Ẹ̀KỌ́ 18
Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan
Ogójì (40) ọdún ni Mósè fi gbé nílẹ̀ Mídíánì. Ó fẹ́ ìyàwó, ó sì ní àwọn ọmọ. Lọ́jọ́ kan, ó ń tọ́jú àwọn àgùntàn ẹ̀ nítòsí Òkè Sínáì, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yà á lẹ́nu. Ṣàdédé ló rí i tí iná ń jó igi kékeré kan tó ní ẹ̀gún lára, síbẹ̀ igi náà ò jóná! Nígbà tí Mósè sún mọ́ tòsí ibẹ̀ kó lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó gbọ́ ohùn kan láàárín igi náà, ohùn yẹn sọ pé: ‘Mósè! Dúró síbi tó o dé yẹn. Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ torí pé ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tó o wà.’ Jèhófà ló rán áńgẹ́lì kan láti bá Mósè sọ̀rọ̀.
Ẹ̀rù ba Mósè, ó sì bo ojú rẹ̀. Ohùn náà wá sọ pé: ‘Mo ti rí ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, màá sì mú wọn lọ sí ilẹ̀ tó dáa gan-an. Ìwọ lo máa kó wọn jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì.’ Ọ̀rọ̀ yẹn máa ya Mósè lẹ́nu gan-an o, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Mósè béèrè pé: ‘Kí ni mo máa sọ táwọn èèyàn náà bá béèrè pé ta ló rán mi?’ Ọlọ́run dáhùn pé: ‘Sọ fún wọn pé Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù ló rán mi sí yín.’ Mósè wá sọ pé: ‘Táwọn èèyàn náà ò bá fetí sí mi ńkọ́?’ Jèhófà wá ṣe ohun kan táá jẹ́ kó mọ̀ pé òun máa ràn án lọ́wọ́. Ó ní kí Mósè sọ ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ sílẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Ṣe ni ọ̀pá yẹn di ejò! Nígbà tí Mósè di ìrù ejò náà mú, ó tún pa dà di ọ̀pá. Jèhófà wá sọ pé: ‘Tí wọ́n bá rí ohun tó o ṣe yìí, wọ́n á gbà pé èmi ni mo rán ẹ.’
Mósè wá sọ pé: ‘Àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ.’ Jèhófà ṣèlérí fún un pé: ‘Màá jẹ́ kó o mọ ohun tí wàá sọ, màá sì ní kí Áárónì ẹ̀gbọ́n ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́.’ Ọkàn Mósè wá balẹ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. Torí náà, òun, ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ pa dà sílẹ̀ Íjíbítì.
“Ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn.”—Mátíù 10:19