ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 4/8 ojú ìwé 10-13
  • Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mósè Gidi
  • Àwọn Ohun Tá A Lè Rí Kọ́ Látinú Àwọn Ìwé Mósè
  • Wòlíì Kan Bíi Mósè
  • Bawo ni Jesu Kristi Ṣe Jẹ́ Wolii kan bii Mose?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Mósè Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 4/8 ojú ìwé 10-13

Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́

Ọ̀PỌ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àtàwọn olùṣelámèyítọ́ ló gbà pé ẹni ìtàn àròsọ lásán ni Mósè. Wọn ò fara mọ́ àkọsílẹ̀ Bíbélì, wọ́n sì ń lo àwọn ìlànà tí yóò mú ká ka irú àwọn ọkùnrin bíi Plato àti Socrates sí àwọn ẹni tí kò gbáyé rí.

Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, kò sí ìdí gúnmọ́ kankan tí ò fi yẹ ká gba ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, fún àwọn ẹni ìgbàgbọ́, ẹ̀rí jaburata wà pé Bíbélì lódindi jẹ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”a (1 Tẹsalóníkà 2:13; Hébérù 11:1) Lójú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Mósè kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀kọ́ ìwé lásán, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ọ̀nà kan láti fi gbé ìgbàgbọ́ wọn ró.

Mósè Gidi

Àwọn tó ń ṣe sinimá sábà máa ń tẹnu mọ́ ìwà akin àti ìgboyà Mósè—àwọn ànímọ́ tó máa ń fa àwọn òǹwòran mọ́ra. Òótọ́ ni Mósè ní ìgboyà. (Ẹ́kísódù 2:16-19) Ṣùgbọ́n, ohun tó tayọ nípa rẹ̀ ni pé ó jẹ́ ẹni ìgbàgbọ́. Mósè gbà pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi gan-an, tó bẹ́ẹ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi wá sọ pé Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.”—Hébérù 11:24-28.

Nípa báyìí Mósè kọ́ wa pé ó pọn dandan láti ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí ojúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti ń mọ́ wa, àwa pẹ̀lú lè máa hùwà bí ẹni tí ń rí Ọlọ́run! Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣe ohun tí kò múnú rẹ̀ dùn. Sì tún kíyè si pé láti pínníṣín làwọn òbí Mósè ti fi ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kọ́ ọ. Ìgbàgbọ́ yìí jinlẹ̀ nínú ẹ̀ débi pé kò yẹsẹ̀ nígbà tó kọ́ “gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:22) Ìṣírí ńláǹlà gbáà nìyẹn jẹ́ fáwọn òbí láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run láti ìgbà ọmọdé jòjòló!—Òwe 22:6; 2 Tímótì 3:15.

Kò tún yẹ ká gbójú fo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Mósè dá. Òun ni “ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Númérì 12:3) Ìdí nìyẹn tí Mósè kì í fi í lọ́ tìkọ̀ láti gba àṣìṣe rẹ̀. Ó tiẹ̀ kọ̀wé nípa bí kò ṣe fọwọ́ pàtàkì mú òfin tó ní kó dádọ̀dọ́ fún ọmọkùnrin rẹ̀. (Ẹ́kísódù 4:24-26) Kò ṣe àbùmọ́ kankan nígbà tó ń ròyìn nípa bó ṣe kùnà láti fògo fún Ọlọ́run nígbà kan báyìí àti bó ṣe jìyà rẹ̀. (Númérì 20:2-12; Diutarónómì 1:37) Láfikún sí i, Mósè múra tán láti gbàmọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn. (Ẹ́kísódù 18:13-24) Kò ha ní bọ́gbọ́n mu kí àwọn ọkọ, baba àtàwọn èèyàn míì tágbára ń bẹ lọ́wọ́ wọn fara wé Mósè?

Òótọ́ ni pé àwọn olùṣelámèyítọ́ kan ṣì ń yiiri ẹ̀ wò pé bóyá ni Mósè jẹ́ ọlọ́kàn tútù, látàrí ìwà ipá tó hù. (Ẹ́kísódù 32:26-28) Òǹkọ̀wé Jonathan Kirsch, sọ pé: “Mósè tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kì í sábà hùwà ìrẹ̀lẹ̀, kò sì níwà tútù rárá, a ò sì lè fìgbà gbogbo kà á sí olódodo. Láwọn ìgbà tí nǹkan ò bá rọgbọ, . . . ńṣe ni Mósè máa ń gbéra ga, tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ á máa gbẹ ẹ́ tá á sì di òkú òǹrorò.” Ẹ̀tanú ló wà nídìí àtakò yìí. Ó gbójú fo òtítọ́ náà dá pé kì í ṣe ìwà òǹrorò ló sún Mósè láti ṣe gbogbo ohun tó ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ní fún ìdájọ́ òdodo àti àìgbàwà búburú láyè ló sún un ṣe bẹ́ẹ̀. Lóde òní tó ti dohun tó wọ́pọ̀ fáwọn èèyàn láti máa fàyè gba ìṣekúṣe, ìtàn Mósè ń rán wa létí bó ti pọn dandan tó láti má ṣe fi ìlànà wa nípa ìwà rere báni dọ́rẹ̀ẹ́.—Sáàmù 97:10.

Jésù—Wòlíì Tó Dà Bíi Mósè

Àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí Jésù gbà dà bíi Mósè rèé:

  • Ikú yẹ̀ lórí Mósè àti Jésù nígbà tí wọ́n pa àwọn ọmọ ọwọ́ púpọ̀ rẹpẹtẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí àwọn olùṣàkóso nígbà ayé wọn pa.—Ẹ́kísódù 1:22; 2:1-10; Mátíù 2:13-18.

  • A pe Mósè jáde wá láti Íjíbítì pa pọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí í ṣe “àkọ́bí” Jèhófà. A pe Jésù jáde láti Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí Ọmọkùnrin Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 4:22, 23; Hóséà 11:1; Mátíù 2:15, 19-21.

  • Mósè àti Jésù gbààwẹ̀ fún ogójì ọjọ́, nínú aginjù.—Ẹ́kísódù 34:28; Mátíù 4:1, 2.

  • Inú tútù àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Mósè àti ti Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ni.—Númérì 12:3; Mátíù 11:28-30.

  • Mósè àti Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu.—Ẹ́kísódù 14:21-31; Sáàmù 78:12-54; Mátíù 11:5; Máàkù 5:38-43; Lúùkù 7:11-15, 18-23.

  • Mósè àti Jésù jẹ́ alárinà fún májẹ̀mú láàárín Ọlọ́run àtàwọn èèyàn Rẹ̀.—Ẹ́kísódù 24:3-8; 1 Tímótì 2:5, 6; Hébérù 8:10-13; 12:24.

Àwọn Ohun Tá A Lè Rí Kọ́ Látinú Àwọn Ìwé Mósè

Àgbàyanu làwọn ìwé tí Mósè kọ. A rí lára àwọn ìwé náà tó jẹ́ ewì (Jóòbù, Sáàmù 90), ìtàn (Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Númérì), ìtàn ìlà ìdílé (Jẹ́nẹ́sísì, orí 5, 11, 19, 22, 25) àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn òfin tí wọ́n ń pè ní Òfin Mósè (Ẹ́kísódù, orí 20 sí 40; Léfítíkù; Númérì; Diutarónómì). Nínú Òfin tó ní ìmísí Ọlọ́run yìí la ti lè rí àwọn àlàyé, òfin àti ìlànà ìṣèjọba tó tayọ jù lọ.

Láwọn orílẹ̀-èdè tó bá ti jẹ́ pé olórí Orílẹ̀-èdè náà ni aṣáájú Ẹ̀sìn, ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni èmi-ò-gbà ìwọ-ò-gbà, rírẹ́ni jẹ lórúkọ ẹ̀sìn àti àṣìlò agbára. A rí ìlànà tó sọ nínú Òfin Mósè pé ó yẹ kí Ẹ̀sìn àti Ìṣèlú dúró lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni. A kò yọ̀ǹda fún ọba láti ṣe iṣẹ́ àlùfáà.—2 Kíróníkà 26:16-18.

Òfin Mósè tún sọ nípa ọ̀ràn ìlera àti béèyàn ṣe lè kòòré àwọn kòkòrò, irú bíi sísé àwọn aláìsàn mọ́ àti kíkó ìgbọ̀nsẹ̀ kúrò nílẹ̀, èyí tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní mu. (Léfítíkù 13:1-59; 14:38, 46; Diutarónómì 23:13) Èyí pabanbarì, pàápàá bá a bá rántí pé ohun táwọn ará Íjíbítì kà sí ìṣègùn nígbà tí Mósè wà láyé ò ju ìtọ́jú tì kò bá ìlànà ìṣègùn mu àti ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán. Láwọn ilẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ì bá tí kárùn, wọn ì bá sì tí kú bí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìmọ́tótó tí Mósè fi kọ́ni.

Àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti tẹ̀ lé Òfin Mósè. (Kólósè 2:13, 14) Ṣùgbọ́n àǹfààní ńláǹlà ṣì wà nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Òfin náà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyànjú láti fún Ọlọ́run ní ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe kí wọ́n sì sá fún ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kísódù 20:4; Diutarónómì 5:9) Ó pàṣẹ fáwọn ọmọ pé kí wọ́n máa bọlá fáwọn òbí wọn. (Ẹ́kísódù 20:12) Òfin náà tún ka ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, olè jíjà, irọ́ pípa àti ṣíṣojú kòkòrò léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:13-17) Lóde òní, àwọn Kristẹni mọyì àwọn ìlànà wọ̀nyẹn.

Àwọn ìlànà ìmọ́tótó tí Òfin Mósè fi kọ́ni lè ranni lọ́wọ́ láti dènà àrùn

Wòlíì Kan Bíi Mósè

Àkókò tí nǹkan ò fara rọ là ń gbé. Ó dájú pé aráyé nílò aṣáájú kan bíi Mósè, ẹni kan tí kì í ṣe agbára àti ọlá àṣẹ nìkan ló ní, àmọ́ tó tún jẹ́ oníwà títọ́, onígboyà, aláàánú, tó sì nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún ìdájọ́ òdodo. Nígbà tí Mósè kú, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ aráyé á tún rẹ́ni bíi ti Mósè mọ́?’ Mósè fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè náà.

Àwọn ìwé tí Mósè kọ ṣàlàyé ohun náà gan-an tó fa àìsàn àti ikú àti ìdí tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda kí ìwà ibi ṣì máa bá a lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-19; Jóòbù, orí 1, 2) Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ó jẹ́ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé bópẹ́ bóyá, ibi ò ní sí mọ́! Lọ́nà wo? Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé a óò bí ẹnì kan tí a ó tipasẹ̀ rẹ̀ rí ìgbàlà. Ìlérí yìí ló mú ká nírètí pé Mèsáyà kan yóò dìde tí yóò gba aráyé là. Ṣùgbọ́n, ta ni yóò jẹ́ Mèsáyà náà? Lọ́nà tí kò mú iyèméjì dání, Mósè jẹ́ ká mọ ẹni tí yóò jẹ́.

Nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, Mósè sọ àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ yìí: “Wòlíì kan láti àárín ìwọ fúnra rẹ, ní àárín àwọn arákùnrin rẹ, bí èmi, ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbé dìde fún ọ—òun ni kí ẹ̀yin fetí sí.” (Diutarónómì 18:15) Nígbà tó ṣe, àpọ́sítélì Pétérù fi hàn pé Jésù ni àwọn ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí ní tààràtà.—Ìṣe 3:20-26.

Ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára àwọn alálàyé Júù máa ń fi gbogbo ara ta kò ó bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi Mósè àti Jésù wéra. Wọ́n máa ń jiyàn pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí lè tọ́ka sí wòlíì tòótọ́ èyíkéyìí lára àwọn tó wá lẹ́yìn Mósè. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Tanakh—The Holy Scriptures tí Ẹgbẹ́ Òǹṣèwé Àwọn Júù gbé jáde ṣe sọ, Diutarónómì 34:10 sọ pé: “Wòlíì kan kò sì dìde mọ́ ní Ísírẹ́lì bíi Mósè—ẹni tí OLÚWA dá yà sọ́tọ̀, ní ojúkojú.”

Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì olùṣòtítọ́, bí Aísáyà àti Jeremáyà, dìde lẹ́yìn Mósè. Ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó ní irú àgbàyanu àjọṣe tí Mósè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyẹn ni ti bíbá tó ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ “ní ojúkojú.” Nítorí náà, ó dájú pé ẹnì kan ṣoṣo ni ìlérí tí Mósè ṣe nípa wòlíì kan ‘bíi tòun’ gbọ́dọ̀ tọ́ka sí, ìyẹn ni Mèsáyà náà! Ó tún yẹ ká kíyè sí i pé ṣáájú kí ìsìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀, àti ṣáájú kí inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni èké tó wáyé, báwọn Júù tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà ṣe rò pé ó yẹ kí nǹkan rí nìyẹn. A lè rí ohun tó fara jọ èyí nínú ìwé táwọn Júù kọ, irú bí ìwé Midrash Rabbah, èyí tó ṣàpèjúwe Mósè gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a rán ṣíwájú “Olùràpadà tó ń bọ̀,” tàbí Mèsáyà.

Kò sẹ́ni tó jẹ́ sọ pé bíbá tí Jésù àti Mósè bára dọ́gba ní ọ̀nà tó pọ̀, kì í ṣòótọ́. (Wo àpótí náà, “Jésù—Wòlíì Tó Dà Bíi Mósè.”) Jésù ní agbára àti ọlá àṣẹ. (Mátíù 28:19) Jésù jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà.” (Mátíù 11:29) Jésù kórìíra ìwà ta-ni-yóò-mú-mi àti ìwà ìrẹ́nijẹ. (Hébérù 1:9) Nítorí náà, ó lè ṣe aṣáájú wa lọ́nà tá à ń fẹ́ gan-an! Òun ló máa tó palẹ̀ ìwà ibi mọ́ tí yóò sì mú àwọn ipò tó dà bíi Párádísè tí Bíbélì ṣàpèjúwe wá sórí ilẹ̀ ayé.b

a Wo ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

b Bó o bá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Kristi, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú wọn yóò dùn láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìgba kọ́bọ̀.

Fífi Ohun Tí Mósè Jẹ́ Wéra Pẹ̀lú Ìtàn Àròsọ

Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi Mósè hàn nínú sinimá ti tan irọ́ àti èrò tí kò tọ̀nà kálẹ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Díẹ̀ lára ohun tá à ń wí rèé:

Àròsọ: Mósè ò mọ̀ pé Júù ni òun.

Òtítọ́: Ó dájú pé ìyá tó bí Mósè tí í ṣe Júù ló tọ́ ọ dàgbà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ni. Ìṣe 7:23-25 fi hàn pé Mósè ka àwọn Júù tó jẹ́ ẹrú náà sí “arákùnrin rẹ̀.”

Àròsọ: Mósè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń du ipò ọba ní Íjíbítì.

Òtítọ́: Bíbélì ò sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Ìwé Daily Bible Illustrations látọwọ́ John Kitto, sọ pé kò sí ìdí èyíkéyìí tí a fi ní láti gbà gbọ́ pé ‘nítorí pé wọ́n gba Mósè ṣọmọ ní Íjíbítì, ó wá dẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbadé. . . . Kò dà bí ẹni pé ìyà ọmọkùnrin tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbadé jẹ wọ́n.’

Àròsọ: Mósè padà sí Íjíbítì láti lọ kojú àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Òtítọ́: Bíbélì sọ pé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti kú tán nígbà tó padà lọ.—Ẹ́kísódù 4:19.

Àròsọ: Ìgbà tí Mósè gun orí Òkè Sínáì lọ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa Òfin Mẹ́wàá.

Òtítọ́: Ọlọ́run ti kọ́kọ́ lo áńgẹ́lì rẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa Òfin Mẹ́wàá fún gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí jìnnìjìnnì dà bò sọ pé kí Mósè gòkè lọ kó sì ṣojú fún àwọn láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.—Ẹ́kísódù 19:20–20:19; 24:12-14; Ìṣe 7:53; Hébérù 12:18, 19.

Àròsọ: Fáráò kò kú nígbà tí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣègbé sínú Òkun Pupa.

Òtítọ́: “Fáráò àti ẹgbẹ́ ológun rẹ̀” ṣègbé sínú Òkun Pupa.—Ẹ́kísódù 14:28; Sáàmù 136:15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́