Ìdí Tí Wọn Fi Ń hùwà ipá
WỌ́N bí ọmọ kan tí oṣù rẹ̀ kò pé, tí oyún rẹ̀ jẹ́ ọ̀sẹ̀ 27, ní Denver, Colorado, U.S.A. Ọmọkùnrin náà yè, wọ́n sì dá a padà fún àwọn òbí rẹ̀ nílé lẹ́yìn oṣù mẹ́ta nílé ìwòsàn. Lọ́sẹ̀ kẹta lẹ́yìn náà, wọ́n gbé ọmọkùnrin náà padà sílé ìwòsàn. Kí ló fà á? Baba rẹ̀ ti pa ọpọlọ rẹ̀ lára nígbà tó fipá mi ọmọ náà jìgìjìgì. Baba ọmọ náà kò rí ara gba igbe tó ń ké. Nípa bẹ́ẹ̀, ojú ọmọ kékeré náà fọ́, ó sì di abirùn. Ìṣègùn òde òní ti gbà á lọ́wọ́ hílàhílo ìgbà tí a bí i, àmọ́ kò lè gbà á lọ́wọ́ ìwà ipá baba rẹ̀.
Àìlóǹkà ọmọdé ni a ń fipá bá lò, tí a ń lù bolẹ̀, tàbí tí a ń pa nínú ọ̀kan lára àwọn ibi tí ìwà ipá ti pọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé—nínú ilé! Àwọn kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ń pa lọ́dọọdún ní United States nìkan tó 5,000! Àwọn ọmọdé nìkan sì kọ́ ló ń fara gbá a. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn World Health ṣe sọ, ní United States, “lílu aya ẹni bolẹ̀ ló ń fa ìpalára jù fún àwọn obìnrin tí kò ì dàgbà jù láti bímọ.” Ní àwọn ilẹ̀ mìíràn ńkọ́? “Láti orí ìdámẹ́ta sí iye tó kọjá ìdajì àwọn obìnrin tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò [ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà] sọ pé àwọn ọkọ wọn máa ń lù wọ́n.” Ní gidi, ìwà ipá ń gbẹ̀mí àwọn ènìyàn, ní pàtàkì, nínú ilé.
Tìpá-tìkúùkù ni ọ̀pọ̀ tọkọtaya fi ń yanjú àwọn èdèkòyédè. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn òbí àti olùkọ́ ń hùwà ipá sí àwọn ọmọdé nítorí inú tí ń bí wọn. Àwọn abúmọ́ni tí ń fẹ́ dá ara wọn lára yá lásán ń fòòró àwọn tí kò lágbára tó wọn, wọ́n sì ń hùwà ipá sí wọn. Kí ló mú kí àwọn ènìyàn máa hùwà ipá tó bẹ́ẹ̀?
Ìdí Tí Àwọn Ènìyàn Fi Di Oníwà Ipá
Àwọn kan sọ pé ìwà ipá jẹ́ àdámọ́ ènìyàn. Nígbà tí ìwà ipá lápapọ̀ dín kù ní United States, ó ti pọ̀ sí i láàárín àwọn ọ̀dọ́. Àwọn ènìyàn túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá. Àwọn àsokọ́ra mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n tó gbajúmọ̀ jù ti sọ iye ìtàn oníwà ipá tí wọ́n ń gbé jáde di ìlọ́po méjì, wọ́n sì sọ iye ọ̀ràn ìpànìyàn tí wọ́n ń gbé jáde di ìlọ́po mẹ́ta. Ní gidi, ìwà ọ̀daràn ń mówó wọlé! Oníṣègùn ọpọlọ, Karl Menninger, sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé a ń fàyè gba ìwà ipá, ńṣe la tún ń gbé e sí ojú ìwé kìíní àwọn ìwé ìròyìn wa. Ìdámẹ́ta tàbí ìdámẹ́rin àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n wa ń fi dá àwọn ọmọ wa lára yá. Kì í ṣe pé a ń fàyè gba ìwà ipá nìkan ni! Ẹ̀yin ènìyàn mi, ó ń dùn mọ́ wa.”
Àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a ṣe ní ìlànà sáyẹ́ǹsì sọ pé, àgbékalẹ̀ ọpọlọ àti àyíká para pọ̀ ń nípa lórí ìwà ipá tí ènìyàn ń hù. Ọ̀mọ̀wé Markus J. Kruesi, láti Ẹ̀ka Ìwádìí Ọ̀rọ̀ Àwọn Èwe ní Yunifásítì Illinois sọ pé: “Ibi tí gbogbo wa bẹ̀rẹ̀ sí í fẹnu kò sí ni pé, àwọn àyíká eléwu tí àwọn ọmọ tí ń pọ̀ sí i ń bá ara wọn ń mú kí ìwà ipá gbilẹ̀ sí i ní gidi. Àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láyìíká ń fa àwọn ìyípadà molecule inú ọpọlọ lọ́nà tí ń mú kí àwọn ènìyàn máa hùwà láìro àbájáde rẹ̀ wò.” Ìwé Inside the Brain sọ pé, àwọn kókó bí “ìṣètò ìdílé tí ó forí ṣánpọ́n, ìdílé olóbìí kan tí ń pọ̀ sí i, ipò òṣì tí kò yí padà, àti ìjoògùnyó tó ti di bárakú lè mú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ọpọlọ tẹ̀ sí híhùwà ipá—ohun kan tí a ti rò pé kò lè ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀.”
Wọ́n sọ pé, lára àwọn ìyípadà inú ọpọlọ náà ni ìdínkù nínú ìwọ̀n èròjà serotonin, kẹ́míkà kan tó wà nínú ọpọlọ, tí a rò pé ó máa ń tẹ ìbínú rì. Àwọn ìwádìí fi hàn pé ọtí líle lè dín ìwọ̀n èròjà serotonin inú ọpọlọ kù, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fúnni ní àlàyé tó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu nípa ìbátan tí a ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé ó wà láàárín ìwà ipá àti ọtí àmujù.
Kókó mìíràn tún wà tó kan bí ìwà ipá ṣe ń pọ̀ sí i lónìí. Ìwé alásọtẹ́lẹ̀ kan, tí ó ṣeé fọkàn tán, Bíbélì, sọ pé: “Máa rántí pé, àwọn àkókò tó ṣòro yóò wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, oníwọra, afọ́nnu, àti ajọra-ẹni-lójú; . . . wọn yóò jẹ́ ìkà, aláìláàánú, abanijẹ́, oníwà ipá àti oníkanra; wọn yóò kórìíra ohun rere; wọn yóò jẹ́ aládàkàdekè, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, awúfùkẹ̀ nítorí ìgbéraga . . . Yẹra fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.” (2 Tímótì 3:1-5, Today’s English Version) Ní tòótọ́, ìwà ipá tí a ń rí lónìí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”
Ohun mìíràn kan tún mú kí àkókò yìí kún fún ìwà ipá púpọ̀. Bíbélì wí pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) A ti lé Èṣù àti ogunlọ́gọ̀ ẹ̀mí èṣù kúrò ní ọ̀run, wọ́n sì ti ń darí gbogbo ìwà ibi wọn sí aráyé. Gẹ́gẹ́ bí “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́,” Èṣù ń lo “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn,” ó sì ń mú kí ìwà ipá gbilẹ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.—Éfésù 2:2.
Báwo wá ni a ṣe lè kojú “afẹ́fẹ́” oníwà ipá ti ayé òde òní? Báwo ni a sì ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro ní ìtùnbí-ìnùbí?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Àìlóǹkà ọmọdé ni a ń fipá bá lò, tí a ń lù bolẹ̀, tàbí tí a ń pa nínú ọ̀kan lára àwọn ibi tí ìwà ipá ti pọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé—inú ilé!