“Ohun Àgbàyanu Tó Ń Yára Kẹ́kọ̀ọ́ Jù Lọ Lágbàáyé”
ÀWỌN kan sọ pé ọpọlọ àwọn ọmọdé ni “ohun àgbàyanu tó ń yára kẹ́kọ̀ọ́ jù lọ lágbàáyé,” òótọ́ sì ni ọ̀rọ̀ yìí. Ní gbàrà tí wọ́n bá bí ọmọ kan, ara rẹ̀ ti máa ń múra tán láti gba àwọn nǹkan tó wà láyìíká rẹ̀ mọ́ra, irú bí ohun tó ń rí, ìró tó ń gbọ́, ó sì tún máa ń ní ìmọ̀lára.
Bí àwọn èèyàn ṣe ń gbé àwọn ọmọ ìkókó, inú àwọn ọmọ náà máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń wo ojú wọn, tí wọ́n ń gbọ́ ohùn wọn, tí àwọn yẹn sì ń fọwọ́ kàn wọ́n. Ìwé Babyhood, tí Penelope Leach kọ sọ pé: “Wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwádìí nípa ohun tí àwọn ọmọ ìkókó fẹ́ràn láti máa rí, ìró tó máa ń fà wọ́n mọ́ra tó sì máa ń gba àfiyèsí wọn, àti irú ìmọ̀lára tí wọ́n máa ń fẹ́ láti ní. Gbogbo èyí ni wọ́n máa ń rí látìgbà-dégbà látọ̀dọ̀ àwọn àgbàlagbà tó ń tọ́jú wọn.” Abájọ tó fi jẹ́ pé àwọn òbí máa ń kó ipa tó pọ̀ nínú ìdàgbàsókè àwọn ọmọ wọn!
“Mo Máa Ń Sọ̀rọ̀ Bí Ìkókó”
Ẹnu máa ń ya àwọn òbí àtàwọn dókítà tó máa ń tọ́jú àwọn ọmọdé láti rí i bí àwọn ọmọ ìkókó ṣe máa ń kọ́ èdè nípa fífetí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé láàárín ọjọ́ mélòó kan, ọmọ ìkókó kan ti máa dá ohùn ìyá rẹ̀ mọ̀, ó sì máa ń fẹ́ gbọ́ ohùn ìyá rẹ̀ dípò ti àjèjì kan; láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ó ti mọ ìyàtọ̀ láàárín bí èdè àwọn òbí rẹ̀ ṣe ń dún yàtọ̀ sí èdè míì; àti pé láàárín oṣù mélòó kan, ó ti mọ bí ọ̀rọ̀ téèyàn ń sọ ṣe ń dún, ó sì lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ téèyàn ń sọ àti ìró lásán.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Báwo ni ìkókó ṣe máa ń sọ̀rọ̀? Ó sábà máa ń ṣe atata-n-toto. Ṣé ó kàn ń pariwo lásán ni? Rárá o! Nínú ìwé What’s Going On in There?—How the Brain and Mind Develop in the First Five Years of Life, tí Dókítà Lise Eliot ṣe, ó sọ pé ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ “ohun ìyanu ńlá, ó nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣan tó máa yára ṣiṣẹ́ pọ̀ láti darí ètè, ahọ́n, òkè ẹnu àti gògóńgò.” Ó fi kún un pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn ọmọ ìkókó ṣe máa ń pariwo jẹ́ ọ̀nà kan láti jẹ́ kí àwọn èèyàn fún wọn ní àfiyèsí, ó tún jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà mú kí àwọn iṣan tó ń jẹ́ kéèyàn lè máa sọ̀rọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀.”
Bí àwọn ọmọ ìkókó bá ń ṣe atata-n-toto tí kò ní ìtumọ̀ pàtó kan, àwọn òbí wọn máa ń fún wọn lésì, àmọ́ èyí náà ní iṣẹ́ tó ń ṣe. Èsì tí àwọn òbí máa ń fún àwọn ọmọ yìí máa ń mú kí àwọn ìkókó ṣe nǹkan kan. Bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí ń kọ́ ọmọ ìkókó báá ṣe máa sọ̀rọ̀, ẹ̀kọ́ yìí sì máa wúlò fún un jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀.
Ìgbà Tí Ojúṣe Òbí Máa Yí Pa Dà
Ọwọ́ àwọn òbí tó ní ọmọ ìkókó máa ń dí bí wọ́n ṣe ń bójú tó ọmọ wọn lójoojúmọ́. Bí ọmọ bá ń ké, ẹnì kan wà tó máa fún un ní oúnjẹ. Bí ọmọ bá ń ké, ẹnì kan wà tó máa pààrọ̀ ìtẹ́dìí rẹ̀. Bí ọmọ bá ń ké, ẹnì kan wà tó máa gbé e jó. Irú ìtọ́jú yìí tọ́, ó sì pọn dandan. Ó jẹ́ ọ̀nà kan tí àwọn òbí ń gbà ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí alágbàtọ́.—1 Tẹsalóníkà 2:7.
Ohun tá a sọ lókè yìí fi hàn pé, ńṣe ni àwọn ọmọdé máa ń rò pé àwọn ló ṣe pàtàkì jù lọ láyé, wọ́n sì gbà pé ojúṣe àwọn àgbàlagbà, ní pàtàkì àwọn òbí wọn ni pé kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí àwọn bá ṣáà ti fẹ́. Èrò yìí kù díẹ̀ káàtó, àmọ́ a lóye ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Má gbàgbé pé, nǹkan tí òbí ń ṣe fún ọmọ lójoojúmọ́ nìyẹn fún ohun tó lé lọ́dún kan. Lójú wọn, ńṣe ni wọ́n dà bí ọba láàárín ìlú, tí àwọn èèyàn ńláńlá sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. Agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìdílé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Rosemond kọ̀wé pé: “Kò tó ọdún méjì tí wọ́n fi ní irú èrò yìí; àmọ́ ó máa gbà tó ọdún mẹ́rìndínlógún kí èrò yẹn tó lè kúrò lọ́kàn wọn! Ojúṣe àwọn òbí sì ni láti mú èrò yìí kúrò lọ́kàn wọn, àmọ́ wọ́n ní láti ṣe é jẹ́jẹ́.”
Nígbà tí ọmọ bá fi wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjì, á bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn òbí kò ní máa ṣe gbogbo nǹkan fún òun títí lọ, ìgbà yìí ni ojúṣe òbí á yí pa dà láti alágbàtọ́ sí agbaninímọ̀ràn. Ní báyìí, ọmọ náà ti wá mọ̀ pé àwọn òbí òun kò ṣe gbogbo ohun tí òun fẹ́; kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fẹ́ kí òun máa ṣe ohun tí àwọn fẹ́. Wọ́n ti gba ìjọba lọ́wọ́ ọmọ tuntun náà, inú rẹ̀ sì lè má dùn sí àyípadà yìí. Ọ̀rọ̀ náà lè wá tojú sú u, á sì fẹ́ máa darí àwọn òbí rẹ̀ nìṣó. Báwo ló ṣe máa ṣe é?
Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Ọmọ Bá Ń Ṣe Ìjọ̀ngbọ̀n
Nígbà tí àwọn ọmọ bá wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjì, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ìwà wọn sábà máa ń yí pa dà látòkèdélẹ̀, wọ́n sábà máa ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n. Àkókó yìí máa ń tán àwọn òbí ní sùúrù gan-an ni. Lójijì, ohun táá máa wá sí ọmọ náà lẹ́nu jù ni “Rárá!” tàbí “Mi ò fẹ́!” Ó lè máa bínú sí ara rẹ̀ tàbí sí àwọn òbí rẹ̀, torí pé ó ṣòro fún un láti mọ ohun tó máa ṣe. Ọmọ náà fẹ́ jìnnà sí ẹ, lẹ́sẹ̀ kan náà ó fẹ́ sún mọ́ ẹ. Tí nǹkan bá ti wá tojú sú àwọn òbí tán, wọ́n lè má mọ ohun tí wọ́n máa ṣe, á sì jọ pé pàbó ni gbogbo ìsapá àwọn ń já sí. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ gan-an?
Ó dáa, ronú nípa àyípadà tó wáyé nínú ìgbésí ayé ọmọdé náà. Nígbà tó ṣì wà ní ìkókó, gbogbo ohun tó ń ṣe kò ju pé kó kàn ṣe bí ẹni tó fẹ́ sunkún lásán, àwọn àgbàlagbà á ti dá a lóhùn. Àmọ́ ní báyìí, ó ti wá rí i pé ìgbà díẹ̀ ni “ìjọba” òun jẹ́ àti pé òun ní láti máa ṣe àwọn nǹkan kan fúnra òun. Ọmọ náà ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i kedere pé òun gbọ́dọ̀ rẹ ara òun sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo.”—Kólósè 3:20.
Ní àkókò tí nǹkan le koko yìí, àwọn òbí gbọ́dọ̀ rí i pé ẹnu àwọn ká ọmọ náà. Bí wọ́n bá ṣe èyí tìfẹ́tìfẹ́, tí wọ́n ò sì gba gbẹ̀rẹ́, ọmọ náà á fara mọ́ ipò tuntun tó wà yìí. Àwọn ohun tó kọ́ ní àkókò yìí á sì ràn án lọ́wọ́ bó ṣe ń dàgbà.
Ìwà Ọmọlúwàbí
Àwọn ẹranko àtàwọn ẹ̀rọ kan, máa ń dá àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn mọ̀. Àmọ́, èèyàn nìkan ló lè ronú kó sì ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀. Torí náà, tí ọmọ bá wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjì tàbí mẹ́ta, á ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ìmọ̀lára bí ọ̀wọ̀ ara ẹni, ìtìjú, ẹ̀bi, ó sì máa mọ̀ bí ẹnì kan bá kàn án lábùkù. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nìyí bó ṣe ń bọ́ sípò àgbà tó sì ń dẹni tó ní ìwà ọmọlúwàbí, ẹni tó lè dúró lórí òtítọ́, kódà bí àwọn ẹlòmíì bá ń ṣe ohun tí kò tọ́.
Ní àárín àkókò yìí, inú àwọn òbí á dùn láti tún rí ohun ìyanu mìíràn. Ọmọ wọn á bẹ̀rẹ̀ sí í mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíì. Nígbà tó wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjì, ńṣe ló máa ń dá ṣeré tó bá wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, àmọ́ ní báyìí ńṣe ni wọ́n jọ máa ń ṣeré. Ó tún lè mọ ìgbà tí ara àwọn òbí rẹ̀ bá yá gágá, kó sì fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú wọn dùn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè dẹni tó máa rọrùn láti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.
Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ọmọ ọdún mẹ́ta á bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa. Torí náà, àkókò yìí gan-an ló yẹ kí àwọn òbí fi ṣe àfojúsùn wọn láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọ tó yàn tó yanjú.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Láàárín ọjọ́ mélòó kan, ọmọ ìkókó kan ti máa dá ohùn ìyá rẹ̀ mọ̀, ó sì máa ń fẹ́ gbọ́ ohùn ìyá rẹ̀ dípò ti àjèjì kan
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ọmọ ọdún mẹ́ta á bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
ÌDÍ TÁWỌN ỌMỌ KAN FI MÁA Ń ṢE ÌJỌ̀NGBỌ̀N
Nínú ìwé New Parent Power tí John Rosemond kọ, ó sọ pé: “Àwọn òbí kan máa ń ronú pé bóyá torí àwọn kò bójú tó ọmọ àwọn ní ọ̀nà tó tọ́ ló jẹ́ kó máa ṣe ìjọ̀ngbọ̀n. Wọ́n gbà pé tó bá jẹ́ pé àwọn ló fà á tí ọmọ náà fi ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n, àwọn ní láti ṣe àtúnṣe kíákíá. Torí náà, ohun tí wọ́n sọ pé àwọn kò fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀, wọ́n á wá ṣe é. Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n bá ọmọ náà wí tẹ́lẹ̀, wọ́n á wá ṣe kọjá ohun tó ń fẹ́ fún un, kó má bàa máa ṣe wọn bíi pé àwọn ló jẹ̀bi. Òbí àti ọmọ náà á gbà pé àwọn ti kẹ́sẹ járí. Ọmọ náà kò ní ṣe ìjọ̀ngbọ̀n mọ́, ara òbí á sì balẹ̀, ọmọ náà á wá rí i pé bí òun ṣe ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n yẹn jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí òun fẹ́, á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é léraléra.”