Ẹrù-Iṣẹ́ Ń Bá Mímọ Ìsìn Tí Ó Tọ̀nà Rìn
“Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́.”—LUKU 11:28.
1. Gbàrà tí wọ́n bá ti dá ìsìn tí ó tọ̀nà mọ̀ yàtọ̀, irú àwọn ènìyàn wo ni wọ́n ń kọ́ ìgbésí-ayé wọn yíká ìsìn tí ó tọ̀nà?
KÒ TÓ láti wulẹ̀ dá ìsìn tí ó tọ̀nà mọ̀ yàtọ̀. Bí a bá jẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́, gbàrà tí a bá ti rí i, àwa yóò kọ́ ìgbésí-ayé wa yí i ká. Ìsìn tí ó jẹ́ òtítọ́ kìí ṣe ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn èrò-orí lásán; ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí-ayé kan.—Orin Dafidi 119:105; Isaiah 2:3; fiwé Ìṣe 9:2.
2, 3. (a) Báwo ni Jesu ṣe tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun? (b) Ẹrù-iṣẹ́ wo ni ó já lórí gbogbo ẹni tí ó ba mọ ìsìn tòótọ́?
2 Jesu Kristi tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ohun tí Ọlọrun ti fihàn pé ó jẹ́ ìfẹ́-inú Òun. Ní mímú ohun tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìwàásù lórí Òkè wá sí ìparí, Jesu sọ ọ́ di mímọ̀ pé kìí ṣe gbogbo ẹni tí ń pe òun ní Oluwa (ní títipa báyìí fẹnujẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ Kristian) ni yóò wọnú Ìjọba náà; ṣùgbọ́n kìkì àwọn wọnnì tí ń ṣe ìfẹ́-inú Baba òun ni yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé, a ó kọ àwọn mìíràn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi “oníṣẹ́ ìwà-àìlófin.” Èéṣe tí ó fi jẹ́ ìwà-àìlófin? Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, ìkùnà láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìwà-àìlófin. (Matteu 7:21-23, NW; 1 Johannu 3:4; fiwé Romu 10:2, 3.) Ẹnìkan lè mọ ìsìn tí ó tọ̀nà, ó lè gbóríyìn fún àwọn tí ń fi kọ́ni, ó sì lè sọ̀rọ̀ rere nípa àwọn tí ń ṣe é, ṣùgbọ́n òun náà ní ẹrù-iṣẹ́ láti fi í sílò nínú ìgbésí-ayé rẹ̀. (Jakọbu 4:17) Bí ó bá tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ yẹn, òun yóò ríi pé a óò mú ìgbésí-ayé òun lọ́rọ̀ síi, òun yóò sì nírìírí ayọ̀ tí kò lè ti ọ̀nà mìíràn wá.
3 Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, a gbé mẹ́fà nínú àwọn àmì tí a fi lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ yẹ̀wò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí kò wulẹ̀ ṣèrànwọ́ fún wa láti dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ ṣùgbọ́n ó tún gbé ìpèníjà àti àǹfààní ka iwájú wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Lọ́nà wo?
Báwo Ni O Ṣe Ń Dáhùnpadà sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
4. (a) Bí àwọn ẹni titun ti bẹ̀rẹ̀ sí darapọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, kí ni wọ́n tètè ń ṣàkíyèsí nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ń lo Bibeli? (b) Báwo ni jíjẹ́ ẹni tí a bọ́yó nípa tẹ̀mí ṣe ń nípa lórí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa?
4 Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń fi Bibeli kọ́ àwọn olùfìfẹ́hàn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni titun wọ̀nyí tètè ń fi òye mọ̀ pé ohun tí a ń fi kọ́ wọn ń wá láti inú Bibeli. Ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọn, a kò tọ́ka wọn sí ìjẹ́wọ́-ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, sí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, tàbí sí èrò àwọn olókìkí ènìyàn. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnraarẹ̀ ni ọlá-àṣẹ. Nígbà tí wọ́n bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n ṣàkíyèsí pé níbẹ̀ pẹ̀lú, Bibeli ni olórí ìwé ẹ̀kọ́. Kìí gba àwọn olùwá òtítọ́ kiri tí wọ́n ní òtítọ́ ọkàn ní àkókò púpọ̀ láti mọ̀ pé kókó abájọ pàtàkì nínú ayọ̀ tí wọn ń rí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni òtítọ́ náà pé à ń bọ́ wọn ní àbọ́yó nípa tẹ̀mí láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.—Isaiah 65:13, 14.
5. (a) Ìpèníjà wo ni a gbé ka iwájú àwọn tí wọ́n ń ṣàkíyèsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? (b) Báwo ni wọ́n ṣe lè nípìn-ín nínú ayọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí?
5 Bí o bá mọ èyí, báwo ni ìwọ ṣe ń hùwàpadà síi? Bí o bá lóye rẹ̀, ìwọ kò lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ wulẹ̀ jẹ́ òǹwòran lásán, kò sì yẹ kí ìwọ kí ó fẹ́ láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bibeli fihàn pé àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ “olùgbọ́ nìkan” ṣùgbọ́n tí kìí ṣe “olùṣe ọ̀rọ̀ náà” ń ‘fi ìgbèrò èké tan ara wọn jẹ.’ (Jakọbu 1:22, NW) Wọ́n ń tan ara wọn jẹ nítorí pé wọ́n kùnà láti mọ̀ pé láìka ohun tí wọ́n lè sọ sí, ìkùnà wọn láti ṣègbọràn sí Ọlọrun fihàn pé wọn kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ìgbàgbọ́ tí a jẹ́wọ́ tí a kò fi iṣẹ́ tìlẹ́yìn jẹ́ òkú ìgbàgbọ́. (Jakọbu 2:18-26; 1 Johannu 5:3) Ní òdìkejì, ẹnìkan tí ìfẹ́ fún Jehofa sún láti jẹ́ “olùṣe iṣẹ́” yóò “láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” Bẹ́ẹ̀ni, gẹ́gẹ́ bí Jesu Kristi ṣe ṣàlàyé, “ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì pa á mọ́.”—Jakọbu 1:25, NW; Luku 11:28; Johannu 13:17.
6. Bí a bá mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nítòótọ́, àwọn àǹfààní wo ni àwa fúnraawa yóò sakun láti gbá mú?
6 Ayọ̀ yẹn yóò pọ̀ síi bí o ṣe ń dàgbà nínú ìmọ̀ nípa ìfẹ́-inú Ọlọrun tí o sì ń fi àwọn nǹkan mìíràn tí o tún kọ́ sílò. Báwo ni ìsapá tí ìwọ yóò fifún kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọrọ Ọlọrun yóò ti pọ̀ tó? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n jẹ́ púrúǹtù tẹ́lẹ̀rí ti ṣiṣẹ́ kára láti lè kàwé, wọ́n ṣe èyí ní pàtàkì kí wọ́n baà lè ka Ìwé Mímọ́ kí wọ́n sì fi wọ́n kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn mìíràn ń tètè jí ní òròòwúrọ̀ kí wọ́n baà lè lo àkókò díẹ̀ lójoojúmọ́ ní kíka Bibeli àti àwọn àrànṣe Bibeli, irú bíi Ilé-Ìṣọ́nà. Bí ìwọ fúnraàrẹ ti ń ka Bibeli léraléra tàbí tí o ń wo àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a yàn nínú àwọn àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ mìíràn fún ìkẹ́kọ̀ọ́, fìṣọ́ra ṣàkíyèsí àwọn òfin àti àṣẹ Jehofa, kí o sì wá ọ̀nà láti fi òye mọ ọ̀pọ̀ àwọn ìlànà tí o wà níbẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wa. Ṣàṣàro lórí ohun tí apá kọ̀ọ̀kan fihàn nípa Ọlọrun, ète rẹ̀, àti ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú aráyé. Fàyègba èyí láti nípa lórí ọkàn-àyà rẹ. Ronú bóyá àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí o ti lè fi ìmọ̀ràn Bibeli sílò ní kíkún síi nínú ìgbésí-ayé tìrẹ fúnraàrẹ.—Orin Dafidi 1:1, 2; 19:7-11; 1 Tessalonika 4:1.
Ìfọkànsìn Rẹ si Jehofa Ha Pé Bí?
7. (a) Báwo ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ti ṣe nípa lórí ìsapà àwọn ènìyàn láti jọ́sìn Ọlọrun? (b) Kí ni ó lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnìkan bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jehofa?
7 Ó ti jẹ́ ìtura fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ pé, Ọlọrun tòótọ́ náà kìí ṣe Mẹ́talọ́kan. Àlàyé náà pé “ó jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀” kò fìgbàkan tẹ́ wọn lọ́rùn. Báwo ni wọ́n ṣe lè súnmọ́ Ọlọrun kan tí kò ṣeé lóye? Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ẹ̀kọ́ yẹn, wọ́n pètepèrò láti ṣá Baba náà tì (ẹni tí wọn kò gbọ́ orúkọ rẹ̀ rí ní ṣọ́ọ̀ṣì) kí wọ́n sì máa jọ́sìn Jesu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun tàbí kí wọ́n darí ìjọsìn wọn sí Maria (ẹni tí a kọ́ wọn pé ó jẹ́ “Ìyá Ọlọrun”). Ṣùgbọ́n inú wọn dùn nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣí Bibeli tí o sì fi orúkọ Ọlọrun fúnraarẹ̀, Jehofa hàn wọ́n. (Orin Dafidi 83:18) Inú obìnrin ará Venezuela kan dùn gan-an nígbà tí a fi orúkọ àtọ̀runwá náà han tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi dìmọ́ ọ̀dọ́mọbìnrin Ẹlẹ́rìí náà tí ó ṣàjọpín òtítọ́ ṣíṣeyebíye yẹn pẹ̀lú rẹ̀ tí ó sì gbà láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé kan. Nígbà tí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pé Jesu sọ̀rọ̀ nípa Baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọlọrun mi, àti Ọlọrun yín” àti pé Jesu bá Bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìwọ nìkan Ọlọrun òtítọ́,” wọn ríi pé ohun tí Bibeli fi kọ́ni nípa Ọlọrun kìí ṣe èyí tí kò ṣeé lóye. (Johannu 17:3; 20:17) Bí wọ́n ṣe wá mọ àwọn ànímọ́ Jehofa, wọ́n nímọ̀lára sísúnmọ́ ọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí i, wọ́n sì fẹ́ láti máa ṣe ohun tí ó dùn mọ́-ọn nínú. Kí ni ìyọrísí rẹ̀?
8. (a) Nítorí ìfẹ́ wọn fún Jehofa àti ìfẹ́-ọkàn wọn láti mú inú rẹ̀ dùn, kí ni ohun tí àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti ṣe? (b) Èéṣe tí baptism Kristian fi ṣe pàtàkì gidigidi?
8 Láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó ti kọjá, 2,528,524 ènìyàn ní kọ́ńtínẹ̀ntì mẹ́fà àti ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ erékùṣù ti ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún Jehofa tí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ yìí hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi. Ìwọ ha jẹ́ ọ̀kan lára wọn, tàbí ìwọ ń múra nísinsìnyí láti ṣe ìrìbọmi? Ìrìbọmi jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ṣíṣe pàtàkì nínú ìgbésí-ayé gbogbo Kristian. Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn kí wọ́n sì baptisi wọn. (Matteu 28:19, 20) Ó tún yẹ fún àfiyèsí pé kété lẹ́yìn ìrìbọmi Jesu ni Jehofa fúnraarẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, ní wíwí pé: “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”—Luku 3:21, 22.
9. Láti lè di ipò-ìbátan kan tí Jehofa tẹ́wọ́gbà mú, kí ni ohun tí a ń béèrè níhà ọ̀dọ̀ wa?
9 Ipò-ìbátan kan tí a fọwọ́sí pẹ̀lú Jehofa jẹ́ ohun kan tí a níláti ṣìkẹ́. Bí o bá ti wọnú irú ìbátan bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi, yẹra fún ohunkóhun tí ó lè bà á jẹ́. Máṣe fàyègba àníyàn ìgbésí-ayé àti ìdàníyàn lórí ohun-ìní ti ara láti tì í sí ipò kejì. (1 Timoteu 6:8-12) Fi tòótọ́tòótọ́ gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Owe 3:6: “Mọ [Jehofa] ní gbogbo ọ̀nà rẹ: òun ó sì máa tọ́ ipa-ọ̀nà rẹ.”
Báwo Ni Ìfẹ́ Kristi Ṣe Nípa Jíjinlẹ̀ Lórí Rẹ Tó?
10. Èéṣe tí jíjọ́sìn tí a ń jọ́sìn Jehofa kò fi níláti mú kí a ṣá Jesu tì?
10 Dájúdájú, ìmọrírì yíyẹ fún Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun tòótọ́, kìí mú kí ẹnìkan ṣá Jesu Kristi tì. Ní òdìkejì pátápátá, Ìfihàn 19:10 (NW) sọ pé: “Jíjẹ́rìí Jesu ni ohun tí ń mí sí ìsọtẹ́lẹ̀.” Láti Genesisi sí Ìfihàn, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a mísí pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ipa-iṣẹ́ Jesu Kristi nínú ète Jehofa. Bí ẹnìkan ti ń mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí dunjú, àwòrán fífanimọ́ra kan tí ó bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìfèrúyípo àti èrò òdì tí ó ti jẹyọ láti inú àwọn ẹ̀kọ́ èké Kristẹndọm yóò bẹ̀rẹ̀ sí farahàn.
11. Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bibeli fi kọ́ni nípa Ọmọkùnrin Ọlọrun ṣe nípa lórí obìnrin kan ní Poland?
11 Mímọ òtítọ́ nípa Ọmọkùnrin Ọlọrun lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ẹnìkan. Bí ọ̀ràn ti rí nìyẹn nínú ọ̀ràn Danuta, obìnrin kan ní Poland. Ó ti ní ìfarakanra pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún ọdún mẹ́jọ, ó gbádùn ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni, ṣùgbọ́n kò sọ ìjọsìn náà di ọ̀nà ìgbésì-ayé rẹ̀. Nígbà yẹn ó gba ẹ̀dà ìwé náà Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, èyí tí ó ṣe ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa ìgbésí-ayé Kristi lọ́nà tí ó rọrùn láti lóye.a Ó ṣí ìwé náà, ní àṣálẹ́, ní níní èrò láti ka àkòrí kan péré. Bí ó ti wù kí ó rí, kò gbé e sílẹ̀ títí àfẹ̀mọ́jú, nígbà tí ó ka ìwé náà tán. Ó bú sẹ́kún. Ó bẹ̀bẹ̀ pé, “Jehofa, dáríjì mí.” Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ohun tí ó kà, ó rí ìfẹ́ tí Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀ fihàn kedere ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ó ríi pé fún ọdún mẹ́jọ òun ti ń fi àìmọrírì kọ ẹ̀yìn sí ìrànwọ́ tí Ọlọrun ti ń fi sùúrù nawọ́ rẹ̀ sí òun. Ní 1993 ó ṣe ìrìbọmi ní àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jehofa lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi.
12. Báwo ni ìmọ̀ pípéye nípa Jesu Kristi ṣe ń nípa lórí ìgbésí-ayé wa?
12 “Ìmọ̀ Oluwa wa Jesu Kristi” ní ìsopọ̀ pẹ̀lú jíjẹ́ Kristian aláápọn tí ń mésojáde. (2 Peteru 1:8) Títí dé àyè wo ni ìwọ yóò lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò yẹn, ní ṣíṣàjọpín ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn mìíràn? Àwọn ipò àyè máa ń nípa lórí ìwọ̀n tí ẹnìkọ̀ọ̀kan lè ṣe. (Matteu 13:18-23) A kò lè yí àwọn ipò àyè kan padà; a sì lè yí àwọn mìíràn padà. Kí ni yóò sún wa láti mọ̀ àti láti ṣe àwọn ìyípadà tí a bá lè ṣe? Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá”; lọ́rọ̀ mìíràn, ìfẹ́ tí ó fihàn ní fífi ìwàálàyè rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa tayọlọ́lá tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé bí ìmọrírì wa fún un ti ń pọ̀ síi, a óò ru ọkàn-àyà wa sókè lọ́nà jíjinlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, a mọ̀ pé kì yóò bójúmu rárá fún wa láti máa báa lọ ní lílépa góńgó onímọ-tara-ẹni-nìkan kí á sì máa gbé ìgbésí-aye wa lọ́nà púpọ̀ jùlọ láti tẹ́ ara wa lọ́rùn. Dípò bẹ́ẹ̀, a ń tún àwọn àlámọ̀rí wa ṣe bọ̀sípò láti fi iṣẹ́ tí Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe sí ipò kìn-ín-ní.—2 Korinti 5:14, 15.
Ìyàsọ́tọ̀ Kúrò Nínú Ayé—Dé Ìwọ̀n Àyè Wo?
13. Èéṣe tí àwa kò fi níláti fẹ́ apá èyíkéyìí nínú ìsìn kan tí ó ti sọ ara rẹ̀ di apákan ayé?
13 Kò ṣòro láti rí àkọsílẹ̀ tí Kristẹndọm àti àwọn ìsìn mìíràn ti ní nítorí pé wọ́n fẹ́ jẹ́ apákan ayé. Wọ́n ti lo owó ṣọ́ọ̀ṣì láti fi gbọ́ bùkátà ìgbòkègbodò ìṣọ̀tẹ̀. Àwọn àlùfáà ti di ọ̀jagun abẹ́lẹ̀. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ìwé ìròyìn ń gbé ìròyìn nípa àwọn ẹ̀yà ìsìn tí ń bá araawọn jà ní apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀-ayé jáde. Ọwọ́ wọn kún fún ẹ̀jẹ̀. (Isaiah 1:15) Ní gbogbo ayé sì ni àwọn àlùfáà ti ń gbìyànjú láti dọ́gbọ́n darí ọ̀ràn òṣèlú. Àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ kìí lọ́wọ́ nínú èyí.—Jakọbu 4:1-4.
14. (a) Kí ni ohun tí àwa fúnraawa gbọ́dọ̀ yẹra fún bí a bá fẹ́ ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé? (b) Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún dídi ẹni tí ìwà àti ìṣe ayé dẹkùn mú?
14 Ṣùgbọ́n ìyàsọ́tọ̀ kúrò nínú ayé ní nínú ju ìyẹn lọ. Ìfẹ́ owó àti ohun tí owó lè rà, ìfẹ́ ọkàn fún ìyọrí-ọlá, àti ìlépa aláìdáwọ́dúró fún adùn, papọ̀ pẹ̀lú àwọn nǹkan bí àìbìkítà fún àwọn ẹlòmíràn, irọ́ pípa àti ọ̀rọ̀ èébú, ìṣọ̀tẹ̀ lòdìsí àwọn aláṣẹ, àti ìkùnà láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu jẹ́ ànímọ́ ayé yìí. (2 Timoteu 3:2-5; 1 Johannu 2:15, 16) Nítorí àìpé wa, nígbà mìíràn a lè fi díẹ̀ lára irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ hàn lọ́nà kan. Kí ni ó lè ṣèrànwọ́ fún wa nínú ìjàkadì wa láti yẹra fún iru ìdẹkùn bẹ́ẹ̀? A gbọ́dọ̀ rán ara wa létí ẹni náà tí ó wà lẹ́yìn gbogbo rẹ̀. “Gbogbo ayé ni ó wà [lábẹ́] agbára ẹni búburú nì.” (1 Johannu 5:19) Bí ó ti wù kí ipa-ọ̀nà kan dàbí èyí tí ó fanimọ́ra tó, bí ó ti wù kí iye àwọn ènìyàn tí ń gbé irú igbésí-ayé yẹn ti pọ̀ tó, nígbà tí a bá rí Satani Eṣu, olórí elénìní Jehofa, lẹ́yìn rẹ̀, a ń mọ bí ó ti burẹ́wà tó níti gidi.—Orin Dafidi 97:10.
Báwo Ni Ìfẹ́ Rẹ Ti Lọ Jìnnà Tó?
15. Báwo ni ìfẹ́ aláìnímọtara-ẹni-nìkan tí o ṣàkíyèsí ṣe ṣèrànwọ́ fún ọ láti dá ìsìn tí ó tọ̀nà mọ̀ yàtọ̀?
15 Nígbà tí o kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí darapọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, láìṣiyèméjì ìfẹ́ tí o rí láàárín wọn fà ọ́ mọ́ra nítorí òdìkejì tí ó jẹ́ sí ẹ̀mí ayé. Ìtẹnumọ́ lórí ìfẹ́ aláìnímọtara-ẹni-nìkan mú kí ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa yàtọ̀ gédégbé sí ti gbogbo ọ̀nà ìgbàjọ́sìn mìíràn. Ó lè jẹ́ pé ohun tí ó yí ọ lérò padà nìyí pé níti tòótọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe ìsìn tí ó tọ̀nà. Jesu Kristi fúnraarẹ̀ sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin ń ṣe, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọnìkejì yín.”—Johannu 13:35.
16. Àwọn àǹfààní wo ni ó ṣì lè wà fún wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan láti mú ìfẹ́ wa gbòòrò síwájú?
16 Ǹjẹ́ ànímọ́ yẹn ha fi ọ́ hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi bí? Àwọn ọ̀nà èyíkéyìí ha wà tí o lè gbà mú kí fífi ìfẹ́ rẹ hàn gbòòrò síi bí? Láìsí iyèméjì, gbogbo wa lè ṣe bẹ́ẹ̀. Púpọ̀ síi ṣì wà ju híhùwà bí ọ̀rẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí a bá sì níláti fi ìfẹ́ han sí kìkì àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, àwa yóò ha yàtọ̀ sí ayé bí? “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàárín ara yín,” ni Bibeli gbani nímọ̀ràn. (1 Peteru 4:8) Àwọn wo ni a lè fi ìfẹ́ títóbi jù hàn sí? Ó ha jẹ́ Kristian arákùnrin kan tàbí arábìnrin tí ipò àtilẹ̀wá rẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa tí ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan rẹ̀ sì ń bí wa nínú? O ha jẹ́ ẹnìkan tí kò lè wá sí àwọn ìpàdé déédéé, nítorí àmódi tàbí ọjọ́ ogbó? Ó ha jẹ́ alábàáṣègbéyàwó wa bí? Tàbí, ó ha lè jẹ́ àwọn òbí wa tí ń darúgbó bí? Àwọn kan tí wọ́n ń ṣe dáradára ní fífi èso ti ẹ̀mí hàn, títíkan ìfẹ́, nímọ̀lára bí ẹni pé wọ́n ń tún nǹkan wọ̀nyí kọ́ lẹ́ẹ̀kan síi nígbà tí wọ́n bá dojúkọ ipò lílekoko gan-an tí ó lè dìde ní fífún mẹ́ḿbà ìdílé kan tí ó ti di aláàbọ̀ ara pátápátá ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìtọ́jú. Dájúdájú, àní nígbà tí a bá dojúkọ àwọn ipò wọ̀nyí, ìfẹ́ wa níláti lọ jìnnà rékọjá agbo ìdílé tiwa fúnraawa.
Jíjẹ́rìí Ìjọba—Báwo Ní Ó Ṣe Ṣe Pàtàkì fún Ọ Tó?
17. Bí àwa fúnraawa bá ti jàǹfààní nínú ìbẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, kí ni ìmọ̀lára wa yẹ kí ó sún wa ṣe nísinsìnyí?
17 Ọ̀nà pàtàkì kan tí a gbà ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ wa ni nípa jíjẹ́rìí fún wọn nípa Ìjọba Ọlọrun. Kìkì ẹgbẹ́ àwùjọ kanṣoṣo ni ó ń ṣe iṣẹ́ yìí tí Jesu sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. (Marku 13:10) Àwọn wọ̀nyí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Àwa fúnraawa ti jàǹfààní láti inú èyí. Ó jẹ́ àǹfààní wa nísinsìnyí láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́. Bí a bá ṣàjọpín ojú ìwòye Ọlọrun nínú ọ̀ràn yìí, iṣẹ́ náà yóò mú ipò iwájú nínú ìgbésí-ayé wa.
18. Báwo ni kíkà tí a ń ka ìwé náà Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom ṣe lè nípa lórí bí a ṣe ń nípìn-ín nínú jíjẹ́rìí Ìjọba?
18 Àkọsílẹ̀ tí ń rùmọ̀lárasókè nípa bí a ti ṣe mú ìhìn-iṣẹ́ náà lọ sí àwọn apá ibi jíjìnnà réré nínú ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ni a sọ nínú ìwé náà Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom. Bí o bá mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, máṣe ṣaláì kà á. Bí o sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, fi àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ sí àwọn ọ̀nà tí ẹnìkọ̀ọ̀kan gbà nípìn-ín nínú jíjẹ́rìí fúnni nípa Ìjọba náà. Àpẹẹrẹ àwọn kan ha wà tí o lè ṣàfarawé bí? Ọ̀pọ̀ àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún gbogbo wa. Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ wa fún Jehofa sún wa láti lò wọ́n lọ́nà rere.
19. Báwo ni a ṣe jàǹfààní nígbà tí a bá tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ tí ń bá mímọ ìsìn tí ó tọ̀nà rìn?
19 Nígbà tí a bá fi ara wa fún ṣíṣe ìfẹ́-inú Jehofa lọ́nà yìí, a ń rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà pé, Kí ni ìgbésí-ayé túmọ̀sí? (Ìfihàn 4:11) A kò táràrà kiri mọ, kí á sì máa nímọ̀lára wíwà gẹ́gẹ́ bí aláìsí. Kò sí iṣẹ́ ìgbésí-ayé mìíràn tí o lè fi ara fún tí yóò mú ìtẹ́lọ́rùn ọkàn púpọ̀ wá ju fífi tọkàntọkàn mú ara rẹ bá iṣẹ́-ìsìn Jehofa Ọlọrun mu. Ẹ wo ọjọ́ ọ̀la títóbilọ́lá tí ó nawọ́ rẹ̀ sí wa! Ayérayé kan tí ó kún fún ìgbésí-ayé títẹ́nilọ́rùn nínú ayé titun rẹ̀, níbi tí a o ti lè lo ọgbọ́n-orí wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ète onífẹ̀ẹ́ nítorí èyí tí Ọlọrun fi ṣẹ̀dá aráyé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èéṣe tí ó fi ṣekókó pé kí ìsìn kan tẹ́wọ́gba Bibeli gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí ó sì bọlá fún Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun òtítọ́?
◻ Kí ni ìsìn tòótọ́ ń kọ́ni níti ipa-iṣẹ́ Jesu gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà?
◻ Èéṣe tí àwọn Kristian fi níláti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé kí wọ́n sì sọ ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan dàṣà?
◻ Ipa wo ni ìjẹ́rìí Ìjọba náà ń kó nínú ìsìn tí ó tọ̀nà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ ṣíṣekókó ní títẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ ìjọsìn tòótọ́. Lóṣooṣù, nǹkan bíi 25,000 kárí ayé ń gbé ìgbésẹ̀ yẹn
Russia
Senegal
Papua New Guinea
U.S.A.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ṣíṣàjọpín òtítọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́ apákan ìjọsìn tòótọ́
U.S.A.
Brazil
U.S.A.
Hong Kong