ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 1/1 ojú ìwé 3-5
  • Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí Gbogbo Wa Yin Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí Gbogbo Wa Yin Ọlọ́run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Jèhófà Nìkan Ni Ó Lè Fún Mi Ní Ìrètí’
  • ‘Bí Mo Tilẹ̀ Jẹ́ Afọ́jú, Mo Ń Ríran’
  • Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa “Yin Jáà”
  • Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Pa Ara Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ẹ Bá Mi Yin Jáà
    Kọrin sí Jèhófà
  • Jẹ́ Ká Yin Jáà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 1/1 ojú ìwé 3-5

Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí Gbogbo Wa Yin Ọlọ́run?

ALELÚYÀ! Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì ní Kirisẹ́ńdọ̀mù mọ ọ̀rọ̀ yìí bí ẹní mowó. Àwọn kan lára wọn máa ń kígbe rẹ̀ nígbà ìsìn wọn ní ọjọọjọ́ Sunday. Ṣùgbọ́n, mélòó nínú wọn ni ó mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ní ti gidi? Ní tòótọ́, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ èdè Hébérù fún “Ẹ yin Jáà!” Ó jẹ́ fífi ìdùnnú kókìkí Ẹlẹ́dàá náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, lọ réré.a

Ọ̀rọ̀ náà “Alelúyà” fara hàn léraléra nínú Bíbélì. Èé ṣe? Nítorí ìdí púpọ̀ wà fún yíyin Ọlọ́run. Jáà (Jèhófà) ni Ẹlẹ́dàá àti Olùmúdúró àgbáálá ayé wa títẹ́ rẹrẹ. (Orin Dáfídì 147:4, 5; 148:3-6) Ó pilẹ̀ ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn, tí ó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Orin Dáfídì 147:8, 9; 148:7-10) Ó sì ní ọkàn-ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú aráyé. Bí a bá ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀, ó ń bù kún wa nínú ayé yìí, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́, ó sì ń nawọ́ ìrètí kan ti ìgbésí ayé tí ó dára jù tí ń bọ̀ sí wa. (Orin Dáfídì 148:11-14) Jáà (Jèhófà) ni ẹni tí ó mí sí ọ̀rọ̀ náà: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.”—Orin Dáfídì 37:29.

Nítorí náà, a darí ọ̀rọ̀ ìyànjú náà sì gbogbo wa pé: “Alelúyà!” “Ẹ yin Jáà, ẹ̀yin ènìyàn!” (Orin Dáfídì 104:35, NW, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé) Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó fẹ́ dáhùn pa dà. Lónìí, àwọn ènìyàn ń jìyà. Ebi ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ ń ṣàìsàn, tàbí kí ọ̀pọ̀ wà lábẹ́ ìnilára. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fara da ọ̀pọ̀ ẹ̀dùn ọkàn nítorí ìlòkulò oògùn tàbí ìmukúmu ọtí tàbí nítorí àbájáde ìwà pálapàla tàbí ìwà ọ̀tẹ̀. Ìdí kankan ha wà fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti yin Ọlọ́run bí?

‘Jèhófà Nìkan Ni Ó Lè Fún Mi Ní Ìrètí’

Bẹ́ẹ̀ ni, ìdí ń bẹ. Jèhófà ń ké sí gbogbo ènìyàn láìdá ẹnì kan sí, láti wá mọ òun, láti kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe ìfẹ́ inú òun, kí wọ́n sì gbádùn àwọn ìbùkún tí ń mú kí àwọn ènìyàn fẹ́ láti yin òun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì dáhùn pa dà. Gbé àpẹẹrẹ Adriana ní Guatemala yẹ̀ wò. Nígbà tí Adriana jẹ́ ọmọ ọdún méje ni màmá rẹ̀ kú. Kété lẹ́yìn ìyẹn bàbá rẹ̀ kúrò ní ilé. Nígbà ó di ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Níwọ̀n bí màmá rẹ̀ ti sọ fún un pé kí ó ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run àti ṣọ́ọ̀ṣì, Adriana dara pọ̀ mọ́ onírúurú àwùjọ ìsìn Kátólíìkì, ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi tó ọmọ ọdún 12, a já a kulẹ̀, ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá, ó ń lo oògùn líle, ó sì ń jalè. Èé ṣe tí irú ọ̀dọ́mọbìnrin bẹ́ẹ̀ yóò fi fẹ́ láti yin Ọlọ́run?

Ẹ̀gbọ́n Adriana obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n Adriana fi í rẹ́rìn-ín. Lẹ́yìn èyí, àǹtí wọ́n kú. Nígbà ìsìnkú àǹtí wọn, àwọn ìbéèrè tí ń da Adriana láàmú mú inú bí i. Níbo ni àǹtí òun lọ? Ṣé ọ̀run ni ó wà ni? Ṣé ó lọ sí ọ̀run àpáàdì ni? Ọkàn rẹ̀ pòrúurùu, Adriana sì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì itẹ́ òkú láti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́, ní lílo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kọ́ ọ.

Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni wọn. Èyí jẹ́ kí ó ní ojú ìwòye tuntun pátápátá nípa ìgbésí ayé, ó sì fi ìgboyà já ìdè rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta. Adriana, ẹni tí ó wà láàárín ogún ọdún sí ọgbọ̀n ọdún báyìí, sọ pé: “Ìfẹ́ fún Jèhófà nìkan ni ó mú mi fi irú ọ̀nà ìgbésí ayé búburú bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Jèhófà nìkan nínú àánú rẹ̀ ńláǹlà ni ó lè fún mi ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.” Adriana, láìka bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà ti ó nira sí, ní ìdí rere láti yin Ọlọ́run.

A fi ìròyìn ipò kan tí ó tilẹ̀ túbọ̀ dà bí èyí tí kò ní yọrí sí rere tó ni létí láti Ukraine. Ọkùnrin kan jókòó sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó ń retí kí a yẹgi fún òun. Àánú ara rẹ̀ ha ṣe é bí? Ó ha sorí kọ́ bí? Rárá o, òdì kejì pátápátá ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Níwọ̀n bí kò tí ì pẹ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí i, tí ó sì ti jèrè ìmọ̀ díẹ̀ nípa Jèhófà, ó ní kí wọ́n kàn sí màmá òun. Nísinsìnyí, ó ń kọ lẹ́tà sí wọn, nítorí pé, ó ti gbọ́ pé wọ́n ṣe ohun tí ó bẹ̀ wọ́n láti ṣe. Ó sọ pé: “Ẹ ṣeun púpọ̀ fún bíbẹ màmá mi wò. Òun ni ìròyìn tí ó mú inú mi dùn jù lọ tí mo rí gbà ní ọdún tí ó kọjá.”

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí òun ti jẹ́rìí fún, ó kọ̀wé pé: “Nísinsìnyí a nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, a sì ń gbìyànjú láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa.” Ó parí lẹ́tà rẹ̀ ní sísọ pé: “A dúpẹ́ púpọ̀ fún ríràn tí ẹ ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ nípa ohun tí ìfẹ́ jẹ́ àti láti jèrè ìgbàgbọ́. Bí mo bá ṣì wà láàyè, èmi pẹ̀lú yóò ràn yín lọ́wọ́. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé ẹ wà láàyè àti pé ẹ ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti láti nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.” Ọkùnrin yìí ti pẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn látàrí ìdájọ́ ikú tí a dá a. Ṣùgbọ́n, ì báà jẹ́ pé a yẹgi fún un tàbí pé ó lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó ní ìdí tí ó ṣe kedere láti yin Ọlọ́run.

‘Bí Mo Tilẹ̀ Jẹ́ Afọ́jú, Mo Ń Ríran’

Wàyí o, ronú nípa ọ̀ràn ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí kò tí ì pé ogún ọdún, tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, tí ó ṣàdédé pàdánù agbára ìríran rẹ̀. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Gloria nìyẹn, tí ń gbé ní Argentina. Gloria fọ́ lójú lójijì nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 19, kò sì pa dà ríran mọ́. Ní ẹni ọdún 29, ó bá ọkùnrin kan dálè, ó sì lóyún. Wàyí o, ó rò pé ìgbésí ayé òun ti nítumọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ̀ kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Ó ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí èyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí mi? Kí ni mo ṣe? Ọlọ́run ha wà ní tòótọ́ bí?’

Níbi tí ọ̀ràn dé yìí, àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì kọ́ nípa ìlérí rẹ̀ pé nínú ayé tuntun, àwọn afọ́jú yóò pa dà ríran. (Aísáyà 35:5) Ẹ wo irú àgbàyanu ìfojúsọ́nà tí èyí jẹ́ fún Gloria! Ayọ̀ kún inú rẹ̀, pàápàá nígbà tí ọkọ rẹ̀ gbà láti mú ìgbéyàwó wọn bá òfin mu. Lẹ́yìn èyí, ọkọ náà kàgbákò jàǹbá, ó sì di aláàbọ̀ ara, tí kò lè rìn láìjẹ́ pé ó lo kẹ̀kẹ́ àṣemága. Lónìí, obìnrin afọ́jú yìí ní láti ṣiṣẹ́ kára kí ó tóó lè gbọ́ bùkátà. Ní àfikún sí i, ó ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé, títí kan bíbójú tó àìní ọkọ rẹ̀. Síbẹ̀ Gloria ń yin Jèhófà! Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀, ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Braille tí a ṣe fún àwọn afọ́jú, àwọn ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba sì ń fún un níṣìírí ńláǹlà. Ó sọ pé: “Ó ṣòro láti ṣàlàyé, ṣùgbọ́n bí mo tilẹ̀ jẹ́ afọ́jú, ńṣe ni ó dà bíi pé mò ń ríran.”

Nígbà míràn, a ń ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn, nígbà tí wọ́n bá ń yin Ọlọ́run. Obìnrin kan tí ó jẹ́ ará Croatia láyọ̀ nígbà tí ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ ta ko ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí, ó sì pa á tì, tí ó sì gba ọmọbìnrin wọn tí ó jẹ́ ọmọ ọdún kan lọ́wọ́ rẹ̀. Ní òpópónà, tí ọkọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ pa á tì sí, láìní ilé, iṣẹ́, tàbí ọmọ pàápàá, ọkàn rẹ̀ dàrú lákọ̀ọ́kọ́. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó ní sí Ọlọ́run mú un dúró, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní àǹfààní rírí ọmọ rẹ̀ nígbà gbogbo, àyàfi ìgbà tí ọmọ kékeré náà tóó dàgbà. Obìnrin yìí ti rí “péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga,” kì yóò sì fi í sílẹ̀. (Mátíù 13:45, 46) Báwo ni ó ṣe pa ìdùnnú rẹ̀ mọ́ jálẹ̀ àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí? Ó sọ pé: “Èso ẹ̀mí Ọlọ́run ni ìdùnnú jẹ́. A lè ní in láìka àyíká ipò sí, gan-an gẹ́gẹ́ bí ewéko kan ṣe lè dàgbà nínú ilé ewéko tí a fi gíláàsì kọ́ láìka bí ipò ojú ọjọ́ ti rí ní ìta sí.”

Ní Finland, a ṣàwárí àrùn iṣan tí kò gbóògùn lára Markus, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà. Kò pẹ́ kò jìnnà kò lè rìn láìjẹ́ pé ó lo kẹ̀kẹ́ àṣemága. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, màmá rẹ̀ mú un lọ sí ọ̀dọ̀ onísìn Pentecostal kan tí òkìkí rẹ̀ ń tàn kálẹ̀ pé ó ń wo àwọn aláìsàn sàn. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìyanu kankan kò ṣẹlẹ̀. Nítorí náà, Markus pàdánù ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run, ó sì lépa ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn iṣẹ́ ayé mìíràn. Lẹ́yìn èyí, ní nǹkan bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn, obìnrin kan tí ń lo kẹ̀kẹ́ àṣemága, pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó tẹ̀ lé e, wá sí ilé tí Markus ń gbé. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Markus ti di aláìgbọlọ́rungbọ́ nísinsìnyí, ṣùgbọ́n kì í ta ko jíjíròrò nípa ìsìn, ó sì ké sí wọn wọlé.

Lẹ́yìn náà, tọkọtaya kan bẹ̀ ẹ́ wò, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sì bẹ̀rẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, agbára òtítọ́ Bíbélì yí ojú ìwòye Markus nípa àwọn nǹkan pa dà, ó sì mọ̀ pé láìka ààbọ̀ ara tí òun ní sí, ní tòótọ́, òun ní ìdí láti yin Ọlọ́run. Ó wí pé: “Mo láyọ̀ púpọ̀ nítorí tí mo ti rí òtítọ́ àti ètò àjọ tí Jèhófà ń lò. Nísinsìnyí, ìgbésí ayé mi ní ibi tí ó dorí kọ, ó sì ní ìtumọ̀. A ti rí àgùntàn míràn tí ó sọnù, kò sì fẹ́ẹ́ fi agbo àgùntàn Jèhófà sílẹ̀!”—Fi wé Mátíù 10:6.

Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa “Yin Jáà”

Ìwọ̀nyí jẹ́ kíkì díẹ̀ ráńpẹ́ nínú àìníye ìrírí tí a lè sọ láti fi hàn pé àwọn ènìyàn lónìí, láìka àyíká ipò wọn sí, lè ní ìdí láti yin Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ́lù ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà yí pé: “Ìfọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyíinì tí ń bọ̀.” (Tímótì Kíní 4:8) Bí a bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun yóò mú “ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí” ṣẹ. Àmọ́ ṣáá o, òun kì yóò mú kí tálákà di ọlọ́rọ̀ tàbí kí aláìsàn di onílera nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ṣùgbọ́n ó ń fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn ín ní ẹ̀mí rẹ̀, kí wọ́n baà lè rí ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn láìka ohun tí ipò wọn lè jẹ́ sí. Bẹ́ẹ̀ ni, àní nínú “ìyè ti ìsinsìnyí,” àwọn aláìsàn, àwọn tí a ni lára, àti àwọn òtòṣì lè ní ìdí láti yin Ọlọ́run.

Ṣùgbọ́n ti ìyè “tí ń bọ̀” ńkọ́? Họ́wù, ríronú nípa rẹ̀ lásán yẹ kí ó mú wa yin Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara ńláǹlà! Inú wa dùn jọjọ láti ronú nípa àkókò kan nígbà tí a kò ní mọ òṣì; nígbà tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òtútù ń pa mi”; àti nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run ‘yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, tí ikú kì yóò sí mọ́, tí kì yóò sì sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Tí àwọn ohun àtijọ́ yóò ti kọjá lọ.’ (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:3, 4; Orin Dáfídì 72:16) Ojú wo ni o fi ń wo àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe wọ̀nyí?

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní El Salvador tẹ́wọ́ gba ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì kan tí ó ṣàlàyé àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ó wí fún Ẹlẹ́rìí tí ó fún un pé, “Arábìnrin, ohun tí ìwé àṣàrò kúkúrú yìí sọ ti dára ju ohun tí ó lè jẹ́ òtítọ́ lọ.” Ọ̀pọ̀ ń dáhùn pa dà lọ́nà yẹn. Síbẹ̀, àwọn wọ̀nyí jẹ́ ìlérí Ẹni náà tí ó dá àgbáálá ayé, ẹni tí ó mú kí àyípoyípo ilẹ̀ ayé lọ́nà ìṣẹ̀dá máa ṣiṣẹ́, àti ẹni tí ń ṣèrànwọ́ fún àwọn òtòṣì àti aláìsàn pàápàá láti rí ìdùnnú. A lè gba ohun tí ó sọ gbọ́. Ọ̀dọ́mọkùnrin tí a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì rí i pé òtítọ́ ni nǹkan yìí. Bí ìwọ kò bá tí ì máa ṣe bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Lẹ́yìn náà, ǹjẹ́ kí o lè wà níbẹ̀ nígbà tí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí bá ti kọjá lọ, tí gbogbo ẹ̀dá yóò sì dara pọ̀ nínú igbe náà pé: “Alelúyà!” “Ẹ yin Jáà, ẹ̀yin ènìyàn!”—Orin Dáfídì 112:1; 135:1, NW.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú Bíbélì, nígbà míràn, a máa ń lo “Jáà” fún ìkékúrú “Jèhófà.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ǹjẹ́ kí o lè wà níbẹ̀ nígbà tí gbogbo ẹ̀dá yóò dara pọ̀ nínú igbe náà pé: “Alelúyà!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́