ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 4/8 ojú ìwé 14-18
  • Ayọ̀ Àti Ìpèníjà Tó Wà Nínú Jíjẹ́—Òbí Àgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayọ̀ Àti Ìpèníjà Tó Wà Nínú Jíjẹ́—Òbí Àgbà
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Tí Òbí Àgbà Ń Kó
  • Àwọn Pákáǹleke Inú Ìdílé
  • Ìfẹ́ àti Ọ̀wọ̀ Ni Àṣírí Rẹ̀!
  • Ohun Tí Àwọn Òbí Àgbà Lè Fúnni
  • Nígbà Tí Àwọn Òbí Àgbà Bá Tún ń tọ́mọ
    Jí!—1999
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lájọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Oríṣi Àwọn Òbí Àgbà “Tuntun”
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 4/8 ojú ìwé 14-18

Ayọ̀ Àti Ìpèníjà Tó Wà Nínú Jíjẹ́—Òbí Àgbà

“Mo nífẹ̀ẹ́ sí jíjẹ́ òbí àgbà! Ìwọ yóò gbádùn àwọn ọmọ-ọmọ rẹ láìsí ríronú pé ìwọ ni yóò jẹ̀bi ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. O mọ̀ pé o ní ipa kan lórí ìgbésí ayé wọn ṣùgbọ́n pé ìwọ kọ́ lo ní àṣẹ pátápátá lórí wọn. Àwọn òbí wọn ló ní in.”—Gene, òbí àgbà kan.

KÍ LÓ wà nínú jíjẹ́ òbí àgbà tó lè fa irú ìtara ọkàn bẹ́ẹ̀? Àwọn olùwádìí sọ pé ohun tí àwọn òbí sábà máa ń fi dandan béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tẹ̀dá lè fa àìfararọ gan-an. Nítorí pé kì í sábà sí ìdí fún àwọn òbí àgbà láti béèrè irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀, wọ́n lè gbádùn ipò ìbátan tó dánmọ́rán pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ wọn. Bí Arthur Kornhaber, tí ó jẹ́ oníṣègùn, ṣe sọ ọ́, tiwọn ni láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ-ọmọ wọn kìkì “nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ-ọmọ wọn.” Ìyá àgbà kan tí ń jẹ́ Esther sọ pé: “Gbogbo ohun tí àwọn ọmọ mi ń ṣe máa ń nípa lórí ìmọ̀lára mi ojoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí òbí àgbà kan, mo lómìnira láti wulẹ̀ bá àwọn ọmọ-ọmọ mi ṣeré, kí n sì nífẹ̀ẹ́ wọn.”

Bákan náà ni ọgbọ́n àti ìtóótun tí ń pọ̀ sí i, tí ń bá ọjọ́ orí rìn wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Jóòbù 12:12) Àwọn òbí àgbà kì í tún ṣe ọmọdé àti aláìnírìírí mọ́, wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu ọmọ títọ́. Níwọ̀n bí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn àṣìṣe wọn, wọ́n lè túbọ̀ jáfáfá nínú títọ́ ọmọ ju ìgbà tí wọn ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ lọ.

Nítorí náà, dókítà Kornhaber parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Ó yẹ kí ìfararora onífẹ̀ẹ́ tó gbámúṣé wà láàárín àwọn òbí àgbà àti àwọn ọmọ-ọmọ kí àtìyá, àtọmọ, àtàwọn òbí àgbà lè ní ìmọ̀lára rere kí wọ́n sì láyọ̀. Ìdè yìí jẹ́ ogún tí a bí mọ́ àwọn ọmọdé, . . . èyí tí wọ́n jogún lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n wọn tí olúkúlùkù ẹni tó wà nínú ìdílé náà sì jàǹfààní rẹ̀.” Ìwé àtìgbàdégbà Family Relations sọ bákan náà pé: “Àwọn òbí àgbà tí ń ṣe iṣẹ́ wọn bí òbí àgbà tí wọ́n sì lóye rẹ̀ ń mú ìtẹ́lọ́rùn àti ìwà rere púpọ̀ sí i dàgbà.”

Ipa Tí Òbí Àgbà Ń Kó

Ipa pàtàkì tí àwọn òbí àgbà lè kó pọ̀ gan-an. Gene sọ pé: “Wọ́n lè ran àwọn ọmọ wọn tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́. Mo lérò pé bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè bá wọn yanjú díẹ̀ lára ìṣòro tí àwọn òbí tí kò tí ì dàgbà bá ara wọn nínú rẹ̀.” Àwọn òbí àgbà tún lè ṣe ohun púpọ̀ láti ran àwọn ọmọ-ọmọ wọn lọ́wọ́. Àwọn òbí àgbà ló sábà máa ń sọ àwọn ìtàn tí ń jẹ́ kí ọmọ kan mọ̀ nípa ìtàn ìdílé fún un. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí àgbà máa ń kó ipa pàtàkì nínú títàtaré ẹ̀sìn ìdílé tí wọ́n jogún sí àwọn ọmọ-ọmọ.

Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, àwọn òbí àgbà máa ń jẹ́ atọ́nisọ́nà tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Jane tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ náà ní àwọn ohun tí wọn yóò sọ fún ọ àmọ́ tí wọn kò ní ìgboyà láti bá àwọn òbí wọn sọ.” Àwọn òbí sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, “ó lé ní ìpín ọgọ́rin lára ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́langba tí ń wo àwọn òbí wọn àgbà bí ẹni tí a lè fi àṣírí pamọ́ sí lọ́wọ́. . . . Ọ̀pọ̀ ọmọ-ọmọ tó ti dàgbà ló máa ń ṣèbẹ̀wò déédéé sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn àgbà tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́.”

Ọmọ kan tí wọn kò bójú tó dáradára nílé lè fọwọ́ pàtàkì mú òbí àgbà kan tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Selma Wassermann kọ̀wé pé: “Ìyá mi àgbà ló ṣe pàtàkì jù lọ fún mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Ìyá àgbà ló wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, tó sì ṣìkẹ́ mi. Abiyamọ abitanpẹ̀rẹ̀mù tí í rẹmọ lẹ́kún ni. . . . Ìyá àgbà ló kọ́ mi ní àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nípa ara mi—pé a nífẹ̀ẹ́ mi àti pé mo ní àwọn ànímọ́ tí ń fani mọ́ra.”—The Long Distance Grandmother.

Àwọn Pákáǹleke Inú Ìdílé

Kì í ṣe pé àwọn òbí àgbà kò ní àwọn pákáǹleke àti ìṣòro tí ń bá wọn fínra. Fún àpẹẹrẹ, òbí kan rántí awuyewuye bíburú jáì kan tó wáyé láàárín òun àti ìyá rẹ̀ látàrí ọ̀nà tó yẹ láti mú kí ọmọ gùfẹ̀. “Ó da àárín wa rú ní àkókò tí nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fún mi rárá.” Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn òbí tí wọn kò tí ì dàgbà ń fẹ́ kí àwọn òbí àwọn tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tí àwọn ń gbà tọ́ ọmọ àwọn. Àbá tí àwọn òbí wọn mú wá pẹ̀lú èrò rere lọ́kàn lè tipa bẹ́ẹ̀ dà bíi ṣíṣe lámèyítọ́ tí ń mú inú ẹni bà jẹ́.

Nínú ìwé Between Parents and Grandparents tí Ọ̀mọ̀wé Kornhaber ṣe, ó sọ nípa àwọn òbí méjì tí wọ́n ní ìṣòro kan náà. Òbí kan sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni àwọn òbí mi máa ń wá yọ mí lẹ́nu, inú sì máa ń bí wọn bí wọn kò bá bá mi nílé. . . . Wọn kì í gba tèmi rò—ìmọ̀lára mi àti àkókò láti fi gbọ́ tara mi.” Òmíràn ṣàròyé pé: “Àwọn òbí mi fẹ́ gba ọmọdébìnrin mi lọ́wọ́ mi. Ọ̀ràn Susie ti fẹ́ gba gbogbo ìgbésí ayé wọn. . . . A ń ronú nípa kíkó lọ sí ibòmíràn.”

Nígbà mìíràn, a tún máa ń fẹ̀sùn kan àwọn òbí àgbà pé wọ́n ń kẹ́ àwọn ọmọ-ọmọ wọn bà jẹ́ nítorí àwọn ẹ̀bùn púpọ̀ tí wọ́n máa ń fún wọn. Òtítọ́ ni pé bí afẹ́fẹ́ ti di apá kan ara ènìyàn bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà ọ̀làwọ́ ti di apá kan ara àwọn òbí àgbà kan, ṣùgbọ́n ó jọ pé àwọn kan máa ń ti àṣejù bọ̀ ọ́. Àmọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè jẹ́ pé owú ló fa àròyé tí àwọn òbí ń ṣe. (Òwe 14:30) Mildred sọ pé: “Àwọn òbí mi kò gba gbẹ̀rẹ́, wọ́n ti le mọ́ mi jù. Àmọ́ wọ́n lawọ́ sí àwọn ọmọ mi, wọn [kó sì le mọ́ wọn]. Mo ń jowú nítorí pé wọn kò tí ì yé ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe sí mi tẹ́lẹ̀.” Ohun yòówù tí ì báà fà á, ìṣòro lè ṣẹlẹ̀ bí òbí àgbà kan kò bá bọ̀wọ̀ fún ohun tí àwọn òbí ń fẹ́ tó bá di ọ̀ràn ti fífúnni lẹ́bùn.

Nípa bẹ́ẹ̀, yóò bọ́gbọ́n mu fún àwọn òbí àgbà láti lo òye nígbà tí wọ́n bá ń fi ìwà ọ̀làwọ́ wọn hàn. Bíbélì sọ pé àpọ̀jù nǹkan tó dára pàápàá lè burú. (Òwe 25:27) Bí o kò bá mọ irú ẹ̀bùn tó yẹ, béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí ọmọ náà. Nípa bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò ‘mọ bí o ṣe lè fi ẹ̀bùn rere fúnni.’—Lúùkù 11:13.

Ìfẹ́ àti Ọ̀wọ̀ Ni Àṣírí Rẹ̀!

Ó bani nínú jẹ́ láti sọ pé àwọn òbí àgbà kan ń ṣàròyé pé a kò mọrírì iṣẹ́ àbójútó àti abánigbọ́mọ tí àwọn ń ṣe. Àwọn mìíràn ń ronú pé a kò fún àwọn láyè tó láti máa rí àwọn ọmọ-ọmọ àwọn. Síbẹ̀, àwọn mìíràn sọ pé àwọn ọmọ àwọn tó ti dàgbà pa àwọn tì, wọn kò sì sọ ohun tó fà á. Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè yẹra fún irú àwọn ìṣòro tí ń dunni bẹ́ẹ̀ bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá ń fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bá ara wọn lò. Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. . . . A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5, 7.

Bóyá ìwọ jẹ́ òbí tí kò tí ì dàgbà, ó sì ṣẹlẹ̀ pé Ìyá Àgbà dá àbá kan tàbí sọ ohun kan tó bí ọ nínú bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹ̀lú èrò rere lọ́kàn ló fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o ní ìdí tó ṣe gúnmọ́ láti di ẹni tí ‘a tán ní sùúrù’? Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé iṣẹ́ àwọn àgbàlagbà obìnrin Kristẹni ni láti kọ́ “àwọn ọ̀dọ́bìnrin . . . láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, láti jẹ́ ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, oníwà mímọ́, òṣìṣẹ́ ní ilé.” (Títù 2:3-5) Àbí kì í ṣe irú ohun dídára jù lọ kan náà tí ìwọ àti àwọn òbí àgbà ń fẹ́ fún àwọn ọmọ rẹ nìyẹn? Níwọ̀n bí ìfẹ́ “kì í [ti í] wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan,” bóyá yóò dára láti gbájú mọ́ ohun tí àwọn ọmọ náà nílò—kì í ṣe ìmọ̀lára tìrẹ. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún “fífipá mú ẹnì kìíní-kejì láti figagbága” lórí gbogbo ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí ń bíni nínú.—Gálátíà 5:26, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

Lóòótọ́, o lè máa bẹ̀rù pé fífún ọmọ rẹ ní nǹkan jù yóò bà á jẹ́. Ṣùgbọ́n òbí àgbà kì í ní èrò burúkú lọ́kàn nígbà tí ó bá ń fi ìwà ọ̀làwọ́ hàn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ àbójútó ọmọ dunjú ló gbà pé bí o ṣe ń tọ́ ọmọ rẹ tí o sì ń bá a wí yóò ní ipa púpọ̀ lórí rẹ̀ ju èyí tí òbí àgbà ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ. Dókítà kan dámọ̀ràn pé: “Níní ànímọ́ ìdẹ́rìn-ín pani dáadáa yóò ṣèrànwọ́.”

Bí ìdí tó ṣe gúnmọ́ bá wà tí o fi ní láti dààmú lórí àwọn ọ̀ràn díẹ̀ tó jẹ mọ́ àbójútó ọmọ, má ṣe gbé ọmọ rẹ pa mọ́ fún àwọn òbí rẹ tàbí àwọn àna rẹ. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Bá wọn sọ̀rọ̀ gidi ní ìgbà “tí ó bọ́ sí àkókò,” kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun tí ń dà ọ́ láàmú. (Òwe 15:23) Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ lè rí ojútùú rẹ̀.

Òbí àgbà ha ni ọ́ bí? Nígbà náà, fífi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn òbí ọmọ-ọmọ rẹ̀ ṣe pàtàkì. Lóòótọ́, o lè ronú pé dandan ni kí o sọ tọkàn rẹ jáde bí o bá lérò pé ọmọ-ọmọ rẹ wà nínú ewu. Síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohun tó burú nínú pé kí o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, kí o sì fi ìfẹ́ hàn sí wọn, àwọn òbí ló ni ẹrù iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ wọn, kì í ṣe àwọn òbí àgbà. (Éfésù 6:4) Bíbélì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ láti bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. (Éfésù 6:1, 2; Hébérù 12:9) Nítorí náà, gbìyànjú láti má ṣe fi ìmọ̀ràn tí a kò béèrè fún pá àwọn òbí wọn lórí, má sì ṣe jin àṣẹ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí lẹ́sẹ̀.—Fi wé 1 Tẹsalóníkà 4:11.

Lóòótọ́, títakété, dídákẹ́—àti bóyá fífọwọ́lẹ́rán—kí o sì jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Gene ṣe sọ ọ́, “o ní láti gbà pẹ̀lú ohun tí wọ́n rò pé ó dára jù fún àwọn ọmọ wọn àyàfi bí wọ́n bá béèrè fún ìmọ̀ràn.” Jane sọ pé: “Mo máa ń ṣọ́ra láti má ṣe sọ pé, ‘Báyìí ló ṣe yẹ kí o ṣe é!’ Oríṣiríṣi ọ̀nà ló wà tí a lè gbà ṣe nǹkan, bí o bá sì jẹ́ elérò tèmi-ló-tọ̀nà, ó lè dá ìṣòro sílẹ̀.”

Ohun Tí Àwọn Òbí Àgbà Lè Fúnni

Bíbélì ṣàpèjúwe níní ọmọ-ọmọ bí ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 128:3-6) Nípa lílọ́kàn-ìfẹ́ nínú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, o lè ní ipa alágbára nínú ìgbésí ayé wọn, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú àwọn ìwà ọmọlúwàbí dàgbà. (Fi wé Diutarónómì 32:7.) Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, obìnrin kan tí ń jẹ́ Lọ́ìsì kó ipa pàtàkì kan nínú ríran Tímótì, ọmọ-ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti dàgbà di ọkùnrin tí ó ta yọ bí ènìyàn Ọlọ́run. (2 Tímótì 1:5) Irú ayọ̀ kan náà lè jẹ́ tìrẹ bí àwọn ọmọ-ọmọ rẹ ṣe ń mú ẹ̀kọ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń kọ́ lò.

O tún lè jẹ́ orísun ìfẹ́ àti ìfẹ́ni tí wọ́n nílò. Lóòótọ́, o lè máà jẹ́ irú ẹni tí ó kún fún ìfẹ́ni, tí ń fi ìmọ̀lára hàn ṣáá. Ṣùgbọ́n, o tún lè fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nípa fífi ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan, tí kò lábòsí hàn sí àwọn ọmọ-ọmọ rẹ. Òǹkọ̀wé Selma Wassermann sọ pé: “Níní ọkàn-ìfẹ́ nínú ohun tí ọmọ náà ń sọ fún ọ . . . yóò fi hàn pé o bìkítà ní gidi. Jíjẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀ rere, tí kì í já lu ọ̀rọ̀, tí kì í ṣàríwísí ń fi ọ̀wọ̀, ìfẹ́ni, àti ìbuyìfúnni hàn lápapọ̀.” Irú àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀bùn dídára jù lọ tí òbí àgbà kan lè fún ọmọ-ọmọ kan.

Ohun tí a ti ń jíròrò bọ̀ dá lórí àwọn ipa tí òbí àgbà ń kó lọ́nà ti àbáláyé. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ lára àwọn òbí àgbà lóde òní ní ẹrù iṣẹ́ tó túbọ̀ wúwo gan-an.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]

“Ìyá àgbà ló kọ́ mi ní àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nípa ara mi—pé a nífẹ̀ẹ́ mi àti pé mo ní àwọn ànímọ́ tí ń fani mọ́ra”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

Ohun Àmúlò fún Àwọn Òbí Àgbà Tí Ọ̀nà Wọn Jìn

• Ẹ ní kí àwọn òbí fi kásẹ́ẹ̀tì fídíò tàbí fọ́tò àwọn ọmọ-ọmọ yín ránṣẹ́ sí yín.

• Ẹ fi kásẹ́ẹ̀tì “tí a gba ohùn sínú rẹ̀” ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ-ọmọ yín. Ẹ gba àwòrán ara yín sílẹ̀ nígbà tí ẹ ń ka ìtàn Bíbélì tàbí nígbà tí ẹ ń kọ àwọn orin arẹmọtẹ́ kí ẹ sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ tí wọ́n ṣì kéré.

• Ẹ fi káàdì ìkíni ránṣẹ́ kí ẹ sì kọ lẹ́tà sí àwọn ọmọ-ọmọ yín. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ ṣètò láti máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn déédéé.

• Bí ẹ bá lágbára rẹ̀, ẹ máa kàn sí àwọn ọmọ-ọmọ yín lórí tẹlifóònù. Bí ẹ bá ń bá àwọn ọmọ tí wọ́n ṣì kéré sọ̀rọ̀, ẹ máa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yín pẹ̀lú àwọn ìbéèrè rírọrùn bí, “Kí lo jẹ láàárọ̀ yìí?”

• Bó bá ṣeé ṣe, ẹ máa lọ bẹ̀ wọ́n wò déédéé, kí ẹ má sì pẹ́ níbẹ̀.

• Ẹ bá àwọn òbí wọn ṣètò pé kí àwọn ọmọ-ọmọ yín wá kí yín nílé. Ẹ wéwèé àwọn ìgbòkègbodò amóríyá, bí lílọ sí ọgbà ẹranko, ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, àti àwọn ọgbà ìṣiré.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọ̀pọ̀ òbí àgbà ló ń bójú tó àwọn ọmọ-ọmọ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Pákáǹleke lè ṣẹlẹ̀ nípa ọ̀nà tí a ó gbà tọ́ ọmọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn òbí àgbà ló sábà máa ń sọ ìtàn ìdílé fún àwọn ọmọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́