Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Nílò àti Ohun Tí Wọ́n Fẹ́
LÁTI ìgbà tí wọ́n bá ti bí ọmọ ọwọ́ kan ló ti nílò ìtọ́jú jẹ̀lẹ́ńkẹ́, lára èyí sì ni fífọwọ́ pa á lára àti gbígbé e mọ́ra. Àwọn oníṣègùn kan gbà gbọ́ pé wákàtí méjìlá àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ṣe pàtàkì gan-an ni. Wọ́n sọ pé ohun tí ìyá àti ọmọ nílò jù lọ ní gbàrà tí ìyá bá ti bímọ tán “kì í ṣe oorun tàbí oúnjẹ, àmọ́ kí ìyá gbé ọmọ náà mọ́ra kó sì máa fi ọwọ́ pa á lára. Bákan náà, kí ìyá àti ọmọ máa wo ojú ara wọn, kí wọ́n sì máa tẹ́tí sí ara wọn.”a
Láìsí pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn, àwọn òbí máa ń gbé ọmọ wọn mọ́ra, wọ́n sì máa ń fọwọ́ pa á lára. Èyí ló máa sún ọmọ náà láti fà mọ́ àwọn òbí rẹ̀ láìsí ìbẹ̀rù èyíkéyìí, tí òun náà á sì máa fi ìfẹ́ hàn sí wọn padà. Ìfẹ́ tó wà láàárín wọn yìí lágbára gan-an débi pé àwọn òbí náà yóò fi àwọn ohun kan du ara wọn láti lè tọ́jú ọmọ ọwọ́ náà láìkáàárẹ̀.
Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí àwọn òbí kò bá fi ìfẹ́ hàn sí ọmọ wọn jòjòló, ó lè máa di aláìlágbára díẹ̀díẹ̀ títí tó máa fi kú. Nítorí náà, àwọn dókítà kan gbà gbọ́ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n gbé ọmọ fún ìyá rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó bá ti bí i tán. Wọ́n dábàá pé ó yẹ kí wọ́n fún ìyá àti ọmọdé jòjòló láǹfààní láti wà pa pọ̀ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan ó kéré tán lẹ́yìn ìbímọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń tẹnu mọ́ ọn pé ìfẹ́ àárín ìyá àti ọmọ ṣe pàtàkì gidigidi, jíjẹ́ kí ìyá àti ọmọ jọ wà pa pọ̀ ní gbàrà tí ìyá bá bímọ lè má rọrùn, àní ó lè má ṣeé ṣe pàápàá láwọn ilé ìwòsàn kan. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìdí tí wọ́n fi máa ń gbé ọmọ ìkókó kúrò lọ́dọ̀ ìyá ni pé ìyá náà lè kó àrùn ran ọmọ náà. Àmọ́ o, àwọn ìwádìí kan ti fi hàn pé bí àwọn ọmọ ìkókó bá ń wà lọ́dọ̀ àwọn ìyá wọn, ó ṣeé ṣe kí àwọn àrùn tó lè ṣekú pa wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ nípa lórí wọn. Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ló ti ń gbà báyìí pé kí àkókò tí àwọn ìyá ìkókó fi ń gbé ọmọ wọn ní gbàrà tí wọ́n bá bí i tán túbọ̀ gùn sí i.
Àwọn Ìyá Tó Ń Ṣàníyàn Nípa Nínífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọmọ Wọn
Àwọn ìyá kan wà tó jẹ́ pé ọkàn wọn kì í fà sí ọmọ wọn ní gbàrà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí i. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń wò ó pé, ‘Ṣé nínífẹ̀ẹ́ ọmọ mi ò ní ṣòro fún mi báyìí?’ Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìyá ló máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá rí i. Síbẹ̀, kò sídìí láti máa ṣàníyàn.
Kódà bí ìyá ò bá fìfẹ́ hàn sí ọmọ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìfẹ́ yìí lè máa wá díẹ̀díẹ̀. Ìyá kan tó jẹ́ onírìírí sọ pé: “Kò sí ohun kan ní pàtó tó wáyé nígbà ìbí tó ń pinnu bóyá wàá nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ tàbí o kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.” Síbẹ̀síbẹ̀, bó o bá jẹ́ aboyún tó o sì ń ṣàníyàn nípa nínífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ, á dára kó o lọ bá olùtọ́jú aboyún tó ń ṣètọ́jú rẹ sọ̀rọ̀ ṣáájú àkókò. Ṣe àlàyé yékéyéké fún un pé wàá fẹ́ láti gbé ọmọ rẹ mọ́ra ní gbàrà tó o bá ti bí i tán kó o sì tún jẹ́ kó mọ bí wàá ṣe fẹ́ láti gbé e mọ́ra pẹ́ tó.
“Ẹ Bá Mi Sọ̀rọ̀!”
Ó dà bíi pé àwọn àkókò pàtó kan wà tí àǹfààní máa ń ṣí sílẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ ọwọ́ máa ń lóye àwọn ohun tí wọ́n bá gbọ́ tàbí tí wọ́n bá rí gan-an. Àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wọ̀nyẹn máa ń lọ lẹ́yìn àkókò díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó rọrùn fún àwọn ọmọdé láti kọ́ èdè, kódà bí èdè ọ̀hún bá ju ẹyọ kan lọ pàápàá. Ṣùgbọ́n ó dà bíi pé àǹfààní tí àwọn ọmọdé máa ń ní jù lọ láti lóye èdè máa ń wá sópin ní nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún.
Lẹ́yìn tí ọmọ kan bá ti pé ọmọ ọdún méjìlá sí mẹ́rìnlá, ó lè nira gan-an fún un láti kọ́ èdè. Peter Huttenlocher, onímọ̀ nípa ìtọ́jú àrùn iṣan ara àwọn ọmọdé, sọ pé ìgbà yẹn ni “àwọn fọ́nrán iṣan tó wà lápá ibi téèyàn fi ń kọ́ èdè nínú ọpọlọ máa ń dín kù.” Láìsí àní-àní, àwọn ọdún tí ọmọ kan kọ́kọ́ lò láyé jẹ́ àkókò tó ṣe pàtàkì gan-an fún kíkọ́ èdè!
Báwo làwọn ìkókó ṣe máa ń kọ́ láti sọ̀rọ̀, èyí tó jẹ́ ohun àgbàyanu tó sì ṣe pàtàkì gan-an fún wọn láti túbọ̀ lo ọpọlọ wọn dáadáa fún kíkẹ́kọ̀ọ́, ríronú àti lílóye nǹkan? Ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n ń gbà ṣe èyí ni nípa bíbá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọ ọwọ́ máa ń fi ìmọ̀lára wọn hàn, ní pàtàkì, sí ohun tí wọ́n bá gbọ́ tàbí tí wọ́n bá rí tí àwọn èèyàn ń ṣe láyìíká wọn. Barry Arons tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Ìmọ̀ Ẹ̀rọ ti Massachusetts sọ pé: “Ọmọ ọwọ́ . . . máa ń sín ohùn ìyá rẹ̀ jẹ.” Àmọ́ o, ohun tó gbàfiyèsí ni pé kì í ṣe gbogbo ìró ohùn làwọn ọmọ ọwọ́ máa ń sín jẹ. Gẹ́gẹ́ bí Arons ṣe ṣàkíyèsí, àwọn ọmọ ọwọ́ “kì í sín gbogbo ariwo mìíràn tí wọ́n bá gbọ́ láyìíká wọn jẹ nígbà tí ìyá wọn bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́.”
Nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀nà kan náà làwọn òbí máa ń gbà bá àwọn ọmọ ọwọ́ wọn sọ̀rọ̀, nípa lílo èdè táwọn ọmọdé lè tètè gbọ́. Bí òbí bá ṣe ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ tìfẹ́tìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn-àyà ọmọ ọwọ́ náà á túbọ̀ máa lù kìkì sí i. Èyí ni wọ́n sọ pé ó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọdé láti tètè lóye ọ̀rọ̀ àti ohun tí wọ́n dúró fún. Láìsí pé ọmọ ọwọ́ náà sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, ńṣe ló máa dà bíi pé ó ń rọ àwọn òbí rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi sọ̀rọ̀!”
“Ẹ Wò Mí!”
Àwọn ògbógi ti ṣàwárí pé ní nǹkan bí ọdún àkọ́kọ́ tí wọ́n bá bí ọmọ kan, ọmọ ọwọ́ náà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ẹni tó bá ń tọ́jú rẹ̀, pàápàá ìyá rẹ̀. Nígbà tí ọkàn ọmọ náà bá ti fà sí ìyá rẹ̀ báyìí láìsí ìbẹ̀rù èyíkéyìí, ara rẹ̀ á yọ̀ mọ́ọ̀yàn ju àwọn ọmọ tí kò bá ní irú ìfẹ́ òbí bẹ́ẹ̀. Wọ́n ní ó ti yẹ kí ọmọ ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí òbí rẹ̀ nígbà tó bá fi máa pé ọdún mẹ́ta.
Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí ọmọ ọwọ́ kan bá di ẹni tá a pa tì ní àkókò ẹlẹgẹ́ yìí, nígbà tí àwọn ohun tó ń lọ láyìíká rẹ̀ lè nípa lórí ìrònú rẹ̀ gan-an? Martha Farrell Erickson, ẹni tó fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ìyá àti ọmọ wọn tí iye wọn jẹ́ àádọ́rin lé rúgba ó dín mẹ́ta [267] fún ogún ọdún, sọ pé: “Ńṣe ni pípa ọmọ tì máa ń paná ìtara ọkàn ọmọdé kan díẹ̀díẹ̀, tí kò ní jẹ́ kí ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ọ̀yàn, títí dìgbà tí [ọmọ náà] kò ní fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tàbí mímọ̀ nípa àwọn ohun tó ń lọ láyé.”
Dókítà Bruce Perry, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ìwòsàn Àwọn Ọmọ Wẹ́wẹ́ ní Texas, ṣe àkàwé kan nípa àbájáde bíburú jáì tó wà nínú ṣíṣàì bìkítà rárá fún ọmọ, ó ní: “Bí wọ́n bá ní kí n mú ọ̀kan lára ohun méjì kan, ìyẹn ni pé bóyá kí n fọ́ gbogbo eegun tó wà lára ọmọ oṣù mẹ́fà kan tàbí kí n pa á tì fún oṣù méjì, mo gbà pé kéèyàn fọ́ gbogbo eegun ara rẹ̀ ló máa dára jù fún ọmọ náà.” Kí nìdí? Lójú ìwòye Perry, “eegun lè padà bọ̀ sípò, àmọ́ bí ọmọ ọwọ́ kò bá ní àǹfààní láti rí ohun tí ọpọlọ rẹ̀ yóò máa ṣiṣẹ́ lé lórí fún odindi oṣù méjì, ọpọlọ rẹ̀ lè má ṣiṣẹ́ dáadáa títí ayé.” Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé irú àkóbá bẹ́ẹ̀ ò ṣeé ṣàtúnṣe sí. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ìwádìí tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe ti fi hàn pé fífi ìfẹ́ hàn sí ọmọ ṣe kókó fún ọpọlọ ọmọ ọwọ́ kan.
Ìwé náà Infant sọ pé: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, [àwọn ọmọ ọwọ́] máa ń fẹ́ láti fìfẹ́ hàn àti láti di ẹni tí a nífẹ̀ẹ́.” Nígbà tí ọmọ ọwọ́ kan bá ń ké, lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ló ń bẹ àwọn òbí rẹ̀ pé: “Ẹ wò mí!” Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí dá a lóhùn tìfẹ́tìfẹ́. Nípasẹ̀ irú àwọn ìfararora bẹ́ẹ̀, ọmọ ọwọ́ náà á mọ̀ pé ó ṣeé ṣe fún òun láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ ohun tí òún nílò. Ó ti ń kọ́ béèyàn ṣe ń ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nìyẹn.
‘Ṣé Mi Ò Ní Kẹ́ Ọmọ Mi Bà Jẹ́ Báyìí?’
O lè máa wò ó pé, ‘Bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tí ọmọ mi ń ké ni mò ń dá a lóhùn, ṣé mi ò ní kẹ́ ẹ bà jẹ́ báyìí?’ Ó ṣeé ṣe kí èyí ṣẹlẹ̀. Èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn sì ní lórí ìbéèrè yìí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọmọ yàtọ̀ síra, ó yẹ kí àwọn òbí pinnu ohun tó máa gbéṣẹ́ jù lọ fún wọn láti ṣe. Àmọ́, àwọn ìwádìí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti fi hàn pé nígbà tí ebi bá ń pa ọmọ ọwọ́ kan, tí ara ń ni ín tàbí tí ohun kan ń dà á láàmú, àwọn èròjà kan nínú ara rẹ̀ á jẹ́ kó nímọ̀lára pé ohun kan ń ṣẹlẹ̀ sí i. Ó máa ń ké láti fi hàn pé ara ń ni òun. Àwọn ògbógi sọ pé nígbà tí òbí bá ń dá ọmọ rẹ̀ lóhùn, ńṣe ni òbí náà ń mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ ọmọ jòjòló náà tó lè ràn án lọ́wọ́ láti wá ìtura fúnra rẹ̀ gbára jọ. Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọ̀mọ̀wé Megan Gunnar sọ, ọmọ ọwọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ máa ń gbọ́ tirẹ̀ dáadáa kì í fi bẹ́ẹ̀ nímọ̀lára pé ohun kan ń yọ òun lẹ́nu. Àti pé, bí ohun kan bá ń dààmú rẹ̀, kò ní pẹ́ tí ara á fi rọ̀ ọ́.
Erickson, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Àní, àwọn ọmọ ọwọ́ tí àwọn òbí wọn máa ń tètè dá lóhùn tí wọ́n bá ń ké, pàápàá láàárín oṣù mẹ́fà sí mẹ́jọ lẹ́yìn tí wọ́n dáyé, kì í fi bẹ́ẹ̀ ké bíi ti àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ń fi sílẹ̀ láti ké ṣáá.” Ó tún ṣe pàtàkì láti máa dá ọmọ rẹ lóhùn ní onírúurú ọ̀nà. Bó bá jẹ́ pé ọ̀nà kan náà lò ń gbà dá a lóhùn ní gbogbo ìgbà tó bá ń ké, irú bíi fífún un lóúnjẹ tàbí gbígbé e mọ́ra, kò sí àní-àní pé yóò di àkẹ́bàjẹ́. Nígbà míì, wíwulẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ kan fún un ti tó láti fi hàn pé ò ń gbọ́ igbe rẹ̀. Tàbí kẹ̀, o lè sún mọ́ ọmọ náà, kó o sì máa sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ sí i létí. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, fífi ọwọ́ lé e lẹ́yìn tàbí fífọwọ́ lé ikùn rẹ̀ lè jẹ́ kó dákẹ́ ẹkún sísun.
“Ọmọ ò lè ṣe kó máà ké.” Ohun tí wọ́n máa ń sọ nìyí ní ìhà Ìlà Oòrùn ayé. Ẹkún sísun ni ọ̀nà pàtàkì tí ọmọ ọwọ́ kan fi ń jẹ́ káwọn òbí rẹ̀ mọ ohun tó nílò. Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ bó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í kà ọ́ sí ní gbogbo ìgbà tó o bá ń béèrè nǹkan? Nígbà náà, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe máa rí lára ọmọ rẹ, ẹni tó jẹ́ pé kò lè dá ṣe ohunkóhun láìsí olùtọ́jú, bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tó bá ń fẹ́ kí wọ́n fún òun ní nǹkan ni wọ́n máa ń pa á tì? Ṣùgbọ́n, ta ló yẹ kó rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún?
Ta Ló Yẹ Kó Bójú Tó Ọmọ Ọwọ́?
Ètò ìkànìyàn ẹnu àìpẹ́ yìí kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ìdá mẹ́rìnléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé (láti ìgbà ìbí títí dìgbà tí wọ́n á fi pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án) ló jẹ́ pé àwọn ẹlòmíràn yàtọ̀ sí àwọn òbí wọn ló máa ń bójú tó wọn. Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, ó pọn dandan fún àwọn òbí méjèèjì láti máa ṣiṣẹ́ kí awọ lè kájú ìlù. Ọ̀pọ̀ àwọn ìyá ló sì máa ń gbàyè ìsinmi ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù díẹ̀ níbi iṣẹ́, bó bá ṣeé ṣe, láti lè bójú tó ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Ṣùgbọ́n, ta ni yóò máa bójú tó ọmọ ọwọ́ náà lẹ́yìn ìgbà yẹn?
Ká sòótọ́, kò sí òfin kàn-ń-pá kan nípa ṣíṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó dára láti rántí pé ọmọ náà kò lè dá ṣe ohunkóhun lákòókò ẹlẹgẹ́ yìí nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó yẹ kí àwọn òbí méjèèjì ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí. Nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò lórí ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọ́n ní láti gbé ìpinnu wọn yẹ̀ wò dáadáa.
Dókítà Joseph Zanga, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àjọ Àwọn Oníṣègùn Tó Ń Tọ́jú Àìsàn Àwọn Ọmọdé Nílẹ̀ Amẹ́ríkà, sọ pé: “Ó ti wá túbọ̀ ń ṣe kedere sí i báyìí pé jíjẹ́ kí àwọn ètò womọdèmí tó tiẹ̀ dára jù lọ pàápàá bá wa tọ́ ọmọ wa kò rọ́pò àkókò tó yẹ kí àwọn ìyá àtàwọn bàbá lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.” Àwọn ògbógi kan ti ń ké gbàjarè pé àwọn ọmọ ọwọ́ tó wà láwọn ilé womọdèmí kì í fi bẹ́ẹ̀ ní ìfararora bó ṣe yẹ pẹ̀lú àwọn tó ń bójú tó wọn.
Àwọn ìyá kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tí wọ́n mọ àwọn ohun pàtàkì tí àwọn ọmọ wọn nílò, pinnu pé àwọ́n á dúró sílé láti tọ́ ọmọ àwọn dípò kí àwọ́n jẹ́ kí ẹlòmíràn máa bá wọn ṣe ìtọ́jú àti àbójútó ọmọ wọn. Obìnrin kan sọ pé: “Iṣẹ́ ọmọ títọ́ ti fún mi ní ayọ̀ tí mo gbà gbọ́ tọkàntọkàn pé n kò lè rí nínú iṣẹ́ mìíràn.” Ká sòótọ́, ipò ìṣúnná owó kò lè jẹ́ kí gbogbo àwọn ìyá ọmọ ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Kò sí ohun mìíràn tí ọ̀pọ̀ òbí lè ṣe ju pé kí wọ́n fi àwọn ọmọ wọn sí àwọn ilé womọdèmí, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n máa ń sapá gidigidi láti rí i pé àwọ́n fìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ wọn, àwọ́n sì bójú tó wọn nígbà tí wọ́n bá jọ wà pa pọ̀. Bákan náà, ìwọ̀nba ni ọ̀pọ̀ àwọn òbí anìkàntọ́mọ lè ṣe nínú irú ọ̀ràn yìí, iṣẹ́ kékeré sì kọ́ ni wọ́n ń ṣe láti bójú tó àwọn ọmọ wọn, èyí sì ń so èso rere.
Iṣẹ́ ọmọ títọ́ jẹ́ iṣẹ́ aláyọ̀, iṣẹ́ tó ń múni lára yá gágá. Àmọ́, ó tún jẹ́ iṣẹ́ tí kò rọrùn láti ṣe, iṣẹ́ tó ń tánni lókun. Báwo lo ṣe lè ṣe é láṣeyọrí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, Jí! sọ̀rọ̀ nípa ojú ìwòye ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi tó jẹ́ lóókọlóókọ nínú ìtọ́jú ọmọ, nítorí pé irú àwọn ìwádìí báyìí lè wúlò gan-an fún àwọn òbí ó sì lè là wọ́n lóye. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé irú àwọn ojú ìwòye bẹ́ẹ̀ máa ń yí padà, àtúnṣe sì máa ń dé bá wọn bí àkókò ṣe ń lọ, láìdàbí àwọn ìlànà Bíbélì tí Jí! ń gbé lárugẹ láìsí iyèméjì èyíkéyìí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Tó Ń Wò Sùn-ùn
Àwọn oníṣègùn kan nílẹ̀ Japan sọ pé ńṣe làwọn ọmọ ọwọ́ tí wọn kì í ké tàbí rẹ́rìn-ín túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Satoshi Yanagisawa, onímọ̀ nípa ìtọ́jú àrùn àwọn ọmọdé, pe irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ ọwọ́ tó ń wò sùn-ùn. Kí nìdí tí àwọn ọmọ ọwọ́ náà fi máa ń dáwọ́ fífi ìmọ̀lára wọn hàn dúró? Àwọn dókítà kan gbà gbọ́ pé ohun tó fà á ni bí àwọn òbí kì í ṣeé ní ìfararora pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ohun tí wọ́n ń pe irú ipò yìí ni sísọ ọmọ di olúńdù. Àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí òbí kì í bá dá sí ọmọ ọwọ́ tó sì ń ṣì í lóye, ni ọmọ ọwọ́ náà á bá kúkú dáwọ́ gbígbìyànjú láti máa fi ìmọ̀lára hàn dúró.
Bí àwọn òbí kì í bá dá sí ọmọ wọn ní àkókò tó yẹ, apá kan lára ọpọlọ rẹ̀ tó máa jẹ́ kó di agbatẹnirò lè má dàgbà dáadáa, gẹ́gẹ́ bí Dókítà Bruce Perry, ọ̀gá ní ẹ̀ka ìtọ́jú ìṣòro ọpọlọ ní Ilé Ìwòsàn Àwọn Ọmọ Wẹ́wẹ́ ní Texas ṣe sọ. Bó bá wá lọ jẹ́ pé àwọn ọmọ tí wọn kì í ṣú já rárá ni, ó lè má ṣeé ṣe fún irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ títí ayé láti ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò. Dókítà Perry gbà gbọ́ pé nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé pípa tí wọ́n ń pa àwọn ọmọdé tì bẹ́ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn ló máa ń sún wọn láti di ẹni tó ń sọ oògùn olóró tàbí ọtí líle di bárakú, tàbí kí wọ́n di ọ̀dọ́langba oníwà ipá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìfẹ́ tó wà láàárín òbí àti ọmọ máa ń lágbára sí i bí wọ́n bá ṣe ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀