Oorun Báwo Ló Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
● Ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ní báyìí àwọn tó ń gbé ní Amẹ́ríkà ti Àríwá máa ń sun oorun wákàtí méje sí méje ààbọ̀ lóru.a Báwo ni oorun sísùn ti ṣe pàtàkì tó? Nígbà tó o bá sùn, o máa ń dé ìpele kan ní gbogbo wákàtí kan sí wákàtí kan ààbọ̀, èyí tí wọ́n máa ń pè ní àkókò tí ojú máa ń yí bíríbírí. Láàárín ìpele yìí, ọpọlọ máa ń ṣiṣẹ́, àwọn tó ń ṣèwádìí sì gbà pé àkókò yẹn ni ọpọlọ máa ń ṣe àtúnṣe ara rẹ̀. Àwọn ògbógi kan sọ pé, tá a bá dá jí, tí èèyàn ò sì rí oorun sùn mọ́, ó máa ń fàbọ̀ síni lára. Kò ní jẹ́ kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ dáadáa, èyí kì í sì í jẹ́ kí ara èèyàn gbé kánkán, ó sì tún máa ń fa ọ̀pọ̀ àìlera ara míì.
Béèyàn bá lo kaféènì, ó lè ṣèdíwọ́ ìgbà díẹ̀ fún ohun tó máa ń mú kí oorun kunni. Síbẹ̀, ọpọlọ wa ní ohun kan tó máa ń jẹ́ kí oorun kunni nígbà tí a ò bá tíì sùn tó, ohun ló sì máa ń fa kéèyàn máa tòògbé. Bí ìwé ìròyìn The Toronto Star ṣe sọ, “Ohun yòówù kó o máa ṣe, bí ọpọlọ rẹ kò bá sinmi nítorí pé o kò sùn tó bó ṣe yẹ, èyí á mú kó o máa tòògbé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fún nǹkan bíi ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá sí ohun tó lé ní ìṣẹ́jú kan.” Ká sọ pé ò ń wa ọkọ̀, tó ò ń rin ìrìn àádọ́ta kìlómítà ní wákàtí kan, tó o sì wá tòògbé fún nǹkan bí ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá. Láàárín àkókò yẹn, wàá ti rin ìrìn tó ju pápá ìṣeré tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù lọ. Láfikún sí i, tí o kì í bá sùn tó, kò ní jẹ́ kí ara rẹ lágbára láti dènà àrùn, torí pé ìgbà téèyàn bá sùn ni ara máa ń mú àwọn sẹ́ẹ̀lì tó máa ń gbógun ti àrùn jáde. Nígbà téèyàn bá sùn, ara wa tún máa ń mú èròjà kan tó ń jẹ́ leptin jáde, tó máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé ebi ń pa wá. Kò sí àní-àní pé ara wa nílò oorun, bó ṣe nílò eré ìmárale àti oúnjẹ tó ṣara lóore.
Ṣé àfikún iṣẹ́ tó ò ń ṣe kì í jẹ́ kó o sùn tó bó ṣe yẹ? Àníyàn ìgbésí ayé ńkọ́ àti ìdààmú nítorí àwọn ohun tó o ti kó jọ fún ọjọ́ ọ̀la? Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ nígbà kan rí pé: “Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.”—Oníwàásù 5:12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìṣòro Àìkìísùntó—Ǹjẹ́ Ó Ń Yọ Ọ́ Lẹ́nu?” nínú Jí! February 8, 2004.