Bíbímọ Sínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́
INÚ ayé aláìnífẹ̀ẹ́, ayé òǹrorò, ayé tó kún fún másùnmáwo làwọn ìyá ń bímọ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ọwọ́ kò lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn gan-an jáde, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà gbọ́ pé kódà ṣáájú kí wọ́n tó bímọ rárá ni ọmọ inú ti ń mọ ohun tó ń lọ láyìíká rẹ̀.
Ìwé náà The Secret Life of the Unborn Child sọ pé: “A ti wá mọ̀ báyìí pé ọmọ tí a kò tíì bí jẹ́ ẹ̀dá èèyàn kan tó lè fi ìmọ̀lára rẹ̀ hàn bí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ sí i, tó jẹ́ pé láti oṣù mẹ́fà tí wọ́n bá ti lóyún rẹ̀ (àní bóyá ṣáájú ìgbà yẹn pàápàá) ni agbára ìrònú àti ìmọ̀lára rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọwọ́ náà lè máà rántí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé àfàìmọ̀ ni másùnmáwo tó ń wáyé nígbà ìbímọ kò ní nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la.
Lẹ́yìn tí wọ́n bá bí i tán, másùnmáwo náà á ṣì máa bá a lọ. Nísinsìnyí tí kò sí nínú ilé ọlẹ̀ mọ́, ọ̀nà tó ń gbà jẹun á yí padà nítorí kò tún ní máa gba oúnjẹ láti ara ìyá rẹ̀ mọ́ bó ṣe rí ṣáájú kí wọ́n tó bí i. Ibi ọmọ tó ń gbé afẹ́fẹ́ ọ́síjìn àtàwọn èròjà aṣaralóore lọ sára rẹ̀ kò sí mọ́. Kó lè yè, ó gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mí, kó sì máa gba àwọn èròjà aṣaralóore sínú fúnra rẹ̀. Ó nílò ẹnì kan láti máa fún un lóúnjẹ àti láti máa pèsè àwọn ohun mìíràn tó nílò.
Ìdàgbàsókè tún ní láti bá ọpọlọ ìkókó náà àti agbára ìmọ̀lára rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ní láti dàgbà nípa tẹ̀mí. Látàrí èyí, ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà tí yóò máa ṣìkẹ́ ọmọ jòjòló náà. Ta ló tóótun jù lọ láti ṣe èyí? Kí ni ọmọ ọwọ́ náà nílò látọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀? Ọ̀nà wo ló dára jù lọ láti gbà pèsè àwọn ohun wọ̀nyí? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.