ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 4/8 ojú ìwé 18-20
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ń Jẹ́ Ká Jìyà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ń Jẹ́ Ká Jìyà?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Kojú Àwọn Nǹkan Tí Kò Bára Dé
  • Ṣé Ẹ̀bi Ọlọ́run Ni?
  • Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ibi
  • Ìwọ Nìkan Kọ́
  • Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Jìyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Tá A sì Ń Jìyà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 4/8 ojú ìwé 18-20

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ń Jẹ́ Ká Jìyà?

“Ọlọ́run wà lókè ọ̀run níbi tí gbogbo nǹkan ti ń rọ̀ṣọ̀mù, nígbà táwa sì wà nísàlẹ̀ níbí tá à ń jìyà.”—Mary.a

INÚ ayé eléwu la bí àwọn ọ̀dọ́ ayé òde òní sí. Kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́ láti gbọ́ pé ìsẹ̀lẹ̀ àti ìjábá ń dẹ́mìí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn légbodò. Ọ̀rọ̀ ogun àti tàwọn apániláyà la sábà máa ń gbọ́ jù nínú ìròyìn. Àìsàn, àrùn, àwọn ọ̀daràn àti ìjàǹbá mọ́tò ń pa tẹbí tará mọ́ wa lọ́wọ́. Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ Mary tó sọ̀rọ̀ tá a kọ sókè yẹn. Lẹ́yìn ikú bàbà rẹ̀ ló sọ̀rọ̀ kíkorò náà.

Nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wa, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara gbogbo nǹkan á tojú ṣú wa, a óò máa ronú ohun tá a pàdánù, inú á sì máa bí wa. O lè ronú pé: ‘Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀?’ ‘Ó ṣe jẹ́ èmi ló ṣẹlẹ̀ sí?’ tàbí ‘Kí ló dé tó fi ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí?’ Ó yẹ kéèyàn rí ìdáhùn tó tẹ́rùn sírú àwọn ìbéèrè yẹn. Ṣùgbọ́n láti lè rí ìdáhùn tó tọ́, a gbọ́dọ̀ lọ síbi tó tọ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Turrell ṣe sọ gan-an lọ̀rọ̀ rí. Nígbà míì, “ìbànújẹ́ tó ń bá àwọn èèyàn máa ń ká wọn lára kọjá kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ lórí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ọ̀hún.” Nítorí náà á dára kó o sinmẹ̀dọ̀ díẹ̀ kó o má bàa ṣinú rò.

Bá A Ṣe Lè Kojú Àwọn Nǹkan Tí Kò Bára Dé

Kò sẹ́ni tó jẹ́ ro búburú ro ara ẹ̀ o, àmọ́, ikú àti ìjìyà ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Òdodo ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ni Jóòbù sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.”—Jóòbù 14:1.

Bíbélì ṣèlérí ayé tuntun nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Àmọ́, ká tó lè gbádùn àkókò ìtura yẹn, aráyé á kọ́kọ́ fojú winá àkókò ibi tá ò tíì rí irú rẹ̀ rí. Bíbélì sọ pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.”—2 Tímótì 3:1.

Báwo làwọn àkókò líle yìí á ṣe gùn tó? Ìbéèrè táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè fara pẹ́ ìbéèrè yìí. Àmọ́, Jésù ò sọ ọjọ́ tàbí wákàtí pàtó tí ètò àwọn nǹkan tó ti kàgbákò yìí yóò dópin. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:3, 13) Ọjọ́ iwájú ni ọ̀rọ̀ Jésù yẹn rọ̀ wá pé ká máa wò. A gbọ́dọ̀ múra tán láti fara da ọ̀pọ̀ ipò tí ò fara rọ kí òpin tó dé.

Ṣé Ẹ̀bi Ọlọ́run Ni?

Ṣé ó bọ́gbọ́n mu láti máa bínú sí Ọlọ́run torí pé ó fàyè gbà ìjìyà? Tá a bá ro ti ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun á mú gbogbo ìyà kúrò, a ó rí i pé kò yẹ bẹ́ẹ̀. Kò sì tún bọ́gbọ́n mu láti ronú pé Ọlọ́run ló ń jẹ́ kí láburú ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ láabi tó ń ṣẹlẹ̀ ló jẹ́ pé ó ń ṣèèṣì ni. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé atẹ́gùn wó igi kan lulẹ̀ tó sì ṣe ẹnì kan léṣe. Àwọn èèyàn lè pe ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní àmúwá Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ́ ló wó igi yẹn. Bíbélì jẹ́ kó yé wa pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ló máa ń fà á tí irú àwọn nǹkan tó ń bani nínú jẹ́ bẹ́ẹ̀ fi máa ń wáyé.—Oníwàásù 9:11.

Ìwà òmùgọ̀ tẹ́nì kan hù tún lè kó o sí yọ́ọ́yọ́. Ká sọ pé àwọn ọ̀dọ́ kan mutí yó kẹ́ri, wọ́n sì wá kóra wọn sínú mọ́tò. Ìjàǹbá ńlá kan wá ṣẹlẹ̀. Ta ni ká dẹ́bi fún? Ṣé Ọlọ́run ni? Rárá o, wọ́n jèrè ìwà òmùgọ̀ wọn ni.—Gálátíà 6:7.

Àmọ́, o lè béèrè pé: ‘Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run ò lágbára tó láti fòpin sí ìjìyà nísinsìnyí ni?’ Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣe kàyéfì báyẹn pẹ̀lú. Wòlíì Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé: “Èé ṣe tí o fi ń wo àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè, tí o fi dákẹ́ nígbà tí ẹni burúkú gbé ẹnì kan tí ó jẹ́ olódodo jù ú mì?” Àmọ́ ṣá o, Hábákúkù ò fi ìwàǹwára dá Ọlọ́run lẹ́bi. Ó sọ pé: “Èmi yóò sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́, láti rí ohun tí yóò sọ nípasẹ̀ mi.” Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run fi dá a lójú pé òun ti ‘yan àkókò kan kalẹ̀’ tí òun yóò fòpin sí ìjìyà. (Hábákúkù 1:13; 2:1-3) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ní sùúrù ká sì dúró de Ọlọ́run láti wá fòpin sí ìjìyà ní àkókò tí ó ti yàn kalẹ̀.

Má fi ìwàǹwára ronú pé Ọlọ́run mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ ká máa jìyà tàbí pé ńṣe ló ń dán wa wò. Òótọ́ ni pé ìjìyà lè jẹ́ ká gbọ́n sí i, Bíbélì sì sọ pé àwọn àdánwò tí Ọlọ́run bá fàyè gbà lè fún ìgbàgbọ́ wa lágbára. (Hébérù 5:8; 1 Pétérù 1:7) Àní, ọ̀pọ̀ àwọn tí àdánwò ti bá tàbí tí jàǹbá ti ṣẹlẹ̀ sí rí, ló ti wá kọ́ sùúrù àti ìyọ́nú. Ṣùgbọ́n, a ò lè torí ìyẹn sọ pé iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ni ìyà tó jẹ wọ́n. Ẹni tó bá ń ronú bẹ́ẹ̀ ò gbà pé Ọlọ́run ní ìfẹ́ àti ọgbọ́n. Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” Kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ti ń wá!—Jákọ́bù 1:13, 17.

Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ibi

Ọ̀dọ̀ ta wá ni nǹkan burúkú ti ń wá nígbà náà? Rántí pé Ọlọ́run ní àwọn alátakò, olórí wọn sì ni “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Inú ayé tí kò sí ìdààmú kankan ni Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà sí. Àmọ́, Sátánì sọ fún Éfà pé ńṣe lá máa gbádùn bó ṣe wù ú tí kò bá sí lábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ó mà ṣe o, Éfà gba irọ́ tí Sátánì pa gbọ́, ó sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ádámù náà dara pọ̀ mọ́ ìyàwó rẹ̀ nínú ìdìtẹ̀ yìí. Kí ló wá tẹ̀yìn ẹ̀ wá? Bíbélì sọ pé: “Ikú . . . tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 5:12.

Dípò tí Ọlọ́run ì bá fi paná ọ̀tẹ̀ yìí lójú ẹsẹ̀ nípa pípa Sátánì àtàwọn tó ṣe tiẹ̀ run, ó fi àkókò sílẹ̀ kó tó ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ló ṣe ṣe bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, á fi Sátánì hàn lónírọ́! Á jẹ́ ká lè rí ẹ̀rí tó pọ̀ pé kò sí nǹkan mìíràn tí òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run máa ń mú wá ju ìparun lọ. Ṣé ìyẹn sì kọ́ là ń rí báyìí? “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Láfikún sí i, “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Àmúlùmálà ẹ̀kọ́ làwọn ìsìn táwọn èèyàn dá sílẹ̀ fi ń kọ́ni. Ìwà ọmọlúàbí ò já mọ́ nǹkan kan mọ́. Gbogbo oríṣiríṣi ètò ìjọba làwọn èèyàn ti dán wò. Wọ́n ti fọwọ́ sí onírúuru àdéhùn, wọn sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin, síbẹ̀síbẹ̀, wọn ò tíì lè ṣe nǹkan táwọn mẹ̀kúnnù nílò fún wọn. Àwọn ogun tó ń jà ń pa kún ìṣòro tó ń dé bá àwọn èèyàn.

Ó ṣe kedere pé àfi kí Ọlọ́run bá wa dá sọ́ràn náà kó sì fòpin sí gbogbo láabi! Ṣùgbọ́n ó dìgbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run kó tó dá sí i. Títí dìgbà yẹn, a láǹfààní láti ti ìṣàkóso Ọlọ́run lẹ́yìn nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Nígbà tí àwọn nǹkan búburú bá ṣẹlẹ̀, ó dájú pé ìrètí tó ṣeé gbára lé nípa ayé kan níbi tí kò ti ní sí wàhálà mọ́ á tù wá nínú.

Ìwọ Nìkan Kọ́

Síbẹ̀, tó bá jẹ́ àwa gan-an ni ohun búburú ṣẹlẹ̀ sí, a lè máa bi ara wa pé: ‘Ó ṣe jẹ́ èmi?’ Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé àwa nìkan kọ́ ni ìyà ń jẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Mímọ èyí á jẹ́ kó o lè fara dà á. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn táwọn apániláyà kọ lu ìlú New York City àti Washington, D.C., ní September 11, 2001, ìdààmú ọkàn bá Nicole. Ó sọ pé: “Orí mi fò lọ, ẹ̀rù sì bà mí.” Ṣùgbọ́n nígbà tó kà nípa báwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe kojú àjálù náà, ó mọ́kàn.b Ó sọ síwájú sí i pé: “Mo wá ri pe èmi nìkan kọ́ rárá. Bó ṣe di pé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ tó bá mi nìyẹn.”

Nígbà míì, ó dáa kó o wá ẹnì kan tó o lè fọ̀rọ̀ lọ̀ bí òbí rẹ, ọ̀rẹ́ rẹ kan tó dàgbà jù ẹ́ lọ, tàbí alàgbà kan nínú ìjọ. Tó o bá sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ẹnì kan tó o lè fọkàn tán, á jẹ́ kó o rí “ọ̀rọ̀ rere” tá fún ẹ níṣìírí gbà. (Òwe 12:25) Ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni kan tó jẹ́ ará Brazil sọ pé: “Ọdún kẹsàn-án rèé tí bàbà mi ti kú, mo sì mọ̀ pé Jèhófà yóò jí i dìde lọ́jọ́ kan. Àmọ́, ohun kan tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo kọ bó ṣe ń ṣe mí sílẹ̀. Mi ò tún fi bó ṣe ń ṣe mí bò fáwọn Kristẹni ọ̀rẹ́ mi.” Ǹjẹ́ o láwọn “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́” kankan tó o lè finú hàn? (Òwe 17:17) Nígbà náà jàǹfààní látinú ìrànlọ́wọ́ tí wàá rí gbà lọ́dọ̀ wọn! Bí ẹkún bá ń gbọ̀n ọ́, má bẹ̀rù láti sunkún tàbí láti sọ bó ṣe ń ṣe ọ́ fún wọn. Ṣebí Jésù alára náà “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé” lójú nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan kú ikú òjijì!—Jòhánù 11:35.

Bíbélì fi dá wa lójú pé ọjọ́ ọjọ́ kan ń bọ̀ tí “a óò dá ìṣẹ̀dá . . . sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́” wọn yóò sì gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Títí dìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn dáadáa lè jìyà. Jẹ́ kí mímọ̀ tó o mọ ìdí tí irú àwọn ìjìyà bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ máa tù ẹ́ nínú, àti pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lá máa rí lọ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Ìgboyà Lákòókò Àjálù,” nínú Jí! January 8, 2002.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

O lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà bó ò bá fi bó ṣe ń ṣe ẹ́ pa mọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́