípe ohun tí wọ́n bá sọ sínú. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tétí wọn ò di wá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ọ̀rọ̀ mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì dáa tó. Inú àwọn òbí mi àtàwọn ará ilé ẹ̀kọ́ mi dùn gidigidi fún àṣeyọrí mi yìí. Síbẹ̀síbẹ̀, rororo lojú mi wà nílé.
Ìgbàkigbà táa bá gba ìsinmi ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni mo máa ń bẹ àwọn òbí mi pé kí wọ́n jẹ́ kí n dúró sílé kí n sì máa lọ síléèwé ní Iowa, àmọ́ irú ètò ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kò sí lágbègbè náà. Lẹ́yìn tí mo bá padà dé iléèwé, ojoojúmọ́ ni màmá mi máa ń kọ lẹ́tà sí mi táá sì fi ṣingọ́ọ̀mù kan sínú rẹ̀. Ṣingọ́ọ̀mù yẹn mà jọ mí lójú o, nítorí pé ó jẹ́ àmì ìfẹ́! Dípò kí n jẹ ẹ́, ńṣe ni mo máa ń tọ́jú wọn níkọ̀ọ̀kan, mo sì máa ń mọyì wọn gan-an nígbà tí ìbànújẹ́ bá sorí mi kodò.
Mo Padà Sílé, àmọ́ Ìṣòro Tún Dé
Níkẹyìn, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, àwọn òbí mi mú mi wálé. Inú mi dùn gidigidi mo sì nímọ̀lára ààbò bí mo ṣe wà pẹ̀lú ìdílé mi! Mo bẹ̀rẹ̀ iléèwé àkànṣe fáwọn adití lágbègbè Des Moines. Níkẹyìn, wọ́n fi mí sí kíláàsì àwọn ọmọ tó gbọ́rọ̀ nítorí pé mo mọ bí wọ́n ṣe ń wo ètè ẹni tó ń sọ̀rọ̀ láti mọ ohun tó ń sọ mo sì ti lè sọ̀rọ̀ káwọn èèyàn sì lóye rẹ̀. Síbẹ̀, ipò mi tuntun yìí kò ṣàì mú ọ̀pọ̀ ìṣòro wá.
Nínú ilé elérò púpọ̀ tí mo ń gbé ní CID, ọ̀pọ̀ ojúgbà mi tó jẹ́ adití ló gba tèmi. Àmọ́ báyìí, táwọn tó ń sọ̀rọ̀ ti ju ẹyọ kan lọ tí wọ́n sì ń yára sọ̀rọ̀, wíwo ètè wọn nìkan kò tó fún mi láti mọ nǹkan tí wọ́n ń sọ dáadáa. Ni wọ́n á bá pa mí tì. Èmi sì ń fẹ́ kí wọ́n gba tèmi lójú méjèèjì!
Èyí sún mi dédìí wíwá ojú rere àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́langba, tó sì yọrí sí lílọ́wọ́ nínú àwọn ìwà tí kò tọ́. Mi ò tún mọ bí wọ́n ṣe ń sọ pé rárá. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, wọ́n fipá bá mi lò pọ̀; ṣùgbọ́n mi ò sọ fẹ́nì kankan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà làwọn òbí mi ń ṣàníyàn nípa mi tí wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn sí mi, ńṣe ló dá bíi pé mi ò lálábàárò.
Nípa lílo ohun èlò àfigbọ́ròó mi, ó ṣeé ṣe fún mi láti gbádùn orin díẹ̀, àmọ́ irú orin tí mo yàn láàyò jẹ́ èyí tí ń kọni lóminú. Orin rọ́ọ̀kì aláriwo bíi tàwọn tó ti joògùn yó ni mo máa ń gbọ́. Mo tún dẹni tó ń mugbó nígbà gbogbo tí mo sì túbọ̀ ń ya ara mi kúrò láàárín àwọn èèyàn. Mo ṣì máa ń kábàámọ̀ gan an tí n bá rántí àwọn ohun tí mo ṣe láàárín àwọn ọdún onírúkèrúdò yẹn àti ìbànújẹ́ tó kó bá èmi àti ìdílé mi.
Àwọn Ìsapá Láti Mú Káyé Mi Sàn Sí I
Ní gbogbo àsìkò yìí, mo nífẹ̀ẹ́ sí kíkọ́ àwọn nǹkan gan an kí n sì máa fọwọ́ ara mi ṣe wọ́n. Mo máa ń kàwé ṣáá, mo máa ń kun nǹkan, mo ń ránṣọ, mo sì tún ń fabẹ́rẹ́ ṣọnà sára aṣọ. Mo fẹ́ kí ìgbésí ayé mi lọ́jọ́ iwájú dára ju tàwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọn kò mọ̀ ju jíjoògùnyó lọ. Ni mo bá forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan nítòsí ilé wa kọ́wọ́ mi lè tẹ ìfẹ́ tí mo ní sí iṣẹ́ ọnà. Láàárín àkókò yìí, mo pinnu láti kọ́ èdè àwọn adití nítorí bí àwọn èèyàn ṣe pa mí tì kò múnú mi dùn.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mó bọ́ sí Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Iṣẹ́ Ọwọ́ Ìjọba Fáwọn Adití ní Rochester, New York láti di ògbóǹtagí nínú lílo amọ̀ fún iṣẹ́ ọnà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti ń di bàìbàì díẹ̀díẹ̀, mi ò kọbiara sí i, gbogbo èrò mi sì ni pé ayé mi ti ń dáa wàyí. Àmọ́, ìgbà yìí gan an ni agbaninímọ̀ràn ni ilé ẹ̀kọ́ gíga náà wá sọ ojú abẹ níkòó fún mi pé, láìpẹ́ màá di afọ́jú.
Kò sọ́nà tí ilé ẹ̀kọ́ yìí fi lè bojú tó ipò mi, nítorí náà mo ní láti fibẹ̀ sílẹ̀. Kí ni màá ṣe báyìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mímọ̀ pé mo máa tó di afọ́jú kó ìbànújẹ́ bá mi, mo pinnu láti wá ọ̀nà tí màá fi gbé láìsí pé mo ń dara dé ẹnì kankan kí ọ̀rọ̀ mi má lọ dà bí ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ tí agbaninímọ̀ràn náà fún mi pé màá ‘di ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó dá wà jù lọ láyé.’ Mo padà sílé ní Iowa láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ka Ìwé Àwọn Afọ́jú àti bi mo ṣe lè máa lo igi láti rìn.
Mo Kó Lọ sí Ìlú Washington, D.C.
Yunifásítì Gallaudet ní Washington, D.C. nìkan ni ilé ẹ̀kọ́ náà lágbàáyé tó ń pèsè àpapọ̀ ẹ̀kọ́ fún àwọn adití, ó tún ní àkànṣe ẹ̀kọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ adití tí wọ́n tún fọ́jú. Mo kọjá síbẹ̀, mo sì gboyè jáde lọ́dún 1979. Lẹ́ẹ̀kan sí i, inú mi tún dùn pé mo lè ṣàṣeyọrí nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́.
Síbẹ̀, ńṣe ló ṣì ń dà bíi pé mi ò bẹ́gbẹ́ mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ń fọ́ lọ, mo lọ kọ́ èdè àwọn adití mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò pé mo ń bá àwùjọ kan mu, ìyẹn àwọn tó jẹ́ Adití. Èdè táwọn adití mìíràn ń lò lèmi náà ń lò. Àmọ́, nígbà tọ́rọ̀ mi wá di pé mo gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ mi kan tiwọn kí n tó lè lóye wọn, làwọn adití kan bá pa mí tì nítorí pé ó nira fún wọn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì bóyá àwọn èèyàn kankan tún wà tó lè tẹ́wọ́ gbà mí.
Wíwá Ìsìn Tòótọ́ Kiri
Ìsìn kò fún mi ní ìtùnú ní gbogbo ìgbà tí mo ń dàgbà. Nílé ẹ̀kọ́ gíga sì rèé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣe ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan nípa ìsìn, mi ò rí ìdáhùn rí sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí mo ní. Lẹ́yìn tí mo gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga, mo ń bá a lọ láti máa wá ìdáhùn. Láàárín àkókò yìí inú mi ò dùn sí bí àjọṣe èmi àtàwọn èèyàn ṣe rí, ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó tọ́ mi sọ́nà.
Ní 1981, mo tún padà sí Yunifásítì Gallaudet láti gba oyè ìjìnlẹ̀ nínú ìgbaninímọ̀ràn amúnibọ̀sípò. Síbẹ̀ mi ò jáwọ́ gbígbàdúrà pé kí n rí ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ òótọ́. Àwọn èèyàn bíi mélòó kan ní àwọ́n á mú mi lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn, àmọ́ fún ìdí kan tàbí òmíràn, wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo pàdé Bill, ó gbọ́ràn dáadáa ní tiẹ̀ ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gboyè sí i. Ó ṣèèṣì mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì bíi tòun, ó sì sọ fún mi pé òun ń kọ́ oríṣiríṣi nǹkan àgbàyanu lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Èrò tí mo kọ́kọ́ ní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé ẹgbẹ́ òkùnkùn Júù ni wọ́n, ìyẹn sì jẹ́ èrò tí mo rí i pé ó wọ́pọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó jẹ́ adití. Bill mú un dá mi lójú pé wọn kì í ṣèèyàn bẹ́ẹ̀, ó sọ pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti mọ̀ nípa wọn ni láti lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wọn. Kò wù mí láti lọ rárá, àmọ́ mo rántí àdúrà mi. Mo gbà bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, lórí àdéhùn pé ọwọ́ ẹ̀yìn la máa jókòó ká lè tètè rọ́nà jáde tí wọ́n bá fẹ́ fagbára mú wa.
Pẹ̀sẹ̀ Lára Tù Mí
Ara mi ò balẹ̀ báa ti ń wakọ̀ lọ sí ìpàdé náà. Jí-ǹ-sì aláwọ̀ búlúù làwa méjèèjì wọ̀ pẹ̀lú ṣẹ́ẹ̀tì olówùú. Inú mi dùn pé a pẹ́ díẹ̀ ká tó débẹ̀ nítorí ìyẹn ò jẹ́ ká bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ṣáájú ìpàdé náà. Bill túmọ̀ gbogbo nǹkan tí mi ò lè rí tí mi ò sì lè gbọ́ fún mi lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bo tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ló yé mi dáadáa, nǹkan méjì ló wú mi lórí: Ìgbà gbogbo ni alásọyé náà ń lo Bíbélì, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ọmọdé tí wọ́n jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn kópa gan-an nínú ìpàdé náà. Nígbà tí ìpàdé náà parí, wọn ò fagbára mú wa rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ kí wa káàbọ̀ láìka ti aṣọ wa àti ẹ̀yà wa tó yàtọ̀ sí.
Àwa méjì yìí nìkan la jẹ́ aláwọ̀ funfun nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé mo ní ẹ̀tanú èyíkéyìí sáwọn adúláwọ̀, ara mi kò kọ́kọ́ balẹ̀ láti wà níbẹ̀. Àmọ́ o, ìsọfúnni nípa òtítọ́ Bíbélì lágbára gan-an ju kí n gba àìfararọ mi láyè láti dá mi dúró. A bẹ̀rẹ̀ sí lọ sáwọn ìpàdé déédéé. Ìṣòro ńlá tí mo tún ní ni pé kò sáwọn èèyàn tó jẹ́ adití nínú ìjọ yẹn. Nítorí náà, nígbà táa gbọ́ pé ìjọ kan wà táwọn adití díẹ̀ máa ń wá, a bẹ̀rẹ̀ sí lọ síbẹ̀. Nínú ìjọ tuntun yìí, àwa nìkan tún ni aláwọ̀ funfun tó ń wá síbẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n mú kára tù wá gan an ni.
A gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níkẹyìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi. Ń kì í lóye àwọn ìdáhùn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ mo mọ̀ pé wọ́n bá Ìwé Mímọ́ mu. Nípa ṣíṣe ìwádìí sí i àti ṣíṣàṣàrò, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, òye òtítọ́ Bíbélì wá yé mi. Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé mi, mo rí i pé mo túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà bí Ọlọ́run òtítọ́. Ìgbà yìí kan náà lèmi àti Bill tún wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ sí i. Mo mọ̀ pé ó fẹ́ràn mi, àmọ́ ó yà mí lẹ́nu nígbà tó sọ pé kí n fẹ́ òun. Pẹ̀lú ìdùnnú ni mo fi gbà. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ni Bill ṣèrìbọmi, oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn ní February 26, 1983, èmi náà ṣèrìbọmi.
Rírí Ààbò Tí Mo Ti Ń Wá
Ẹ̀rù kọ́kọ́ ń bà mí pé màá nìkan wà nítorí kìkì adití méjì péré ló wà nínú ìjọ wa, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń bá ẹni tó jẹ́ adití tó tún fọ́jú sọ̀rọ̀. Mo lè sọ pé ìjọ wa nífẹ̀ẹ́, ara wọ́n sì yọ̀ mọ́ni, síbẹ̀ kò ṣeé ṣe fún mi níbẹ̀rẹ̀ láti bá wọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Èyí bà mí lọ́kàn jẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìrẹ̀wẹ̀sì á mú mi táá sì dà bíi pé mo nìkan wà. Àmọ́, ìwà rere arákùnrin kan tàbí arábìnrin tẹ̀mí kan máa ń wọ̀ mí lọ́kàn ó sì tún ń mú ara mi yá gágá. Bill náà tún fún mi níṣìírí pé kí n tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi kí n sì máa gbàdúrà pé kí Jèhófà túbọ̀ mú àwọn èèyàn tó jẹ́ adití wá sínú ìjọ náà.
Mo pinnu láti ní ajá kan tó máa ń tọ́ afọ́jú sọ́nà kí n lè túbọ̀ máa dá ṣe àwọn nǹkan fúnra mi. Ajá náà ti ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí èrò ìnìkanwà mi dàwátì. Tí Bill bá lọ síbi iṣẹ́, mo lè rìn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba láti lọ pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó péjọ láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Bọ́dún ti ń gorí ọdún, mo ti ní àwọn ajá afinimọ̀nà mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì dà bí apá kan ìdílé wa.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ajá afinimọ̀nà ń ṣèrànwọ́, níní ìfararora sí i pẹ̀lú àwọn èèyàn ló jẹ mí lọ́kàn. Bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà bù kún ìsapá wa láti mú ìfẹ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dàgbà láàárín àwọn adití. Ìfẹ́ náà dàgbà débi pé wọ́n dá ìjọ kan tó ń sọ èdè adití sílẹ̀ ní Washington, D.C. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó wá ṣeé ṣe fún mi láti bá mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ sọ̀rọ̀!
Bill tóótun láti sìn bí alàgbà wọ́n sì yàn án gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága ìjọ tó ń sọ èdè adití náà. Ìtẹ́lọ́rùn tí mo ń rí nínú kíkọ́ àwọn adití àtàwọn tó dití tó sì tún fọ́jú lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọyọyọ, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń fi òtítọ́ ọkàn sin Jèhófà báyìí. Mo tún kọ́ àwọn arábìnrin tí wọ́n kì í ṣe adití ní èdè àwọn adití kí wọ́n lè túbọ̀ gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láàárín àwọn adití.
Àkókò Ìdánwò
Ní 1992, ìsoríkọ́ lílekoko, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà àìdáa tí wọ́n hù sí mi nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́ bò mí pátápátá. Fún odindi ọdún méjì, ìgbésí ayé kò rọrùn fún mi. Ó dà bí ìgbà tí mi ò lé dá ohunkóhun ṣe mọ́—kì í ṣe nítorí pé mo jẹ́ adití tàbí afọ́jú—àmọ́ nítorí wàhálà lílekoko tó bá èrò inú mi ni. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni màá rò pé ara mi ò gbà á láti lọ sípàdé tàbí jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ni màá bá bẹ Jèhófà pé kó jọ̀ọ́ kó fún mi lágbára láti pa ìwà títọ́ mọ́. Àbájáde rẹ̀ ni pé, ṣàṣà ní ìgbà tí mo pa ìpàdé jẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò jẹ́ kí jíjáde mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ já létí láàárín àwọn ọdún líle koko yẹn.—Mátíù 6:33.
Ní 1994, a kó lọ sí Vancouver, British Columbia, ní Kánádà, láti lọ ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ mìíràn tó ń sọ èdè àwọn adití sílẹ̀. Kíkó lọ yìí kò rọrùn rárá. Mo fi ìlú tí mo ti mọ̀ bí ẹni mowó àtàwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò tíì bọ́ lọ́wọ́ ìsoríkọ́ àti hílàhílo mi, ayọ̀ rírí ìjọ tuntun tí a dá sílẹ̀ ní Vancouver mú kí gbogbo ìrúbọ náà tó bẹ́ẹ̀ kó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Mo ti wá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣọ̀wọ́n nínú ìjọ tuntun náà, débi pé, bí ilé ló ṣe rí lára mi báyìí.
Baba Wa Onífẹ̀ẹ́ Bù Kún Wa
Ní 1999, èmi àti ọkọ mi àtàwọn Ẹlẹ́rìí méjì mìíràn ṣèbẹ̀wò sí Haiti fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láàárín àwọn adití. Ní ṣíṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀, a kọ́ àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ náà ní èdè àwọn adití táa sì wàásù pẹ̀lú wọn ní ìpínlẹ̀ àwọn adití táa lè sọ pé wọn ò tíì ṣe rí. Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó lé ní ọgbọ̀n ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn adití tó fìfẹ́ hàn! Mo padà sílé pẹ̀lú àkọ̀tun okun tẹ̀mí tí mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní September 1999. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àti tọkọ mi ọ̀wọ́n, pẹ̀lú ìjọ tí wọ́n ò fi mí sílẹ̀, ìsoríkọ́ tó ń yọjú kò rí ayọ̀ mi já gbà.
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, mo ti nírìírí bí Jèhófà ti jẹ́ onífẹ̀ẹ́ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. (Jákọ́bù 5:11) Ó bìkítà fún gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀—àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, àwọn tó ní àkànṣe àìní. Nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti ní Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mìíràn ní Èdè Àwọn Afọ́jú. Mo ń gbádùn àwọn ìpàdé àgbègbè àti ti àyíká ní èdè àwọn adití. Ìjọ sì tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣèrànwọ́ fún mi nípa fífi ìfọwọ́-kanwọ́ bá mi sọ̀rọ̀, tó fi jẹ́ pé mo máa ń kópa ní kíkún nínú gbogbo àwọn ìpàdé. Láìka ti àléébù ara méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí, mo ti rí ààbò láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà. Kì í ṣe pé mo ń gbà nìkan ni, àmọ́ èmi náà tún lè fi fúnni, èyí sì ń fún mi láyọ̀ rẹpẹtẹ.—Ìṣe 20:35.
Mo ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí màá fetí mi gbọ́ràn tí màá sì fojú mi ríran nínú ayé tuntun Jèhófà. Ní báyìí ná, mi ò sí lára àwọn èèyàn tó dá wà jù lọ láyé, àmọ́ mo jẹ́ ara ìdílé àgbáyé kan tó ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ arákùnrin àti arábìnrin tẹ̀mí. Fún gbogbo èyí, Jèhófà lọpẹ́ yẹ, ẹni tó ti ṣèlérí pé òun kò jẹ́ fi mí sílẹ̀ tàbí kọ̀ mí sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, lójú gbogbo àwọn ìṣòro wọ̀nyí, mo lè sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.”—Hébérù 13:5, 6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Fífi ìfọwọ́-kanwọ́ bá mi sọ̀rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Èmi pẹ̀lú Bill ọkọ mi lónìí