Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìrìn Rírìn Ṣe Eré Ìmárale?
Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn rò pé táwọn ò bá lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n máa ń fowó ṣeré ìmárale, táwọn ò sì lè wáyè fún un, àwọn á kúkú mọ́kàn kúrò lára àwọn àǹfààní tí eré ìmárale lè ṣe fún ìlera àwọn. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ náà rí. Ọ̀mọ̀wé Russell Pate ti Yunifásítì Gúúsù Carolina sọ pé: “Mo rò pé ó yẹ ká fọwọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ pé rírin gbẹ̀rẹ́ káàkiri àdúgbò lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́ máa ń gbádùn mọ́ni gan-an.”
Àmọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni ìrìn rírìn ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní tó? Ǹjẹ́ àwọn àǹfààní gbòógì kan tiẹ̀ wà tí ìrìn rírìn lè ṣe fún ìlera èèyàn?
Ìrìn Dára fún Ìlera Rẹ
Oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Hippocrates máa ń wo ìrìn rírìn bí “oògùn tó dára jú lọ fún ènìyàn.” Kódà òwe kan sọ pé: “Dókítà méjì péré ni mo ní, àwọn ni ẹsẹ̀ mi ọ̀tún àti tòsì.” Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni ìrìn rírìn ṣe dára fún ìlera wa tó?
Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn tó bá ń rìn déédéé kì í sábà ṣàìsàn bí àwọn tó máa ń jókòó sójú kan. Àwọn ìwádìí náà fi hàn pé ìrìn rírìn máa ń lé àrùn ọkàn àti rọpárọsẹ̀ jìnnà sí ènìyàn. Ó lè dènà àrùn àtọ̀gbẹ nípa fífún ara wa lágbára láti lè lo èròjà inú ara tó ń dín bí ṣúgà ṣe ń pọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ kù, ìyẹn insulin. Ó ń fún egungun wa lágbára, ó ń dènà àrùn tó ń sọ egungun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ìrìn rírìn ń fún wa lágbára, ó ń jẹ́ kára wa rọ̀, o sì ń jẹ́ ká lókun. Ó lè mú kéèyàn fọn, téèyàn ò sì ní wúwo rinrin. Ó tún ń jẹ́ kéèyàn máa rí oorun sùn dáadáa, á jẹ́ kí ọpọlọ jí pépé kò sì ní jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì rí ibi dúró sí lágọ̀ọ́ ara.
Nínú àbọ̀ ìwádìí táwọn olùwádìí kan ní Yunifásítì Gúúsù California ṣe ní nǹkan bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, wọ́n rí i pé ìrìn ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré lè gbà ènìyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àníyàn àti pákáǹleke ju bí oògùn amáratuni kan ti lè ṣe lọ! Ńṣe ló dà bi eré ìmárale yòókù, ìrìn rírìn máa ń jẹ́ kí ohun kan tí wọ́n ń pè ní endorphin, ìyẹn ni èròjà, kan tó wà nínú ọpọlọ tó máa ń dín ìrora kù tó sì máa ń jẹ́ kí ara èèyàn balẹ̀ sun jáde.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Medical Post ti Kánádà ṣe sọ, ìrìn gbẹ̀rẹ́ pàápàá ní àǹfààní tó ń ṣe fún ìlera. Ìwádìí táwọn kan gbé jáde nínú ìwé ìròyìn náà The New England Journal of Medicine fi hàn pé téèyàn bá ń rin bí ìdajì kìlómítà péré lójúmọ́, ó lè jẹ́ kí ẹ̀mí èèyàn túbọ̀ gùn sí i. Àwọn ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé tí èèyàn bá ń ṣe eré ìmárale fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá-mẹ́wàá lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́, àǹfààní tá ṣe fún onítọ̀hún á dà bí ìgbà téèyàn bá ń ṣeré ìmárale fún odindi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú láìsinmi. O ò ṣe dá ọkọ̀ rẹ dúró tó bá kù díẹ̀ kó o dé ibi tóò ń lọ kó o sì fẹsẹ̀ rin ìyókù ìrìn náà. Tàbí kó o wáyè rìn díẹ̀ lójúmọ́.
Àwọn àǹfààní tó wà nínú rírìn kánmọ́kánmọ́ tún jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀mọ̀wé Carl Caspersen tó ń ṣiṣẹ́ ní Ibùdó Tí Wọ́n Ti Ń Ṣèkáwọ́ Àrùn Tí Wọ́n sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Amẹ́ríkà tó wà nílùú Atlanta ní ìpínlẹ̀ Georgia sọ pé: “Tí èèyàn bá ń dìde kúrò lórí ìjókòó tó sì ń rìn kánmọ́kánmọ́ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú fún ọjọ́ mélòó kan láàárín ọ̀sẹ̀, ó lè lé àìsàn jìnnà sí onítọ̀hún.” Ohun tó tún mú ìrìn rírìn dára ni pé gbogbo èèyàn pátá, àtọmọdé àtàgbà, ló máa ń rìn títí kan àwọn tí ara wọn le àti àwọn tára wọn ò le. Síwájú sí i, o ò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àrà ọ̀tọ̀ kan lórí bí wọ́n ṣe ń rìn—ṣáà ti wá bàtà tó bá ọ lẹ́sẹ̀ mu.
Bí O Ṣe Lè Gbádùn Ìrìn Rírìn
Wọ aṣọ tó fẹ́rẹ̀ lára tí kò sì fún jù. Nítorí òtútù, o lè wọ àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kó jẹ́ èyí tá rọrùn fún ọ láti bọ́ tí ooru bá dé. Wọ bàtà rírọ̀ tó fúyẹ́, tí ìtẹ̀lẹ̀ rẹ̀ rọ̀ tó sì pẹlẹbẹ tí kò sì fún ọ lẹ́sẹ̀. Ó yẹ kí bàtà yẹn tóbi díẹ̀ ju èyí tó o máa ń wọ̀ lọ sóde. Tó o bá fẹ́ rìn fún àkókò tó ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ tí kò sì ní sí omi mímu lójú ọ̀nà, á dáa kó o gbé omi díẹ̀ dání. O lè kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rìn díẹ̀díẹ̀ fún bí ìṣẹ́jú márùn-ún àkọ́kọ́ láti fi nara. Dúró dáadáa, máà jẹ́ kí ìgúnpá àti orúnkún rẹ le wọnwọnwọn jù, kí o má sì di ẹ̀ṣẹ́.
Lẹ́yìn tó o bá ti fẹ̀lẹ̀ rìn díẹ̀, bẹ̀rẹ̀ sí rìn kánmọ́kánmọ́, gìgísẹ̀ rẹ ni kó o kọ́kọ́ máa fi tẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni kó o wá da ẹsẹ̀ délẹ̀, kó o sì jẹ́ kí orí ẹsẹ̀ rẹ kanlẹ̀ kó o tó máa gbéra. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bàtà tó rọ̀ lo nílò. Ǹjẹ́ gbogbo èyí ò ti wá pọ̀ jù fún ọ láti rántí báyìí? Má bẹ̀rù—bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó máa ń rìn ṣe máa ń rìn nìyí tí wọn ò sì mọ̀ ọ́n lára. Rọra máa rìn, ìrìn rẹ ò gbọ́dọ̀ le débi pé wàá máa mí túpetúpe, tóò sì ní lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Tó bá jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rìn ní irú ọ̀nà yìí ni, máà kánjú, máà pẹ́ lórí ìrìn, má ṣe rìn púpọ̀ jù, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni kó o sì jẹ́ kí ìrìn rẹ máa yá. Tó o bá débi tóò ń lọ, máà dúró ṣìí lójijì, ńṣe ni kó o rọra dúró.a
Bí eré ìmárale tóò ń ṣe bá mú kí ọkàn rẹ máa lù kìkì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tó o sì ń mí túpetúpe, o sì lè máa làágùn níwọ̀nba pẹ̀lú, má fòyà bó ṣe yẹ̀ kó rí nìyẹn. Iṣan lè máa ro ọ́ díẹ̀díẹ̀ fún bí ọjọ́ mélòó kan nígbà tó o bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Máa kíyè sí ara rẹ bó o ti ń ṣe eré ìmárale. Tó bá dà bíi pé ò ń sáré rìn jù tó sì fẹ́ máa pin ọ́ lẹ́mìí, dẹ̀rìn tàbí kó o sinmi díẹ̀. Àmọ́ ṣá o, tó o bá rí i pé àyà máa ń dùn ọ́, tóò ń mí lókèlókè, tóò lè mí délẹ̀, tí òòyì ń kọ́ ọ lójú tàbí tí èébì ń gbé ọ, ṣíwọ́ rírìn kó o sì tètè lọ tọ́jú ara rẹ.b
Ohun tó mú kí ìrìn rírìn dára ju eré sísá àtàwọn eré mìíràn tó ń mú èémí sunwọ̀n ni pé kì í ṣe èèyàn léṣe. Nítorí náà, ṣàṣà èèyàn ni oríkèé wọn máa ń yẹ̀ tàbí kí wọ́n ní ìrora níbi iṣan. Lóòótọ́, ìrìn rírìn ni àwọn tó mọ̀ nípa bí ara ṣe lè dúró kanpe sọ pé ó dára jù nínú eré ìmárale. Nítorí náà, tó o bá fẹ́ kí ará rẹ le dáadáa, máa rìn!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àwọn tó bá fẹ́ kí ara wọn fẹ́rẹ̀, bí wọ́n bá ṣe ń yara rìn sí ni ara wọn yòó ṣe máa fẹ́rẹ̀ sí. Àwọn tó máa ń rìn láti jẹ́ kí ara wọn dá ṣáṣá máa ń rin ìrìn kìlómítà kan láàárín ìṣẹ́jú méjìlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.
b Ì bá dára jù pé kó o lọ rí dókítà rẹ kó o tó dáwọ́ lé ṣíṣe eré ìmárale kan, pàápàá tó bá jẹ́ pé o ní àrùn ọkàn, ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí àìsàn mìíràn lára.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]
ÀWỌN OHUN TÓ YẸ ÀTÈYÍ TÍ Ò YẸ TÓ O BÁ Ń RÌN
● Máa nàró dáadáa, má ṣe dorí kodò, kí ibi tó máa ríran dé lọ́wọ́ iwájú tó bíi mítà mẹ́fà
● Rọra máa rìn. Má rò pé ó pọn dandan pé kó o yára rìn débi tá fi wá ṣòro fún ọ láti mí tó o bá ń sọ̀rọ̀
● Má ṣe na ẹsẹ̀ gùn ju bó ṣe yẹ lọ. Tó o bá fẹ́ kí ìrìn rẹ yá, gbẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ ṣùgbọ́n má na ẹsẹ̀ jù
● Máa ju apá ẹ síwá sẹ́yìn, kó o sì jẹ́ kí ìgúnpá ẹ sún mọ́ ara rẹ dáadáa. Má ṣe ju apá rẹ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti òsì
● Má da gbogbo ẹsẹ̀ délẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ dúró nílẹ̀ dáadáa, kí orí ẹsẹ̀ rẹ sì kanlẹ̀ kó o tó gbéra
● Má rò pé dandan ni kó o gbé nǹkan kan dání. Ẹrù tó o bá gbé dání kò ní jẹ́ kó o lè gbé ẹsẹ̀ bó ṣe yẹ á sì jẹ́ kí iṣan máa ro ọ́