Rírí Oorun Tó Pọ̀ Tó Sùn
KÒ TÍÌ ju àádọ́ta ọdún sẹ́yìn tá a ní ọ̀pọ̀ òye tá a wá ní báyìí nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara nígbà téèyàn bá ń sùn. Àwọn ohun tá a ti wá mọ̀ ti jẹ́ ká rí i pé àwọn èrò kan tá a ti ní látọjọ́ pípẹ́ kò tọ̀nà. Ọ̀kan lára irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ni pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀ya ara ni iṣẹ́ wọ́n máa ń dín kù jọjọ nígbà tá a bá ń sùn, oorun kò yàtọ̀ sí pé èèyàn wà nípò àìmọ̀kan.
Nípa ṣíṣèwádìí ọ̀nà tí ọpọlọ ń gbà ṣiṣẹ́, àwọn olùṣèwádìí nípa ìṣègùn ti rí i pé oorun pín sí ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọpọlọ sì máa ń ṣiṣẹ́ lọ ṣiṣẹ́ bọ̀ láti ìpele kan sí òmíràn nígbà tá a bá ń sùn. Dípò tí ì bá fi jẹ́ pé ńṣe ni ọpọlọ èèyàn máa ń wà láìṣiṣẹ́, ó máa ń ṣiṣẹ́ lọ ní pẹrẹu láwọn ìpele oorun kan. Oorun tí yóò ṣe ara lóore ń béèrè pé káwọn ìpele oorun wọ̀nyí wáyé lẹ́ẹ̀mẹrin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lálaalẹ́, kéèyàn sì lo àkókò tó tó ní ìpele kọ̀ọ̀kan.
Oorun Díjú Gan-an
A lè pín oorun téèyàn ń sùn mọ́jú sí ọ̀nà méjì: ọ̀kan ni èyí tí wọ́n sábà máa ń pè ní oorun tí ẹyinjú ẹni ti máa ń yí lọ yí bọ̀ (tàbí oorun téèyàn ti ń lálàá) àti oorun tí ẹyinjú ẹni kì í ti í yí lọ yí bọ̀ (oorun téèyàn kì í ti í lálàá). O lè mọ̀ bí ẹnì kan bá wà ní ìpele oorun tí ẹyinjú ti máa ń yí lọ yí bọ̀ nígbà tí ẹyinjú rẹ̀ bá ń yí lọ sọ́tùn-ún sósì léraléra lábẹ́ ìpéǹpéjú rẹ̀.
A tún lè pín oorun tí ẹyinjú ẹni kì í ti í yí lọ yí bọ̀ sí ìpele mẹ́rin. Lẹ́yìn tó o bá fẹ̀yìn lélẹ̀, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wàá wọ ìpele kìíní, ìyẹn ni ìgbà tí oorun bẹ̀rẹ̀ sí kùn ọ́ tàbí tí oorun kò tíì wọra. Ní ìpele yìí, àwọn iṣan ara rẹ á sinmi pátápátá, ìṣiṣẹ́ lọ ṣiṣẹ́ bọ̀ ọpọlọ rẹ á máa yára àmọ́ kò ní ṣe lemọ́lemọ́. Nígbà àkọ́kọ́ tí èyí bá ṣẹlẹ̀ lóru, kì í ju ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú méje lọ. Nígbà tó o bá bọ́ sí ìpele kejì, ìyẹn oorun gidi, níbi tí wàá ti lo ìdá ogún nínú ìdá ọgọ́rùn-ún gbogbo òru, ọpọlọ rẹ á wá máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Ìrònú rẹ lè máà já geere tàbí kó máa ṣe ọ́ bí ẹni pé ò ń rí àwọn nǹkan kan fìrífìrí, àmọ́ oò ní mọ ibi tó o wà óò sì ní rí ohunkóhun kódà bó o tiẹ̀ lajú sílẹ̀.
Lẹ́yìn èyí ló kan ìpele kẹta àti ìkẹrin, ìyẹn oorun tó wọra gan-an àtèyí tó máa ń wọra pátápátá. Ní ìpele tí oorun àsùnwọra ti máa ń wáyé yìí, bí ọpọlọ rẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ á dín kù gan-an. Àkókò yìí ló máa ṣòro gan-an fún ọ láti ta jí, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò ti darí lọ sára àwọn iṣan. Láàárín àkókò yìí (tó sábà máa ń jẹ́ nǹkan bí ìdajì gbogbo òru) ni ara máa ń padà bọ̀ sípò tó sì máa ń ṣàtúnṣe ara rẹ̀, àkókò tí oorun wọra gan-an yìí sì ni àwọn ọmọdé máa ń dàgbà sókè. Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé, yálà èèyàn jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, bí oorun èèyàn kò bá wọ ìpele oorun àsùnwọra yìí, ó ṣeé ṣe kó rẹ èèyàn tẹnutẹnu lọ́jọ́ kejì, kó máa wò duu tàbí kó tiẹ̀ ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn pàápàá.
Níkẹyìn, oorun tí ẹyinjú ẹni ti ń yí lọ yí bọ̀ tó yàtọ̀ pátápátá ló máa ń kádìí ìpele kọ̀ọ̀kan. Ní ìpele téèyàn ti máa ń lálàá yìí (tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo wákàtí kan àtààbọ̀), ẹ̀jẹ̀ á túbọ̀ ṣàn lọ sí ọpọlọ, ọpọlọ rẹ á sì máa ṣiṣẹ́ bí ìgbà tóò sùn. Àmọ́, o ò ní lè lo àwọn iṣan rẹ. Ó jọ pé àìlè lo àwọn iṣan rẹ yìí ni kì í jẹ́ kó o lè ṣe àwọn ohun tóò ń rí nínú àlá kó o sì ṣe ara rẹ tàbí àwọn mìíràn léṣe.
Àwọn ìpele oorun tí ẹyinjú ẹni ti ń yí lọ yí bọ̀ tàbí téèyàn ti ń lálàá yìí máa ń gùn sí i nígbà kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá wáyé lóru ó sì dà bíi pé wọ́n ṣe pàtàkì gan-an fún mímú ọpọlọ jí pépé. Lọ́nà kan náà tí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ń gbà ṣiṣẹ́, ọpọlọ máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni tó fi pa mọ́, á máa mú àwọn tí kò ṣe pàtàkì kúrò á sì máa fi àwọn tí wàá fẹ́ láti máa rántí fúngbà pípẹ́ sílẹ̀. Wọ́n sọ pé àìkìí lo àkókò tó ní ìpele oorun tí ẹyinjú ẹni ti ń yí lọ yí bọ̀ lè fa ìdààmú ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, àkókò táwọn tí kì í rí oorun sùn ń lò ní ìpele oorun tí ẹyinjú ti ń yí lọ yí bọ̀ kì í pọ̀, èyí tó máa ń mú kí àníyàn wọn túbọ̀ ga sí i.
Nítorí náà, kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí a kì í bá sun àwọn ìpele oorun tó máa ń wáyé tẹ̀ léra wọ̀nyí déédéé (yálà àwa la fà á tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́), tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ gbèsè oorun? Bí wákàtí oorun táà ń sùn kò bá tó iye tára wa nílò, tí èyí sì ń ṣẹlẹ̀ léraléra, ìpele oorun tí ẹyinjú ẹni ti máa ń yí lọ yí bọ̀ tó kẹ́yìn tó sì máa ń gùn jù kò ní máa wáyé, èyí tó ṣe pàtàkì gidigidi fún ọpọlọ. Bí oorun wa bá ń ṣe ségesège, tó jẹ́ pé oorun ṣẹ́ẹ́-ṣẹ̀ẹ̀-ṣẹ́ la máa ń sùn, ó túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ò ní lè sun oorun àsùnwọra tára wa nílò láti bọ̀ sípò. Àwọn tí kì í sùn tó rárá kì í lè pọkàn pọ̀ fún àkókò gígùn, wọ́n máa ń tètè gbàgbé nǹkan, wọn kì í sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ lò nígbà míì, wọn kì í lè ronú lọ́nà tó já gaara bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í lè fọkàn yàwòrán ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe.
Kí ló máa ń mú oorun kunni? Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló para pọ̀ tó ń mú kéèyàn máa sùn kó sì máa jí láwọn àkókò kan. Ó jọ pé ọ̀nà tí ọpọlọ wa ń gbà ṣiṣẹ́ wà lára ohun tó ń mú kí èyí ṣẹlẹ̀. Bákan náà, àgbájọpọ̀ àwọn sẹ́ẹ̀lì kan tún wà nínú ọpọlọ tó dájú pé ó máa ń darí oorun táà ń sùn. Ibi tí àwọn iṣan ojú ti pàdé ni ohun tó ń darí sísùn àti jíjí yìí wà. Ìyẹn ni ìmọ́lẹ̀ fi máa ń nípa lórí bí oorun ṣe ń kùn wá tó. Ìmọ́lẹ̀ lè jí ọ lójú oorun, nígbà tí òkùnkùn sì lè mú kí oorun máa kùn ọ́.
Bí ara rẹ ṣe ń móoru tàbí silé sí náà tún wà lára rẹ̀. Nígbà tí inú ara bá móoru, lọ́pọ̀ ìgbà ní nǹkan bí ọwọ́ àárọ̀ àti ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, wàá wà lójúfò gan-an. Bí ara rẹ bá ti wá ń silé, oorun á bẹ̀rẹ̀ sí kùn ọ́ gan-an. Àwọn olùṣèwádìí gbà pé bí kálukú ṣe ń wà lójúfò sí àti bí oorun ṣe máa ń kunni sí yàtọ̀ síra.
Báwo Ni Oorun Tó O Nílò Ṣe Pọ̀ Tó?
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì jẹ́ ká mọ̀ pé, ní ìpíndọ́gba, ara èèyàn nílò nǹkan bí oorun wákàtí mẹ́jọ lálaalẹ́. Àmọ́, àwọn ìwádìí tún fi hàn pé ohun tí ara kálukú nílò yàtọ̀ síra gan-an.
Ṣíṣàyẹ̀wò ara rẹ láìtan ara rẹ jẹ á jẹ́ kó o mọ̀ yálà ò ń sun oorun tí ara rẹ nílò déédéé tàbí ò ń jẹ gbèsè oorun. Àwọn àmì tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí làwọn ògbógi pẹnu pọ̀ lé pé ó ń fi hàn pé ẹnì kan ń sun oorun tó ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní:
◼ Oorun ń wá tìrọ̀rùntìrọ̀rùn láìṣẹ̀ṣẹ̀ lo oògùn oorun tàbí pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbìyànjú láti mú kí ara rẹ balẹ̀ tàbí láti mú àníyàn kúrò lọ́kàn.
◼ O kì í fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ bóyá o ta jí lóru rárá, àmọ́ bó o bá tiẹ̀ ta jí, kíá lo máa ń sùn padà.
◼ Kì í ṣòro fún ọ láti jí láràárọ̀ lọ́wọ́ àkókò kan náà, èyí sì sábà máa ń jẹ́ láìlo aago tí ń jíni.
◼ Bó o bá ti jí tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí káàkiri, ojú rẹ á dá ara rẹ á sì jí pépé látàárọ̀ ṣúlẹ̀.
Àwọn Kókó Tó Lè Ṣèrànwọ́
Ti àwọn tí kì í rí oorun sùn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ńkọ́? Àwọn ògbógí kan dábàá àwọn kókó tó lè ṣèrànwọ́ wọ̀nyí:
1. Má ṣe mu àwọn nǹkan tó máa ń mú ara yá gágá, irú bíi kọfí tàbí tíì, tó bá kù díẹ̀ kó o lọ sùn. Ọ̀pọ̀ máa ń ní èrò kan tí kò tọ̀nà, ìyẹn ni pé mímu ọtí líle á jẹ́ káwọn tètè rí oorun sùn. Àmọ́ ṣá, ìwádìí táwọn oníṣègùn ṣe fi hàn pé ọtí líle lè mú kó o jí kalẹ̀ láàárín oru lẹ́yìn tó bá ti kọ́kọ́ jẹ́ kó o sùn.
2. Jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ìwé kan sọ pé: “Ó máa ń ṣòro gan-an fún àwọn tó ń mu sìgá láti tètè rí oorun sùn, nítorí pé sìgá máa ń mú kí ìfúnpá ga, ó máa ń jẹ́ kí ọkàn yára lù kìkì, kì í sì í jẹ́ kí ọpọlọ sinmi. Àwọn tó ń mu sìgá tún máa ń dá jí gan-an láàárín òru, bóyá nítorí pé ara wọn máa ń béèrè fún un.”
3. Yẹra fún ohun táá mú kó o máa ronú lọ ronú bọ̀ tàbí tí kò ní jẹ́ kára rẹ balẹ̀ tó bá kù díẹ̀ kó o lọ sùn. Ṣíṣeré ìmárale máa ń jẹ́ kéèyàn sùn dáadáa àmọ́ ìyẹn téèyàn ò bá ṣe é ní kété téèyàn fẹ́ lọ sùn. Bíbójú tó àwọn ìṣòro ńlá tàbí àwọn ọ̀ràn tó gbàrònú gan-an kété kó o tó lọ sùn lè ṣàkóbá fún ìbalẹ̀ ara téèyàn nílò kí oorun lè múni lọ.
4. Rí i dájú pé yàrá tóò ń sùn pa rọ́rọ́, ó ṣókùnkùn, níbi tó bá sì ti ṣeé ṣe, rí i pé ó máa ń silé dáadáa. Ní ti ariwo, gbé ìwádìí kan tó gbajúmọ̀ yẹ̀ wò nípa àwọn tó ń gbé nítòsí pápákọ̀ òfuurufú kan tí wọ́n sọ pé àwọn kì í gbọ́ ìró ọkọ̀ òfuurufú mọ́. Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ṣe ń sùn sí, ọpọlọ wọn ṣì lè rántí ariwo tí ọkọ̀ òfuurufú ń pa nígbà kọ̀ọ̀kan tó bá ń gbéra tàbí tó bá ń balẹ̀! Àwọn olùṣèwádìí náà wá sọ pé lálaalẹ́, ní ìpíndọ́gba, nǹkan bíi wákàtí kan loorun tó yẹ kó ṣe ara àwọn tí wọ́n lò fún ìwádìí náà lóore fi ń dín sí tàwọn tó ń gbé lágbègbè tó pa rọ́rọ́ ju tiwọn lọ. Lílo ohun èlò tí wọ́n fi ń dí etí nítorí ariwo tàbí ṣíṣe àwọn nǹkan mìíràn ì bá ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an láti lè sun oorun àsùngbádùn. Àwọn kan ti rí i pé ariwo tí kò pọ̀, bí irú èyí tí fáànù máa ń pa máa ń ṣèrànwọ́ gan-an bó bá di dandan láti bo àwọn ariwo tó ń wá láti ìta mọ́lẹ̀.
5. Ṣọ́ra fún lílo oògùn oorun. Ńṣe lẹ̀rí túbọ̀ ń pọ̀ sí i tó ń fi hàn pé ọ̀pọ̀ oògùn tí wọ́n máa ń ní káwọn èèyàn lò láti lè sùn máa ń di ohun tó mọ́ wọn lára, kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ mọ́ tó bá ti pẹ́ tí wọ́n ti ń lò ó, ó sì máa ń láwọn àkóbá tó ń ṣe. Bá a bá tiẹ̀ máa lò ó rárá, ìgbà díẹ̀ ló yẹ ká fi lò ó.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìdààmú ọkàn lè fa àìróorunsùntó, àwọn kan ronú pé fífira ẹni lọ́kàn balẹ̀ kété kéèyàn tó lọ sùn àti mímú àkókò náà lárinrin jẹ́ ọ̀nà kan láti rí oorun tó máa ṣe ara láǹfààní sùn. Mímú àwọn ìdààmú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kúrò lọ́kàn àti ṣíṣe ohun tó gbádùn mọ́ni, irú bíi kíkàwé, lè ṣèrànwọ́. Dájúdájú, àǹfààní kékeré kọ́ ló wà nínú ìmọ̀ràn Bíbélì, èyí tó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run . . . yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”—Fílípì 4:6, 7.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwọn Èrò Tí Kò Tọ̀nà Àmọ́ Tó Wọ́pọ̀
1. Mímu àwọn nǹkan tó ní èròjà kaféènì nínú kò ní jẹ́ kí oorun kunni rárá téèyàn bá ń wakọ̀ lọ sọ́nà jíjìn.
Àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn awakọ̀ sábà máa ń tanra wọn jẹ pé ojú àwọn dá gan-an nígbà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Bó bá di dandan pé kó o wakọ̀ ọ̀nà jíjìn tó sì jẹ́ lálẹ́, ó sàn kó o máa wá ibi tí kò léwu dúró sí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó o sì fi oorun díẹ̀ rajú (bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú), lẹ́yìn náà kó o rìn kúṣẹ́kúṣẹ́ díẹ̀ tàbí kó o rọra sáré díẹ̀ kó o sì máa na apá àti ẹsẹ̀ rẹ káwọn iṣan ibẹ̀ lè nà.
2. Bí n kì í bá sùn tó, fífi oorun díẹ̀ rajú lásán ti tó.
Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi gbà pé sísùn fún àkókò gígùn lálaalẹ́ ló dára jù lọ. Rírẹjú lọ́sàn-án (tó sábà máa ń jẹ́ ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú) lè jẹ́ kí ojú dá lákòókò tí oorun máa ń kunni lọ́wọ́ ọ̀sán láìsí pé ó ń ṣèdíwọ́ fún oorun tóò ń sùn fún àkókò gígùn lóru. Àmọ́, rírẹjú ní nǹkan bíi wákàtí mẹ́rin sígbà tí wà á lọ sùn lálẹ́ lè máà jẹ́ kó o rí oorun tó máa ṣe ara láǹfààní sùn lóru.
3. Àlá tá a bá rántí fi hàn pé a ò sùn dáadáa lóru.
Àlá (tó sábà máa ń wáyé lákòókò oorun tí ẹyinjú ti máa ń yí lọ yí bọ̀) jẹ́ àmì pé èèyàn sùn dáadáa ó sì sábà máa ń wáyé nígbà mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní gbogbo òru téèyàn bá sùn dáadáa. Àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn àlá tá a bá rántí jẹ́ àwọn tó jẹ́ pé a ta jí, bóyá nígbà táà ń lá wọn lọ́wọ́ tàbí níṣẹ̀ẹ́jú díẹ̀ lẹ́yìn tá a lá wọn tán. Àmọ́ ṣá o, àlá bíbanilẹ́rù lè kó ìdààmú báni kó sì mú kó ṣòro láti sùn padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Bó o bá sùn dáadáa lóru, ojú rẹ á dá ara rẹ á sì jí pépé látàárọ̀ ṣúlẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti wá mọ̀ báyìí pé oorun ní onírúurú ìpele
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ó máa ń ṣòro gan-an fún àwọn amusìgá láti tètè rí oorun sùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ṣọ́ra fún lílo àwọn oògùn tó ń fi oorun kunni