ORÍ KỌKÀNLÁ
Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?
1, 2. Ìbéèrè wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè?
ÀKÚNYA omi gbá odindi abúlé kan lọ. Ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣèṣe, àwọn míì sì kú. Àrùn jẹjẹrẹ pa obìnrin kan, bí àwọn ọmọ rẹ̀ márààrún ṣe di aláìní ìyá nìyẹn.
2 Tí irú àwọn àjálù tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí bá wáyé, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè pé, “Kí ló fà á?” Àwọn míì sì máa ń béèrè pé, kí nìdí tí ìkórìíra àti ìyà fi pọ̀ láyé? Ṣé ìwọ náà ti béèrè bẹ́ẹ̀ rí?
3, 4. (a) Àwọn ìbéèrè wo ni Hábákúkù béèrè? (b) Ìdáhùn wo ni Jèhófà fún un?
3 Nínú Bíbélì, a kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ọkùnrin tó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Kí nìdí tí o fi ń jẹ́ kí ohun búburú ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára? Kí nìdí tí ìparun àti ìwà ipá fi ń ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí ìjà àti aáwọ̀ fi wà káàkiri?”—Hábákúkù 1:3.
4 Ní Hábákúkù 2:2, 3, Ọlọ́run dáhùn àwọn ìbéèrè Hábákúkù, ó sì ṣèlérí fún un pé òun máa ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Bíbélì sọ pé: “Ó ń bójú tó yín.” (1 Pétérù 5:7) Kódà, Ọlọ́run mọ ìyà tó ń jẹ wá ju bí àwa fúnra wa ṣe mọ̀ ọ́n lára lọ. (Àìsáyà 55:8, 9) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí tí ìyà fi pọ̀ láyé.
KÍ NÌDÍ TÍ ÌYÀ FI PỌ̀ LÁYÉ?
5. Kí ni àwọn olórí ẹ̀sìn ń sọ nípa ìyà tó ń jẹ wá? Kí ni Bíbélì kọ́ wa?
5 Àwọn pásítọ̀, àwọn àlùfáà àtàwọn olórí ẹ̀sìn sábà máa ń sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni ìyà tó ń jẹ aráyé. Àwọn kan máa ń sọ pé Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá, títí kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú àti pé àdììtú ni ọ̀rọ̀ náà, kò lè yé wa. Àwọn míì máa ń sọ pé ọ̀run ni gbogbo ẹni tó bá kú ń lọ, títí kan àwọn ọmọdé, kí wọ́n lè wà pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́, ìyẹn kì í ṣòótọ́. Jèhófà kọ́ ló ń fa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!”—Jóòbù 34:10.
6. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé?
6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi lórí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé, torí wọ́n rò pé Ọlọ́run ló ń ṣàkóso ayé. Àmọ́, a ti kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí 3 pé Sátánì Èṣù ló ń ṣàkóso ayé.
7, 8. Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ láyé?
7 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Sátánì ló ń ṣàkóso ayé yìí. Ó burú gan-an, ìkà sì ni. Ó ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà.” (Ìfihàn 12:9) Òun ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń fara wé. Ìdí nìyẹn tí irọ́, ìkórìíra àti ìwà ìkà fi pọ̀ láyé.
8 Àwọn ìdí míì wà tí ìyà fi pọ̀ láyé. Bí Ádámù àti Éfà ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n sọ àwọn ọmọ wọn di ẹlẹ́ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ló sì ń mú káwọn èèyàn máa fìyà jẹ àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Wọ́n sábà máa ń ka ara wọn sí pàtàkì ju àwọn míì lọ. Èyí máa ń fa ìjà àti ogun, tàbí kí àwọn kan máa halẹ̀ mọ́ àwọn míì. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Nígbà míì, àwọn èèyàn lè jìyà nítorí “ìgbà àti èèṣì.” (Oníwàásù 9:11) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ṣe kòńgẹ́ aburú tàbí kí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí wọn torí pé wọ́n wà níbi tí kò yẹ kí wọ́n wà.
9. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà ní ìdí pàtàkì tó fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ èèyàn?
9 Jèhófà kọ́ ló ń fa ìyà. Òun kọ́ ló jẹ̀bi ogun, ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ tó kún inú ayé. Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀, bí ìmìtìtì ilẹ̀, ìjì líle àti àkúnya omi. Àmọ́, o lè ronú pé, ‘Ṣebí Jèhófà lẹni gíga jù lọ láyé àtọ̀run, kí wá nìdí tí kò fi fòpin sí àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀?’ A mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, torí náà, ó gbọ́dọ̀ nídìí pàtàkì kan tó fi fàyè gbà á kí ìyà máa jẹ èèyàn.—1 Jòhánù 4:8.
ÌDÍ TÍ ỌLỌ́RUN FI FÀYÈ GBA ÌYÀ
10. Báwo ni Sátánì ṣe fẹ̀sùn kan Jèhófà?
10 Sátánì Èṣù tan Ádámù àti Éfà jẹ ní ọgbà Édẹ́nì. Ó tún fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ìṣàkóso rẹ̀ kò dára. Ó sọ pé Ọlọ́run kò fẹ́ kí Ádámù àti Éfà gbádùn ayé wọn. Sátánì fẹ́ kí wọ́n rò pé ìṣàkóso òun dáa ju ti Jèhófà lọ àti pé wọn ò nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 3:2-5; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 27.
11. Ìbéèrè wo ló yẹ ká wá ìdáhùn rẹ̀?
11 Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Wọ́n rò pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti dá pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Báwo ni Jèhófà ṣe máa fi hàn pé ohun táwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe kò tọ́ àti pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó dáa fún wa?
12, 13. (a) Kí nìdí tí Jèhófà kò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì láti máa ṣàkóso ayé yìí, tó tún gbà kí àwọn èèyàn máa ṣàkóso ara wọn?
12 Jèhófà ò pa Ádámù àti Éfà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n bímọ. Èyí á mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ náà láti yan ẹni tí wọ́n fẹ́ kó máa ṣàkóso àwọn. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn èèyàn pípé máa gbé ayé, ohun tó sì máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn láìka ohun yòówù tí Sátánì lè ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Àìsáyà 55:10,11.
13 Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà níṣojú àìmọye àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 38:7; Dáníẹ́lì 7:10) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fún Sátánì láyè láti fi hàn bóyá òótọ́ ni ẹ̀sùn tó fi kan òun. Ó tún fún àwọn èèyàn láyè láti ní ìjọba ti wọn lábẹ́ ìdarí Sátánì kí wọ́n lè fi hàn bóyá wọ́n á ṣàṣeyọrí láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.
14. Kí ni ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ṣàkóso ti fi hàn?
14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún làwọn èèyàn ti fi ṣàkóso ara wọn, àmọ́ wọn ò ṣàṣeyọrí. Èyí sì fi hàn kedere pé òpùrọ́ ni Sátánì. Ká sòótọ́, àwa èèyàn nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí wòlíì Jeremáyà fi sọ pé: “Jèhófà, mo mọ̀ dáadáa pé ọ̀nà èèyàn kì í ṣe tirẹ̀. Àní kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI JẸ́ KÍ ÌṢÒRO WÀ TÍTÍ DI BÁYÌÍ?
15, 16. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí ìyà máa jẹ wá títí di báyìí? (b) Kí nìdí tí Jèhófà kò fi tíì yanjú àwọn ìṣòro tí Sátánì fà?
15 Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí ìyà máa jẹ wá títí di báyìí? Kí nìdí tí kò fi fòpin sí àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀? Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀nà tí Sátánì ń gbà ṣàkóso kò yọrí sí rere láti ọ̀pọ̀ ọdún yìí wá. Oríṣiríṣi ìjọba làwọn èèyàn ti ṣe, àmọ́ wọn ò ṣàṣeyọrí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ti ṣe nínú ìmọ̀ ṣáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, síbẹ̀ ogun, ìṣẹ́, ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ọ̀daràn ń pọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. A ò lè ṣàṣeyọrí tá a bá ń ṣàkóso ara wa láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.
16 Àmọ́, Jèhófà ò tíì yanjú àwọn ìṣòro tí Sátánì dá sílẹ̀. Torí pé tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa fi hàn pé ó ń ti àkóso Sátánì lẹ́yìn, kò sì jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Ohun míì ni pé àwọn èèyàn á rò pé àwọn lè ṣàkóso ara wọn káwọn sì ṣàṣeyọrí. Irọ́ nìyẹn náà, ó sì dájú pé Jèhófà ò ní ti irú àkóso bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn láé, torí pé kò lè purọ́.—Hébérù 6:18.
17, 18. Kí ni Jèhófà máa ṣe láti ṣàtúnṣe gbogbo ohun tí Sátánì ti bà jẹ́?
17 Ṣé Jèhófà lè ṣàtúnṣe gbogbo ohun tó ti bà jẹ́ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ Sátánì àti tàwọn èèyàn? Bẹ́ẹ̀ ni. Kò sóhun tí Ọlọ́run ò lè ṣe. Tó bá tó àsìkò, Jèhófà máa yanjú gbogbo ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án. Ayé á wá di Párádísè, bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí. Gbogbo àwọn tó wà nínú “ibojì ìrántí” ló máa jí dìde. (Jòhánù 5:28, 29) Àwa èèyàn ò ní máa ṣàìsàn, a ò sì ní máa kú mọ́. Jésù máa ṣàtúnṣe gbogbo ohun tí Sátánì ti bà jẹ́. Jèhófà máa lo Jésù láti “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ní báyìí, ó ń ní sùúrù fún wa ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, ká sì pinnu pé òun la fẹ́ kó jẹ́ Alákòóso wa. (Ka 2 Pétérù 3:9, 10.) Kódà, tá a bá ń jìyà, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á.—Jòhánù 4:23; ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.
18 Jèhófà ò fipá mú wa láti máa jọ́sìn òun. Ó fún gbogbo wa ní ẹ̀bùn kan, ìyẹn òmìnira láti yan ohun tó wù wá. Ẹ jẹ́ ká wo bí ẹ̀bùn iyebíye yìí ṣe lè ṣe wá láǹfààní.
BÁWO LO ṢE MÁA LO Ẹ̀BÙN ÒMÌNIRA YÌÍ?
19. Ẹ̀bùn àgbàyanu wo ni Jèhófà fún wa? Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ẹ̀bùn yìí?
19 Òmìnira láti yan ohun tó wù wá jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu tí Jèhófà fún àwa èèyàn, èyí sì jẹ́ ká yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹranko. Àwọn ẹranko ò lè ṣe kọjá bí Ọlọ́run ṣe dá wọn pé kí wọ́n máa ṣe, àmọ́ àwa lè yan bá a ṣe fẹ́ gbé ìgbé ayé wa, a sì lè yàn bóyá a fẹ́ ṣe ìfẹ́ Jèhófà àbí a ò ní ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Òwe 30:24) Bákan náà, a ò dà bí ẹ̀rọ tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n bá fẹ́ kó ṣe nìkan ló máa ń ṣe. A ní òmìnira láti yan irú ẹni tá a fẹ́ jẹ́, irú ọ̀rẹ́ tá a fẹ́ ní àti ohun tá a fẹ́ fi ìgbésí ayé wa ṣe. Jèhófà fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa.
20, 21. Ìpinnu wo ló dáa jù tó o lè ṣe báyìí?
20 Jèhófà fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òun. (Mátíù 22:37, 38) Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ọmọ kan bá sọ fún bàbá ẹ̀ pé: “Bàbá mi mo nífẹ̀ẹ́ yín.” Ó dájú pé inú bàbá náà máa dùn tó bá jẹ́ pé ńṣe ni ọmọ náà sọ ọ́ látọkàn wá. Jèhófà fún wa ní òmìnira láti yàn bóyá a máa jọ́sìn òun àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Sátánì, Ádámù, àti Éfà yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Ó yẹ ká bi ara wa pé ‘Báwo ni màá ṣe lo ẹ̀bùn òmìnira tèmi?’
21 Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o fi òmìnira rẹ sin Jèhófà. Àìmọye èèyàn ló ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dípò kí wọ́n máa ṣe ìfẹ́ Sátánì. (Òwe 27:11) Ní báyìí, kí lo lè ṣe kó o lè wà nínú ayé tuntun nígbà tí Ọlọ́run bá ti mú gbogbo ìyà kúrò? Orí tó kàn máa dáhùn ìbéèrè yẹn.