Ọjọ́ Lọjọ́ Tí “Olú Ìlú Ọsirélíà Tí Igi Pọ̀ Sí” Jóná
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ
JÌNNÌJÌNNÌ iná tó ń sọ kẹ̀ù ló jí àwọn èèyàn tó ń gbé ní Canberra, tí í ṣe olú ìlú ilẹ̀ Ọsirélíà láàárọ̀ January 18, 2003. Èéfín ṣíṣú dùdù àti iná tó ń jó wì-wì-wì, èyí tó bo oòrùn tó ń ràn lójú, mú kí ojú ọjọ́ pọ́n yòò. Afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ gbóná girigiri ó sì ń rani lára. Ọ̀dá tó dá ní Ọsirélíà pọ̀ débi pé gbogbo igi àtewé àti ìràwé ló gbẹ bí awọ. Ó tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí iná fi ń jó igbó tí igi eucalyptus pọ̀ sí tó yí ìlú náà ká. Wọ́n tún máa ń pe ìlú náà ní Olú Ìlú Ọsirélíà tí Igi Pọ̀ Sí.
Lọ́sàn-án ọjọ́ táà ń wí yìí, ńṣe ni atẹ́gùn gbígbóná tó ń fẹ́ kíkankíkan bẹ̀rẹ̀ sí ṣọṣẹ́ tí ò ṣeé fẹnu sọ. Iná yìí jó débi pé ó fo títì àti gbogbo nǹkan tó yẹ kó dá a dúró láàárín ìgboro kọjá, ó jó wọnú igbó igi ahóyaya tó wà nínú ìlú Canberra, àti yíká ìhà ìwọ̀ oòrùn gúúsù ìlú náà.
Iná Ṣàdédé Ṣẹ́ Yọ Nínú Igbó
Elliot, olùyọ̀ǹda ara ẹni kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ panápaná, sọ pé: “Aago mẹ́ta ọ̀sán ni iná ṣàdédé ṣẹ́ yọ nínú igbó igi ahóyaya. Iná yìí lágbára débi pé ẹ̀ṣẹ́ná fẹ́rẹ̀ẹ́ bo àwa àtàwọn tó ń gbé lẹ́yìn odi ìlú mọ́lẹ̀. Ẹ̀rù bà wá nígbà tá a rí ọwọ́ iná tó ń jó lala, èyí tí gíga rẹ̀ tó ogójì mítà [nǹkan bí òpó iná mẹ́rin ní ìdúró] tó ń jó bọ̀ lọ́dọ̀ wa.” Ooru gbígbóná girigiri àti ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́ lẹlẹ wá mú kí ojú ọjọ́ ṣú dùdù, àgbáàràgbá iná tó ń jó kíkankíkan sì sọ gbogbo ìgbèríko Chapman di eérú, ọ̀pọ̀ igi ló wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ tó sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé jẹ́. Àìmọye òpó wáyà iná àti tẹlifóònù tí iná jó ló wó lulẹ̀, táwọn wáyà iná sì já lulẹ̀. Láàárín wákàtí kan tí iná ti bẹ̀rẹ̀, ọgbọ̀n lé rúgba [230] ilé ló ti jó kanlẹ̀.
Ọwọ́ àwọn panápaná kò ká iná kíkàmàmà yìí. Elliot sọ pé: “Ńṣe là ń tara pàrà bá a ṣe ń wo àwọn ilé tó ń jóná, nítorí a ò tiẹ̀ mọ ilé táà bá ní ká kọ́kọ́ paná ibẹ̀ àtèyí tá ó ṣì fi sílẹ̀ ná. Èyí tó tún wá burú jù ni tàwọn tó ń fi ìnira pẹ̀lú omijé lójú padà sílé wọn tó ti jóná.”
Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Iná Náà
Èèyàn mẹ́rin ló kú nínú ìjàǹbá iná náà, tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn míì sì fara pa. Ńṣe ni obìnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì kan tó kú nínú ìjàǹbá ọ̀hún sáré lọ sínú ilé láti lọ kó àwọn fọ́tò rẹ̀. Bí àjà ilé náà ṣe jìn lé obìnrin yìí lórí nìyẹn, tó sì gbabẹ̀ kú nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tó lè yọ ọ́.
Nígbà tí ẹ̀fúùfù àti iná yẹn fi máa rọlẹ̀ ọgbọ̀n lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ilé [530] ló ti jó, tó sì sọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] èèyàn di aláìnílélórí. Iná mànàmáná, gáàsì àtàwọn ọ̀nà tómi ẹ̀gbin ń gbà kọjá ti bà jẹ́ kọjá ààlà, ó wá fa àìsàn fáwọn aráàlú. Àwọn tí wọ́n ní ìṣòro àtimí dáadáa kún ẹ̀ka tí wọ́n ti ń ṣe ìtọ́jú pàjáwìrì ní Ilé Ìwòsàn ìlú Canberra. Ó mà ṣe o, bí àwọn èèyàn ṣe ń sá lọ síbi tí wọ́n á ti rí ààbò, ṣe làwọn ọ̀dájú jàǹdùkú kan lọ ń jí ẹrù tó wà nínú àwọn ilé tí wọ́n fi sílẹ̀ kó. Ṣùgbọ́n ẹnu kọ ìròyìn nípa ìwà akin àti ojú àánú táwọn èèyàn fi hàn. Àwọn ará àdúgbò ń ran ara wọn lọ́wọ́, àwọn àlejò gbẹ̀mí àwọn ẹranko là, àwọn ilé ẹ̀kọ́ gbà àwọn tí kò nílé lórí mọ́ láyè nínú ọgbà wọn, àwọn panápaná tó yọ̀ọ̀da ara wọn pa iná ilé àwọn ẹlòmíràn tí ilé tiwọn sì jóná.
Bópẹ́ bóyá àwọn igi tún lè rúwé o, wọ́n sì lè tún àwọn ilé tó jóná kọ́, ṣùgbọ́n Olóòtú Ìjọba ilẹ̀ Ọsirélíà John Howard sọ pé ọṣẹ́ tí jàǹbá yẹn ṣe “kì í ṣe nǹkan tó lè kúrò . . . lọ́kàn àwọn ará Canberra.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
AP Photo/Fairfax, Pat Scala