ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 9/8 ojú ìwé 31
  • Ọ̀dọ́bìnrin Kan Tó Ní Ìrètí Amọ́kànyọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀dọ́bìnrin Kan Tó Ní Ìrètí Amọ́kànyọ̀
  • Jí!—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ayé Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Bá Ń Fìyìn fún Jèhófà Máa Ń Dára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Gánà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ẹ̀mí Mímọ́ Ń fún Wa Lágbára Ká Lè Kojú Ìdẹwò Ká Sì Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ ní Rwanda—Ẹ̀bi Ta Ni?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 9/8 ojú ìwé 31

Ọ̀dọ́bìnrin Kan Tó Ní Ìrètí Amọ́kànyọ̀

ÀWỌN tó ń tẹ Jí! jáde gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìlá kan tó ń jẹ́ Stephanie. Ohun tó kọ rèé: “Mo fẹ́ sọ fún un yín nípa bí àwọn ìtẹ̀jáde yín ṣe ràn mí lọ́wọ́ tó níléèwé. Láìpẹ́ yìí, wọ́n fún wa níṣẹ́ kan pé ká sọ̀rọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ náà, ‘Onírúurú Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀.’ Èmi àti ìdílé mi wá inú àwọn ìtẹ̀jáde, a sì gé àwọn ọ̀rọ̀ àti àwòrán tó bá ẹṣin ọ̀rọ̀ náà mu jáde. Lẹ́yìn náà ni mo wá lẹ àwọn tí a rí mọ́ ara páálí kan.” Olùkọ́ Stephanie sọ fún àwọn ọmọ kíláàsì pé kí wọ́n mú márùn-ún tí wọ́n rò pé ó dára jù lọ lára àwọn iṣẹ́ náà. Stephanie kọ̀wé pé: “Lọ́jọ́ kejì, mo rí i pé tèmi wà lára márùn-ún tó dára jù lọ.”

Ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tí Stephanie lò ni Jí! ti November 8, 1998, tó ní àpilẹ̀kọ kan tó sọ pé “Ǹjẹ́ Gbogbo Ènìyàn Lè Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé?” Níwọ̀n bí Stephanie ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbà dájúdájú pé ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn tó ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. Ní tòótọ́, Stephanie wà lára ẹgbẹ́ ará kan tó wà kárí ayé níbi tí òtítọ́ Bíbélì ti ń so àwọn tó ti jẹ́ ọ̀tá tẹ́lẹ̀ rí pọ̀ ṣọ̀kan—àwọn bíi Tutsi àti Hutu, àwọn ará Jámánì àti àwọn ará Rọ́ṣíà, àwọn ará Áméníà àti àwọn ará Turkey, àwọn ará Japan àtàwọn ará Amẹ́ríkà. Gbogbo wọ́n ń tiraka láti máa ṣàfarawé Ẹlẹ́dàá wọn. Lọ́nà wo? Ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tí Stephanie lò nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ pèsè ìdáhùn, ó sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sa gbogbo ipá wọn láti máa fi irú àìṣègbè kan náà hàn nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

Stephanie ń fojú sọ́nà de ìmúṣẹ ìlérí tí Bíbélì ṣe pé láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú àwọn ipò òdodo wá sórí ilẹ̀ ayé wa. (Ìṣípayá 21:3, 4) Nínú ayé kan tí ọkàn àwọn èwe kò ti balẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú wọn tí kò sì dá wọn lójú yìí, ti Stephanie yàtọ̀ gédégbé, nítorí ó ní ìrètí amọ́kànyọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́