ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 12/1 ojú ìwé 9
  • A San Èrè fún Mímú Ìdúró Gbọn-in ní Ilé Ẹ̀kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A San Èrè fún Mímú Ìdúró Gbọn-in ní Ilé Ẹ̀kọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ọdún Halloween Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ẹyin Ọdọ Kristẹni Ẹ Duro Gbọnyin Ninu Igbagbọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 12/1 ojú ìwé 9

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

A San Èrè fún Mímú Ìdúró Gbọn-in ní Ilé Ẹ̀kọ́

BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A óò . . . kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá; àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀.” (Aísáyà 54:13) Lọ́nà tí a mú gbòòrò, “gbogbo àwọn ọmọ rẹ” lè tọ́ka sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, títí kan àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Lónìí, àwọn Kristẹni òbí ń rí i dájú pé “a . . . kọ́” àwọn ọmọ wọn “láti ọ̀dọ̀ Olúwa” ní ilé àti ní àwọn ìpàdé Kristẹni.

Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n bá wà ní ilé ẹ̀kọ́, àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ máa ń dojú kọ àwọn ìpèníjà tí ó ṣòro. Nígbà míràn, ó máa ń pọn dandan fún wọn láti di ìdúró fífẹsẹ̀ múlẹ̀ mú lórí ohun tí wọ́n ti kọ́ láti inú Bíbélì. Nígbà tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyọrísí rẹ̀ lè ṣàǹfààní fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́ pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí láti Micronesia ti fi hàn.

Lórí erékùṣù kékeré ti ìwọ̀ oòrùn Pacific ti Tol, ní àwọn Erékùṣù Chuuk, àwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ àdúgbò sọ fún àwọn ọmọ láti múra sílẹ̀ fún ayẹyẹ Halloween ti ilé ẹ̀kọ́, kí wọ́n sì kópa nínú rẹ̀. Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí mọ̀ pé ayẹyẹ náà yóò ní ìṣelóge àti ìmúra tí ń ṣàgbéyọ àwọn iwin, àǹjọ̀nnú, àti àjẹ́—tí gbogbo wọ́n ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ìbẹ́mìílò. Ẹ̀rí ọkàn àwọn ọmọ wọ̀nyí kò gbà kí wọ́n lọ́wọ́ nínú rẹ̀.a

Láti inú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn tí a gbé karí Bíbélì nínú ilé àti nínú ìjọ Kristẹni, wọ́n mọ̀ pé irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, àní nígbà tí a bá ṣe é fún eré ìnàjú lásán pàápàá. Láti ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé ìdúró wọn lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe kedere, àwọn ọmọ náà ké sí Barak, ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní erékùṣù náà, láti bá àwọn olùkọ́ wọn náà sọ̀rọ̀.

Lẹ́yìn gbígbọ́ àlàyé náà, àwọn olùkọ́ ṣètò fún ìpàdé kejì, nínú èyí tí Barak ti lè bá gbogbo òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀. Níbi ìpàdé yìí, Barak gbé àwọn òkodoro òtítọ́ kalẹ̀ láti fi ohun tí ayẹyẹ Halloween jẹ́ gan-an hàn. Ó fa ìsọfúnni rẹ̀ yọ láti inú onírúurú ìtẹ̀jáde Watch Tower àti àwọn ìwé mìíràn. Ẹnu ya àwọn olùkọ́ àti àwọn olùṣàbójútó nípa ohun tí wọ́n gbọ́ nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀, ìtàn, àti bí ayẹyẹ náà ṣe jẹ mọ́ ìsìn. Wọ́n yàn láti ṣe ìpàdé àwọn òṣìṣẹ́ láti pinnu bí wọn yóò ṣe yanjú ọ̀ràn náà.

Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, a kéde ìpinnu kan tí a kò retí. A ti fagi lé gbogbo ìmúrasílẹ̀ fún ayẹyẹ Halloween. Láìsí àní-àní, ilé ẹ̀kọ́ náà kì yóò ṣayẹyẹ Halloween ní ọdún yẹn rárá. Ẹ wo irú àbájáde rere tí ó wà láti inú ìpinnu àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí láti ṣe ohun tí ó tọ́ ní ilé ẹ̀kọ́! Àwọn ọ̀dọ́ kò ní láti bẹ̀rù tàbí tijú láé láti mú ìdúró gbọn-in fún òtítọ́ Bíbélì.

Yíká ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ṣiṣẹ́ kára ní ilé ẹ̀kọ́. A tún ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì, kí wọ́n sì ṣàjọpín ìrètí àti ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn bí wọ́n bá ṣe ń ní àǹfààní rẹ̀. Kódà nígbà tí ìyọrísí náà kò bá bára dé tàbí kí ó jẹ́ lójú ẹsẹ̀ bí ó ṣe rí nínú ọ̀ràn yìí, àwọn ọ̀dọ́ lè ní ìgbọ́kànlé àti ìtẹ́lọ́rùn tí ń wá láti inú ṣíṣe ohun tí ó tọ́. Èyí tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, wọ́n lè ní ìdánilójú pé inú Bàbá wọn ọ̀run dùn, yóò sì bù kún wọn fún ìgbọràn tí wọ́n fi tòótọ́tòótọ́ ṣe.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí ayẹyẹ Halloween àti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní ti ìbẹ́mìílò, wo ìtẹ̀jáde Jí! ti November 22, 1993, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́