ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 3/8 ojú ìwé 13-17
  • Ìmúra àti Ìwọṣọ Ni Kò Jẹ́ Kí N Tètè Rí Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmúra àti Ìwọṣọ Ni Kò Jẹ́ Kí N Tètè Rí Òtítọ́
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Ṣègbéyàwó Mo sì Bímọ
  • Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n
  • A Bẹ̀rẹ̀ sí Wá Ìsìn Tòótọ́ Kiri
  • Bí Mo Ṣe Wá Gbà Gbọ́
  • Fífi Ohun Tí A Kọ́ Sílò
  • Àwọn Àǹfààní Tí Gbogbo Wa Ń Gbádùn
  • Wọ́n Wà Ojú Ọ̀nà Híhá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ẹrù-Iṣẹ́ Ń Bá Mímọ Ìsìn Tí Ó Tọ̀nà Rìn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 3/8 ojú ìwé 13-17

Ìmúra àti Ìwọṣọ Ni Kò Jẹ́ Kí N Tètè Rí Òtítọ́

GẸ́GẸ́ BÍ EILEEN BRUMBAUGH ṢE SỌ Ọ́

INÚ ẹ̀sìn kan tó ń jẹ́ Old Order German Baptist Brethren (Ìjọ Onítẹ̀bọmi Àwọn Ará Jámánì Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́) tí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn jọ ti àwọn Ámíṣì àti Mẹ́nónáìtì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Ọdún 1708 ni wọ́n dá ìjọ Onítẹ̀bọmi yìí sílẹ̀ nílùú Jámánì gẹ́gẹ́ bí ara ètò tí wọ́n fi ń sọ àwọn èèyàn jí nípa tẹ̀mí tí wọ́n ń pè ní ètò Ìsọnidolùfọkànsìn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopedia of Religion sọ pé ohun tá a fi ń dá àwọn onígbàgbọ́ Ìsọnidolùfọkànsìn mọ̀ ni “ìgbàgbọ́ pé aráyé nílò ìhìn rere Kristi.” Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní yìí ló jẹ́ kí àwọn ẹgbẹ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí rán àwọn míṣọ́nnárì lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.

Lọ́dún 1719 ẹgbẹ́ kékeré kan tí Alexander Mack jẹ́ aṣáájú rẹ̀, wá fi ibi tó ń jẹ́ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà báyìí ṣe ibùgbé. Látìgbà náà, ọ̀kan-ò-jọ̀kan ẹgbẹ́ làwọn èèyàn ti dá sílẹ̀ tí àwọn ẹgbẹ́ náà sì ń yapa síra wọn. Ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ń tẹ̀ lé ìtumọ̀ tí olúkúlùkù wọn fún ẹ̀kọ́ Alexander Mack. Àwa tá a wà ní ṣọ́ọ̀ṣì tiwa ò ju nǹkan bí àádọ́ta lọ. Kíka Bíbélì àti dídúró lórí ìpinnu tí àwọn ọmọ ìjọ bá panu pọ̀ ṣe lọ̀rọ̀ wa sábà máa ń dá lé lórí.

Ó kéré tán, àtìrandíran wa mẹ́ta ló ṣe ẹ̀sìn yìí tí wọ́n sì gbé ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn náà ṣe là á kalẹ̀. Ṣọ́ọ̀ṣì yìí lèmi náà ń lọ nígbà tí mo sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni mo ṣèrìbọmi níbẹ̀. Ohun tí wọ́n fi kọ́ mi láti kékeré ni pé kò dára kéèyàn ní mọ́tò tàbí kó máa lò ó, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ katakata, tẹlifóònù, tàbí rédíò pàápàá, tàbí ohun èlò mìíràn tó ń lo iná mànàmáná. Àwọn obìnrin ìjọ wa rọra máa ń múra níwọ̀nba, a kì í gẹrun wa bẹ́ẹ̀ la kì í ṣí orí sílẹ̀. Àwọn ọkùnrin wa máa ń dá irùngbọ̀n sí. Lójú tiwa ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé túmọ̀ sí kéèyàn yẹra fún wíwọṣọ ìgbàlódé, lílo àwọn nǹkan ìṣaralóge tàbí àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́, èyí tí a gbà pé àwọn tí ìgbéraga ń mú dẹ́ṣẹ̀ ló máa ń lò wọ́n.

Wọ́n kọ́ wa láti ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Bíbélì tá a kà sí oúnjẹ tẹ̀mí. Láràárọ̀ ká tó jẹun, gbogbo wa á kóra jọ sí pálọ̀ láti tẹ́tí sí orí Bíbélì tí Bàbá máa ń kà láràárọ̀ àti àlàyé tó máa ṣe lórí ẹ̀. Gbogbo wa á wá kúnlẹ̀ Bàbá á sì gbàdúrà. Lẹ́yìn náà, Màmá á wá tún Àdúrà Olúwa kà. Ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé kí àkókò àdúrà àárọ̀ ti tó nítorí pé gbogbo wa nínú ìdílé la máa ń wà pa pọ̀ tí a sì máa ń pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí.

Oko kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú Delphi ní ìpínlẹ̀ Indiana là ń gbé, a sì gbin oríṣiríṣi nǹkan tẹ́nu ń jẹ síbẹ̀. Kẹ̀kẹ́ tí wọ́n ń fi ẹṣin fà la fi máa ń kó lára rẹ̀ lọ sáàárín ìgboro fún títà lójú pópó tàbí láti ilé kan sí èkejì. A gbà pé ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Nítorí náà, a tẹpá mọ́ iṣẹ́ wa, àyàfi lọ́jọ́ Sunday nìkan tá ò gbọ́dọ̀ ṣe “iṣẹ́ agbára” kankan. Nígbà míì ṣá o, iṣẹ́ oko máa ń ká gbogbo wa nínú ìdílé lára débi pé ó máa ń ṣòro fún wa láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́.

Mo Ṣègbéyàwó Mo sì Bímọ

Lọ́dún 1963, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo fẹ́ James, tóun náà jẹ́ ọmọ Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́. Àwọn baba-ńlá rẹ̀ ló mú ìsìn yìí wọ inú ìdílé wọn. A fẹ́ láti sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, a sì gbà gbọ́ pé àwa nìkan là ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́.

Nígbà tó fi máa di ọdún 1975 a ti bímọ mẹ́fà, a sì bí àbígbẹ̀yìn wa tó ṣìkeje lọ́dún 1983. Rebecca, tá a bí lé dáódù wa nìkan ni obìnrin. À ń ṣiṣẹ́ bí erin, a sì ń jìjẹ ẹ̀lírí, owó táà ń ná kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ la sì rọra ń gbé ìgbésí ayé wa ní kẹ́jẹ́bú. A gbìyànjú láti kọ́ àwọn ọmọ wa ní ìlànà Bíbélì kan náà tá a kọ́ lọ́dọ̀ àwọn òbí wa àtàwọn míì nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́.

Ìrísí èèyàn làwọn ọmọ Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́ máa ń kà sí pàtàkì. Èrò wa sì ni pé níwọ̀n bí ẹnikẹ́ni ò ti lè rínú ẹlòmíì, béèyàn bá ṣe múra ló máa jẹ́ ká mọ bínú ẹni náà ṣe rí. Látàrí èyí, tí obìnrin kan bá ṣe irun lóge, àmì pé ó ń gbéra ga nìyẹn. Tí iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe sí ara aṣọ wa bá ti pọ̀ jù, àpẹẹrẹ pé èèyàn ń gbéra ga tún nìyẹn náà. Àwọn nǹkan bí èyí táà ń tẹnu mọ́ jù ti jẹ́ ká gbójú fo àwọn nǹkan tí Ìwé Mímọ́ gan-an sọ dá.

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n

Nígbà tó kù díẹ̀ kó di ọdún 1970, wọ́n ju Jesse, àbúrò ọkọ mi tí wọ́n tọ́ òun náà dàgbà nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́ sẹ́wọ̀n nítorí pé ó kọ̀ láti gbaṣẹ́ ológun. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn náà gbà pé kíkópa nínú ogun jíjà kò bá ìlànà Bíbélì mu. (Aísáyà 2:4; Mátíù 26:52) Jesse gbádùn ọ̀pọ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí látinú Bíbélì, ó sì wá fojú ara rẹ̀ rí bí ìwà wọn ṣe rí. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—ohun tó ṣe yẹn ò dùn mọ́ wa nínú rárá.

Jesse bá ọkọ mi sọ̀rọ̀ nípa ohun tó kọ́. Ó tún ṣètò bí ọkọ mi á ṣe máa rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! gbà déédéé. Bí ọkọ mi ṣe ń ka àwọn ìwé ìròyìn yìí ni ìfẹ́ tó ní sí Bíbélì túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i. Níwọ̀n bó ti wu ọkọ mi láti sin Ọlọ́run àmọ́ tó rò pé Ọlọ́run jìnnà sí òun, gbogbo ohun tó bá lè mú kó túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ló máa ń nífẹ̀ẹ́ sí.

Àwọn alàgbà wa ní Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́ máa ń gbà wá níyànjú pé ká máa ka àwọn ìwé ìròyìn táwọn ìsìn Ámíṣì àti Mẹ́nónáìtì àti àwọn ẹ̀ya ìsìn mìíràn tó wá látinú Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́ kọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ka àwọn ìsìn yẹn mọ́ apá kan ayé. Ṣùgbọ́n bàbá mi kò lérò tó dáa rárá nípa àwọn Ẹlẹ́rìí. Kò tiẹ̀ fẹ́ ká máa ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! rárá. Nítorí náà ẹ̀rù bà mí nígbà tí mo rí James tó ń ka àwọn ìwé ìròyìn yìí. Ohun tó ń dẹ́rù bà mí ni pé ẹ̀kọ́ èké lè kó sí i lórí.

Síbẹ̀, ó ti pẹ́ tí ọkọ mi ti máa ń ṣiyèméjì nípa àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́, èyí tí kò bá Bíbélì mu—pàápàá jù lọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi kọ́ni pé ẹ̀ṣẹ̀ ni láti ṣe “iṣẹ́ agbára” èyíkéyìí lọ́jọ́ Sunday. Bí àpẹẹrẹ, ìsìn Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́ kọ́ni pé èèyàn lè fún àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ lómi lọ́jọ́ Sunday àmọ́ kò lè tu koríko. Àwọn alàgbà náà ò lè fìdí òfin yìí múlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ lèmi náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀.

Nítorí pé ó ti pẹ́ tá a ti gbà gbọ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì wa nìkan ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, tá a sì mọ ohun tójú wa máa rí tá a bá fi ṣọ́ọ̀ṣì yìí sílẹ̀, ó ṣòro fún wa láti kúrò nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́. Síbẹ̀, ẹ̀rí ọkàn wa kò gbà wá láyè láti jókòó sínú ìsìn tá a gbà pé kó tẹ̀ lé Bíbélì tímọ́tímọ́. Nítorí náà, lọ́dún 1983, a kọ lẹ́tà kan tá a fi ṣàlàyé ìdí tá a fi ń fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ a sì ní kí wọ́n kà á sí gbogbo ìjọ létí. Ńṣe ni wọ́n yọ wá kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì yẹn.

A Bẹ̀rẹ̀ sí Wá Ìsìn Tòótọ́ Kiri

Lẹ́yìn ìgbà náà, a wá bẹ̀rẹ̀ sí wá ìsìn tòótọ́ kiri. À ń wá ìsìn tí ẹ̀kọ́ wọn àti ìwà wọn bára mu, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn ṣèwà hù. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a yọ ìsìn èyíkéyìí tó bá ti ń lọ́wọ́ sí ogun kúrò lára èyí tá a fẹ́. Ọkàn wa ṣì wà lára àwọn ìsìn tí kì í wọ aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, ìdí ni pé a rò pé ara àmì téèyàn fi lè dá ìsìn tí kì í ṣe apá kan ayé mọ̀ ni pé kí àwọn tó ń ṣe ìsìn náà máa gbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ kí wọ́n sì máa wọ aṣọ tí wọn kò ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára. Látọdún 1983 si 1985, a rìnrìn àjò káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà a sì ń yẹ onírúurú ìsìn wò ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé, irú bíi Mẹ́nónáìtì, Quakers àtàwọn àwùjọ ẹlẹ́sìn míì tí kì í wọṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára.

Láàárín àkókò yẹn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá wàásù ní oko wa nítòsí ìlú Camden, ní ìpínlẹ̀ Indiana. A máa ń fetí sí wọn, a ó sì sọ fún wọn pé Bíbélì King James nìkan ni kí wọ́n lò. Mo gbóṣùbà fún àwọn Ẹlẹ́rìí nítorí pé wọn kì í lọ́wọ́ sógun jíjà. Ṣùgbọ́n ó ṣòro fún mi láti fetí sí wọn nítorí mo rò pé tí wọn ò bá lè rí ìdí láti ta kété sí nǹkan tayé nípa ṣíṣàì wọ aṣọ tí wọ́n siṣẹ́ ọnà sí lára, a jẹ́ pé ìsìn wọn kò lè jẹ́ ìsìn tòótọ́ nìyẹn. Mo rò pé ìgbéraga ló ń mú káwọn èèyàn máa wọṣọ tó yàtọ̀ sí irú èyí táwa máa ń wọ̀. Mo gbà gbọ́ pé àwọn dúkìá tàbí nǹkan téèyàn bá ní máa ń jẹ́ kó gbéra ga.

Ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ń mú lára àwọn ọmọkùnrin wa dání tó bá ń lọ. Ohun tó ń ṣe yẹn mú orí mi gbóná. Ọkọ mi rọ̀ mí kí n ká lọ, ṣùgbọ́n mi ò dá a lóhùn. Nígbà tó wá dọjọ́ kan, ó sọ fún mi pé: “Bí ẹ̀kọ́ wọn ò bá tiẹ̀ bá ọ lára mu, ṣáà kàn wá lọ wò ó fúnra rẹ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe láàárín ara wọn.” Ohun tó wú ohun alára gan-an lórí nìyẹn.

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo tẹ̀lé e lọ àmọ́ mò ń ṣọ́ra gidigidi. Aṣọ mi tí wọn ò ṣiṣẹ́ ọnà sí lára ni mo wọ̀ wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí mo sì wa fìlà mi mọ́ orí. Àwọn kan lára àwọn ọmọ tí mo kó dání ò wọ bàtà, aṣọ tí wọn ò ṣé iṣẹ́ ọnà kankan sí lára làwọn náà sì wọ̀. Síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí wá sọ́dọ̀ wa, wọ́n sì fìfẹ́ hàn sí wa. Mo wá rò ó sínú pé: ‘Pẹ̀lú bá a ṣe yàtọ̀ sí wọn yìí, wọ́n tún gbà wá bá a ṣe rí.’

Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí wa yẹn jọ mí lójú gan-an, ṣùgbọ́n orí ìpinnu mi pé mo kàn fẹ́ lọ wò wọ́n lásán ni mo ṣì wà. Bí wọ́n bá ń kọrin n kì í dìde bẹ́ẹ̀ sì ni n kì í bá wọn dá sí i. Lẹ́yìn ìpàdé náà mo da ìbéèrè bò wọ́n nípa àwọn nǹkan tí mo rò pé wọ́n ń ṣe tí kò dáa tó àti ohun tí mo rò pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan túmọ̀ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìbéèrè yẹn lè dà bí ìbéèrè òmùgọ̀, olúkúlùkù ẹni tí mò ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ló ń dáhùn tìfẹ́tìfẹ́. Ohun tó tún jọ mí lójú ni pé bí mo bá béèrè ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìdáhùn kan náà ni mò ń bá lẹ́nu wọn. Nígbà míì wọ́n á bá mi kọ ìdáhùn wọ̀nyẹn sílẹ̀, ìyẹn sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an, nítorí pé mo tún láǹfààní láti tún wọn kà nígbà tí mo bá ráyè.

Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1985, ìdílé wa lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣe ní ìlú Memphis, ní ìpínlẹ̀ Tennessee. Ṣùgbọ́n, a kàn fẹ́ láti wo bó ṣe máa ń rí ni o. Irùngbọ̀n ọkọ mi ṣì kún síbẹ̀, aṣọ wa tí wọn ò ṣe iṣẹ́ ọnà kankan sí lára náà la ṣì wọ̀. Láti ìgbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ti bẹ̀rẹ̀ títí tó fi parí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àkókò tí ẹnì kankan wọn kò wá sọ́dọ̀ wa. Ìfẹ́ tí wọ́n fi bá wa lò, bí wọn ò ṣe fi ojú pa wá rẹ́, àti bí wọ́n ṣe kó wa mọ́ra wọ̀ wá lọ́kàn gan-an. Ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn tún wù wá nítorí pé ibì yòówù ká ti lọ ṣèpàdé, ẹ̀kọ́ kan náà ni wọ́n fi ń kọ́ni.

Ìfẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ń fi hàn sí wa ló mú ọkọ mi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo nǹkan tó ń kọ́ ló yẹ̀ wò fínnífínní kó bàa lè dá a lójú pé òótọ́ ni wọ́n fi ń kọ́ òun. (Ìṣe 17:11; 1 Tẹsalóníkà 5:21) Nígbà tó yá, ọkọ mi wá mọ̀ pé òun ti rí òtítọ́. Síbẹ̀síbẹ̀ mi ò tíì mọ ohun tí mo máa ṣe. Mo fẹ́ ṣe ohun tó tọ́ ṣùgbọ́n mi ò fẹ́ “jájú oge” mi ò sì fẹ́ káwọn èèyàn máa fi ojú tá a fi ń wo àwọn “èèyàn ayé” wò mí. Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbà láti jókòó tì wọ́n níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo gbé Bíbélì King James Version sórí itan mi kan, mo sì gbé Bíbélì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a fi èdè tó bóde mu kọ, sórí itan kejì. Nínú ìtumọ̀ Bíbélì méjèèjì ni mo ti ń yẹ gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ táà ń kà wò kó lè dá mi lójú pé ẹnì kankan ò ṣì mí lọ́nà.

Bí Mo Ṣe Wá Gbà Gbọ́

Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó yé wa pé Ọlọ́run kan ni Bàbá wa ọ̀run kì í ṣe ọlọ́run mẹ́ta nínú ọ̀kan, a tún kẹ́kọ̀ọ́ pé àwa fúnra wa ni ọkàn kì í ṣe pé a ní ọkàn kan tí kì í kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Diutarónómì 6:4; Ìsíkíẹ́lì 18:4; 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Ó sì tún yé wa pé sàréè gbogbo aráyé ni hẹ́ẹ̀lì, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti ń fi iná dá èèyàn lóró. (Jóòbù 14:13; Sáàmù 16:10; Oníwàásù 9:5, 10; Ìṣe 2:31) Nígbà tá a mọ òtítọ́ nípa hẹ́ẹ̀lì lọ̀rọ̀ wá dójú ọ̀gbagadè nítorí pé ẹnu àwọn ọmọ Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́ ò kò lórí ìtumọ̀ rẹ̀.

Síbẹ̀, mo ṣì ń kọminú lórí bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe lè jẹ́ ìsìn tòótọ́ nítorí pé lọ́kàn tèmi, apá kan ayé ṣì làwọn náà. Mo rò pé wọn kì í gbé ìgbé ayé “mímọ́” tó yẹ kéèyàn Ọlọ́run máa gbé. Àmọ́, lọ́wọ́ kan náà, mo mọ̀ pé àwọn ló ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún gbogbo ènìyàn. Gbogbo ẹ̀ ò tiẹ̀ wá yé mi mọ́!—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

Lákòókò tí gbogbo nǹkan rú mi lójú yìí, ìfẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí fi ń bá mi lò gan-an ló jẹ́ kí n máa bá ìwádìí tí mò ń ṣe nìṣó. Gbogbo ará ìjọ ló nífẹ̀ẹ́ ìdílé wa. Nígbà mìíràn, báwọn ará ìjọ ṣe ń wá sọ́dọ̀ wa, tí wọ́n á ṣe bí ẹni pé mílíìkì àtẹyin nìkan làwọn wá rà—a bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé èèyàn dáadáa ni wọ́n. Wọn ò tìtorí pé Ẹlẹ́rìí kan ti ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n wá pa ilé wa tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbàkigbà tí àwọn kan láti inú ìjọ bá wá sítòsí ilé wa, wọ́n á yà. Ohun tí à ń fẹ́ gan-an rèé láti lè mọ àwọn Ẹlẹ́rìí dáadáa, ó sì tún jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ tí wọ́n ní ṣe jinlẹ̀ tó.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ìjọ tó sún mọ́ wa nìkan kọ́ ni wọ́n ń fi irú ìfẹ́ yìí hàn sí wa. Nígbà tí mo ṣì ń ronú lórí ọ̀ràn bó ṣe yẹ ká wọṣọ ká sì múra, Kay Briggs, obìnrin Ẹlẹ́rìí kan ní ìjọ kan tó wà nítòsí wa, ẹni tó fẹ́ràn láti máa múra níwọ̀n tí kì í sì í lo àwọn nǹkan ìṣaralóge wá sọ́dọ̀ mi. Ó rọrùn fún mi láti bá a sọ̀rọ̀ dáadáa, mo sì sọ tinú mi fún un. Lọ́jọ́ kan ni Lewis Flora bẹ̀ mí wò, inú ìsìn tí wọ́n ti máa ń wọ aṣọ tí wọn ò ṣe iṣẹ́ ọnà kankan sí lára lòun náà dàgbà sí. Ó rí i lójú mi pé nǹkan kan ń dà mí lọ́kàn rú, ló bá kọ lẹ́tà tó gba ojú ìwé mẹ́wàá sí mi láti fi mí lọ́kàn balẹ̀. Inú rere tó fi hàn sí mi yẹn wú mi lórí tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi yọ omijé lójú, mo sì ka lẹ́tà yẹn láìmọye ìgbà.

Mo ní kí alábòójútó arìnrìn-àjò kan Arákùnrin O’Dell ṣàlàyé Aísáyà 3:18-23 àti 1 Pétérù 3:3, 4 fún mi. Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé àwọn ẹsẹ yìí kò fi hàn pé ó yẹ kéèyàn máa wọṣọ tí wọn ò ṣe iṣẹ́ ọnà kankan sí lára kí inú Ọlọ́run tó lè dùn sí èèyàn?” Ó wá béèrè àwọn ìbéèrè kan tá jẹ́ kí n ronú jinlẹ̀, ó ní: “Ǹjẹ́ ó burú láti máa dé fìlà? Ṣé ó burú láti máa dirun?” Nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́, a máa ń dirun àwọn ọmọdé, àwọn obìnrin tí wọ́n ti dàgbà sì máa ń dé fìlà tàbí àkẹtẹ̀. Mo wá rí i pé ọ̀rọ̀ wọn ò dúró sójú kan lórí ọ̀ràn yẹn, sùúrù àti inúure tí alábòójútó arìnrìn-àjò yẹn fi bá mi lò sì wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lójú pé mo ti rí òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣì ku nǹkan kan tó ṣì ń dà mí láàmú gidigidi, ìyẹn ni, tàwọn obìnrin tó gẹrun wọn. Àwọn alàgbà nínú ìjọ ràn mí lọ́wọ́ láti ronú pé ó níbi tí irun àwọn obìnrin kan máa ń gùn dé nígbà tí tàwọn mìíràn sì máa ń gùn gan-an. Ṣé ó wá fi hàn pé irun obìnrin kan dáa jù tòmíràn lọ nìyẹn? Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ràn án lọ́wọ́ láti pinnu irú aṣọ tí yóò wọ̀ àti bí yóò ṣe múra, wọ́n sì fún mi láwọn ìwé kan láti lọ kà nílé.

Fífi Ohun Tí A Kọ́ Sílò

Ìsìn tó ń so èso rere là ń wá, a sì rí i. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ó dá wa lójú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn èèyàn tí ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn. Síbẹ̀síbẹ̀, lákòókò yẹn Nathan tó jẹ́ dáódù wa àti Rebecca tá a bí tẹ̀ lé e kò mọ èyí táwọn ì bá ṣe nítorí pé wọ́n ti gbà ìsìn Ìjọ Onítẹ̀bọmi Tó Ń Tẹ̀ Lé Ètò Àtijọ́ tí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi nínú ìsìn yẹn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, òtítọ́ Bíbélì tá a fi ń kọ́ wọn àti ìfẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí fi hàn gún wọn ní kẹ́ṣẹ́.

Bí àpẹẹrẹ, Rebecca ti ń wá bí àárín òun àti Ọlọ́run ṣe máa gún régé. Ó wá rí i pé ó rọrùn fún òun láti máa gbàdúrà nígbà tó yé e pé Ọlọ́run kò kádàrá gbogbo ohun téèyàn á ṣe láyé tàbí bí ọjọ́ iwájú wa ṣe máa rí. Ó tún sún mọ́ Jèhófà sí i nígbà tó yé e pé Ọlọ́run kì í ṣe apá kan àdììtú Mẹ́talọ́kan, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni gidi kan tóun lè fara wé ni. (Éfésù 5:1) Ó sì dùn mọ́ ọn nínú nígbà tó rí i pé kò pọn dandan láti lo àwọn èdè àtijọ́ tó wà nínú Bíbélì King James Version tóun bá ń bá a sọ̀rọ̀. Nígbà tó kọ́ nípa irú àdúrà tí Ọlọ́run máa ń gbọ́, àti ète tó ní fún ìran ènìyàn láti máa gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, ńṣe ló ń ṣe é bí i pé ó tún sún mọ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ sí i.—Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.

Àwọn Àǹfààní Tí Gbogbo Wa Ń Gbádùn

Èmi àti ọkọ mi àtàwọn ọmọ wa márùn-ún tó dàgbà jù, ìyẹn Nathan, Rebecca, George, Daniel àti John ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1987. Harley ṣèrìbọmi lọ́dún 1989, Simon sì ṣe lọ́dún 1994. Gbogbo wa nínú ìdílé wa là ń bá iṣẹ́ tí Jésù Kristi gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ́ lọ́wọ́ lọ ní pẹrẹu, ìyẹn pípòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

Gbogbo àwọn ọmọkùnrin wa márùn-ún tó dàgbà jù, Nathan, George, Daniel, John, Harley àti Rebecca ọmọbìnrin wa ti sìn ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rí. George ṣì wà níbẹ̀ títí di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti lo ọdún mẹ́rìnlá níbẹ̀, Simon, tóun náà ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ilé ìwé rẹ̀ ní 2001 ti di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Amẹ́ríkà láìpẹ́ yìí. Alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni gbogbo àwọn ọmọkùnrin wa nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọkọ mi náà ń sìn bí alàgbà nínú Ìjọ Thayer ní ìpínlẹ̀ Missouri, èmi náà ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lọ ní pẹrẹu.

A ti ní ọmọ-ọmọ mẹ́ta báyìí—orúkọ wọn ni Jessica, Latisha àti Caleb inú wa sì ń dùn bí bàbá àti ìyá wọn ṣe ń gbin ìfẹ́ Jèhófà sí wọn lọ́kàn láti kékeré ayé wọn. A láyọ̀ nínú ẹbí wa pé Jèhófà fà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi àwọn èèyàn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ òun hàn wá nípa ìfẹ́ bíi ti Ọlọ́run tí wọ́n ní.

Ọkàn wa wà lára àwọn tí wọ́n fẹ́ fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n fi tọ́ wọn láti kékeré náà ni wọ́n ṣì dìrọ̀ mọ́ dípò kí wọ́n fi Bíbélì fúnra rẹ̀ kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn. Ìrètí wa ni pé wọ́n á rí ayọ̀ táwa ní nísinsìnyí láti inú lílọ láti ilé dé ilé kì í ṣe láti ta irè oko, bí kò ṣe láti kéde Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn nǹkan àgbàyanu tí yóò mú wá. Omijé máa ń lé ròrò sí mi lójú nígbà tí mo bá ronú lórí sùúrù àti ìfaradà táwọn èèyàn tí wọ́n ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà fi hàn sí mi, mo mọrírì rẹ̀ gan-an ni!

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, àti nígbà tí mo ti wá dàgbà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

James, George, Harley àti Simon, wọ́n wọ aṣọ tí kò ní iṣẹ́ ọnà kankan lára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Èmi rèé níbi tí mo ti ń gbé irè oko lọ sí ọjà, àwòrán mi yìí wà nínú ìwé ìròyìn kan tó máa ń jáde ládùúgbò wa

[Credit Line]

Journal and Courier, Lafayette, Indiana

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Èmi àti ìdílé wa lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́