Pípèsè Ohun Tí Àwọn Ọmọdé Nílò fún Wọn
Ó TI wá ṣe kedere báyìí pé àwọn ọmọdé nílò ọ̀pọ̀ àfiyèsí látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára wọn ni kì í rí àfiyèsí yìí gbà. Ipò tí àwọn èwe òde ìwòyí bá ara wọn fi hàn pé bẹ́ẹ̀ gan-an lọ̀rọ̀ rí. Ìwé ìròyìn The Globe and Mail ti ìlú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà, fa ọ̀rọ̀ olùṣèwádìí kan yọ, ẹni tó fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lórí ọ̀ràn yìí nípa sísọ pé: “Kò tíì sí ìgbà kankan rí tí àwọn èwe wa tíì jìnnà sí ìdílé wọn, tí wọ́n sì ṣaláìní ìrírí àti ọgbọ́n àgbà, bíi ti àkókò wa yìí.”
Kí ló fa ìṣòro yìí ná? Ǹjẹ́ a lè sọ pé lára ohun tó fa ìṣòro ọ̀hún, bóyá lọ́nà kan ṣáá, ni ìkùnà àwọn òbí láti mọ ìjẹ́pàtàkì fífún àwọn ọmọ ní àfiyèsí nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an? Obìnrin kan tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú, tó máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ láti bójú tó ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, sọ pé: “Ó yẹ kí gbogbo wa kọ́ bí a ṣe lè di òbí tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Ó sì yẹ ká mọ̀ pé a ṣì máa jèrè ọ̀pọ̀ àkókò tí à ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wa nísinsìnyí padà.”
Àní, àwọn ọmọ ọwọ́ pàápàá nílò ìtọ́ni ìgbà gbogbo. Kì í wulẹ̀ ṣe ìtọ́ni tá a kàn ń pèsè lóòrèkóòrè, àmọ́ ó yẹ kó jẹ́ ohun tá à ń ṣe déédéé—bẹ́ẹ̀ ni o, látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Àkókò téèyàn ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló ṣe pàtàkì kí wọ́n lè di ẹni tó dàgbà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Ìmúrasílẹ̀ Pọn Dandan
Àwọn òbí ní láti múra sílẹ̀ fún ìbí ọmọ wọn kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti gbé ẹrù iṣẹ́ bàǹtà-banta tó wà níwájú wọn. Wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìlànà kan tí Jésù Kristi tọ́ka sí nípa ìjẹ́pàtàkì wíwéwèé ṣáájú. Ó sọ pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà?” (Lúùkù 14:28) Ọmọ títọ́—tí àwọn èèyàn sábà máa ń pè ní iṣẹ́ ológún ọdún—nira gan-an ju kíkọ́ ilé ìṣọ́ lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, kéèyàn tó lè tọ́ ọmọ ní àtọ́yanjú, ó pọn dandan láti ní ètò nílẹ̀ nípa àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe, gẹ́gẹ́ bí kọ́lékọ́lé kan ti nílò ìwé ìtọ́ni fún iṣẹ́ ṣíṣe.
Lákọ̀ọ́kọ́, ríronú jinlẹ̀ nípa àwọn ẹrù iṣẹ́ jíjẹ́ òbí àti mímúra sílẹ̀ láti pèsè àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe pàtàkì. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn aboyún tí iye wọn tó ẹgbàá [2,000] lórílẹ̀-èdè Jámánì fi hàn pé ara àwọn ọmọ tí ìyá wọn ń fojú sọ́nà láti ní ìdílé máa ń dá ṣáṣá, wọn kò sì ń fi bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dùn ọkàn bíi ti àwọn ọmọ tí ìyá wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí wọn. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, olùṣèwádìí kan sọ pé bí ìgbéyàwó obìnrin kan kò bá fún un láyọ̀, àfàìmọ̀ ni irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ò ní bí ọmọ tí yóò máa sorí kọ́ tàbí tí yóò máa ṣàìsàn ní ìyàtọ̀ sí obìnrin kan tí ìgbéyàwó rẹ̀ fi í lọ́kàn balẹ̀.
Nígbà náà, ó ṣe kedere pé ipa tó ṣe pàtàkì ni bàbá ń kó kó bàa lè ṣeé ṣe láti tọ́ ọmọ ní àtọ́yanjú. Dókítà Thomas Verny sọ pé: “Kò sí ohun tó lè ba ọmọdé láyé jẹ́ tó kí bàbá kan máa lu ìyàwó rẹ̀ aboyún tàbí kó pa á tì, níwọ̀n bí èyí ti lè fa ẹ̀dùn ọkàn àti àìsàn fún ọmọ náà.” Àní, àwọn èèyàn máa ń sábà sọ pé ẹ̀bùn tó dára jù lọ tí ọmọdé kan lè rí gbà ni bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ìyá rẹ̀.
Àwọn ohun kan nínú ara, èyí tó ń jẹ́ kéèyàn nímọ̀lára pé ìnira tàbí másùnmáwo ti bá ara, tí wọ́n máa ń tú sínú ẹ̀jẹ̀ ìyá, tún lè nípa lórí ọlẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ó dà bíi pé ìwádìí ti fi hàn pé kì í ṣe àwọn ohun tó ń múni rẹ̀wẹ̀sì tàbí àwọn ohun tó ń fa másùnmáwo lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló léwu fún aboyún, bí kò ṣe àníyàn tó légbá kan tàbí tí kò lọ bọ̀rọ̀ tí ìyá lè máa ní. Ó jọ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni èrò tí aboyún náà ní nípa ọmọ tí kò tíì bí náà.a
Kí ló yẹ kó o ṣe bó o bá jẹ́ aboyún tí ọkọ rẹ ò sì ṣètìlẹyìn fún ọ, tàbí bí ìwọ fúnra rẹ ò bá fẹ́ di ìyá ọmọ? Kì í ṣe ohun tí etí ò gbọ́ rí pé àwọn ipò nǹkan lè mú kí obìnrin kan máa sorí kọ́ nítorí oyún tó ní. Síbẹ̀, máa rántí nígbà gbogbo pé kì í ṣe ọmọ rẹ ló lẹ̀bi. Nígbà náà, báwo lo ṣe lè fi ara rẹ lọ́kàn balẹ̀ lójú ipò tí kò bára dé yìí?
Ìtọ́ni ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Yóò yà ọ́ lẹ́nu láti rí i bí fífi ọ̀rọ̀ yìí sílò ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun.” (Fílípì 4:6, 7) Wàá rí ìtìlẹyìn àti àbójútó Ẹlẹ́dàá, ẹni tó lè bójú tó ọ.—1 Pétérù 5:7.
Kì Í Ṣe Ohun Tuntun
Ní àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ìyá kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ọmọ bíbí bá bímọ, wọ́n máa ń ní ìbànújẹ́ àti àárẹ̀ ara tó ṣòroó ṣàlàyé. Àní, àwọn obìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí dídi ìyá ọmọ pàápàá lè máa sorí kọ́. Irú àwọn ìyípadà nínú ìṣesí bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun àjèjì. Ìdí ni pé lẹ́yìn tí àwọn obìnrin bá bímọ, àwọn ohun kan nínú ara tó ń nípa lórí ìmọ̀lára ẹni, èyí tí ara ń mú jáde, lè pọ̀ sí i tàbí kó dín kù. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ìyá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ni àwọn ojúṣe abiyamọ máa ń tojú sú pátápátá, irú bíi fífún ọmọ lóúnjẹ, pípààrọ̀ ìtẹ́dìí ọmọ àti bíbójútó ọmọ ìkókó náà, ẹni tó jẹ́ pé tiẹ̀ ṣáà ni pé kó ti rí ohun tó bá ń fẹ́ gbà.
Ìyá ọmọ kan sọ pé ńṣe ló dà bíi pé ọmọ òun ń sunkún láti wulẹ̀ dá òun lóró. Abájọ nígbà náà tí ògbógi kan tó mọ̀ nípa ọmọ títọ́ nílẹ̀ Japan fi sọ pé: “Kò sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ másùnmáwo tó ń bá ọmọ títọ́ rìn.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ògbógi yìí sọ, “ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ìyá kan má ṣe ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀.”
Kódà bí ìyá kan bá ń sorí kọ́ nígbà míì, ó lè dáàbò bo ọmọ rẹ̀ kí ìṣesí rẹ̀ tó ń yí padà má bàa ṣàkóbá fún ọmọ náà. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Àwọn ìyá tó máa ń sorí kọ́, àmọ́ tí wọ́n gbìyànjú láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn wọn, tí wọ́n ń bójú tó àwọn ọmọ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, tí wọ́n sì ń bá wọn ṣeré dáadáa, máa ń ní àwọn ọmọ tó jẹ́ ọlọ́yàyà, tí ara wọn yọ̀ mọ́ni.”b
Bí Bàbá Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
Bàbá ọmọ ọwọ́ náà lẹni tó yẹ kó ṣe ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹyìn tó pọn dandan. Nígbà tí ọmọ ọwọ́ náà bá ń ké láàárín òru, lọ́pọ̀ ìgbà bàbá náà lè máa bójú tó ọmọ náà kí ìyàwó rẹ̀ lè rí oorun sùn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ máa fi ìgbatẹnirò bá àwọn aya wọn lò nínú ìgbésí ayé àwọn méjèèjì.”—1 Pétérù 3:7, The Jerusalem Bible.
Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún àwọn ọkọ láti tẹ̀ lé. Àní, ó tún fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Éfésù 5:28-30; 1 Pétérù 2:21-24) Nípa bẹ́ẹ̀, aláfarawé Kristi làwọn ọkọ tó bá múra tán láti fi àwọn ohun kan du ara wọn kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ọmọ títọ́. Ká sòótọ́, iṣẹ́ ẹni méjì ni iṣẹ́ ọmọ títọ́ jẹ́. Iṣẹ́ tó gba ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí àwọn òbí méjèèjì gbọ́dọ̀ kópa nínú rẹ̀.
Ọmọ Títọ́ Kì Í Ṣe Iṣẹ́ Ẹnì Kan
Yoichiro, bàbá ọmọbìnrin ọlọ́dún méjì kan, sọ pé: “Ńṣe lèmi àti ìyàwó mi jọ jíròrò ní kíkún nípa bá a ṣe máa tọ́ ọmọbìnrin wa. Nígbàkigbà tí ìṣòro kan bá yọjú, a máa ń jíròrò bí a ṣe máa yanjú rẹ̀.” Yoichiro mọ̀ pé aya òun ní láti máa sinmi dáadáa, nípa bẹ́ẹ̀ ó máa ń mú ọmọ rẹ̀ dání pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tó bá fẹ́ lọ sí ibì kan tí kò jìn.
Láyé ọjọ́un, nígbà tí àwọn ìdílé sábà máa ń tóbi tí wọ́n sì máa ń wà pa pọ̀, àwọn ọmọ tó ti dàgbà àtàwọn mọ̀lẹ́bí máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn òbí nínú iṣẹ́ ọmọ títọ́. Nípa báyìí, kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu pé òṣìṣẹ́ kan ní Ibùdó Tó Ń Ṣèrànwọ́ Nípa Ọmọ Títọ́ ní ìlú Kawasaki, lórílẹ̀-èdè Japan, sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ara yóò tu àwọn ìyá bí wọ́n bá fi ọ̀ràn náà lọ àwọn ẹlòmíràn. Ìtìlẹyìn díẹ̀ tí ọ̀pọ̀ àwọn ìyá rí gbà ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ní.”
Ìwé ìròyìn Parents sọ pé àwọn òbí “nílò àwọn èèyàn kan tó máa jẹ́ igi-lẹ́yìn-ọgbà fún wọn, tí wọ́n lè máa sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn fún.” Níbo ni wọ́n ti lè rí irú àwọn adúrótini-lọ́jọ́-ìṣòro bẹ́ẹ̀? Bí àwọn ìyá àtàwọn bàbá ìkókó bá múra tán láti gbàmọ̀ràn, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí àwọn òbí wọn tàbí àwọn àna wọn, wọ́n á jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. Síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn òbí àgbà mọ̀ pé àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ náà lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣèpinnu tó bá wù wọ́n.c
Ìrànwọ́ mìíràn tí àwọn òbí tó ń tọ́mọ lè gbára lé ni àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà. Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè rí àwọn èèyàn tí wọ́n ti ní ìrírí nípa ọmọ títọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí wọ́n sì múra tán láti fetí sí àwọn ẹ̀dùn ọkàn rẹ. Wọ́n lè fún ọ ní àwọn ìdámọ̀ràn tó máa wúlò fún ọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, o lè béèrè fún ìrànwọ́ “àwọn àgbàlagbà obìnrin”—gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti pe àwọn tó ní ọ̀pọ̀ ìrírí nínú fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò—tí wọ́n ti múra tán láti ṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin tí kò tíì dàgbà púpọ̀.—Títù 2:3-5.
Láìsí àní-àní, àwọn òbí ní láti mọ èyí tí wọ́n á mú nínú gbogbo ìmọ̀ràn tí wọ́n bá ń fún wọn. Yoichiro sọ pé: “Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, gbogbo èèyàn ti di ògbógi nínú ọ̀ràn ọmọ títọ́.” Ìyàwó rẹ̀, Takako, sọ pé: “Àwọn ìdámọ̀ràn tí àwọn ẹlòmíràn fún mi kọ́kọ́ dà mí lọ́kàn rú, nítorí pé mò ń wò ó pé wọ́n ń ṣe lámèyítọ́ pé mi ò ní ìrírí nípa ọmọ títọ́.” Síbẹ̀, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ àti aya ti rí ìrànwọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè ní èrò tó tọ́ nípa pípèsè ohun tí àwọn ọmọ wọn nílò.
Ìrànlọ́wọ́ Tó Ṣeé Gbára Lé Jù Lọ
Kódà bó bá dà bíi pé kò sí ẹnì kankan nítòsí tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́, orísun ìtìlẹyìn kan tó ṣeé gbára lé wà. Òun ni Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó dá wa, ẹni tí ojú rẹ̀ lè rí ‘àní ọlẹ̀’ àwọn táà ń bí lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 139:16) Nígbà kan, Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí fún àwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, ó ní: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.”—Aísáyà 49:15; Sáàmù 27:10.
Rárá o, Jèhófà kò gbàgbé àwọn òbí. Nínú Bíbélì, ó ti pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà tó dára gan-an fún wọn nípa ọmọ títọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn, Mósè, wòlíì Ọlọ́run, kọ̀wé pé: “Kí [o] fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Mósè tún sọ lẹ́yìn náà pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí [títí kan ọ̀rọ̀ ìyànjú náà láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti láti sìn ín] tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:5-7.
Kí lo rò pé ó jẹ́ kókó pàtàkì tó wà nínú ìtọ́ni yìí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Kì í ṣe ohun mìíràn yàtọ̀ sí pé kí kíkọ́ ọmọ rẹ jẹ́ ohun tí wàá máa ṣe déédéé láìdáwọ́dúró, lójoojúmọ́, àbí? Ká sòótọ́, wíwulẹ̀ ṣètò àwọn àkókò pàtàkì kan lóòrèkóòrè láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ kò tó. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe làwọn àkókò pàtàkì tó dára fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ sábà máa ń ṣàdédé wá, ó yẹ kó o ṣètò ara rẹ láti máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọmọ rẹ ní gbogbo ìgbà. Èyí yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti pa àṣẹ Bíbélì náà mọ́, èyí tó sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.”—Òwe 22:6.
Fífún àwọn ọmọ ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ yíyẹ tún béèrè pé ká máa kàwé sókè ketekete fún wọn. Bíbélì sọ fún wa pé Tímótì, ọmọ ẹ̀yìn kan ní ọ̀rúndún kìíní, ‘ti mọ ìwé mímọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló.’ Nítorí náà, ó hàn gbangba pé ìyá rẹ̀, Yùníìsì, àti Lọ́ìsì ìyá rẹ̀ àgbà, máa ń kàwé sókè ketekete fún un. (2 Tímótì 1:5; 3:14, 15) Ó dára láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe èyí ní gbàrà tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí bá ọmọ ọwọ́ rẹ sọ̀rọ̀. Àmọ́, irú ìwé wo lo lè kà, ọ̀nà wo ló sì dára jù lọ tó o lè gbà kọ́ àwọn ọmọ ọwọ́?
Jẹ́ kí ọmọ rẹ máa gbọ́ bó o ṣe ń ka Bíbélì. Ó ṣe kedere pé ohun tí wọ́n kà sí Tímótì létí nìyẹn. Àwọn ìwé tún wà tí àwọn ọmọdé lè máa wo àwọn àwòrán mèremère inú wọn láti fi mọ Bíbélì. Ìwọ̀nyí ń ran ọmọdé kan lọ́wọ́ láti lè fọkàn yàwòrán ohun náà gan-an tí Bíbélì ń fi kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo Iwe Itan Bibeli Mi àti ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Nípa lílo irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀, ó ti ṣeé ṣe láti gbin àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sínú èrò àti ọkàn àwọn ògo wẹẹrẹ.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè.” (Sáàmù 127:3) Ẹlẹ́dàá rẹ ti fi “ogún” kan sí àbójútó rẹ, ìyẹn ni ọmọ tuntun jòjòló kan, tó lè fúnni láyọ̀. Láìsí àní-àní, ọmọ títọ́, ní pàtàkì títọ́mọ láti di olùjọsìn Ẹlẹ́dàá, jẹ́ iṣẹ́ kan tí ń mérè wá!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe àwọn ohun tó wà nínú ara, tó ń jẹ́ kéèyàn nímọ̀lára pé másùnmáwo ti bá ara nìkan ló lè ṣàkóbá bíburú jáì fún ọlẹ̀, àmọ́ àwọn nǹkan bíi tábà, ọtí líle àti oògùn olóró náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dára kí àwọn ìyá tó jẹ́ aboyún yẹra fún lílo ohunkóhun tó bá léwu. Láfikún sí i, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n lọ ṣàyẹ̀wò lọ́dọ̀ dókítà nípa àbájáde tí àwọn oògùn tí wọ́n ń lò lè ní lórí ọlẹ̀.
b Bí ìyá kan bá ní ìbànújẹ́ àti àìnírètí tó lékenkà, tó tún jẹ́ pé lọ́wọ́ kan náà, kò nífẹ̀ẹ́ sí ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ohun mìíràn tó ń lọ láyìíká rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìṣòro tó ní ni àárẹ̀ ọkàn tó ń wáyé lẹ́yìn ìbímọ. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ olùtọ́jú aboyún tó ń tọ́jú rẹ̀. Jọ̀wọ́ wo Jí!, July 22, 2002, ojú ìwé 19 sí 23 (Gẹ̀ẹ́sì) àti Jí!, June 8, 2003, ojú ìwé 21 sí 23 (Gẹ̀ẹ́sì).
c Jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà “Ayọ̀ Àti Ìpèníjà Tó Wà Nínú Jíjẹ́—Òbí Àgbà,” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti April 8, 1999.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Èrò tí aboyún ní nípa ọmọ tí kò tíì bí ṣe pàtàkì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣesí ìyá kan lè máa yí padà lẹ́yìn tó bá bímọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó lè ṣe láti mú kí ọmọ rẹ̀ mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ òun, ìfọ̀kànbalẹ̀ sì wà fún òun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ẹrù iṣẹ́ àwọn bàbá ni láti kópa nínú títọ́mọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìgbà ọmọdé jòjòló ló yẹ kí kíkàwé sí ọmọ létí ti bẹ̀rẹ̀