ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 12/1 ojú ìwé 4-8
  • Pípèsè Ìrànwọ́ Ní Ibi Àwókù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pípèsè Ìrànwọ́ Ní Ibi Àwókù
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Accra—“Ọjọ́ Nóà Kékeré”
  • San Angelo—“Ó Dún Bí Ẹni Pé Ayé Fẹ́ Parẹ́”
  • Kobe—“Ìrunwómúwómú Igi, Ilé àti Ara Ẹ̀dá Ènìyàn”
  • Ìpèsè Ìrànwọ́ Pípẹ́ Títí Láìpẹ́!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ohun Kan Tí Ìjì Kò Lè Gbé Lọ
    Jí!—2003
  • Nígbà Tí Ìjábá Ti Ìṣẹ̀dá Bá Ṣẹlẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àwọn Ìṣe Ìgbàlà Jehofa Nísinsìnyí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 12/1 ojú ìwé 4-8

Pípèsè Ìrànwọ́ Ní Ibi Àwókù

DÁJÚDÁJÚ, ó yẹ kí a gbóṣùbà fún ìsapá ènìyàn láti pèsè ìrànwọ́ nítorí ìyọrísí ìjábá. Ọ̀pọ̀ ètò ìrànwọ́ ti ṣèrànwọ́ láti tún àwọn ilé kọ́, láti tún ìdílé sopọ̀ ṣọ̀kan, àti, ju gbogbo rẹ̀ lọ, láti gba ẹ̀mí là.

Nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo—wọ́n sì ń dúpẹ́ fún—ìpèsè èyíkéyìí tí a bá tipasẹ̀ ètò ìrànwọ́ tí kì í ṣe ti ìsìn ṣe. Lọ́wọ́ kan náà, wọ́n ní ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ láti “máa ṣe ohun rere . . . ní pàtàkì sí àwọn wọnnì tí wọ́n bá [wọn] tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn Ẹlẹ́rìí ń nímọ̀lára bí ẹni pé wọ́n bá ara tan; wọ́n ń wo ara wọn bí “ìdílé.” Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ara wọn ní “arákùnrin” àti “arábìnrin.”—Fi wé Máàkù 3:31-35; Fílémónì 1, 2.

Nítorí náà, nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀ sí àdúgbò kan, àwọn alàgbà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá gidigidi láti mọ ibi tí àwọn mẹ́ḿbà ìjọ kọ̀ọ̀kan wà àti àìní wọn àti láti ṣètò ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò. Gbé bí èyí ṣe jẹ́ òtítọ́ yẹ̀ wò ní Accra, Gánà; San Angelo, U.S.A.; àti Kobe, Japan.

Accra—“Ọjọ́ Nóà Kékeré”

Nǹkan bí aago 11 alẹ́ ni òjò náà bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, ó sì rọ̀ láìdáwọ́ dúró fún ọ̀pọ̀ wákàtí. John Twumasi, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Accra, sọ pé: “Ọwọ́ rẹ̀ le tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí gbogbo ìdílé mi kò fi lè sùn.” Ìwé agbéròyìnjáde Daily Graphic pè é ní “Ọjọ́ Nóà kékeré.” John ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “A gbìyànjú láti kó àwọn ohun ṣíṣeyebíye díẹ̀ lọ sí orí òkè, ṣùgbọ́n bí a ṣe ń ṣi ilẹ̀kùn ọ̀nà àtẹ̀gùn, àgbàrá òjò ni ó ya wọlé.”

Àwọn aláṣẹ kìlọ̀ pé kí olúkúlùkù sá kúrò, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lọ́ra, ní bíbẹ̀rù pé ilé tí ó ṣófo—kódà bí omi tilẹ̀ kún un bámúbámú—lè fa àwọn jàgùdà mọ́ra. Àwọn kan kò lè lọ, bí wọ́n tilẹ̀ fẹ́ lọ. Ọmọdébìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Paulina sọ pé: “Èmi àti màmá mi kò lè ṣí ilẹ̀kùn. Omi náà ń pọ̀ sí i, nítorí náà, a dúró sórí àgbá onígi, a sì di ọ̀pá àjà ilé mú. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní nǹkan bí aago márùn-ún ìdájí, àwọn aládùúgbò wa yọ wá nínú ewu.”

Gbàrà tí ó ti ṣeé ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Kristẹni arábìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Beatrice sọ pé: “Àwọn alàgbà nínú ìjọ ń wá wa kiri, wọ́n sì rí wa nínú ilé Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa kan, níbi tí a sá sí. Ọjọ́ mẹ́ta péré lẹ́yìn omíyalé náà, àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ḿbà ìjọ náà wá sọ́dọ̀ wa, wọ́n sì fọ ẹrẹ̀ tí ó wà nínú àti níta ilé wa kúrò. Watch Tower Society fi ọṣẹ, kẹ́míkà apakòkòrò, ọ̀dà, mátírẹ́ẹ̀sì, kúbúsù, aṣọ, àti ẹ̀wù ọmọdé ránṣẹ́. Àwọn ará fi oúnjẹ ṣọwọ́ sí wa fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Orí mi wú gidigidi!”

John Twumasi, tí a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú, ròyìn pé: “Mo sọ fún àwọn ayálégbé yòó kù pé Society wa ti fi ọṣẹ àti kẹ́míkà apakòkòrò—tí ó tó láti fọ gbogbo ilé náà ṣọwọ́ sí wa. Nǹkan bí 40 ayálégbé ṣèrànwọ́ láti fọ ilé náà mọ́ tónítóní. Mo fún àwọn aládùúgbò mi ní díẹ̀ nínú ọṣẹ náà, títí kan ọkùnrin kan tí ó jẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò. Àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi ṣàṣìṣe láti ronú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn nìkan.”

Àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mọrírì ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ tí a ṣe fún wọn gidigidi. Arákùnrin Twumasi mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá sí ìparí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó ohun tí mo pàdánù nínú omíyalé náà pọ̀ ju àwọn ìpèsè ìrànwọ́ tí mo rí gbà lọ, èmi àti ìdílé mi nímọ̀lára pé a ti jèrè fíìfíì ju ohun tí a pàdánù lọ, nítorí ìpèsè arùmọ̀lárasókè yìí láti ọ̀dọ̀ Society.”

San Angelo—“Ó Dún Bí Ẹni Pé Ayé Fẹ́ Parẹ́”

Ìjì líle tí ó fọ́ San Angelo túútúú ní May 28, 1995, fa igi tu, ó ṣẹ́ òpó iná, ó sì fọ́n wáyà iná káàkiri ojú pópó. Ẹ̀fúùfù ń fẹ́ ní nǹkan bí 160 kìlómítà ní wákàtí kan, ó sì ba àwọn ohun amáyédẹrùn jẹ́. Ilé tí ó lé ní 20,000 ni iná mànàmáná wọn lọ. Lẹ́yìn náà ni yìnyín bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́. Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ipò Ojú Ọjọ́ Káàkiri Orílẹ̀-Èdè ròyìn pé “yìnyín tí ó tó bọ́ọ̀lù golf” já bọ́, lẹ́yìn náà “yìnyín tí ó tó bọ́ọ̀lù softball,” lẹ́yìn náà sì ni “yìnyín tí ó tó èso àjàrà.” Ìró yìnyín náà lè dini létí. Olùgbé kan wí pé: “Ó dùn bí ẹni pé ayé fẹ́ parẹ́.”

Ìparọ́rọ́ abàmì kan tẹ̀ lé ìjì náà. Àwọn ènìyàn rọra yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ jáde láti inú àwọn ilé wọn tí a ti sọ di ahẹrẹpẹ, láti baà lè rí àwókù náà. Ẹ̀ka àwọn igi tí ó ṣì wà ní ìdúró ti ya lulẹ̀. Àwọn ilé tí ó ṣì wà ní ìdúró dà bí ẹni pé ara wọ́n ti ṣí dànù. Ní àwọn agbègbè kan yìnyín bo ilẹ̀ gègèrè, ó jìn tó mítà kan. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún fèrèsé ilé àti ọkọ̀ ni ó ti fọ́ nínú ìjì náà, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí èkúfọ́ gíláàsì fi ń tàn yanran lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìnyín tí ó bo ilẹ̀. Obìnrin kan sọ pé: “Nígbà tí mo dé ilé, mo ṣáà jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi lójú pópó ni, mo sì bú sẹ́kún. Ìbàjẹ́ náà burú púpọ̀, ó mú ọkàn mi pòrúurùu.”

Àwọn elétò ìrànwọ́ àti àwọn ilé ìwòsàn yára pèsè ìrànlọ́wọ́ owó, ohun èlò ìkọ́lé, ìtọ́jú ìṣègùn, àti ìmọ̀ràn. Lọ́nà tí ó yẹ kí a gbòríyìn fún, ọ̀pọ̀ àwọn tí ìjì náà fìyà jẹ ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.

Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú. Aubrey Conner, alàgbà kan ní San Angelo, ròyìn pé: “Gbàrà tí ìjì náà ti parí, a bẹ̀rẹ̀ sí í fi fóònù wá ara wa kiri. A ran ara wa lọ́wọ́, a sì ran àwọn aládùúgbò wa tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti dí ojú fèrèsé, láti fi ike sí òrùlé, àti láti fi nǹkan tẹ́ ara ògiri ilé bí ó ti ṣeé ṣe tó. Lẹ́yìn náà, a ṣe àkọsílẹ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ tí ilé wọn bà jẹ́. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ilé nílò àtúnṣe, ohun èlò tí àwọn elétò ìrànwọ́ kó wá kò sì tó. Nítorí náà, a rá àfikún ohun èlò, a sì ṣètò iṣẹ́ náà. Lápapọ̀, nǹkan bí 1,000 Ẹlẹ́rìí yọ̀ǹda láti ṣèrànwọ́, nǹkan bí 250 ní òpin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá láti ibi tí ó jìnnà tó 740 kìlómítà. Gbogbo wọ́n ṣiṣẹ́ àṣekára, lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà tí ipò ojú ọjọ́ dé ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìwọ̀n 40 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Kódà arábìnrin kan ẹni 70 ọdún bá wa ṣiṣẹ́ ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀, àyàfi ní òpin ọ̀sẹ̀ kan, ìyẹn sì jẹ́ nígbà tí a ń tún ilé tirẹ̀ ṣe. Ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn, ó wà lórí òrùlé ilé tirẹ̀, ní ṣíṣèrànwọ́ láti tún un ṣe!

“A sábà máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ bíi, ‘Kì yóò ha dára bí àwọn ìsìn yòó kù bá lè máa ṣe èyí fún àwọn mẹ́ḿbà wọn bí?’ lẹ́nu àwọn tí ń wò wá. Orí àwọn aládùúgbò wa wú láti rí agbo òṣìṣẹ́ ẹlẹ́ni 10 sí 12, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn (títí kan àwọn arábìnrin) tí wọ́n dé sí ilé Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn kan ní kùtùkùtù òwúrọ̀ Friday, tí wọ́n múra tán láti tún gbogbo òrùlé náà ṣe lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí kí wọn tilẹ̀ tún un kàn. Nínú àwọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jù lọ, a máa ń parí iṣẹ́ náà ní òpin ọ̀sẹ̀ kan. Nígbà mìíràn, ará ìta kan tí ó jẹ́ agbaṣẹ́ṣe yóò ti bá iṣẹ́ ilé kíkàn kan jìnnà kí agbo òṣìṣẹ́ wa tó dé ẹnu ọ̀nà kejì. A óò tú òrùlé náà, a óò tún un kàn, a óò sì fọ àyíká náà mọ́ tónítóní kí wọn tó parí tiwọn. Nígbà míràn, wọ́n máa ń pa iṣẹ́ wọn tì, tí wọn yóò sì máa fiwá ṣèranwò!”

Arákùnrin Conner parí ọ̀rọ̀ ní sísọ pé: “Gbogbo wa pátá ni aáyun ìrírí tí a gbádùn papọ̀ yóò yun. A ti wá mọ ara wa láti ojú ìwòye mìíràn nípa fífi ìfẹ́ ará hàn sí ara wa ju ti ìgbàkígbà rí lọ. A nímọ̀lára pé èyí wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò bí ayé tuntun Ọlọ́run yóò ti rí, nígbà tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin bá ń ran ara wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́.”—Pétérù Kejì 3:13.

Kobe—“Ìrunwómúwómú Igi, Ilé àti Ara Ẹ̀dá Ènìyàn”

A rò pé àwọn olùgbé Kobe yóò ti múra sílẹ̀ ni. Ní tòótọ́, gbogbo September 1 ni wọ́n fi ń ṣàyájọ́ Ọjọ́ Ìdènà Ìjábá. Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ máa ń ṣe ìdánrawò eré ìsẹ̀lẹ̀, àwọn ológun máa ń ṣàfidánrawò bí a ṣe lè fi hẹlikọ́pítà yọni nínú ewu, àwọn ẹ̀ka panápaná sì máa ń gbé àwọn àdàmọ̀dì ẹ̀rọ ìsẹ̀lẹ̀ wọn jáde, nínú èyí tí àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ti máa ń fi òye wọn nínú yíyè bọ́ dánra wò nínú àpòtí tí ó tóbi tó iyàrá kan tí ń mì tìtì, tí ó sì ń gbọ̀n bí ìgbà tí ìsẹ̀lẹ̀ bá wáyé ní ti gidi. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ gan-an wáyé ní January 17, 1995, gbogbo ìmúrasílẹ̀ náà dà bí èyí tí kò wúlò. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá òrùlé ilé wọlẹ̀—ohun kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí nínú àdàmọ̀dì náà. Ọkọ̀ ojú irin fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀; àwọn òpópónà kan di kélekèle; òpó gáàsì àti omi bà jẹ́; ilé wó bíi páálí. Ìwé ìròyìn Time ṣàpèjúwe ìran náà bí “ìrunwómúwómú igi, ilé àti ara ẹ̀dá ènìyàn.”

Lẹ́yìn náà ni iná sọ. Ilé ń jó fòfò nígbà tí àwọn panápaná tí a ti pin lẹ́mìí sì ti há sáàárín sún-kẹẹrẹ-gbà-kẹẹrẹ ojú pópó. Àwọn tí wọ́n dé àwọn ibi tí iná ti ń jó sábà ń rí i pé omi kò lè jáde láti inú ẹ̀rọ omi ìlú ńlá náà tí ó ti bà jẹ́. Ọ̀gá oníṣẹ́ ọba kan sọ pé: “Ọjọ́ àkọ́kọ́ páni láyà gidigidi. N kò tí ì nímọ̀lára àìlágbára tó bẹ́ẹ̀ rí nínú ìgbésí ayé mí, ní mímọ̀ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n ti wọlẹ́ sínú àwọn ilé tí ń jó wọ̀nyẹn. Àti ní mímọ̀ pé kò sí ohunkóhun tí mo lè ṣe sí i.”

Lápapọ̀, nǹkan bí 5,000 ènìyàn kú, nǹkan bí 50,000 ilé sì bà jẹ́. Kobe ní kìkì ìdá mẹ́ta oúnjẹ tí ó nílò. Láti lè rí omi, àwọn kan yíjú sí gbígbọ́n omi ìdọ̀tí láti inú òpó omi tí ó ti bà jẹ́. Ọ̀pọ̀ aláìrílégbé sá lọ sí ibi tí wọn yóò forí pamọ́ sí, àwọn kan nínú wọn ń díwọ̀n oúnjẹ, ní fífún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìrẹsì díẹ̀ ní ọjọ́ kan. Àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn tàn kálẹ̀ kíá. Ọkùnrin kan ṣàròyé pé: “Àwọn aláṣẹ kò tí ì ṣe ohunkóhun. Bí a bá ń bá a nìṣó láti gbára lé wọn, ebi yóò pa wá kú.”

Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kobe àti ní àwọn agbègbè tí ó wà nítòsí ṣètò ara wọn lójú ẹsẹ̀. Awakọ̀ hẹlikọ́pítà kan tí ó rí iṣẹ́ wọn fún ìgbà àkọ́kọ́ sọ pé: “Mo lọ sí agbègbè tí ìjábá náà ti ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tí ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé, mo sì lo ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀. Nígbà tí mo dé ilé kan, ohun gbogbo rí jáujàu. A kò tí ì ṣe ètò fún iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ kankan. Kìkì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n rọ́ lọ sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ní ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì.”

Ní tòótọ́, iṣẹ́ rẹpẹtẹ wà láti ṣe. Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́wàá kò ṣeé lò mọ́ rárá, iye tí ó lé ní 430 Ẹlẹ́rìí kò sì nílé lórí mọ́. Àwọn 1,206 ilé tí wọ́n ń gbé nílò àtúnṣe. Kì í ṣe ìyẹn nìkan, ìdílé Ẹlẹ́rìí 15 tí wọ́n ti kú nínú ìjábá náà nílò ìtùnú.

Nǹkan bí 1,000 Ẹlẹ́rìí láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè náà yọ̀ǹda àkókò wọn láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ àtúnṣe náà. Arákùnrin kan sọ pé: “Nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ lórí ilé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí wọn kò tí ì ṣe batisí, a sábà máa ń bí wa léèrè pé, ‘Eélòó ni kí a san fún èyí?’ Nígbà tí a bá sọ fún wọn pé ìjọ ni ó fi iṣẹ́ náà ṣèrànwọ́, wọ́n máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa, ni sísọ pé, ‘Ohun tí a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ti di òtítọ́ gidi nísinsìnyí!’”

Orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wú nítorí bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe yára dáhùn padà sí ìjábá náà àti bí ó ṣe ká wọn lára tó. Awakọ̀ hẹlikọ́pítà tí a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó wú mi lórí gidigidi. Ẹ ń pe ara yín ní ‘arákùnrin’ àti ‘arábìnrin.’ Mo ti rí i bí ẹ ṣe ń ran ara yín lọ́wọ́; ìdílé kan ṣoṣo ní ẹ̀yin ènìyàn yìí jẹ́ ní tòótọ́.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó ṣeyebíye láti inú ìsẹ̀lẹ̀ náà. Arábìnrin kan sọ pé: “Mo ti máa ń fìgbà gbogbo nímọ̀lára pé bí ètò àjọ kan bá ṣe tóbi tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe nira tó láti fi ìdàníyàn ara ẹni hàn.” Ṣùgbọ́n ìtọ́jú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ó rí gbà yí ojú ìwòye rẹ̀ padà. “Mo wá mọ̀ nísinsìnyí pé Jèhófà ń bójú tó wa kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ nìkan ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìpèsè ìrànwọ́ pípẹ́ títí kúrò lọ́wọ́ ìjábá wà níwájú.

Ìpèsè Ìrànwọ́ Pípẹ́ Títí Láìpẹ́!

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wo ọjọ́ iwájú fún àkókò náà nígbà tí ìjábá kì yóò fòpin sí ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn ní rèwerèwe mọ́, tí kì yóò sì fòpin sí ọ̀nà àtigbọ́ bùkátà. Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a óò kọ́ ènìyàn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àyíká ilẹ̀ ayé. Bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń fi ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan sílẹ̀, ìpalára tí ìjábá ti ìṣẹ̀dá ń ṣe yóò dín kù.

Síwájú sí i, Jèhófà Ọlọ́run—Ẹlẹ́dàá ipá ìṣẹ̀dá—yóò rí sí i pé àwọn ipá ìṣẹ̀dá kò wu ìdílé ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀ àti ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé léwu mọ́. Nígbà náà ilẹ̀ ayé yóò di párádísè kan. (Aísáyà 65:17, 21, 23; Lúùkù 23:43) Àsọtẹ́lẹ̀ Ìṣípayá 21:4 yóò ní ìmúṣẹ ológo pé: “Òun yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Beatrice Jones (lọ́wọ́ òsì) ń fi bí òun àti àwọn mìíràn ṣe so ọwọ́ wọn pọ̀ láti la inú àgbàrá kọjá hàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Iṣẹ́ ìpèsè ìranwọ́ lẹ́yìn ìjì líle náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́