ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 2/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìwà Ipá Wà Níbi Gbogbo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Ipá Wà Níbi Gbogbo
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwà Ipá Nínú Ilé
  • Ìwà Ipá Níbi Iṣẹ́
  • Ìwà Ipá Nínú Eré Ìdárayá àti Eré Ìnàjú
  • Ìwà Ipá ní Ilé Ẹ̀kọ́
  • Àṣà Ìwà Ipá
  • Irú Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Ipá?
    Jí!—2002
  • Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ipá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìwà Ipá
    Jí!—2015
  • Kí Ló Dé Táwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Fi Wọ́pọ̀ Tó Báyìí?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 2/15 ojú ìwé 3-4

Ìwà Ipá Wà Níbi Gbogbo

Ó JÓKÒÓ sínú ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, ó ń dúró kí iná tí ń darí ọkọ̀ ní kí ó máa lọ, lójijì, awakọ̀ náà kíyè sí ọkùnrin kan tí ó síngbọnlẹ̀ tí ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, tí ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ rírùn jáde, tí ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ṣàpèjúwe. Awakọ̀ náà yára ti ilẹ̀kùn rẹ̀, ó sì sé fèrèsé rẹ̀, ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó síngbọnlẹ̀ náà túbọ̀ ń sún tọ̀ ọ́. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ọkùnrin náà mi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà jìgìjìgì, ó sì ṣí ilẹ̀kùn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó fi tìbínútìbínú gbé ọwọ́ rẹ̀ títóbi sókè, ó sì jàn án mọ́ gíláàsì ọkọ̀ náà, ó sì fọ́ ọ yángá.

Ìran yìí ha jẹ́ láti inú sinimá amúnigbọ̀nrìrì kan bí? Rárá o! Èyí jẹ́ ìjà òpópónà kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní erékùṣù Oahu, Hawaii, tí a mọ̀ bí àyíká títòrò, tí kò ti sí wàhálà.

Kò yani lẹ́nu. Àwọn àgádágodo ẹnu ilẹ̀kùn, irin ojú fèrèsé, àwọn ẹ̀ṣọ́ níwájú ilé, àní àwọn àmì lára bọ́ọ̀sì pàápàá, tí ń sọ pé “Awakọ̀ yìí kò gbówó rìn”—gbogbo rẹ̀ tọ́ka sí ohun kan pé: Ìwà ipá wà níbi gbogbo!

Ìwà Ipá Nínú Ilé

Ó ti pẹ́ gan-an tí a ti ń ṣìkẹ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ààbò. Ṣùgbọ́n, èrò yìí ti ń yí padà kíákíá. Ìwà ipá nínú ìdílé, èyí tí ó ní ìfìyàjẹ ọmọdé, lílu aya ẹni, àti ìpànìyàn nínú, ń di kókó inú ìròyìn jákèjádò ayé.

Fún àpẹẹrẹ, ìwé agbéròyìnjáde Manchester Guardian Weekly sọ pé: “Ó kéré tán 750,000 àwọn ọmọ ní Britain lè jìyà ìdààmú ọkàn fún ìgbà pípẹ́ nítorí pé a ti jọ̀wọ́ wọn fún agbára ìdarí ìwà ipá abẹ́lé.” A gbé ìròyìn náà karí ìwádìí kan tí ó rí i pẹ̀lú pé, “mẹ́ta nínú àwọn obìnrin mẹ́rin tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò wí pé, àwọn ọmọ wọn ti rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oníwà ipá, èyí tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọ náà ti rí i tí a ń lu ìyá wọn.” Lọ́nà tí ó jọra, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report pẹ̀lú ti sọ, Àjọ Afúnninímọ̀ràn Lórí Ìfìyàjẹ Ọmọdé àti Pípa Ọmọdé Tì ní United States, fojú díwọ̀n pé, “2,000 àwọn ọmọ, tí púpọ̀ jù lọ nínú wọn kò tí ì pé ọdún 4, ń kú mọ́ àwọn òbí tàbí àwọn agbọmọtọ́jú lọ́wọ́ lọ́dọọdún.” Ìròyìn náà sọ pé, èyí ju iye ikú tí jàm̀bá ojú pópó, rírì sínú odò, tàbí ṣíṣubú ń fà lọ.

Ìwà ipá abẹ́lé tún ní ìfìyàjẹ aya ẹni nínú, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ láti orí títaari ẹni tàbí títini, títí dé orí gbígbáni létí, títani nípàá, mímúni bínú, fífi ọ̀bẹ tàbí ìbọn halẹ̀ mọ́ni, tàbí pípani pàápàá. Lónìí, tọkùnrin tobìnrin sì ni irú ìwà ipá yìí ń ṣẹlẹ̀ sí. Ìwádìí kan rí i pé, nínú àwọn ìwà ipá tí a ròyìn rẹ̀ láàárín àwọn lọ́kọláya, ìdá mẹ́rin nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ìdá mẹ́rin mìíràn jẹ́ láti ọ̀dọ̀ obìnrin, a sì lè ṣàpèjúwe àwọn yòókù gẹ́gẹ́ bí asọ̀, èyí tí apá méjèèjì gbọ́dọ̀ jùmọ̀ pín ẹ̀bi náà.

Ìwà Ipá Níbi Iṣẹ́

Ní ibi tí kì í ṣe ilé, ibi iṣẹ́ ti sábà jẹ́ ibi tí ẹnì kan ti ń rí ìwàlétòlétò, ọ̀wọ̀ àti ẹ̀yẹ. Ṣùgbọ́n, ó dà bíi pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Fún àpẹẹrẹ, àkójọ ìṣọfúnni oníṣirò tí Ẹ̀ka Ìdájọ́ ní United States gbé jáde fi hàn pé, lọ́dọọdún, iye ènìyàn tí ó lé ní 970,000 ń nírìírí ìwà ipá ní ibi iṣẹ́. Bí a bá sọ ọ́ lọ́nà míràn, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn inú ìwé ìròyìn Professional Safety—Journal of the American Society of Safety Engineers ti sọ: “Ó ṣeé ṣe kí ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn òṣìṣẹ́ nírìírí ìwà ipá.”

Ohun tí ń dani láàmú jù lọ ni pé, ìwà ipá ní ibi iṣẹ́ kò mọ sí asọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí nìkan. Ìròyìn kan náà sọ pé: “Báyìí, ìwà ipá tí àwọn mìíràn tí a gbà síṣẹ́ ń darí ní tààràtà sí àwọn agbanisíṣẹ́ àti àwọn tí a gbà síṣẹ́ ni ìpànìyàn tí ń peléke sí i jù lọ ní U.S.” Ní 1992, 1 nínú àwọn ìjàm̀bá 6 tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ jẹ́ ìpànìyàn; ní ti àwọn obìnrin, iye náà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1 nínú 2. Kò ṣeé sẹ́ pé, ìwà ipá ń gba ibi iṣẹ́ tí ó wà létòlétò tẹ́lẹ̀ rí kan.

Ìwà Ipá Nínú Eré Ìdárayá àti Eré Ìnàjú

A ti lépa eré ìdárayá àti eré ìnàjú gẹ́gẹ́ bí ohun àyàbá tàbí ohun tí ó lè mú ìtura bá ẹnì kan, nítorí àwọn ìdáwọ́lé pàtàkì púpọ̀ sí i nínú ìgbésí ayé. Lónìí, eré ìnàjú jẹ́ ilé iṣẹ́ ọlọ́kẹ̀ẹ́ àìmọye bílíọ̀nù dọ́là. Láti lè jèrè rẹpẹtẹ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti inú ọjà tí ń mówó wọlé yìí, àwọn olùṣe eré ìnàjú kò lòdì sí lílo ọ̀nàkọnà tí ó bá wà níkàáwọ́ wọn. Ọ̀kan nínú irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ sì ni ìwà ipá.

Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn iṣẹ́ ajé kan, Forbes, ròyìn pé, olùṣe eré fídíò kan ní eré ológun kan tí ó lókìkí, nínú èyí tí jagunjagun kan ti ń fọ́ orí àti ògóóró ẹ̀yìn ẹni tí ó ń bá jà, tí àwọn òǹwòran sì ń pariwo pé, “Pa á! Pa á!” Ṣùgbọ́n, ẹ̀dà eré náà tí ó ṣe fún ilé iṣẹ́ kan tí ń bá a díje kò ní ìran afẹ̀jẹ̀wẹ̀ yìí. Kí ni ó yọrí sí? Ẹ̀dà tí ó jẹ́ oníwà ipá jù lọ tà ju ti ẹni tí ń bá a díje lọ lórí ìṣirò ìfiwéra 3 sí 2. Owó ńlá sì ni èyí jẹ́. Nígbà tí ẹ̀dà eré yìí tí a lè wo lábẹ́lé de orí àtẹ, àwọn ilé iṣẹ́ náà pa 65 mílíọ̀nù dọ́là káàkiri àgbáyé ní ọ̀sẹ̀ méjì àkọ́kọ́! Nígbà tí èrè bá ti wọ̀ ọ́, ìwà ipá wulẹ̀ jẹ́ ohun ọdẹ mìíràn fún àwọn olùrà.

Ọ̀ràn míràn ni ìwà ipá nínú eré ìdárayá. Àwọn eléré ìdárayá náà máa ń fi bí wọ́n ti lè pani lára tó yangàn. Fún àpẹẹrẹ, níbi eré họ́kì kan ní 1990, ìgbà 86 ni a gbá pẹnáritì—iye tí ó pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Rúkèrúdò àmọ̀ọ́mọ̀-dá-sílẹ̀ dá eré náà dúró fún wákàtí mẹ́ta àbọ̀. A tọ́jú eléré ìdárayá kan fún kíkán ní egungun iwájú orí, ọgbẹ́ ẹyinjú, àti ọgbẹ́ ńlá kan nínú ẹran ara. Kí ni ó fa irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀? Eléré ìdárayá kan ṣàlàyé pé: “Nígbà tí o bá gbégbá orókè nínú eré ìdárayá kan tí ó kún fún èrò ìmọ̀lára gidi, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjà, ìwọ yóò lọ sílé pẹ̀lú ìmọ̀lára títúbọ̀ wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ. Mo rò pé, ìjà náà túbọ̀ mú kí ó jẹ́ eré nípa tẹ̀mí ní ti gidi.” Nínú èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú eré ìdárayá lónìí, ó dà bíi pé, ìwà ipá kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀nà láti rí ohun tí ọkàn ẹní fẹ́ gan-an, ṣùgbọ́n ìwà ipá fúnra rẹ̀ jẹ́ ohun tí ọkàn ẹní fẹ́.

Ìwà Ipá ní Ilé Ẹ̀kọ́

A ti fìgbà gbogbo ka ilé ẹ̀kọ́ sí ibi ààbò, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ ti lè gbàgbé gbogbo àníyàn wọn, kí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí mímú ìrònú àti ara wọn dàgbà sókè. Ṣùgbọ́n, lónìí, ilé ẹ̀kọ́ kì í ṣe ibi ààbò tí kò sì léwu mọ́. Ìwádìí èrò kiri ti Gallup ní 1994 fi hàn pé, ìwà ipá àti àwọn ẹgbẹ́ jàǹdùkú jẹ́ ìṣòro àkọ́kọ́ tí ó wà ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba ní United States, ó ré kọjá ti ìnáwó, tí ó gba ipò kíní ní ọdún tí ó ṣáájú. Báwo ni ipò náà ṣe burú tó?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ 1 nínú àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ 4 tí a wádìí lẹ́nu wọn ni ó dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ ni sí ìbéèrè náà pé: “O ha ti jìyà ìṣe oníwà ipá tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí ní agbègbè rẹ rí bí?” Iye tí ó lé ní ìdá kan nínú mẹ́wàá àwọn olùkọ́ pẹ̀lú dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ ni. Ìwádìí kan náà tún rí ìpín mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọ́n ti mú ohun ìjà lọ sí ilé ẹ̀kọ́ nígbà kan tàbí òmíràn. Púpọ̀ jù lọ nínú wọ́n jẹ́wọ́ pé, àwọn ṣe bẹ́ẹ̀ kìkì láti wú àwọn ẹlòmíràn lórí tàbí láti dáàbò bo ara àwọn. Ṣùgbọ́n, akẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún 17 kan yìnbọn sí olùkọ́ rẹ̀ ní igbá àyà, nígbà tí olùkọ́ náà gbìyànjú láti gba ìbọn rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

Àṣà Ìwà Ipá

Kò ṣeé sẹ́ pé, ìwà ipá wà ní ibi gbogbo lónìí. Nínú ilé, ní ibi iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, àti nínú eré ìnàjú, a ń dojú kọ àṣà ìwà ipá. Nítorí tí a ń rí i ní ojoojúmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti wá gbà á gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò burú—àfi ìgbà tí wọ́n tó nírìírí rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n yóò béèrè pé, Yóò ha dópin láé bí? Ìwọ pẹ̀lú yóò ha fẹ́ láti mọ ìdáhùn náà bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́