Kí Ló Dé Táwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Fi Wọ́pọ̀ Tó Báyìí?
KÒ SÍ ìwà ọ̀daràn tí kò burú. Àmọ́, àwọn ìwà ọ̀daràn táwọn èèyàn máa ń hù láìnídìí máa ń ṣòro gan-an láti lóye. Ohun tó máa ń rú àwọn olùṣèwádìí lójú ni pé lọ́pọ̀ ìgbà, kì í sí ìdí gúnmọ́ kan táwọn èèyàn yìí fi máa ń hùwà ìkà. Nítorí títàn tí ìròyìn máa ń yára tàn kálẹ̀ láwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, kì í pẹ́ táwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè kan tàbí ní gbogbo ayé pàápàá, fi máa ń mọ̀ nípa irú àwọn ìwà ọ̀daràn bíbùáyà bẹ́ẹ̀. Ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde sọ pé “ìwà ọ̀daràn ò yọ orílẹ̀-èdè kankan sílẹ̀, ṣàṣà sì ni àgbègbè tí kò sí.”
Kódà, àwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti máa ń wò láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn pé kò fi bẹ́ẹ̀ léwu ti wá di ibi tí ọ̀pọ̀ ìwà ipá tí kò mọ́gbọ́n dání ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, látìgbà pípẹ́ wá ni orílẹ̀-èdè Japan kò ti fi bẹ́ẹ̀ ní ìṣòro ìwà ọ̀daràn. Àmọ́, ní oṣù June ọdún 2001, ní ìlú Ikeda, ọkùnrin kan tó mú ọ̀bẹ tí wọ́n fi ń gé ẹran dání rìn wọ inú ilé ẹ̀kọ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gún àwọn ọmọ iléèwé náà, bẹ́ẹ̀ ló sì ń fi ṣá wọn. Láàárín ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré, ó ti pa ọmọ mẹ́jọ ó sì ti ṣe àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún léṣe. Tá a bá pa ìròyìn yìí pọ̀ mọ́ àwọn ìròyìn mìíràn tó ń wá láti ilẹ̀ Japan, irú bíi ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń pa àwọn tí wọn ò mọ̀ rí rárá nítorí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kàn ń mórí wọn yá lásán, èèyàn á rí i dájúdájú pé nǹkan ti yí padà ní orílẹ̀-èdè náà.
Kódà, láwọn orílẹ̀-èdè tí ìwà ipá ti máa ń fìgbà gbogbo ṣẹlẹ̀ pàápàá, àwọn ìwà ipá kan ti wáyé tó jẹ́ pé ó kó àwọn èèyàn nírìíra gan-an. Èyí lohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àjálù tó wáyé ní September 11, 2001, nígbà táwọn kan lọ kọ lu Ibùdó Ìṣòwò Àgbáyé ní Ìlú New York. Gerard Bailes, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú, sọ gbólóhùn yìí pé: “Ńṣe ni [àjálù] náà sọ ayé di ibi àjèjì pátápátá, ibi eléwu téèyàn ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀.”
Kí Ló Ń Mú Wọn Hu Irú Ìwà Bẹ́ẹ̀?
Èèyàn ò lè sọ pé kókó kan báyìí pàtó ló ń fa onírúurú ìwà ọ̀daràn bíburú jáì tó ń ṣẹlẹ̀. Ohun tó mú kí àwọn ìwà ọ̀daràn kan túbọ̀ ṣòro láti lóye ni ọ̀nà tí kò mọ́gbọ́n dání rárá tí wọ́n ń gbà ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣòro láti lóye ohun tó máa mú kí ẹnì kan rìn lọ bá àwọn èèyàn tí kò ṣẹ̀ ẹ́ tí kò rò ó tí yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀bẹ gún wọn títí wọ́n á fi kú tàbí tí ẹnì kan á fi wakọ̀ lọ sí itòsí ilé kan táá sì bẹ̀rẹ̀ sí yìnbọn fún ẹnikẹ́ni tó bá rí.
Àwọn kan sọ pé ìwà ipá ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn. Àwọn mìíràn sì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ sọ bẹ́ẹ̀, pé ohun tá a lè yẹ̀ sílẹ̀ ni.—Wo àpótí náà, “Ṣé Èèyàn Ò Lè Ṣe Kó Má Hùwà Ipá Ni?”
Ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi gbà pé oríṣiríṣi nǹkan àti onírúurú ipò ló máa ń mú kí àwọn èèyàn hu àwọn ìwà ìkà tó burú jáì. Ìròyìn kan tí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde tiẹ̀ sọ ọ́ débi pé: “Èèyàn kan tórí ẹ̀ pé, tí ọpọlọ rẹ̀ sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa kò jẹ́ pààyàn.” Àwọn aláṣẹ kan ò fara mọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Fún ìdí kan tàbí òmíràn, ńṣe làwọn tó ń hu ìwà ọ̀daràn bíburú jáì máa ń ronú lódìlódì, èyí ló sì máa ń sun wọ́n láti ṣe ohun tí èèyàn kan tó gbádùn kò jẹ́ ronú láti ṣe láéláé. Àwọn nǹkan wo ló ń sún àwọn èèyàn sí ṣíṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn nǹkan táwọn ògbógi sọ pé ó ṣeé ṣe kó máa fà á.
Ìdílé Tó Ń Tú Ká
Akọ̀ròyìn Jí! kan béèrè lọ́wọ́ Marianito Panganiban, tó jẹ́ agbẹnusọ fún Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ ní orílẹ̀-èdè Philippines, nípa bí ìgbésí ayé àwọn tó máa ń hu ìwà ọ̀daràn tó burú jáì ṣe máa ń rí látilẹ̀wá. Ó dáhùn pé: “Inú ìdílé tó ti túká ni wọ́n ti máa ń wá. Kò sẹ́ni tó bìkítà nípa wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn ò rẹ́ni fìfẹ́ hàn sí wọn. Wọn ò rẹ́ni sọ fún wọn pé ìwà kan dára tàbí pé ìwà kan burú, nípa bẹ́ẹ̀ wọn ò ní ìtọ́sọ́nà kankan èyí ló sì ń mú kí wọ́n ṣáko lọ.” Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèwádìí sọ pé inú ìdílé tí kò sí àjọṣe tó dán mọ́rán, tí wọ́n sì ti máa ń hùwà ipá síra wọn ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀daràn tó jẹ́ ẹhànnà ti máa ń wá.
Ẹ̀ka Tó Ń Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwà Ọ̀daràn Tó Burú Jáì Nílẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ àkọsílẹ̀ kan jáde, èyí tó to àwọn kókó kan lẹ́sẹẹsẹ téèyàn lè fi dá àwọn ọmọ tó ṣeé ṣe kí wọ́n hu ìwà ọ̀daràn tó lékenkà níléèwé mọ̀. Lára àwọn ìṣòro ìdílé tí wọ́n mẹ́nu kàn nìwọ̀nyí: kí aáwọ̀ máa wà láàárín òbí àti ọmọ ṣáá, àwọn òbí tí kì í mọ̀ pé àwọn ọmọ wọn níṣòro, àìsí àjọṣe tímọ́tímọ́ láàárín òbí àti ọmọ, àwọn òbí tí kì í fi bẹ́ẹ̀ fi òfin lélẹ̀ lórí ìwà tí ọmọ wọn ń hù tàbí kó má tiẹ̀ sí òfin rárá, àtàwọn ọmọ tí kì í dá sí ẹnì kankan rárá àmọ́ tó jẹ́ pé ṣekuṣẹyẹ ni wọ́n, nípa bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní jẹ́ kí àwọn òbí wọn mọ̀ pé wọ́n ní àwọn ìwà kan lọ́wọ́.
Lónìí, ọ̀pọ̀ ọmọ ló bá ara wọn nínú ìdílé tó ti tú ká. Àwọn kan sì rèé, àwọn òbí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún wọn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ló ń dàgbà láìsí ẹ̀kọ́ ilé tàbí ìtọ́sọ́nà lórí ìwà tó dára láti hù. Àwọn ògbógi kan gbà pé irú àwọn ipò wọ̀nyí lè máà jẹ́ kí àwọn ọmọ mọ béèyàn ṣe ń wà nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nípa bẹ́ẹ̀ yóò rọrùn fún wọn láti hùwà ipá sí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, àti pé lọ́pọ̀ ìgbà, wọn ò ní kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe náà.
Àwọn Ẹgbẹ́ Akórìíra Àtàwọn Ẹgbẹ́ Òkùnkùn
Ẹ̀rí fi hàn pé ipa kékeré kọ́ ni àwọn ẹgbẹ́ akórìíra tàbí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn ti kó nínú híhu àwọn ìwà ìkà kan. Ní ìpínlẹ̀ Indiana, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀dọ́mọkùnrin adúláwọ̀ kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ń padà sílé lẹ́yìn tó kúrò ní ilé ìtajà ńlá kan. Kò pẹ́ sí àkókò náà, òkú rẹ̀ ni wọ́n rí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà pẹ̀lú ọta ìbọn kan nínú ọpọlọ rẹ̀. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń wá ẹni tó fẹ́ yìnbọn fún ló pà á. Kí nìdí tó fi pa á? Wọ́n sọ pé apààyàn náà fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan tí wọ́n gbà pé ìran aláwọ̀ funfun lọ̀gá, ó sì fẹ́ gba àmì kan sára nínú ẹgbẹ́ náà fún pípa aláwọ̀ dúdú kan.
Gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí ló jẹ́ pé àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ṣokùnfà wọn: Afẹ́fẹ́ olóró tí wọ́n tú jáde lójú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan ní ìlú Tokyo lọ́dún 1995; pípa tí ọ̀pọ̀ èèyàn fọwọ́ ara wọn para wọn bí-ilẹ̀-bí-ẹní nílùú Jonestown, ní orílẹ̀-èdè Guyana; àti ikú àwọn èèyàn mọ́kàndínláàádọ́rin tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan tó ń jẹ́ Order of the Solar Temple, èyí tó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Switzerland, Kánádà, àti ilẹ̀ Faransé. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn bí àwọn ẹgbẹ́ kan ti ṣe nípa lórí ìrònú àwọn èèyàn kan lọ́nà tó lágbára gan-an. Àwọn aṣáájú tó jẹ́ ẹnú-dùn-ju-yọ̀ náà tún máa ń mú káwọn èèyàn ṣe nǹkan “tí èèyàn kan tó gbádùn kò jẹ́ ronú láti ṣe láéláé” nípa ṣíṣèlérí àwọn àǹfààní kan fún wọn.
Ipa Táwọn Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn Ń Kó Nínú Àwọn Ìwà Ipá Tó Ń Ṣẹlẹ̀
Àwọn kan ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé oríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà gba ìsọfúnni lóde òní lè máa dá kún híhu ìwà jàǹdùkú. Wọ́n ní wíwo ìran oníwà ipá nígbà gbogbo, èyí tí wọ́n ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú fíìmù, nínú àwọn eré ìdárayá orí fídíò, àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, máa ń pa ẹ̀rí ọkàn àwọn èèyàn kú, ó sì máa ń mú kí wọ́n hu àwọn ìwà ọ̀daràn lílékenkà. Dókítà Daniel Borenstein, tó jẹ́ alága Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Ọpọlọ ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, sọ pé: “Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ẹ̀rí tá a ní lọ́wọ́, èyí tá a gbé ka ìwádìí tá a ṣe fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún, tó fi hàn pé àwọn ìwà ipá tí wọ́n ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n ló ń ṣokùnfà ìwà òfínràn táwọn ọmọdé kan máa ń hù.” Nígbà tí Dókítà Borenstein ń sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ó fẹ̀rí ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ nídìí nípa sísọ pé: “Ó dá wa lójú gbangba pé, wíwo onírúurú ìwà ipá nígbà gbogbo fún eré ìnàjú ń ní ipa tó burú gan-an lórí àwọn aráàlú.”—Wo àpótí náà, “Ohun Tí Dókítà Kan Sọ Nípa Ìwà Ipá Tó Máa Ń Wà Nínú Àwọn Eré Ìdárayá Orí Kọ̀ǹpútà.”
Wọ́n sábà máa ń mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ kan ní pàtó láti fi hàn pé òótọ́ lèyí. Nínú ọ̀ràn ti ọkùnrin tó yìnbọn pa tọkọtaya kan tó ń wo bí oòrùn ṣe ń yọ bọ̀ létíkun, èyí tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, tí ọkùnrin náà ò sì kábàámọ̀ kankan, àwọn olùpẹ̀jọ́ mú ẹ̀rí jáde tó fi hàn pé wíwò tí ọkùnrin náà ti máa ń wo ìran oníwà ipá nígbà gbogbo ló sún un dédìí ìpànìyàn tó kà sí nǹkan ìmóríyá yìí. Nínú ọ̀ràn ti ìbọn yíyìn tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ kan, èyí tó ṣekú pa èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, wọ́n sọ pé ọ̀pọ̀ wákàtí làwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì tó hùwà ọ̀daràn náà máa ń lò nídìí eré ìdárayá oníwà ipá orí fídíò lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni wọ́n máa ń wo àwọn fíìmù tó jẹ́ pé ìwà ipá àti ìpànìyàn ṣáá ni wọ́n máa ń gbé lárugẹ.
Oògùn Olóró
Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, iye ìpànìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ látọwọ́ àwọn ọ̀dọ́langba wọ ìlọ́po mẹ́ta láàárín ọdún mẹ́jọ péré. Kí ni ọ̀kan lára ohun tí àwọn aláṣẹ sọ pé ó fa èyí? Àwọn àjọ ìpàǹpá ni, pàápàá àwọn tí wọ́n máa ń lo kokéènì. Nínú ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìpànìyàn tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ní ìlú Los Angeles, ní ìpínlẹ̀ California, “àwọn ọlọ́pàá sọ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló wá látọwọ́ àwọn àjọ ìpàǹpá.”
Ìròyìn kan tí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde sọ kókó yìí pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn kàn ló ń lo oògùn olóró.” Àwọn èèyàn kan tí oògùn olóró ti sọ ìrònú wọn dìdàkudà máa ń pààyàn nígbà tí oògùn náà bá ń darí wọn lọ́wọ́. Àwọn kan tó máa ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró sì máa ń lo ìwà ipá láti fi gbara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn agbófinró. Ó hàn gbangba pé, oògùn olóró jẹ́ kókó kan pàtàkì nínú ohun tó ń ti àwọn èèyàn láti hu àwọn ìwà tó burú jáì.
Kò Ṣòro Láti Rí Àwọn Ohun Ìjà
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, èèyàn márùndínlógójì ni ọkùnrin kan tó gbé ìbọn lọ́wọ́ ní ìlú Tasmania, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, dá nìkan pa, ó sì ṣe àwọn èèyàn mọ́kàndínlógún léṣe. Ìbọn atamátàsé táwọn ológun máa ń lò ni ọkùnrin náà gbé lọ́wọ́. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé bí kò ṣe ṣòro láti rí irú àwọn ohun ìjà bẹ́ẹ̀ tún jẹ́ ohun mìíràn tó ń mú kí ìwà ọ̀daràn tó burú jáì túbọ̀ máa pọ̀ sí i.
Ìròyìn kan fi hàn pé lọ́dún 1995, èèyàn méjìlélọ́gbọ̀n péré ló kú ikú ìbọn ní ilẹ̀ Japan, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó kú wọ̀nyí ni wọ́n sì jẹ́ ara àjọ ìpàǹpá tí àwọn àjọ ìpàǹpá mìíràn ṣekú pa. Àmọ́ ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn èèyàn tí wọ́n fìbọn pa láàárín ọdún yìí kan náà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Kí ló fa ìyàtọ̀ yìí? Àwọn kan sọ pé ohun tó fà á ni pé ilẹ̀ Japan kò gba gbẹ̀rẹ́ lórí òfin níní ìbọn lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè náà.
Àìlè Fàyà Rán Àwọn Ìṣòro Ìgbésí Ayé
Nígbà táwọn kan bá gbọ́ nípa àwọn ìwà ìkà bíburú jáì kan, wọ́n lè sọ pé, ‘Ó ní láti jẹ́ pé orí ẹni yẹn ti yí!’ Ṣùgbọ́n, kì í kúkú ṣe gbogbo àwọn tó ń hu irú ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ ni ọpọlọ wọn dà rú. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló jẹ́ pé ó nira fún wọn láti fara da ìṣòro ìgbésí ayé. Àwọn ọ̀mọ̀ràn mẹ́nu kan àwọn ìhùwàsí kan tó lè mú ẹnì kan hu ìwà ìkà tó burú jáì. Lára wọn nìwọ̀nyí: kéèyàn ní ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti ìṣòro àìlè bá àwọn ẹlòmíràn lò; àwọn àbájáde lílò tí wọ́n ti lo ẹnì kan nílòkulò tàbí tí wọ́n ti fipá bá a lò pọ̀; níní àwọn ìwà tí kò yẹ ọmọlúwàbí lọ́wọ́; níní ìkórìíra fún àwọn èèyàn kan pàtó, irú bí àwọn obìnrin; kéèyàn má màa kábàámọ̀ tó bá ń ṣe ohun tí kò tọ́; àti ìfẹ́ láti máa dọ́gbọ́n rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ.
Ohun tó wù kí ìṣòro wọn jẹ́, àwọn kan máa ń jẹ́ kí ìṣòro wọn bò wọ́n mọ́lẹ̀ débi pé wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò òdì, èyí sì lè mú kí wọ́n ṣe àwọn ohun tí kò bójú mu rárá. Àpẹẹrẹ kan ni ti nọ́ọ̀sì kan tó ń fẹ́ di gbajúmọ̀. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí fún àwọn ọmọ kéékèèké ní abẹ́rẹ́ tó máa mú kí iṣan wọn dẹ̀, àmọ́ táá mú kí wọ́n dáwọ́ mímí dúró. Lẹ́yìn náà, inú rẹ̀ á wá máa dùn báwọn èèyàn ṣe ń wò ó tó ń “dá ẹ̀mí” ọmọ kọ̀ọ̀kan “padà.” Ó ṣeni láàánú pé, kò ṣeé ṣe fún un láti mú kí gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í mí padà. Ni wọ́n bá fẹ̀sùn ìpànìyàn kàn án.
Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, ó hàn gbangba pé, àpapọ̀ oríṣiríṣi nǹkan ló ń mú àwọn èèyàn hu àwọn ìwà ìkà tó burú jáì. Àmọ́ ṣá, àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí kò lè tó láti jẹ́ ká mọ̀dí ọ̀ràn yìí láìgbé kókó kan tó ṣe pàtàkì gan-an yẹ̀ wò.
Ìdáhùn Bíbélì
Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò yìí àti ohun tó ń mú káwọn èèyàn máa hùwà lọ́nà òdì bẹ́ẹ̀. Ó sọ nípa àwọn àṣà tá a máa ń rí nígbà gbogbo lọ́nà tó ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kókó tá a tò lẹ́ṣẹẹsẹ nínú 2 Tímótì 3:3, 4 sọ pé àwọn èèyàn kò ní í ní “ìfẹ́ni àdánidá” àti pé wọ́n á jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere” àti “olùwarùnkì.” Nínú ìwé mìíràn nínú Bíbélì, Jésù sọ pé: “Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”—Mátíù 24:12.
Bíbélì sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” (2 Tímótì 3:1) Láìsí àní-àní, àwọn ohun tí à ń rí yìí jẹ́ ẹ̀rí pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí là ń gbé báyìí. Ńṣe ni ipò àwọn nǹkan, pa pọ̀ pẹ̀lú ìwà àwọn èèyàn, túbọ̀ ń dìdàkudà sí i. Ǹjẹ́ a lè retí pé kí ojútùú dé kíákíá? Bíbélì dá wa lóhùn pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.”—2 Tímótì 3:13.
Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé aráyé ò ní bọ́ nínú ìwà ọ̀daràn tó túbọ̀ ń fojoojúmọ́ ṣẹlẹ̀ yìí ni pa pọ̀ pẹ̀lú ìwà ìkà tó túbọ̀ ń ròkè sí i? Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
ṢÉ ÈÈYÀN Ò LÈ ṢE KÓ MÁ HÙWÀ IPÁ NI?
Àwọn kan sọ pé ìfẹ́ láti hùwà ọ̀daràn tàbí láti pààyàn ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn. Àwọn alátìlẹyìn ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò yé sọ pé ara àwọn ẹranko rírorò la ti ṣẹ̀ wá, nípa bẹ́ẹ̀, láìsí àní-àní, ara wọn la ti jogún ìwà ẹhànnà. Ńṣe ni irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ á fi hàn pé a ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìwà ipá, a ò sì lè rí ọ̀nà àbáyọ.
Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà tó fi hàn pé èyí kì í ṣòótọ́ rárá. Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tá a mẹ́nu kàn lókè yìí kò ṣàlàyé ìdí tí ìwà ipá fi wọ́pọ̀ gan-an láwọn àgbègbè kan ju àgbègbè mìíràn lọ àti ìdí tí wọ́n fi yàtọ̀ síra wọn. Ẹ̀kọ́ náà kò sọ ìdí tó fi jẹ́ pé nínú àwọn àwùjọ kan, ìwà ipá pọ̀ jaburata, nígbà tó jẹ́ pé nínú àwọn àwùjọ mìíràn, a kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ìròyìn ìwà ipá tàbí kí ó má tiẹ̀ sí ìròyìn nípa ìpànìyàn pàápàá. Erich Fromm, tó jẹ́ onímọ̀ nípa èrò inú èèyàn, fi àṣìṣe tó wà nínú ẹ̀kọ́ yìí hàn, ìyẹn jíjogún tí wọ́n sọ pe a jogún ìwà jàgídíjàgan láti ara àwọn ẹranko. Ó sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹranko kan wà tí wọ́n burú nítorí àtirí oúnjẹ tàbí nítorí àtidáàbò bo ara wọn, èèyàn nìkan la mọ̀ tó ń gbẹ̀mí èèyàn tàbí ti ẹranko kìkì láti mórí ara wọn yá.
Nínú ìwé kan tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n méjì, James Alan Fox àti Jack Levin pawọ́ pọ̀ kọ, tí wọ́n pè ní, The Will to Kill—Making Sense of Senseless Murder, wọ́n sọ pé: “Àwọn èèyàn kan máa ń tètè hùwà ipá ju àwọn mìíràn lọ, síbẹ̀ kálukú ló lómìnira láti pinnu ohun tó fẹ́ ṣe. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fà á tí èrò láti pààyàn fi máa ń dìde nínú ẹnì kan, ìyẹn àwọn nǹkan tó wà lọ́kàn onítọ̀hún àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká rẹ̀, síbẹ̀, ohun tí ẹnì kan fẹ́ ṣe àti irú ìpinnu tí ẹni náà ṣe ṣì wé mọ́ ọn, nípa bẹ́ẹ̀ ó tọ́ kí ẹni náà jíhìn kó sì gba ìdálẹ́bi.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
OHUN TÍ DÓKÍTÀ KAN SỌ NÍPA ÌWÀ IPÁ TÓ MÁA Ń WÀ NÍNÚ ÀWỌN ERÉ ÌDÁRAYÁ ORÍ KỌ̀ǸPÚTÀ
Dókítà Richard F. Corlin, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà nígbà kan rí, bá àwùjọ àwọn dókítà kan tó ń gboyè jáde sọ̀rọ̀ ní ìlú Philadelphia, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa àwọn eré ìdárayá orí kọ̀ǹpútà tó jẹ́ pé ìwà ipá ni wọ́n máa ń dá lé lórí. Díẹ̀ nínú àwọn eré ìdárayá yìí máa ń fún àwọn tó bá dá egbò síni lára ní máàkì díẹ̀. Ẹni tí ìbọn rẹ̀ bá ba ẹnì kan á gba máàkì púpọ̀, àmọ́ máàkì ẹni tí ìbọn rẹ̀ bá ṣe kòńgẹ́ agbárí á pọ̀ gan-an. Ẹ̀jẹ̀ á máa tú jáde, mùdùnmúdùn inú ọpọlọ á sì fọ́n káàkiri.
Dókítà Corlin sọ pé, a kì í gba àwọn ọmọ kékeré láyè láti wakọ̀, a kì í jẹ́ kí wọ́n mu ọtí líle, bẹ́ẹ̀ la kì í jẹ́ kí wọ́n mu sìgá nígbà tí wọ́n bá ṣì kéré gan-an. Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Àmọ́, à ń jẹ́ kí wọ́n kọ́ láti di tàbọntàbọn ní ọjọ́ orí tí wọn ò tíì mọ bí wọ́n ṣe lè ṣàkóso àwọn èrò tó bá ṣàdédé wá sí wọn lọ́kàn, tí wọn ò sì tíì dàgbà dénú tàbí kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè kó ara wọn níjàánu láti lo àwọn nǹkan ìjà tí wọ́n ń fi ṣeré náà láìséwu. . . . Ó yẹ ká kọ́ àwọn ọmọ wa nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an pé ìwà ipá [kì í] bímọ re nígbàkigbà, ohun tó máa ń tìdí rẹ̀ jáde kì í dára rárá.”
Ó bani nínú jẹ́ pé, dípò kí àwọn eré náà máa kọ́ àwọn ọmọdé pé àbájáde ìwà ipá kì í dára, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ ọ̀hún gan-an ló máa ń forí fá àwọn àbájáde ìwà ìkà bíburú jáì náà. Ìwádìí fi hàn pé ọmọ mẹ́wàá ló ń kú lójoojúmọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà látàrí ìbọn yíyìn. Dókítà Corlin sọ pé: “Ní gbogbo àgbáyé, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ̀gá nínú bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń kú ikú ìbọn.” Kí ló wá fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ o? “Ewu ńlá ni ìbọn yíyìn jẹ́ fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè wa. Òótọ́ tó dájú hán-ún lèyí.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
ÀWỌN OHUN TÓ Ń FA ÌWÀ ÌKÀ BÍBURÚ JÁÌ
Àwọn ògbógi gbà pé àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí lè fa àwọn ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù láìnídìí:
Kí ìdílé túká
Àwọn ẹgbẹ́ akórìíra, àwọn aláṣerégèé
Àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tó jẹ́ eléwu
Ìwà ipá nínú eré ìnàjú
Kéèyàn máa rí ìwà ipá lójúkojú
Lílo oògùn olóró
Àìlèfàyà-rán-ìṣòro
Rírí àwọn nǹkan ìjà nírọ̀rùn
Oríṣi àwọn àìsàn ọpọlọ kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bọ́ǹbù jíjù márùn-ún tó pa èèyàn méjìlá ó kéré tán, tó sì ṣe àwọn èèyàn tó lé lọ́gọ́rin léṣe ní ìlú Quezon City, lórílẹ̀-èdè Philippines
[Credit Line]
AP Photo/Aaron Favila December 30, 2000
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì pa tíṣà kan àtàwọn ọmọléèwé méjìlá, wọ́n sì tún pa ara wọn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Columbine, ní ìpínlẹ̀ Colorado, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
[Credit Line]
AP Photo/Jefferson County Sheriff’s Department April 20, 1999
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Bọ́ǹbù tí wọ́n fi sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan pa èèyàn méjìlélọ́gọ́sàn-án [182], ó sì ṣe èèyàn méjìléláàádóje [132] léṣe, ní ilé ìgbafàájì alaalẹ́ kan ní ìlú Bali, lórílẹ̀-èdè Indonesia
[Credit Line]
Maldonado Roberto/GAMMA October 12, 2002