ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 3-5
  • Àìkìísùntó—Ṣé Ìṣòro Yìí Ń Burú Sí I Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìkìísùntó—Ṣé Ìṣòro Yìí Ń Burú Sí I Ni?
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oorun—Ṣé Fáwọn Olóòrayè ni Àbí Ohun Àìgbọ́dọ̀máṣe?
    Jí!—2003
  • Bí O Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Sùn Dáadáa
    Jí!—2003
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí N Lè Máa Sùn Dáadáa?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 3-5

Àìkìísùntó—Ṣé Ìṣòro Yìí Ń Burú Sí I Ni?

Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn lónìí ni kì í sùn tó rárá. Ìṣòro yìí lè jẹ́ kókó kan pàtàkì tó lè mú kí ọkọ̀ wọn bà jẹ́ pátápátá nínú ìjàǹbá mọ́tò, kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn, àní kó tiẹ̀ jẹ́ kí ìgbéyàwó wọn dàrú pàápàá. Ó lè dá àìsàn sí wọn lára kó sì ké ìgbésí ayé wọn kúrú. Gbèsè ńlá tó ń sọ adènà àrùn inú ara di aláìlágbára ni, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ mú kí onírúurú àìsàn tètè ṣeni. Wọ́n ti sọ pé ó wà lára àwọn ohun tó ń fa àwọn àìsàn bí àtọ̀gbẹ, àrùn ọkàn àti sísanra jọ̀kọ̀tọ̀, títí kan àwọn àìlera mìíràn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ní ìṣòro yìí ni kò mọ̀ pé àwọn ní gbèsè kan lọ́rùn.

Ohun tó ń fa àwọn ìṣòro wọ̀nyí ni jíjẹ gbèsè oorun, ìyẹn nígbà téèyàn kì í bá sun oorun tó lè ṣe ara láǹfààní. Mímọ̀ọ́mọ̀ fi oorun du ara ẹni nítorí irú ìgbésí ayé téèyàn ń gbé tàbí àìrí oorun sùn nítorí àìsàn lè fa èyí.

Àwọn olùṣèwádìí lórí ọ̀ràn ìlera fojú bù ú pé, ní ìpíndọ́gba, oorun táwọn èèyàn lágbàáyé ń sùn lálaalẹ́ báyìí ti fi wákàtí kan dín sí ohun tí ara nílò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè má fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú, báwọn èèyàn tó wà lágbàáyé tí iye wọn jẹ́ nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́fà ṣe ń jẹ gbèsè oorun wákàtí kọ̀ọ̀kan lálaalẹ́ ní ìpíndọ́gba ti mú kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu lórí àwọn àìsàn tó jẹ mọ́ oorun àti ipa tó ń ní lórí ìlera tó jí pépé.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹyọ ìṣòro kan làwọn onímọ̀ ìṣègùn mọ ìṣòro àìlèsùn tó le gan-an sí, èyí tí wọ́n sábà máa ń pè ní àìróorunsùntó. Àmọ́ ṣá o, ìgbìmọ̀ kan tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà gbé kalẹ̀ ti rí i pé ìṣòro oorun mẹ́tàdínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà. Èyí ó wù ó jẹ́, ohun tó ń fa àìróorunsùntó pọ̀ débi pé, lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n tiẹ̀ máa ń kà á sí àmì pé àwọn àìsàn kan fẹ́ ṣèèyàn ni, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ka ara gbígbóná sí àmì àìsàn kan.

Kódà, àìkìísùntó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pàápàá lè fa jàǹbá. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tom yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbà ló jẹ́ nídìí iṣẹ́ wíwakọ̀ akẹ́rù, ó lọ forí ọkọ̀ akẹ́rù ńlá rẹ̀ sọ odi kan, ó sì tú irínwó lítà ásíìdì tó ń jẹ́ sulfuric acid dà sórí títì márosẹ̀ kan. Tom jẹ́wọ́ pé: “Ńṣe ni oorun gbé mi lọ.” Nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa àwọn títì márosẹ̀ méjì kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n fojú bù ú pé àwọn awakọ̀ tó ń tòògbé ló ń fa nǹkan bí ìdajì nínú gbogbo jàǹbá ọkọ̀ tó ń mẹ́mìí lọ.

Tún gbé ewu téèyàn lè máa dojú kọ wò béèyàn bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òṣìṣẹ́ kan tó máa ń sùn lẹ́nu iṣẹ́. Olùṣèwádìí ọmọ ilẹ̀ Ọsirélíà kan, Ann Williamson sọ pé: “Lẹ́yìn wákàtí mẹ́tàdínlógún sí mọ́kàndínlógún láìsí oorun, bí [àwọn tó kópa] nínú àwọn ìdánwò kan ṣe ń ṣe kò yàtọ̀ sí ti àwọn tó mutí kọjá ohun tí òfin gbà láyè tàbí kó tiẹ̀ burú ju ti àwọn yẹn lọ pàápàá.” Lédè mìíràn, ìṣesí àwọn tó kópa náà dà bí ìgbà tí wọ́n mutí dé ìwọ̀n tí òfin fàyè gbà fún àwọn awakọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan tàbí bí ìgbà tí wọ́n kọjá ìwọ̀n yẹn pàápàá! Pẹ̀lú bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún jàǹbá mọ́tò àti jàǹbá lẹ́nu iṣẹ́ ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́dọọdún, àdánù tó ń fà bá iṣẹ́ àti ìdílé àwọn tó ṣẹlẹ̀ sí kúrò ní kékeré.a

Àwọn nǹkan wo ló lè dá kún ìṣòro àìkìísùntó? Ọ̀kan ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ báyìí, ìyẹn ni káwọn èèyàn máa ṣiṣẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún lóòjọ́, ní ọjọ́ méje lọ́sẹ̀. Ìwé ìròyìn USA Today pe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ní “àṣà tuntun kan tó ń yí ọ̀nà táà ń gbà gbé ìgbésí ayé padà,” ó sì wá fi kún un pé “ńṣe làwọn òǹtajà àtàwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru nítorí àtijèrè àmọ́ tí wọ́n ń ṣàìka oorun sí túbọ̀ ń pọ̀ sí i.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn máa ń wo àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó jẹ́ àṣemọ́jú bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún máa ń wá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lásìkò tó yẹ kí wọ́n máa sùn. Bákan náà, ìdààmú ọkàn tún ń fa àìkìísùntó, èyí sì sábà máa ń jẹ́ nítorí àwọn àníyàn tí másùnmáwo àti kòó-kòó-jàn-án-jàn-án ìgbésí ayé ń mú kó ga sí i. Èyí tó wá kẹ́yìn níbẹ̀ ni pé oríṣiríṣi àìsàn ara ló wà tó lè fa àìkìísùntó.

Ọ̀pọ̀ àwọn dókítà máa ń sọ pé ó ṣòro gan-an láti mú kí àwọn aláìsàn gbà pé àìkìísùntó kì í ṣe ìṣòro kékeré rárá. Dókítà kan sọ pé “nǹkan iyì” làwọn kan tiẹ̀ ka bó ṣe máa ń rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu sí. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni ìṣòro àwọn tí kì í sùn tó máa ń burú sí i, wọ́n lè má mọ̀ pé ìṣòro oorun sísùn tó le koko ló ń yọ wọ́n lẹ́nu. Nǹkan tí ọ̀pọ̀ máa ń sọ ni pé, ‘Torí pé mo ti ń dàgbà ni’ tàbí, ‘Ìgbésí ayé tí kò dẹrùn fún mi ni kò jẹ́ kí ara mi lè gbé kánkán’ tàbí, ‘Torí pé mi ò ráyè sùn fún àkókò gígùn, èyí tí ara mi nílò, ló jẹ́ kó máa rẹ̀ mí nígbà gbogbo.’

Wíwá nǹkan ṣe sí àṣà jíjẹ gbèsè oorun yìí kò rọrùn rárá. Àmọ́, lílóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara nígbà téèyàn bá sùn dáadáa àti dídá àwọn àmì tó ń fi hàn pé èèyàn kì í sùn tó mọ̀ lè fúnni níṣìírí láti yí padà. Mímọ àwọn àmì tó ń fi hàn pé èèyàn ní ìṣòro oorun sísùn tó burú jáì lè dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí sí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èrò tó wọ́pọ̀ ni pé àárẹ̀ ara ló túbọ̀ dá kún ọ̀pọ̀ jàǹbá bíburú jáì tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún. Wo Jí! February 8, 2001, ojú ìwé 6.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Kódà, àìkìísùntó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pàápàá lè fa jàǹbá tó burú jáì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́