Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù September
Lẹ́yìn tá a bá ti kí wọn dáadáa, a lè sọ pe: “À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti jẹ́ kí àwọn tọkọtaya mọ ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n á fi máa láyọ̀. Kí ni ìwọ rò pé ó sábà máa ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ tọkọtaya?” [Jẹ́ kó fèsì.] Fi èpo ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ September 1 hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó dá lórí ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kẹ́ ẹ sì jọ ṣàdéhùn ìgbà tí wàá pa dà lọ jíròrò ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ September 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló fà á tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn?’ Ǹjẹ́ ìwọ náà ti ronú bẹ́ẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Inú wa dùn láti mọ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì pé àsìkò kan ń bọ̀ tí ẹkún àti ìrora máa di ohun àtijọ́. [Ka Ìṣípayá 21:4.] Ìwé yìí sọ ìdí márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ìyà fi ń jẹ àwọn èèyàn. Ó tún jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìyà.”
Ji! September–October
“À ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tó ń kọ ọ̀pọ̀ èèyàn lóminú, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ nípa ìrẹ́jẹ. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe ìwọ́de láti fi gbèjà ara wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń rẹ́ wọn jẹ. Ǹjẹ́ o rò pé ìwọ́de máa jẹ́ kọ́rọ̀ náà yanjú? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa yanjú àwọn ìṣòro tó wà láyé yìí. [Ka Mátíù 6:9, 10.] Ìwé yìí máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìwọ́de lè yanjú ìṣòro yẹn.”