Wọ́n Bọ́ Lọ́wọ́ Ewu Omíyalé!
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Switzerland
NÍ OṢÙ October ọdún 2000, a gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé, jákèjádò àgbáyé. Àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò pọ̀ débi pé gbogbo ohun tó hù síbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ló rin gbingbin fómi, tí ìyẹn sì mú kí iyẹ̀pẹ̀ tó wà níbẹ̀ ya lulẹ̀ wìì tí gbogbo pàǹtírí àti ewéko títí kan àwọn igi fi ń ṣubú lọ bẹẹrẹbẹ!
Ìpínlẹ̀ Valais tó wà níhà gúúsù orílẹ̀-èdè Switzerland wà lára àwọn ibi tí irú àjálù bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Odò kan tí wọ́n ń pè ní Rhône tó ṣàn gba inú ìlú yìí kọjá ló là á sí méjì látòkè désàlẹ̀. Odò yìí ń ṣàn wá láti ibi òkìtì yìnyín tí wọ́n ń pè ní òkìtì yìnyín Rhône níbi òkè ńlá Central Alps, ó sì ń ṣàn gba apá ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ náà lọ sínú Adágún Odò Geneva. Odò náà gùn tó àádọ́sàn [170] kìlómítà. Omi tó ń ṣàn wá látorí àwọn òkè ńlá ńlá tó wà lápátùn-ún àti lápásì odò náà, tún máa ń gba inú àwọn ipadò kéékèèké, tí wọ́n fẹ̀ jura wọn lọ kọjá sínú adágún kan náà yìí. Bí nǹkan bá rí bó ṣe yẹ kó rí, àwọn ipadò tó dà bíi gọ́tà yìí ń ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Ṣùgbọ́n, bí omi bá bo gbogbo àgbègbè yẹn nítorí àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò, ìjàǹbá ló máa ń tẹ̀yìn rẹ̀ wá.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ lábúlé Gondo tó wà níbi tí Switzerland ti bá orílẹ̀-èdè Ítálì pààlà nìyẹn. Ọ̀pọ̀ ẹrọ̀fọ̀ àti òkúta rọ́ wọ abúlé orí òkè yìí, táwọn tó ń gbé ibẹ̀ tó àádọ́jọ, ó sì ba apá ibi tó pọ̀ lábúlé ọ̀hún jẹ́. Omi kún bo gbogbo apá ibi tó kù ní ìpínlẹ̀ Valais nítorí àgbáàràgbá òjò tó rọ̀. Àwọn òpópónà àti ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin ti dí pa, ẹrọ̀fọ̀ àti òkúta sì ti bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ wọnú àwọn ilé. Láwọn ibì kan àbàtà tó kóra jọ pelemọ ga ju odindi ilé kan lọ. Obìnrin kan ń wò láìlè ṣe nǹkan kan títí tí ẹrọ̀fọ̀ tó ń dà wìì, tí gíga rẹ̀ sì ju òpó iná mẹ́ta lọ, fi wọ́ àwọn òkúta ńlá àtàwọn igi lọ sí abúlé rẹ̀!
Ìlú Mörel ni Markus àti Tabitha, tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya, ń gbé lákòókò àjálù yẹn. Markus sọ pé: “Afẹ́fẹ́ tó ń rọ́ yìì, tó ń sọgbá lu àwo tó sì ń mi gbogbo nǹkan tìtì ló jí wa ní nǹkan bí aago mẹ́fà kọjá díẹ̀ láàárọ̀. Mo gbé iná dání lọ síta kí n lè wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ohun tí mo rí bà mí lẹ́rù. Ọ̀pọ̀ ilé àti afárá ni àwọn òkúta tí àgbàrá ń gbé wá ti bà jẹ́, ó sì gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan lọ kọlu ilé ẹnì kan tó ń gbé nítòsí wa. Lápá iwájú lọ́hùn-ún, omi ti ká aládùúgbò wa kan àti ìyàwó rẹ̀ mọ́lé. Mo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gba ojú fèrèsé kan jáde. Nígbà tí mo padà délé, àyè ò sí fún èmi àti ìyàwó mi láti kó ẹrù tó pọ̀, díẹ̀ la lè kó nínú ẹrù wa.”
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Markus àti Tabitha, wọ́n sì rọra kó lọ sọ́dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kan lápá ibi tí omíyalé yẹn ò dé. Markus sọ pé: “Lóòótọ́ a jàjàbọ́ o, àmọ́ ó pẹ́ kí ràbọ̀ràbọ̀ omíyalé yẹn tó kúrò lára Tabitha.” Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti fara da ìṣẹ̀lẹ̀ agbonijìgì náà? Tabitha dáhùn pé: “Báwọn arákùnrin àti arábìnrin ṣe kó wa mọ́ra tí wọ́n sì dúró tì wá ni.” Ó tún wá fi kún un pé: “Báwọn aládùúgbò ò ṣe dá wa dá wàhálà ọ̀hún tún ràn mí lọ́wọ́ pẹ̀lú.”
Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn rán Markus àti Tabitha létí ohun tí Òwe 18:24 sọ pé: “Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” Dájúdájú, ìgbà ìpọ́njú làá mọ̀rẹ́!
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ibi tí omíyalé náà ti ṣọṣẹ́
Gondo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Markus àti Tabitha
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Mise à disposition par www.crealp.ch